Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
June 15, 2015
© 2015 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
JULY 27, 2015–AUGUST 2, 2015
AUGUST 3-9, 2015
AUGUST 10-16, 2015
AUGUST 17-23, 2015
Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà—Apá Kìíní
OJÚ ÌWÉ 20 • ORIN: 138 Jèhófà Ni Orúkọ Rẹ (orin tuntun), 89
AUGUST 24-30, 2015
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́
▪ Kristi—Agbára Ọlọ́run
▪ Ó Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn
Àwọn àpilẹ̀kọ méjì yìí tó dá lórí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe kọ́ wa láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì lórí bá a ṣe lè jẹ́ ọ̀làwọ́, àti bá a ṣe lè máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó sì tún jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ tó fani mọ́ra tí Jésù ní. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí sọ nípa ọjọ́ iwájú kan tí kò jìnnà mọ́ tá a ti máa rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tó kàmàmà tó máa ṣẹlẹ̀ kárí ayé.
▪ A Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́
Nínú ayé tó kún fún ìwàkiwà yìí, ó lè nira díẹ̀ kéèyàn tó lè jẹ́ oníwà mímọ́. Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ bí àjọṣe àwa àti Jèhófà, ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún èròkerò, tí àá sì fọwọ́ pàtàkì mú àwọn ìlànà ìwà rere Jèhófà.
▪ Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà—Apá Kìíní
▪ Máa Gbé Ìgbé Ayé Rẹ Ní Ìbámu Pẹ̀lú Àdúrà Àwòṣe Náà—Apá Kejì
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwa Kristẹni kì í sọ àsọtúnsọ àdúrà àwòṣe tí Jésù kọ́ wa lójoojúmọ́, àwọn ẹ̀bẹ̀ tó wà nínú àdúrà náà ní ìtumọ̀ fún gbogbo wa. Àwọn àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ bá a sẹ lè gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ mu.
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ MÍÌ NÍNÚ ÌTẸ̀JÁDE YÌÍ
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí àwọn erékùṣù tó wà ní Bocas del Toro Archipelago tó wà ní apá àríwá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Panama kí wọ́n lè wàásù fáwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀. Èyí sì ní nínú pé kí wọ́n fi èdè ìbílẹ̀ Ngabere wàásù fáwọn èèyàn
PANAMA
IYE ÈÈYÀN
3,931,000
IYE AKÉDE
16,217
IYE AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ DÉÉDÉÉ
2,534
Ìjọ ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé mẹ́sàn-án [309] ló wà ní orílẹ̀-èdè Panama, àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tí iye wọn lé ní ọgọ́sàn-án [180] ló sì wà láwọn ìjọ náà. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀fà [1,100] àwọn akéde tó ń sìn ní ìjọ márùndínlógójì [35] àti àwùjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] ló ń fi èdè Ngabere ṣèpàdé. Nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] àwọn akéde tó ń sìn ní ìjọ mẹ́rìndínlógún [16] àti àwùjọ mẹ́fà ló sì ń lo èdè adití lọ́nà ti àwọn ará Panama láti fi ṣèpàdé