ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • nwt 2 Tẹsalóníkà 1:1-3:18
  • 2 Tẹsalóníkà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • 2 Tẹsalóníkà
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Tẹsalóníkà

ÌWÉ KEJÌ SÍ ÀWỌN ARÁ TẸSALÓNÍKÀ

1 Pọ́ọ̀lù, Sílífánù* àti Tímótì,+ sí ìjọ àwọn ará Tẹsalóníkà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa:

2 Kí ẹ ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Baba àti Jésù Kristi Olúwa.

3 Ẹ̀yin ará, ó di dandan fún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín. Ó yẹ bẹ́ẹ̀, torí pé ìgbàgbọ́ yín ń lágbára sí i, ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ sì ń pọ̀ sí i.+ 4 Nítorí èyí, à ń fi yín yangàn+ láàárín ìjọ Ọlọ́run nítorí ìfaradà àti ìgbàgbọ́ yín nínú gbogbo inúnibíni àti àwọn ìṣòro* tí ẹ̀ ń dojú kọ.*+ 5 Èyí jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run, tó ń mú kí a kà yín yẹ fún Ìjọba Ọlọ́run tí ẹ̀ ń torí rẹ̀ jìyà.+

6 Èyí jẹ́ nítorí pé Ọlọ́run kà á sí òdodo láti san ìpọ́njú pa dà fún àwọn tó ń pọ́n yín lójú.+ 7 Àmọ́ ẹ̀yin tí ẹ̀ ń ní ìpọ́njú máa rí ìtura gbà pẹ̀lú wa nígbà ìfihàn Jésù Olúwa+ láti ọ̀run pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára+ 8 nínú iná tó ń jó fòfò, bó ṣe ń mú ẹ̀san wá sórí àwọn tí kò mọ Ọlọ́run àti àwọn tí kò ṣègbọràn sí ìhìn rere nípa Jésù Olúwa wa.+ 9 Àwọn yìí máa fara gbá ìyà ìdájọ́ ìparun ayérayé+ láti iwájú Olúwa àti látinú ògo agbára rẹ̀, 10 nígbà tó bá dé kí a lè yìn ín lógo pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, kí gbogbo àwọn tó ní ìgbàgbọ́ sì lè wò ó ní ọjọ́ yẹn tìyanutìyanu, nítorí ẹ gba ẹ̀rí tí a jẹ́ fún yín gbọ́.

11 Torí bẹ́ẹ̀, à ń gbàdúrà fún yín nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run wa kà yín yẹ fún ìpè rẹ̀,+ kó sì fi agbára rẹ̀ ṣe gbogbo ohun rere tó wù ú láṣepé pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ ìgbàgbọ́. 12 Kí a lè yin orúkọ Olúwa wa Jésù lógo nínú yín, kí a sì yin ẹ̀yin náà lógo nínú rẹ̀, nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run wa àti ti Jésù Kristi Olúwa.

2 Àmọ́, ẹ̀yin ará, ní ti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi+ àti kíkó wa jọ sọ́dọ̀ rẹ̀,+ a rọ̀ yín 2 kí ọkàn yín má tètè mì tàbí kí ó dà rú nítorí ọ̀rọ̀ onímìísí*+ tàbí nítorí iṣẹ́ tí a fẹnu jẹ́ tàbí nítorí lẹ́tà kan tó dà bíi pé ó wá látọ̀dọ̀ wa, tó ń sọ pé ọjọ́ Jèhófà*+ ti dé.

3 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnì kankan kó yín ṣìnà* lọ́nàkọnà, nítorí kò ní dé láìjẹ́ pé ìpẹ̀yìndà+ kọ́kọ́ dé, tí a sì fi ọkùnrin arúfin+ hàn, ìyẹn ọmọ ìparun.+ 4 Alátakò ni, ó sì gbé ara rẹ̀ lékè gbogbo àwọn tí wọ́n ń pè ní ọlọ́run tàbí ohun ìjọsìn,* tó fi jẹ́ pé ó jókòó nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run, ó sì ń fi ara rẹ̀ hàn ní gbangba pé òun jẹ́ ọlọ́run. 5 Ṣé ẹ rántí pé nígbà tí mo ṣì wà pẹ̀lú yín, mo máa ń sọ àwọn nǹkan yìí fún yín?

6 Ní báyìí, ẹ mọ ohun tó ń ṣèdíwọ́ kó má bàa fara hàn ṣáájú àkókò rẹ̀. 7 Lóòótọ́, àṣírí ìwà ìkà yìí ti wà lẹ́nu iṣẹ́,+ àmọ́ ó dìgbà tí ẹni tó ń ṣèdíwọ́ ní báyìí bá kúrò lọ́nà. 8 Lẹ́yìn náà, a ó fi arúfin náà hàn, ẹni tí Jésù Olúwa máa fi ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ pa,+ tí á sì sọ di asán nígbà tó bá ṣe kedere+ pé ó ti wà níhìn-ín. 9 Àmọ́ ohun tó mú kí arúfin náà wà níhìn-ín jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ Sátánì+ pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu* tó jẹ́ irọ́ + 10 pẹ̀lú gbogbo ẹ̀tàn àìṣòdodo  + fún àwọn tó ń ṣègbé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san iṣẹ́ wọn nítorí pé wọn ò gba ìfẹ́ òtítọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà. 11 Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí ohun tó ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn kó wọn ṣìnà, kí wọ́n lè gba irọ́ gbọ́,+ 12 kí a lè dá gbogbo wọn lẹ́jọ́ torí pé wọn ò gba òtítọ́ gbọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ni wọ́n ń fi àìṣòdodo ṣayọ̀.

13 Síbẹ̀, ó di dandan fún wa láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà gbogbo nítorí yín, ẹ̀yin ará tí Jèhófà* nífẹ̀ẹ́, torí pé àtìbẹ̀rẹ̀ ni Ọlọ́run ti yàn yín+ fún ìgbàlà nípa fífi ẹ̀mí rẹ̀ sọ yín di mímọ́+ àti nípa ìgbàgbọ́ yín nínú òtítọ́. 14 Ó tipasẹ̀ ìhìn rere tí à ń kéde pè yín sí èyí, kí ẹ lè ní ògo Olúwa wa Jésù Kristi.+ 15 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ dúró gbọn-in,+ kí ẹ sì di àwọn àṣà tí a fi kọ́ yín mú ṣinṣin,+ ì báà jẹ́ nípasẹ̀ iṣẹ́ tí a fẹnu jẹ́ tàbí nípasẹ̀ lẹ́tà látọ̀dọ̀ wa. 16 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí Olúwa wa Jésù Kristi fúnra rẹ̀ àti Ọlọ́run, Baba wa, ẹni tó nífẹ̀ẹ́ wa,+ tó sì fún wa ní ìtùnú ayérayé àti ìrètí rere+ nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, 17 tu ọkàn yín lára, kó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in* nínú gbogbo iṣẹ́ rere àti ọ̀rọ̀ rere.

3 Lákòótán, ẹ̀yin ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa,+ kí ọ̀rọ̀ Jèhófà* lè máa gbilẹ̀ kíákíá,+ kí a sì máa ṣe é lógo, bó ṣe rí lọ́dọ̀ yín, 2 kí a lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn ẹni ibi àti èèyàn burúkú,+ nítorí ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo èèyàn.+ 3 Àmọ́ olóòótọ́ ni Olúwa, yóò fún yín lókun, yóò sì dáàbò bò yín kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà. 4 Yàtọ̀ síyẹn, bí a ṣe wà nínú Olúwa, a ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú yín pé ẹ̀ ń ṣe àwọn ohun tí a sọ fún yín, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n nìṣó. 5 Kí Olúwa máa darí ọkàn yín sínú ìfẹ́ Ọlọ́run+ àti sínú ìfaradà+ fún Kristi.

6 Ní báyìí ẹ̀yin ará, à ń fún yín ní ìtọ́ni ní orúkọ Jésù Kristi Olúwa wa, pé kí ẹ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ gbogbo arákùnrin tó ń rìn ségesège,+ tí kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣà* tí ẹ* gbà lọ́dọ̀ wa.+ 7 Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ bó ṣe yẹ kí ẹ fara wé wa,+ torí a ò ṣe ségesège láàárín yín, 8 bẹ́ẹ̀ la ò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́.*+ Kàkà bẹ́ẹ̀, nínú òpò* àti làálàá, à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sántòru kí a má bàa gbé ẹrù tó wúwo wọ ìkankan nínú yín lọ́rùn.+ 9 Kì í ṣe pé a ò ní àṣẹ,+ àmọ́ a fẹ́ fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ fún yín kí ẹ lè máa fara wé wa.+ 10 Kódà, nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a máa ń pa àṣẹ yìí fún yín pé: “Tí ẹnikẹ́ni ò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kó má jẹun.”+ 11 Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ń rìn ségesège láàárín yín,+ wọn ò ṣiṣẹ́ rárá, ṣe ni wọ́n ń tojú bọ ohun tí kò kàn wọ́n.+ 12 Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni a pa àṣẹ fún, tí a sì gbà níyànjú nínú Jésù Kristi Olúwa pé kí wọ́n gbájú mọ́ iṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì máa jẹ oúnjẹ tí àwọn fúnra wọn ṣiṣẹ́ fún.+

13 Ní tiyín, ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe jẹ́ kó sú yín láti máa ṣe rere. 14 Àmọ́ tí ẹnikẹ́ni ò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ tí a sọ nínú lẹ́tà yìí, ẹ sàmì sí ẹni náà, ẹ má sì bá a kẹ́gbẹ́ mọ́,+ kí ojú lè tì í. 15 Síbẹ̀, ẹ má kà á sí ọ̀tá, àmọ́ ẹ máa gbà á níyànjú+ bí arákùnrin.

16 Tóò, kí Olúwa àlàáfíà máa fún yín ní àlàáfíà nígbà gbogbo àti ní gbogbo ọ̀nà.+ Kí Olúwa wà pẹ̀lú gbogbo yín.

17 Ìkíni èmi Pọ́ọ̀lù nìyí, tí mo fi ọwọ́ ara mi kọ,+ ó jẹ́ àmì nínú gbogbo lẹ́tà mi; bí mo ṣe máa ń kọ̀wé nìyí.

18 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú gbogbo yín.

Wọ́n tún ń pè é ní Sílà.

Tàbí “àwọn ìpọ́njú.”

Tàbí “fara dà.”

Tàbí “torí ẹ̀mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Ẹ̀mí.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “sún yín dẹ́ṣẹ̀.”

Tàbí “ọ̀wọ̀.”

Tàbí “àwọn àmì.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “fún yín lókun.”

Wo Àfikún A5.

Tàbí “ìtọ́ni.”

Tàbí kó jẹ́, “wọ́n.”

Tàbí “láìsanwó.”

Tàbí “iṣẹ́ àṣekára.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́