ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w16 January ojú ìwé 9-13
  • Jẹ́ Kí ‘Ẹ̀bùn Ọ̀fẹ́ Aláìṣeé-Ṣàpèjúwe’ Ti Ọlọ́run Mú Ẹ Lọ́ranyàn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jẹ́ Kí ‘Ẹ̀bùn Ọ̀fẹ́ Aláìṣeé-Ṣàpèjúwe’ Ti Ọlọ́run Mú Ẹ Lọ́ranyàn
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹ̀BÙN PÀTÀKÌ TÍ ỌLỌ́RUN FÚN WA
  • “ÌFẸ́ TÍ KRISTI NÍ SỌ Ọ́ DI Ọ̀RANYÀN FÚN WA”
  • A WÀ LÁBẸ́ ÀÌGBỌ́DỌ̀MÁṢE LÁTI NÍFẸ̀Ẹ́ ARA WA LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ
  • MÁA FI ÀÁNÚ HÀN SÁWỌN ARÁ
  • “Ìfẹ́ Tí Kristi Ní Sọ Ọ́ Di Dandan fún Wa”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Kí Nìdí Tí Ẹ̀bùn Yìí Fi Ṣe Iyebíye Gan-an?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Túbọ̀ Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Àtàwọn Ará
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • ‘Ẹ Máa Rìn Nínú Ìfẹ́’
    Sún Mọ́ Jèhófà
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
w16 January ojú ìwé 9-13
Àwọn ará kan ṣàṣàrò lórí ẹbọ ìràpadà Kristi, wọ́n wá ń ṣàyẹ̀wò aṣọ wọn, géèmù àti fídíò àtàwọn ohun tó wà lórí àwọn ẹ̀rọ ìgbàlódé wọn

Jẹ́ Kí ‘Ẹ̀bùn Ọ̀fẹ́ Aláìṣeé-Ṣàpèjúwe’ Ti Ọlọ́run Mú Ẹ Lọ́ranyàn

“Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run fún ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ rẹ̀ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 9:15.

ORIN: 121, 63

KÍ NI ÌDÁHÙN RẸ?

  • Kí ni ìfẹ́ tí Kristi ní sí wa ń mú ká ṣe?

  • Báwo ni ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ṣe ń mú ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa?

  • Torí pé Ọlọ́run ń dárí jì wá, báwo nìyẹn ṣe máa mú ká máa dárí ji àwọn ará wa?

1, 2. (a) Kí ni ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe’ ti Ọlọ́run ní nínú? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí?

ÌFẸ́ tí Jèhófà ní sí wa mú kó fún wa lẹ́bùn tó ṣeyebíye jù lọ, ó rán Jésù Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n wá sáyé. (Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 4:9, 10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pe ẹ̀bùn yìí ní ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe.’ (2 Kọ́ríńtì 9:15) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi lo gbólóhùn yìí?

2 Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé ẹbọ ìràpadà Jésù ló jẹ́ kó dá wa lójú pé gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe máa nímùúṣẹ. (Ka 2 Kọ́ríńtì 1:20.) Èyí túmọ̀ sí pé ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe’ ti Ọlọ́run ní nínú, ẹbọ ìràpadà Jésù, gbogbo oore tí Jèhófà ń ṣe fún wa àti ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ tó ń fi hàn sí wa. Kò sí bá a ṣe ṣàlàyé ẹ̀bùn pàtàkì yìí tó, tó máa yé àwa èèyàn yékéyéké. Báwo ló ṣe yẹ kí ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ yìí rí lára wa? Báwo ni ẹ̀bùn tá a ní yìí ṣe máa ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ṣe lọ́jọ́ Wednesday, March 23, 2016?

Ẹ̀BÙN PÀTÀKÌ TÍ ỌLỌ́RUN FÚN WA

3, 4. (a) Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ tí ẹnì kan bá fún ẹ lẹ́bùn? (b) Ṣàpèjúwe bí ẹ̀bùn pàtàkì tí ẹnì kan fún ẹ ṣe lè yí ìgbésí ayé rẹ pa dà.

3 Inú wa máa ń dùn tẹ́nì kan bá fún wa lẹ́bùn. Àmọ́, àwọn ẹ̀bùn kan ṣe pàtàkì débi pé wọ́n lè yí ìgbésí ayé wa pa dà. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká sọ pé wọ́n ká iṣẹ́ ibi kan mọ́ ẹ lọ́wọ́, ó sì ṣẹlẹ̀ pé pípa ni wọ́n máa pa ẹni bá ṣiṣẹ́ ibi náà. Àmọ́, ṣàdédé ni ẹnì kan tó ò mọ̀ tẹ́lẹ̀ sọ pé kí wọ́n fi ìyà tó tọ́ sí ẹ jẹ òun. Kódà, ó ṣe tán láti kú fún ẹ. Báwo ni ohun tí ẹni yìí ṣe ṣe máa rí lára rẹ?

4 Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí lè mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà tó yẹ nínú ìgbésí ayé rẹ. Ó ṣeé ṣe kó o tún bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ àwọn míì ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, kó o máa dárí ji àwọn tó ṣàìdáa sí ẹ, kó o sì tún fi kún ìwà ọ̀làwọ́ rẹ. Jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ, ṣe ni wàá máa ṣe ohun tó fi hàn pé o mọrírì ohun tẹ́ni náà ṣe fún ẹ.

5. Báwo ni ẹ̀bùn ìràpadà tí Ọlọ́run fún wa ṣe ṣeyebíye ju ẹ̀bùn èyíkéyìí lọ?

5 Ẹ̀bùn ìràpadà tí Ọlọ́run fún wa ṣeyebíye gan-an ju ohun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣàlàyé rẹ̀ tán yìí lọ. (1 Pétérù 3:18) Ronú nípa èyí ná: Gbogbo wa la jogún ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ádámù, ikú sì ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 5:12) Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa mú kó rán Jésù wá sáyé láti kú fún wa, kó lè “tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn.” (Hébérù 2:9) Àmọ́, ẹbọ ìràpadà Jésù máa ṣe ju ìyẹn lọ. Ó máa gbé ikú mì títí láé. (Aísáyà 25:7, 8; 1 Kọ́ríńtì 15:22, 26) Gbogbo àwọn tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù máa láyọ̀, wọ́n á sì máa gbé lálàáfíà títí láé, yálà wọ́n wà lára àwọn tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Kristi lọ́run tàbí lára àwọn tí yóò máa gbé lórí ilẹ̀ ayé. (Róòmù 6:23; Ìṣípayá 5:9, 10) Àwọn ìbùkún míì wo ni ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa yìí máa mú wá?

6. (a) Èwo lò ń fojú sọ́nà fún lára àwọn ìbùkún tá a máa rí látinú ẹ̀bùn tí Jèhófà fún wa? (b) Sọ nǹkan mẹ́ta tí ẹ̀bùn Ọlọ́run máa mú ká ṣe.

6 Lára ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa ni pé ilẹ̀ ayé á di Párádísè, ara àwọn aláìsàn á yá, àwọn òkú á sì jíǹde. (Aísáyà 33:24; 35:5, 6; Jòhánù 5:28, 29) A nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n torí ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe’ tí wọ́n fún wa. Kí ni ẹ̀bùn yìí á mú ká ṣe? Á mú (1) ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Kristi Jésù pẹ́kípẹ́kí, (2) ká máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ará, àti (3) ká máa dárí jini látọkàn wá.

“ÌFẸ́ TÍ KRISTI NÍ SỌ Ọ́ DI Ọ̀RANYÀN FÚN WA”

7, 8. Báwo ló ṣe yẹ kí ìfẹ́ tí Kristi ní sí wa rí lára wa, kí ló sì yẹ kí ìyẹn mú ká ṣe?

7 Ó yẹ kí ìfẹ́ tí Kristi ní sí wa mú ká fi ìgbésí ayé wa bọlá fún un. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa.” (Ka 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé tá a bá mọrírì ìfẹ́ àrà ọ̀tọ̀ tí Jésù ní sí wa, á mú ká bọlá fún Jésù ká sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Tá a bá lóye àwọn ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa lóòótọ́, ìfẹ́ tó ní sí wa á mú ká máa gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé à ń bọlá fún Jésù. Báwo la ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

8 Ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà á mú ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù pẹ́kípẹ́kí. (1 Pétérù 2:21; 1 Jòhánù 2:6) Tá a bá ń ṣègbọràn sí Ọlọ́run àti Kristi, ìyẹn á fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ wọn. Jésù sọ pé: “Ẹni tí ó bá ní àwọn àṣẹ mi, tí ó sì ń pa wọ́n mọ́, ẹni yẹn ni ó nífẹ̀ẹ́ mi. Ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni Baba mi yóò nífẹ̀ẹ́, ṣe ni èmi yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, èmi yóò sì fi ara mi hàn fún un kedere.”—Jòhánù 14:21; 1 Jòhánù 5:3.

9. Kí làwọn èèyàn inú ayé yìí ń fẹ́ ká ṣe?

9 Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí, ó dáa ká ronú nípa ohun tá à ń fi ìgbésí ayé wa ṣe. Torí náà, bi ara rẹ pé: ‘Àwọn apá wo nínú ìgbésí ayé mi ni mo ti ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù? Àwọn apá wo ló yẹ kí n ṣàtúnṣe sí?’ Ó ṣe pàtàkì pé ká bi ara wa láwọn ìbéèrè yìí torí ohun táyé ń fẹ́ ni pé ká dà bí wọ́n ṣe dà. (Róòmù 12:2) Tá ò bá ṣọ́ra, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í fara wé àwọn gbajúmọ̀ èèyàn, àwọn gbajúgbajà eléré ìdárayá àtàwọn ọ̀jọ̀gbọ́n inú ayé. (Kólósè 2:8; 1 Jòhánù 2:15-17) Kí la lè ṣe táyé ò fi ní sọ wá dà bó ṣe dà?

10. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa lásìkò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí, kí sì ni ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè náà máa mú ká ṣe? (Wo àwòrán tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.)

10 Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi ti ọdún yìí, ó yẹ ká ṣàyẹ̀wò àwọn aṣọ wa, àwọn fíìmù tá à ń wò, àwọn orin tá à ń gbọ́ àtàwọn ohun tó wà lórí kọ̀ǹpútà tàbí fóònù wa. Bi ara rẹ pé: ‘Ṣé ojú ò ní tì mí tí Jésù bá wà níbí, tó sì rí aṣọ tí mo wọ̀?’ (Ka 1 Tímótì 2:9, 10.) ‘Tí mo bá wọ irú aṣọ yìí, ṣé àwọn èèyàn á gbà pé ọmọlẹ́yìn Kristi ni mí lóòótọ́? Ṣé Jésù máa fẹ́ wo irú fíìmù tí mò ń wò? Ṣó máa fẹ́ gbọ́ àwọn orin tí mò ń gbọ́? Bí Jésù bá yá fóònù mi, ṣé ohun tó máa bá níbẹ̀ ò ní mú kójú tì mí? Ṣé ara á tù mí láti ṣàlàyé fún Jésù ìdí tí mo fi nífẹ̀ẹ́ sí géèmù orí kọ̀ǹpútà tàbí géèmù orí fóònù tí mò ń gbá?’ Ó yẹ kí ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà mú ká sọ gbogbo ohun tí kò bójú mu fún Kristẹni nù, láìka iye tó máa ná wa sí. (Ìṣe 19:19, 20) Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a ṣèlérí pé a máa fi ìgbésí ayé wa bọlá fún Kristi. Torí náà, kò yẹ ká ní ohunkóhun tó máa jẹ́ kó ṣòro fún wa láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù níkàáwọ́ wa.—Mátíù 5:29, 30; Fílípì 4:8.

11. (a) Báwo ni ìfẹ́ tá a ní sí Jèhófà àti Jésù ṣe máa mú ká ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? (b) Báwo ni ìfẹ́ tá a ní ṣe máa mú ká ran àwọn míì lọ́wọ́ nínú ìjọ?

11 Ìfẹ́ tá a ní fún Jésù máa mú ká fìtara wàásù ká sì kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́. (Mátíù 28:19, 20; Lúùkù 4:43) Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, ǹjẹ́ o lè ṣètò àkókò rẹ kó o lè gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, kó o sì lo ọgbọ̀n [30] tàbí àádọ́ta [50] wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? Bàbá kan tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84] tí ìyàwó rẹ̀ sì ti kú rò pé òun ò lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà torí àìlera àti ara tó ti dara àgbà. Àmọ́, àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó wà ládùúgbò rẹ̀ ràn án lọ́wọ́. Wọ́n fún un ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tó máa rọrùn fún un, wọ́n sì ṣètò ohun ìrìnnà táá máa gbé e lọ, gbé e bọ̀. Èyí ran arákùnrin náà lọ́wọ́ láti dójú ìlà ọgbọ̀n wákàtí. Ṣé ìwọ náà lè ran ẹnì kan tó wà nínú ìjọ yín lọ́wọ́ kó lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March tàbí April? Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo wa la lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, àmọ́ a lè lo àkókò àti okun wa láti fi kún iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà á fi hàn bíi ti Pọ́ọ̀lù pé a mọrírì ìfẹ́ tí Jésù ní sí wa. Kí ni ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa tún máa mú ká ṣe?

A WÀ LÁBẸ́ ÀÌGBỌ́DỌ̀MÁṢE LÁTI NÍFẸ̀Ẹ́ ARA WA LẸ́NÌ KÌÍNÍ-KEJÌ

12. Kí ni ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa ń mú ká ṣe?

12 Ó tún yẹ kí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa mú ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa, nígbà náà àwa fúnra wa wà lábẹ́ iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe láti nífẹ̀ẹ́ ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Jòhánù 4:7-11) Tá a bá mọrírì ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa, ó pọn dandan pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa. (1 Jòhánù 3:16) Báwo la ṣe lè fìfẹ́ hàn sí wọn?

13. Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn?

13 A rí àpẹẹrẹ bó ṣe yẹ ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn nínú àwọn ohun tí Jésù ṣe. Nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ó ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ pàápàá àwọn òtòṣì. Ó wo àwọn aláìsàn sàn, ó la ojú àwọn afọ́jú, ó sì mú àwọn arọ, adití àtàwọn odi lára dá. (Mátíù 11:4, 5) Jésù ò dà bí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, ó máa ń kọ́ àwọn tó fẹ́ mọ̀ nípa Ọlọ́run lẹ́kọ̀ọ́. (Jòhánù 7:49) Ó nífẹ̀ẹ́ àwọn táwọn èèyàn kà sí òtòṣì yẹn, ó sì máa ń sapá láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Mátíù 20:28.

Àwọn ará kan ń ran àwọn arákùnrin àti arábìnrin kan tó ti dàgbà lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa fi lẹ́tà àti fóònù wàásù

Ṣé o lè ran arákùnrin tàbí arábìnrin kan tó ti dàgbà lọ́wọ́ lóde ẹ̀rí? (Wo ìpínrọ̀ 14)

14. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà fìfẹ́ hàn sáwọn ará?

14 Ìgbà Ìrántí Ikú Kristi tún jẹ́ àkókò tó dáa láti ronú lórí bá a ṣe lè ran àwọn ará inú ìjọ wa lọ́wọ́, pàápàá jù lọ àwọn tó ti dàgbà. Ṣé o lè lọ kí àwọn àgbàlagbà yìí nílé? Ṣé o lè se oúnjẹ wá fún wọn, kó o bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ nínú ilé, kó o gbé wọn wá sí ìpàdé tàbí kó o ní kí wọ́n bá ẹ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí? (Ka Lúùkù 14:12-14.) Jẹ́ kí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ẹ mú kí ìwọ náà máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará.

MÁA FI ÀÁNÚ HÀN SÁWỌN ARÁ

15. Kí ló yẹ ká mọ̀?

15 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí wa ń mú ká dárí ji àwọn ará tó bá ṣẹ̀ wá. Gbogbo wa la ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú láti ọ̀dọ̀ Ádámù, torí náà kò sẹ́ni tó lè sọ pé, “Mi ò nílò ìràpadà.” Kódà, ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ olóòótọ́ jù lọ pàápàá nílò ẹ̀bùn ìràpadà, torí pé Ọlọ́run ti dárí gbèsè ńlá ji ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Kí wá nìdí tó fi pọn dandan pé ká mọ̀ bẹ́ẹ̀? A máa rí ìdáhùn nínú ọ̀kan lára àwọn àpèjúwe Jésù.

16, 17. (a) Kí la rí kọ́ nínú àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa ọba kan àti àwọn ẹrú rẹ̀? (b) Lẹ́yìn tó o ti ronú lórí àpèjúwe Jésù, kí lo pinnu láti ṣe?

16 Jésù sọ àpèjúwe ọba kan tó dárí gbèsè ọgọ́ta [60] mílíọ̀nù owó dínárì ji ẹrú rẹ̀ kan. Àmọ́ nígbà tó yá, ẹrú yìí kan náà kọ̀ láti dárí ji ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ ẹ́ ní gbèsè ọgọ́rùn-ún owó dínárì péré. Àánú tí ọba fi hàn sí ẹrú yìí yẹ kó sún òun náà láti dárí ji ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀. Inú bí ọba gan-an nígbà tó gbọ́ pé ẹrú yìí kọ̀ láti dárí gbèsè bíńtín ji ẹlòmíì. Ọba wá sọ pé: “Ẹrú burúkú, mo fagi lé gbogbo gbèsè yẹn fún ọ, nígbà tí o pàrọwà fún mi. Kò ha yẹ kí ìwọ, ẹ̀wẹ̀, ṣàánú fún ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú ti ṣàánú fún ọ?” (Mátíù 18:23-35) Bíi ti ọba yẹn, Jèhófà ti dárí gbèsè ńlá ji àwa náà. Kí ló yẹ kí ìfẹ́ àti àánú tí Jèhófà fi hàn sí wa mú ká ṣe?

17 Bá a ṣe ń múra sílẹ̀ dé Ìrántí Ikú Kristi, a lè bi ara wa pé: ‘Ṣé arákùnrin tàbí arábìnrin kan ti ṣẹ̀ mí? Ṣé ó ṣòro fún mi láti dárí jì í?’ Tí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, àsìkò yìí ló yẹ kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, ẹni tó “ṣe tán láti dárí jini.” (Nehemáyà 9:17; Sáàmù 86:5) Tá a bá mọrírì àánú ńláǹlà tí Jèhófà fi hàn sí wa, a ó máa fi àánú hàn sáwọn ẹlòmíì, a ó sì máa dárí jì wọ́n látọkàn wá. Tá ò bá nífẹ̀ẹ́ àwọn ará wa, tí a kì í sì í dárí jì wọ́n, a ò lè retí pé kí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa kó sì máa dárí jì wá. (Mátíù 6:14, 15) Tá a bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá, ìyẹn ò sọ pé nǹkan tí wọ́n ṣe ò dùn wá, àmọ́ ó máa jẹ́ ká ní ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀.

18. Báwo ni ìfẹ́ tí arábìnrin kan ní sí Ọlọ́run ṣe mú kó fara da ìwà àìpé arábìnrin míì?

18 Ó lè má rọrùn fún wa láti fara da kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa. (Ka Éfésù 4:32; Kólósè 3:13, 14.) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Lily nìyẹn.[1] (Wo àfikún àlàyé.) Ó ran opó kan tó ń jẹ́ Carol lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó máa ń wa Carol lọ síbikíbi tó bá fẹ́ lọ, ó máa ń lọ bá a ra nǹkan lọ́jà, ó sì máa ń bá a ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan míì. Láìka gbogbo iṣẹ́ tí Lily ń ṣe fún Carol sí, ṣe ni Carol máa ń ṣàríwísí ṣáá, kódà nígbà míì, kì í rọrùn láti ràn án lọ́wọ́. Àmọ́, ibi tí Carol dáa sí ni Lily máa ń wò, ó sì ran Carol lọ́wọ́ fún ọdún bíi mélòó kan kó tó di pé Carol ṣàìsàn tó sì kú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún Lily láti ran Carol lọ́wọ́, ó sọ pé: “Mò ń fojú sọ́nà láti rí Carol nígbà àjíǹde. Màá fẹ́ mọ̀ ọ́n nígbà tó bá di ẹni pípé.” Ó dájú nígbà náà pé ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa máa mú ká fara da kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa, ká sì máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí gbogbo èèyàn máa di pípé.

19. Kí ni ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe’ tí Ọlọ́run fún wa máa mú kó o ṣe?

19 Jèhófà ti fún wa ní ‘ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ aláìṣeé-ṣàpèjúwe’ lóòótọ́. Ẹ jẹ́ kí gbogbo wa máa ṣe ohun tó fi hàn pé a mọrírì ẹ̀bùn yìí. Ìgbà Ìrántí Ikú Kristi ló dára jù lọ fún wa láti ronú lórí gbogbo nǹkan tí Jèhófà àti Jésù ti ṣe fún wa. Ǹjẹ́ kí ìfẹ́ tí Jèhófà àti Jésù ní sí wa mú ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù pẹ́kípẹ́kí, ká máa fìfẹ́ hàn sáwọn ará wa, ká sì máa dárí jì wọ́n látọkàn wá.

^ [1] (ìpínrọ̀ 18) A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

ÀLÀYÉ Ọ̀RỌ̀

  • Mú Lọ́ranyàn: Bí ohun kan bá wù wá láti ṣe torí a mọ̀ pé ohun tó yẹ ká ṣe ni, tó bá wá di ọ̀ranyàn pé ká ṣerú nǹkan bẹ́ẹ̀, a máa ṣe é. Ṣíṣe àṣàrò lórí ẹ̀bùn ìràpadà tí Jèhófà fìfẹ́ pèsè fún wa mú ká lóye bí Ọlọ́run ṣe nífẹ̀ẹ́ wa tó. Ìyẹn ló wá mú ká mọrírì ẹ̀bùn náà, ká sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù pẹ́kípẹ́kí

  • Ìgbà Ìrántí Ikú Kristi: Ìgbà Ìrántí Ikú Kristi àti àkókò díẹ̀ ṣáájú àti lẹ́yìn ìgbà náà. Nígbà míì, ó lè jẹ́ oṣù March, April àti May

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́