ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 9/09 ojú ìwé 4
  • Lo Bíbélì Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lo Bíbélì Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Rántí Àwọn Ẹsẹ Bíbélì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Apá Kẹta: Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ṣó O Máa Ń Ṣalágbàwí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Fúnni Níṣìírí Láti Lo Bíbélì
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
km 9/09 ojú ìwé 4

Lo Bíbélì Lọ́nà Tó Gbéṣẹ́

1. Kí nìdí tí Bíbélì fi ṣe pàtàkì gan-an?

1 Bá a bá ń lo Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí lọ́nà tó gbéṣẹ́, a ó lè fí òótọ́ kọ́ni lọ́nà tó ṣe kedere a ó sì lè túdìí àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà èké táwọn èèyàn ń gbé lárugẹ.—2 Tím. 2:15; 1 Pét. 3:15.

2. Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣe lè máa tètè wá ẹsẹ Ìwé Mímọ́ rí?

2 Túbọ̀ Mọ Bíbélì Dáadáa: Bá a bá ṣe ń lo irinṣẹ́ kan lemọ́lemọ́ tó, bẹ́ẹ̀ la ó ṣe máa mọwọ́ rẹ̀ tó. Tó o bá ka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin á jẹ́ kó o ní òye tó pọ̀ nípa ohun tí Bíbélì dá lé. Èyí á tún jẹ́ kó o lè rántí orí àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́, á sì tún rọrùn fún ẹ láti wá wọn rí. Bó o ṣe túbọ̀ ń mọ ohun tó wà nínú Ìwé Mímọ́ dáadáa, wàá lè fìtara àti ìdánilójú sọ̀rọ̀ nígbà tó o bá ń wàásù láìjẹ́-bí-àṣà àti lóde ẹ̀rí.—1 Tẹs. 1:5.

3, 4. (a) Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà túbọ̀ mọ Bíbélì dáadáa? (b) Ǹjẹ́ o ti ṣe àwọn nǹkan míì tó ti jẹ́ kó o túbọ̀ mọ Ìwé Mímọ́ dáadáa?

3 Nígbà tó o bá wà nípàdé ìjọ jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ṣí Bíbélì kó o sì máa fojú bá ẹsẹ tí wọ́n ń kà lọ. Nígbà tó o bá ń dá kẹ́kọ̀ọ́ àti nígbà tó o bá ń múra àwọn ìpàdé ìjọ sílẹ̀, ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a bá tọ́ka sí kó o sì ronú jinlẹ̀ nípa bó o ṣe lè lò ó. Ọ̀pọ̀ ló ti rí i pé tí wọ́n bá ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run látinú Bíbélì fúnra rẹ̀, dípò kí wọ́n máa kà á látorí kọ̀ǹpútà tàbí látorí ìwé kan tí wọ́n tẹ̀ ẹ́ sí, ó máa ń rọrùn fún wọn láti wá wọn rí nígbà tí wọ́n bá wà lóde ẹ̀rí.—Jòh. 14:26.

4 Àwọn ìdílé kan ti ṣètò àkókò tí wọ́n á máa lò láti há àwọn ẹsẹ Bíbélì kan sórí. Wọ́n lè lo àwọn káàdì kéékèèké tí wọ́n ti kọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan sí apá kan rẹ̀, tí wọ́n sì kọ ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà sí òdì kejì káàdì náà. Wọ́n máa ń fi dánra wò láàárín ara wọn bóyá wọ́n lè sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ orí káàdì náà lórí tàbí ibí tá a ti lè rí i nínú Bíbélì. A tún máa mọ Bíbélì lò lọ́nà tó gbéṣẹ́ bá a bá ń múra ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a lè lò sílẹ̀ àti bá a ṣe lè dá àwọn tí kò fẹ́ gbọ́rọ̀ wa lóhùn tàbí bá a ṣe lè fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè tí wọ́n bá bi wá.

5. Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ mọ Bíbélì lò lọ́nà tó gbéṣẹ́?

5 Kò sí ìwé míì tó ṣeyebíye bíi Bíbélì. Inú rẹ̀ nìkan lèèyàn ti lè ráwọn ọ̀rọ̀ tó lè sọ àwọn èèyàn di “ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà.” (2 Tím. 3:15) Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa ò ti mọ ìṣura iyebíye tó wà nínú Bíbélì, ó yẹ ká túbọ̀ mọ bá a ṣe lè fàwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì hàn wọ́n lọ́nà tó gbéṣẹ́.—Òwe 2:1-5.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́