MÁLÁKÌ
1 Ìkéde:
Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Málákì* sọ fún Ísírẹ́lì nìyí:
2 Jèhófà sọ pé, “Mo ti fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ yín.”+
Àmọ́, ẹ sọ pé: “Kí lo ṣe tó fi hàn pé o nífẹ̀ẹ́ wa?”
Jèhófà sọ pé, “Ṣebí ọmọ ìyá ni Jékọ́bù àti Ísọ̀?+ Àmọ́ mo nífẹ̀ẹ́ Jékọ́bù, 3 mo sì kórìíra Ísọ̀;+ mo sọ àwọn òkè rẹ̀ di ahoro,+ màá jẹ́ kí àwọn ajáko* inú aginjù gba ogún rẹ̀.”+
4 “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Édómù sọ pé, ‘Wọ́n ti fọ́ wa túútúú, àmọ́ a máa pa dà, a ó sì tún àwọn àwókù náà kọ́,’ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Wọ́n máa kọ́ ọ; àmọ́ màá ya á lulẹ̀, wọ́n sì máa pè wọ́n ní “ilẹ̀ ìwà burúkú” àti “àwọn èèyàn tí Jèhófà ti ta nù títí láé.”+ 5 Ẹ ó fi ojú yín rí i, ẹ ó sì sọ pé: “Kí wọ́n gbé Jèhófà ga ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì.”’”
6 Èmi Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ fún ẹ̀yin àlùfáà tó ń tàbùkù sí orúkọ mi+ pé: “‘Ọmọ máa ń bọlá fún bàbá,+ ìránṣẹ́ sì máa ń bọlá fún ọ̀gá rẹ̀. Torí náà, bí mo bá jẹ́ bàbá,+ ǹjẹ́ kò yẹ kí ẹ bọlá fún mi?+ Bí mo bá sì jẹ́ ọ̀gá,* ǹjẹ́ kò yẹ kí ẹ bẹ̀rù* mi?’
“‘Àmọ́, ẹ sọ pé: “Kí la ṣe tí a fi tàbùkù sí orúkọ rẹ?”’
7 “‘Ẹ̀ ń fi oúnjẹ* ẹlẹ́gbin rúbọ lórí pẹpẹ mi.’
“‘Ẹ sì sọ pé: “Kí la ṣe tí a fi sọ ẹ́ di ẹlẹ́gbin?”’
“‘Ẹ̀ ń sọ pé: “Tábìlì Jèhófà+ kò wúlò.” 8 Nígbà tí ẹ bá ń fi ẹran tó fọ́jú rúbọ, ẹ̀ ń sọ pé: “Kò sí ohun tó burú níbẹ̀.” Tí ẹ bá sì ń mú ẹran tó yarọ tàbí èyí tó ń ṣàìsàn wá, ẹ̀ ń sọ pé: “Kò sí ohun tó burú níbẹ̀.”’”+
“Ẹ jọ̀ọ́, ẹ mú un lọ síwájú gómìnà yín. Ṣé inú rẹ̀ á dùn sí yín, ṣé ẹ sì máa rí ojúure rẹ̀?” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
9 “Ní báyìí, ẹ jọ̀ọ́, ẹ bẹ Ọlọ́run,* kó lè ṣojúure sí wa. Ṣé irú ọrẹ tí ẹ mú wá yẹn lè mú kó ṣojúure sí ẹnikẹ́ni nínú yín?” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
10 “Ta ló fẹ́ ti àwọn ilẹ̀kùn* nínú yín?+ Ẹ kì í fẹ́ dá iná pẹpẹ mi láìjẹ́ pé ẹ gba nǹkan kan.+ Inú mi ò dùn sí yín,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “inú mi ò sì dùn sí ìkankan nínú ọrẹ tí ẹ mú wá.”+
11 “Torí láti yíyọ oòrùn dé wíwọ̀ rẹ̀,* wọn yóò gbé orúkọ mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+ Níbi gbogbo, wọ́n á mú kí ẹbọ rú èéfín, wọ́n á sì mú àwọn ọrẹ wá torí orúkọ mi, bí ẹ̀bùn tó mọ́; torí wọn yóò gbé orúkọ mi ga láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
12 “Àmọ́ ẹ̀ ń kẹ́gàn rẹ̀,*+ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Tábìlì Jèhófà jẹ́ ẹlẹ́gbin, ó sì yẹ ká tẹ́ńbẹ́lú èso àti oúnjẹ rẹ̀.’+ 13 Ẹ tún sọ pé, ‘Ẹ wò ó! Ó ti sú wa o!’ ẹ sì fi í ṣe ẹlẹ́yà,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. “Ẹran tí ẹ jí, èyí tó yarọ àti èyí tó ń ṣàìsàn lẹ̀ ń mú wá. Àní, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lẹ̀ ń fún mi! Ṣé ó yẹ kí n gbà á lọ́wọ́ yín?”+ ni Jèhófà wí.
14 “Ègún ni fún ẹni tó ń ṣe àrékérekè, tó ní akọ ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá nínú agbo ẹran rẹ̀, tó sì wá fi ẹran tó ní àbùkù* rúbọ sí Jèhófà lẹ́yìn tó jẹ́ ẹ̀jẹ́. Torí Ọba tó ju ọba lọ ni mí,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “orúkọ mi yóò sì ba àwọn orílẹ̀-èdè lẹ́rù.”+
2 “Ẹ̀yin àlùfáà, ẹ̀yin ni mò ń pa àṣẹ yìí fún.+ 2 Tí ẹ kò bá fetí sílẹ̀, tí ẹ kò sì fi í sọ́kàn, kí ẹ lè yin orúkọ mi lógo,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “èmi yóò gégùn-ún fún yín,+ èmi yóò sì sọ ìbùkún yín di ègún.+ Àní, mo ti sọ ìbùkún yín di ègún torí ẹ kò fi í sọ́kàn.”
3 “Ẹ wò ó! Nítorí yín, màá mú kí ohun tí ẹ gbìn pa run,*+ màá sì da ìgbẹ́ ẹran sí yín lójú, ìgbẹ́ àwọn ẹran tí ẹ fi rúbọ níbi àjọyọ̀ yín; wọ́n á sì gbé yín lọ síbẹ̀.* 4 Ẹ ó sì mọ̀ pé mo ti pa àṣẹ yìí fún yín, kí májẹ̀mú tí mo bá Léfì dá má bàa yẹ̀,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
5 “Májẹ̀mú ìyè àti àlàáfíà ni mo bá a dá, mo sì dá a kó lè bẹ̀rù* mi. Ó bẹ̀rù mi, àní, ó bẹ̀rù orúkọ mi. 6 Òfin* òtítọ́ wà ní ẹnu rẹ̀,+ kò sì sí àìṣòdodo kankan ní ètè rẹ̀. Ó bá mi rìn ní àlàáfíà àti ní òdodo,+ ó sì yí ọ̀pọ̀ pa dà kúrò nínú ìṣìnà. 7 Ó yẹ kí ìmọ̀ máa wà ní ètè àlùfáà, ó sì yẹ kí àwọn èèyàn máa wá òfin* ní ẹnu rẹ̀,+ torí ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni.
8 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé: “Àmọ́ ẹ̀yin fúnra yín ti yà kúrò ní ọ̀nà. Ẹ ti lo òfin* láti mú ọ̀pọ̀ kọsẹ̀.+ Ẹ ti da májẹ̀mú Léfì.+ 9 Torí náà, màá mú kí gbogbo èèyàn tẹ́ńbẹ́lú yín kí wọ́n sì fojú kéré yín, torí ẹ kò pa àwọn ọ̀nà mi mọ́, ẹ sì ń ṣe ojúsàájú dípò kí ẹ tẹ̀ lé òfin.”+
10 “Ṣebí bàbá kan ni gbogbo wa ní?+ Àbí Ọlọ́run kan náà kọ́ ló dá wa? Kí ló wá dé tí a fi ń dalẹ̀ ara wa,+ tí a sì ń pẹ̀gàn májẹ̀mú àwọn baba ńlá wa? 11 Júdà ti dalẹ̀, wọ́n sì ti ṣe ohun tó ń ríni lára ní Ísírẹ́lì àti Jerúsálẹ́mù; torí Júdà ti kẹ́gàn ìjẹ́mímọ́* Jèhófà,+ èyí tí Òun nífẹ̀ẹ́, ó sì ti fi ọmọ ọlọ́run àjèjì ṣe ìyàwó.+ 12 Bí ẹnikẹ́ni nínú àgọ́ Jékọ́bù, tó bá ń ṣe nǹkan yìí bá tiẹ̀ mú ọrẹ wá fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Jèhófà yóò pa á run, ẹni yòówù kó jẹ́.”*+
13 “Ohun míì* wà tí ẹ ṣe, tó mú kí wọ́n fi omijé àti ẹkún sísun pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn bo pẹpẹ Jèhófà, tí kò fi fiyè sí ọrẹ tí ẹ̀ ń mú wá mọ́, tí kò sì gba ohunkóhun lọ́wọ́ yín.+ 14 Ẹ sì sọ pé, ‘Kí nìdí?’ Ìdí ni pé Jèhófà ti ṣe ẹlẹ́rìí láàárín ìwọ àti aya ìgbà èwe rẹ tí o hùwà àìṣòótọ́ sí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni ẹnì kejì rẹ, òun sì ni ìyàwó rẹ tí o bá dá májẹ̀mú.*+ 15 Àmọ́ ẹnì kan wà tí kò ṣe bẹ́ẹ̀ torí èyí tó ṣẹ́ kù lára ẹ̀mí náà wà lára rẹ̀. Kí sì ni ẹni yẹn ń wá? Ọmọ* Ọlọ́run. Torí náà, ẹ ṣọ́ ẹ̀mí tó ń darí yín, ẹ má sì hùwà àìṣòótọ́ sí aya ìgbà èwe yín. 16 Torí mo kórìíra* ìkọ̀sílẹ̀,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, “mo sì kórìíra ẹni tí ìwà ipá ti wọ̀ lẹ́wù,”* ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí. “Ẹ ṣọ́ ẹ̀mí tó ń darí yín, ẹ má sì hùwà àìṣòótọ́.+
17 “Ẹ ti jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín sú Jèhófà.+ Àmọ́ ẹ̀ ń sọ pé, ‘Kí la ṣe tó jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa sú u?’ Torí bí ẹ ṣe ń sọ pé, ‘Gbogbo ẹni tó ń ṣe ohun búburú jẹ́ ẹni rere lójú Jèhófà, inú rẹ̀ sì dùn sí wọn,’+ tàbí bí ẹ ṣe ń sọ pé, ‘Ibo ni Ọlọ́run tó ń ṣe ìdájọ́ òdodo wà?’”
3 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé: “Wò ó! Màá rán ìránṣẹ́ mi, á sì tún ọ̀nà ṣe* dè mí.+ Lójijì, Olúwa tòótọ́, ẹni tí ẹ̀ ń wá yóò wá sí tẹ́ńpìlì rẹ̀;+ ìránṣẹ́ májẹ̀mú yóò sì wá, ẹni tí inú yín dùn sí. Wò ó! Ó dájú pé ó máa wá.
2 “Àmọ́ ta ló máa lè fara da ọjọ́ tó máa wá, ta ló sì máa lè dúró nígbà tó bá fara hàn? Torí òun yóò dà bí iná ẹni tó ń yọ́ nǹkan mọ́ àti bí ọṣẹ+ alágbàfọ̀. 3 Ó máa jókòó bí ẹni tó ń yọ́ fàdákà, tó sì ń fọ̀ ọ́ mọ́,+ ó sì máa fọ àwọn ọmọ Léfì mọ́; á sì yọ́ wọn mọ́* bíi wúrà àti fàdákà, ó sì dájú pé wọ́n á fi ọkàn òdodo mú ọrẹ wá fún Jèhófà. 4 Ní tòótọ́, ọrẹ tí Júdà àti Jerúsálẹ́mù bá mú wá yóò mú inú Jèhófà dùn,* bíi ti àtijọ́ àti àwọn ọdún láéláé.+
5 “Èmi yóò sún mọ́ yín láti dá yín lẹ́jọ́, èmi yóò sì ta ko àwọn oníṣẹ́ oṣó láìjáfara,+ èmi yóò ta ko àwọn alágbèrè, àwọn tó ń búra èké,+ àwọn tó ń lu òṣìṣẹ́ àti opó àti ọmọ aláìníbaba* ní jìbìtì,+ títí kan àwọn tó kọ̀ láti ran àwọn àjèjì lọ́wọ́.*+ Wọn ò bẹ̀rù mi,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
6 “Torí èmi ni Jèhófà; èmi kì í yí pa dà.*+ Ẹ̀yin sì ni ọmọ Jékọ́bù; ẹ kò tíì pa run. 7 Láti ọjọ́ àwọn baba ńlá yín ni ẹ ti kẹ̀yìn sí àwọn ìlànà mi, ẹ kò sì tẹ̀ lé wọn.+ Ẹ pa dà sọ́dọ̀ mi, èmi yóò sì pa dà sọ́dọ̀ yín,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
Àmọ́, ẹ sọ pé: “Báwo la ṣe máa pa dà?”
8 “Ṣé èèyàn lásán lè ja Ọlọ́run lólè? Àmọ́ ẹ̀ ń jà mí lólè.”
Ẹ sì sọ pé: “Ọ̀nà wo ni a gbà jà ọ́ lólè?”
“Nínú ìdá mẹ́wàá àti ọrẹ ni. 9 Ó dájú pé ègún wà lórí yín* torí ẹ̀ ń jà mí lólè, àní gbogbo orílẹ̀-èdè yìí ló ń ṣe bẹ́ẹ̀. 10 Ẹ mú gbogbo ìdá mẹ́wàá wá sínú ilé ìkẹ́rùsí,+ kí oúnjẹ lè wà nínú ilé mi.+ Ẹ jọ̀ọ́, ẹ fi èyí dán mi wò,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “kí ẹ lè rí i bóyá mi ò ní ṣí ibú omi ọ̀run,+ kí n sì tú* ìbùkún sórí yín títí ẹ kò fi ní ṣaláìní ohunkóhun.”+
11 “Èmi yóò sì bá ẹni tó ń jẹ nǹkan run* wí torí yín, kò ní run èso ilẹ̀ yín, àjàrà inú oko yín yóò sì so èso,”+ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
12 “Gbogbo orílẹ̀-èdè yóò pè yín ní aláyọ̀,+ torí ẹ ó di ilẹ̀ tó ń múnú ẹni dùn,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.
13 Jèhófà sọ pé: “Ọ̀rọ̀ líle lẹ sọ sí mi.”
Ẹ sì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ líle wo la sọ sí ọ?”+
14 “Ẹ sọ pé, ‘Kò sí àǹfààní kankan nínú sísin Ọlọ́run.+ Èrè wo la rí gbà bí a ti ń ṣe ojúṣe wa sí i, tí a sì ń kárí sọ níwájú Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun? 15 Ní báyìí, àwọn agbéraga* ni à ń pè ní aláyọ̀. Bákan náà, àwọn tó ń hùwà burúkú ń ṣàṣeyọrí.+ Àyà kò wọ́n láti dán Ọlọ́run wò, wọ́n sì ń mú un jẹ.’”
16 Ní àkókò yẹn, àwọn tó bẹ̀rù Jèhófà bá ara wọn sọ̀rọ̀, kálukú pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ̀, Jèhófà sì ń fiyè sí i, ó sì ń fetí sílẹ̀. Wọ́n sì kọ ìwé ìrántí kan níwájú rẹ̀+ torí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà àti àwọn tó ń ṣe àṣàrò lórí orúkọ rẹ̀.*+
17 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé: “Wọn yóò di tèmi+ ní ọjọ́ tí mo bá sọ wọ́n di ohun ìní mi pàtàkì.*+ Èmi yóò ṣàánú wọn, bí èèyàn ṣe máa ń ṣàánú ọmọ rẹ̀ tó ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu.+ 18 Ẹ ó sì tún rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú,+ láàárín ẹni tó ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”
4 “Wò ó! ọjọ́ náà ń bọ̀, ó ń jó bí iná ìléru,+ nígbà tí gbogbo àwọn agbéraga àti gbogbo àwọn tó ń hùwà burúkú yóò dà bí àgékù pòròpórò. Ọjọ́ tó ń bọ̀ náà yóò jẹ wọ́n run,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “kò sì ní fi gbòǹgbò tàbí ẹ̀ka sílẹ̀ fún wọn. 2 Àmọ́ oòrùn òdodo yóò ràn sórí ẹ̀yin tó bọlá fún* orúkọ mi, ìtànṣán* rẹ̀ yóò mú yín lára dá; ẹ ó sì máa tọ pọ́n-ún pọ́n-ún kiri bí àwọn ọmọ màlúù tí wọ́n bọ́ sanra.”
3 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ pé: “Ẹ ó tẹ àwọn ẹni burúkú mọ́lẹ̀, torí wọ́n á dà bí eruku lábẹ́ ẹsẹ̀ yín, ní ọjọ́ tí mo bá ṣe ohun tí mo sọ.”
4 “Ẹ rántí Òfin Mósè ìránṣẹ́ mi, àwọn ìlànà àti àṣẹ tí mo pa fún gbogbo Ísírẹ́lì ní Hórébù pé kí wọ́n tẹ̀ lé.+
5 “Wò ó! Èmi yóò rán wòlíì Èlíjà sí yín+ kí ọjọ́ ńlá Jèhófà tó ń bani lẹ́rù tó dé.+ 6 Ó sì máa yí ọkàn àwọn bàbá pa dà sọ́dọ̀ àwọn ọmọ+ àti ọkàn àwọn ọmọ pa dà sọ́dọ̀ àwọn bàbá, kí n má bàa fìyà jẹ ayé, kí n sì pa á run.”
(Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Árámáíkì parí, Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ló kàn báyìí)
Ó túmọ̀ sí “Ìránṣẹ́ Mi.”
Tàbí “akátá.”
Tàbí “ọ̀gá àgbà.”
Tàbí “bọ̀wọ̀ fún.”
Ní Héb., “búrẹ́dì.”
Tàbí “tu Ọlọ́run lójú.”
Ó ṣe kedere pé, iṣẹ́ títi àwọn ilẹ̀kùn tẹ́ńpìlì ló ń sọ.
Tàbí “láti ìlà oòrùn dé ìwọ̀ oòrùn.”
Tàbí kó jẹ́, “pẹ̀gàn mi.”
Tàbí “àbààwọ́n.”
Ní Héb., “màá bá ohun tí ẹ gbìn wí.”
Ìyẹn, ibi tí wọ́n ń da ìgbẹ́ àwọn ẹran tí wọ́n fi rúbọ sí.
Tàbí “bọ̀wọ̀ fún; ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún.”
Tàbí “Ẹ̀kọ́.”
Tàbí “ẹ̀kọ́.”
Tàbí kó jẹ́, “ẹ̀kọ́ yín.”
Tàbí kó jẹ́, “ibi mímọ́.”
Ní Héb., “ẹni tí kò sùn àti ẹni tó ń dáhùn.”
Ní Héb., “kejì.”
Tàbí “ìyàwó alárédè.”
Ní Héb., “èso.”
Ní Héb., “ó kórìíra.”
Tàbí “tó ń hùwà ipá.”
Tàbí “palẹ̀ ọ̀nà mọ́.”
Tàbí “mú kí wọ́n mọ́ kedere.”
Tàbí “yóò tẹ́ Jèhófà lọ́rùn.”
Tàbí “ọmọ aláìlóbìí.”
Tàbí “tó ń fi ẹ̀tọ́ àwọn àjèjì dù wọ́n.”
Tàbí “èmi kò yí pa dà.”
Tàbí kó jẹ́, “Ẹ̀ ń gégùn-ún fún mi.”
Ní Héb., “da.”
Ó lè jẹ́ àwọn kòkòrò tó ń ba nǹkan jẹ́ ló ń sọ.
Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”
Tàbí “ronú lórí orúkọ rẹ̀.” Tàbí kó jẹ́, “ka orúkọ rẹ̀ sí pàtàkì.”
Tàbí “tó ṣeyebíye.”
Ní Héb., “bẹ̀rù.”
Ní Héb., “àwọn ìyẹ́.”