Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
FEBRUARY 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 47-51
“Jèhófà Máa Bù Kún Wa Tá A Bá Ṣègbọràn Sí I”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kejì
49:6—Báwo ni Mèsáyà ṣe jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìkan ló ti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú Jésù fi èyí hàn. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 49:6 ṣẹ sí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù lára. (Ìṣe 13:46, 47) Lóde òní, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, tí ogunlọ́gọ̀ ńlá olùjọsìn Ọlọ́run ń ṣèrànlọ́wọ́ fún, jẹ́ “ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè” ní ti pé wọ́n ń la ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yé àwọn èèyàn “títí dé ìkángun ilẹ̀ ayé.”—Mátíù 24:14; 28:19,20.
it-1 643 ¶4-5
Ìkọ̀sílẹ̀
Ìkọ̀sílẹ̀ Ìṣàpẹẹrẹ. Àwọn ibì kan wà tí Ìwé Mímọ́ ti lo àjọṣe lọ́kọláya lọ́nà àpèjúwe. (Ais 54:1, 5, 6; 62:1-6) Bákan náà, Bíbélì tún lo ìkọ̀sílẹ̀ tàbí lílé ìyàwó ẹni lọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ.—Jer 3:8.
Lọ́dún 607 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Bábílónì ṣẹ́gun ìjọba Júdà, wọ́n sì pa Jerúsálẹ́mù run. Wọ́n sì kó àwọn olùgbé ibẹ̀ nígbèkùn lọ sí ilẹ̀ Bábílónì. Ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú àkókò yìí ni Jèhófà ti sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn Júù tí wọ́n máa kó nígbèkùn pé: “Ibo wá ni ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ ìyá yín wà, ẹni tí mo rán lọ?” (Ais 50:1) Jèhófà lé “ìyá” wọn, ìyẹn orílẹ̀-èdè náà lápapọ̀ lọ. Kì í ṣe pé ńṣe ni Jèhófà da májẹ̀mú tó bá wọn dá, tó sì wá ṣètò láti kọ̀ wọ́n sílẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà kọ̀ wọ́n sílẹ̀ nítorí ìwà àìtọ́ tí wọ́n hù sí májẹ̀mú Òfin. Ṣùgbọ́n, àwọn tó ṣẹ́kù lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ronú pìwà dà, wọ́n sì gbàdúrà pé kí Jèhófà tẹ́wọ́ gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí ọkọ olówó orí wọn, kó sì dá wọn pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn. Nítorí orúkọ Jèhófà, ó dá àwọn èèyàn rẹ̀ pa dà sí ìlú wọn, bó ti ṣèlérí. Èyí jẹ́ lọ́dún 537 Ṣáájú Sànmánì Kristẹni, lẹ́yìn tí ìlú wọn ti wà ní ahoro fún àádọ́rin [70] ọdún.—Sm 137:1-9; wo MARRIAGE.
FEBRUARY 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 52-57
“Kristi Jìyà fún Wa”
Ìránṣẹ́ Jèhófà Tí Wọ́n ‘Gún Nítorí Ìrélànàkọjá Wa’
“Wọ́n “Tẹ́ńbẹ́lú Rẹ̀” Wọ́n sì “Kà Á Sí Aláìjámọ́ Nǹkan Kan” ”
3 Ka Aísáyà 53:3. Nǹkan ńláǹlà ni Ọmọ Ọlọ́run yááfì o, bó ṣe fi ẹ̀gbẹ́ Baba rẹ̀ tó ti ń fi ìdùnnú ṣiṣẹ́ lọ́run sílẹ̀, tó wá sáyé láti wá fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ láti lè gba aráyé là kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú! (Fílí. 2:5-8) Ẹbọ tó fẹ̀mí rẹ̀ rú yìí ló jẹ́ kí aráyé lè rí ojúlówó ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà, èyí táwọn ẹbọ tí wọ́n ń fi ẹran rú lábẹ́ Òfin Mósè ṣàpẹẹrẹ rẹ̀. (Héb. 10:1-4) Nígbà náà, ṣebí àwọn èèyàn ì bá máa jó kí wọ́n sì máa yọ̀ mọ́ ọn ni nígbà tó dé sáyé, pàápàá àwọn Júù tó jẹ́ pé ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń retí Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Jòh. 6:14) Àmọ́ kàkà káwọn Júù ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n “tẹ́ńbẹ́lú” Kristi, tí wọ́n sì “kà á sí aláìjámọ́ nǹkan kan,” bí Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé: “Ó wá sí ilé òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tirẹ̀ kò gbà á wọlé.” (Jòh. 1:11) Àpọ́sítélì Pétérù wá sọ fáwọn Júù pé: “Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa, ti ṣe Ìránṣẹ́ rẹ̀, Jésù lógo, ẹni tí ẹ̀yin, ní tiyín, fà léni lọ́wọ́ tí ẹ sì sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní ojú Pílátù, nígbà tí ó ti pinnu láti tú u sílẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni, ẹ sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú ẹni mímọ́ àti olódodo yẹn.”—Ìṣe 3:13, 14.
4 Aísáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé Jésù yóò ní láti ‘di ojúlùmọ̀ àìsàn.’ Òótọ́ ni pé nígbà tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ láyé, a rí ìgbà tó rẹ̀ ẹ́, àmọ́ kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé ó ṣàìsàn. (Jòh. 4:6) Àmọ́ ṣá, ó mọ bí àìsàn ṣe máa ń rí lára àwọn tó wàásù fún. Àánú wọn ṣe é, ó sì wo àwọn púpọ̀ sàn. (Máàkù 1:32-34) Jésù wá tipa bẹ́ẹ̀ mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ, èyí tó sọ pé: “Lóòótọ́, àwọn àìsàn wa ni òun fúnra rẹ̀ gbé; àti pé ní ti ìrora wa, ó rù wọ́n.”—Aísá. 53:4a; Mát. 8:16, 17.
Ó Dà Bí “Ẹni Tí Ọlọ́run Kọlù”
5 Ka Aísáyà 53:4b. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn tí àwọn àti Jésù jọ gbé láyé kò mọ ìdí tó fi ní láti jìyà kó sì kú. Wọ́n gbà pé ṣe ni Ọlọ́run jẹ Jésù níyà, bíi pé ó mú kí àrùn burúkú kan máa yọ ọ́ lẹ́nu. (Mát. 27:38-44) Ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì làwọn Júù fi kan Jésù. (Máàkù 14:61-64; Jòh. 10:33) Láìsí àní-àní, Jésù kì í ṣe ẹlẹ́ṣẹ̀ tàbí asọ̀rọ̀-òdì. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù Ìránṣẹ́ Jèhófà nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ gan-an débi pé, èrò pé ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run ni wọ́n máa fi kan òun tí wọ́n á sì tìtorí ẹ̀ pa òun ti ní láti fi kún ìrora rẹ̀. Síbẹ̀, ó fínnúfíndọ̀ gbà pé kí ìfẹ́ Jèhófà di ṣíṣe.—Mát. 26:39.
Ìránṣẹ́ Jèhófà Tí Wọ́n ‘Gún Nítorí Ìrélànàkọjá Wa’
“A Ń Mú Un Bọ̀ Gẹ́gẹ́ Bí Àgùntàn fún Ìfikúpa”
10 Ka Aísáyà 53:7, 8. Nígbà tí Jòhánù Olùbatisí rí Jésù tó ń bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán, ó ní: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!” (Jòh. 1:29) Nígbà tí Jòhánù pe Jésù ní Ọ̀dọ́ Àgùntàn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ni ọ̀rọ̀ inú ìwé Aísáyà tó sọ pé: “A ń mú un bọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn fún ìfikúpa.” (Aísá. 53:7) Aísáyà tún sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Ó tú ọkàn rẹ̀ jáde àní sí ikú.” (Aísá. 53:12) Kẹ́ ẹ sì máa wò ó o, lálẹ́ ọjọ́ tí Jésù dá Ìrántí Ikú Kristi sílẹ̀, ó fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́ ní ife wáìnì kan, ó sì sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ‘ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú’ mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.”—Mát. 26:28.
Ìránṣẹ́ Jèhófà Tí Wọ́n ‘Gún Nítorí Ìrélànàkọjá Wa’
Ìránṣẹ́ Náà “Mú Ìdúró Òdodo Wá fún Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ènìyàn”
13 Ka Aísáyà 53:11, 12. Jèhófà sọ nípa Ìránṣẹ́ tó yàn pé: “Ìránṣẹ́ mi, olódodo, yóò . . . mú ìdúró òdodo wá fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” Ọ̀nà wo ni yóò gbà ṣe èyí? A róye ọ̀nà tó gbà ṣe é ní ìparí ẹsẹ kejìlá. Ó sọ pé Ìránṣẹ́ náà “tẹ̀ síwájú láti ṣìpẹ̀ nítorí àwọn olùrélànàkọjá.” Gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù la bí gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ṣẹ̀, ìyẹn “olùrélànàkọjá.” Nítorí náà, gbogbo wọn pátá ló ń gba “owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san,” ìyẹn ikú. (Róòmù 5:12; 6:23) Ó wá pọn dandan káwa èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ rí ọ̀nà láti pa dà bá Jèhófà rẹ́. Ọ̀nà tó fa kíki ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà tó wà ní orí kẹtàléláàádọ́ta gbà ṣàpèjúwe bí Jésù ṣe “ṣìpẹ̀,” tàbí bẹ̀bẹ̀, fún ìran èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó ní: “Ìnàlẹ́gba tí a pète fún àlàáfíà wa ń bẹ lára rẹ̀, àti nítorí àwọn ọgbẹ́ rẹ̀ ni ìmúniláradá fi wà fún wa.”—Aísá. 53:5.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Ìṣàpẹẹrẹ” Tó Ṣe Pàtàkì Gan-an fún Wa
Ta wá ni Sárà, “òmìnira obìnrin” àti Ísákì ọmọ rẹ̀ dúró fún? Pọ́ọ̀lù fi hàn pé Sárà tó jẹ́ “àgàn” dúró fún ìyàwó Ọlọ́run, ìyẹn apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà. Obìnrin ti ọ̀run yìí jẹ́ àgàn ní ti pé kí Jésù tó wá sáyé, obìnrin ìṣàpẹẹrẹ yìí kò ní “ọmọ” kankan tá a fẹ̀mí yàn lórí ilẹ̀ ayé. (Gálátíà 4:27; Aísáyà 54:1-6) Àmọ́, ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn èèyàn kan lọ́kùnrin lóbìnrin. Nípa báyìí, wọ́n di àtúnbí èyí tó mú kí wọ́n di ọmọ obìnrin ti ọ̀run yìí. Ọlọ́run gba àwọn ọmọ tí apá ti òkè ọ̀run lára ètò Jèhófà bí yìí ṣọmọ, wọ́n sì di ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Jésù Kristi lábẹ́ májẹ̀mú tuntun. (Róòmù 8:15-17) Abájọ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tí í ṣe ọ̀kan lára àwọn ọmọ yìí fi sọ nínú ìwé tó kọ pé: “Jerúsálẹ́mù ti òkè jẹ́ òmìnira, òun sì ni ìyá wa.”—Gálátíà 4:26.
Ní Ojúlówó Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀
Ẹni Tí Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Rẹ̀ Ga Jù Lọ
3 Atóbilọ́lá àti ọ̀gá ògo ni Jèhófà, síbẹ̀ “ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.” (2 Kíróníkà 16:9) Kí ni Jèhófà máa ń ṣe nígbà tó bá rí i tí àwọn olùjọsìn rẹ̀ táwọn èèyàn kò fi bẹ́ẹ̀ kà sí bá rẹ̀wẹ̀sì nítorí onírúurú ìṣòro? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà “ń gbé” pẹ̀lú irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀, èyí tó túmọ̀ sí pé ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ wà pẹ̀lú wọn nígbà gbogbo “láti mú ẹ̀mí àwọn ẹni rírẹlẹ̀ sọ jí àti láti mú ọkàn-àyà àwọn tí a tẹ̀ rẹ́ sọ jí.” (Aísáyà 57:15) Ìyẹn ló máa jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fáwọn olùjọsìn rẹ̀ tó ti fún lókun láti tún bẹ̀rẹ̀ sí fi ìdùnnú sìn ín. Ọlọ́run mà ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ o!
FEBRUARY 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 58-62
“Pòkìkí Ọdún Ìtẹ́wọ́gbà Níhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà”
Àwọn “Olùgbé Fún Ìgbà Díẹ̀” Ń Sin Jèhófà Ní Ìṣọ̀kan
5 Ẹnì kan lè máa ṣe kàyéfì nípa ìtumọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Aísáyà orí 61, tó ṣì ń ní ìmúṣẹ nínú ìjọ Kristẹni. Ẹsẹ 6 sọ nípa àwọn tí yóò máa sìn gẹ́gẹ́ bí “àlùfáà Jèhófà.” Ṣùgbọ́n ẹsẹ 5 sọ pé “àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” á máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn “àlùfáà.” Kí nìdí tá a fi pe àwọn kan ní ọmọ ilẹ̀ òkèèrè?
6 Lónìí, àwọn “àlùfáà Jèhófà” ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí wọ́n ní ipa nínú “àjíǹde èkíní” tí “wọn yóò jẹ́ àlùfáà Ọlọ́run àti ti Kristi, tí wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀ fún ẹgbẹ̀rún ọdún.” (Ìṣí. 20:6) Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni adúróṣinṣin mí ì tún wà tí wọ́n ní ìrètí láti gbé nínú ayé tuntun. Àwọn Kristẹni yìí ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn tí yóò máa gbé ní ọ̀run. Ṣùgbọ́n nítorí pé wọn kò sí lára “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” ńṣe ni wọ́n dà bí “ọmọ ilẹ̀ òkèèrè” tàbí àjèjì. Tayọ̀tayọ̀ ni wọ́n fi ń kọ́wọ́ ti “àwọn àlùfáà Jèhófà,” tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú wọn gẹ́gẹ́ bí “àgbẹ̀” àti “olùrẹ́wọ́ àjàrà,” nínú iṣẹ́ ìkórè náà. Wọ́n ń wàásù fún àwọn èèyàn, wọ́n sì ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́nà yìí, wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹni àmì òróró láti bọlá fún Ọlọ́run. Àwọn ẹni àmì òróró àti “àwọn àgùntàn mìíràn” jùmọ̀ ń wá àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n ń ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa sin Ọlọ́run títí láé.—Jòh. 10:16.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kejì
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
61:8, 9—Kí ni “májẹ̀mú tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin,” àwọn wo sì ni “àwọn ọmọ”? Májẹ̀mú yìí ni májẹ̀mú tuntun tí Jèhófà bá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dá. “Àwọn ọmọ” ni “àwọn àgùntàn mìíràn,” ìyẹn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí wọ́n ń tẹ̀ lé ohun táwọn ẹni àmì òróró ń sọ.—Jòhánù 10:16.
FEBRUARY 27–MARCH 5
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | AÍSÁYÀ 63-66
“Ọ̀run Tuntun àti Ayé Tuntun Máa Mú Ká Láyọ̀ Tó Kọ Yọyọ”
Àlàáfíà Yóò Wà Fún Ẹgbẹ̀rún Ọdún Àti Títí Láé!
‘WỌN YÓÒ KỌ́ ILÉ, WỌN YÓÒ SÌ GBIN ỌGBÀ ÀJÀRÀ’
4 Ta ni kò ní wù pé kó ní ilé tirẹ̀, níbi tí òun àti ìdílé rẹ̀ lè forí pa mọ́ sí tí ọkàn wọn á sì balẹ̀? Àmọ́ lóde òní, kò rọrùn rárá láti rí ilé tó dára gbé. Àwọn ìlú ńláńlá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kún àkúnya. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló jẹ́ pé àwọn ilé kẹ́jẹ́bú ni wọ́n ń gbé láwọn àdúgbò táwọn akúṣẹ̀ẹ́ pọ̀ sí táwọn ilé tó wà níbẹ̀ kò sì bójú mu rárá. Fún irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀, àlá tí kò lè ṣẹ ni ọ̀rọ̀ pé wọ́n máa ní ilé tiwọn.
5 Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo èèyàn pátá ló máa ní ilé tirẹ̀, torí pé Ọlọ́run mú kí wòlí ì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.” (Aísá. 65:21) Ṣùgbọ́n, ọ̀rọ̀ pé gbogbo èèyàn máa ní ilé tirẹ̀ nìkan kọ́ ni ohun tá à ń retí. Torí pé, lóde òní pàápàá, àwọn kan wà tó ń gbé nínú ilé ara wọn, a sì rí àwọn díẹ̀ tó ń gbé nínú ilé aláruru tàbí tí wọ́n kọ́lé sórí ilẹ̀ tó fẹ̀ gan-an. Ṣùgbọ́n, ọkàn irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ kì í sábàá balẹ̀ torí pé ìṣòro ìṣúnná owó lè mú kí ilé náà bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n máa bẹ̀rù pé àwọn adigunjalè tàbí àwọn mí ì tó burú ju ìyẹn lọ lè wọlé wá bá àwọn. Àmọ́, gbogbo nǹkan máa yàtọ̀ pátápátá nínú Ìjọba Ọlọ́run. Wòlí ì Míkà sọ pé: “Wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà. 4:4.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kejì
63:5—Báwo ni ìhónú Ọlọ́run ṣe ń tì í lẹ́yìn? Ọlọ́run kì í ṣẹni tó máa ń bínú sódì, ìyẹn túmọ̀ sí pé ìbínú òdodo ni ìbínú rẹ̀ máa ń jẹ́. Ìhónú rẹ̀ máa ń tì í lẹ́yìn láti mú ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ṣẹ, ó sì máa ń jẹ́ kó gbé ìgbésẹ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Jẹ́ Kí Amọ̀kòkò Tí Kò Lẹ́gbẹ́ Náà Mọ Ẹ́
JÈHÓFÀ LÁṢẸ LÓRÍ WA BÍ AMỌ̀KÒKÒ ṢE LÁṢẸ LÓRÍ AMỌ̀
3 Bíbélì fi Jèhófà wé amọ̀kòkò torí pé ó láṣẹ lórí àwa èèyàn, ó sì lè darí àwọn orílẹ̀-èdè bó ṣe fẹ́. Aísáyà 64:8 sọ pé “Wàyí o, Jèhófà, ìwọ ni Baba wa. Àwa ni amọ̀, ìwọ sì ni Ẹni tí ó mọ wá; gbogbo wa jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” Ohun tó bá wu amọ̀kòkò ló lè fi amọ̀ mọ. Kì í ṣe amọ̀ ló máa sọ ohun tí amọ̀kòkò máa fòun mọ. Bákan náà làwa èèyàn rí lọ́wọ́ Ọlọ́run. A ò lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ fún Ọlọ́run pé báyìí ni kí ó ṣe mọ wá, gẹ́gẹ́ bí amọ̀ kò ṣe lè sọ ohun tí amọ̀kòkò máa fi òun mọ.—Ka Jeremáyà 18:1-6.
4 Jèhófà ṣe mọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́. Àmọ́, ìyàtọ̀ wo ló wà láàárín amọ̀kòkò àti Jèhófà? Ohun kan ni pé Jèhófà fún àwa èèyàn lómìnira láti ṣe ohun tó wù wá, ó sì fún àwọn orílẹ̀-èdè náà láǹfààní láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Kì í ṣe pé ó dá àwọn kan lẹ́ni rere, nígbà tó jẹ́ pé ó dá àwọn mí ì lẹ́ni burúkú. Bákan náà, kì í fipá mú àwọn èèyàn láti ṣe ohun tó fẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa èèyàn la máa yàn bóyá a máa fẹ́ kí Jèhófà Ẹlẹ́dàá mọ wá, ìyẹn ni pé kó sọ wá di èèyàn tó dára lójú rẹ̀.—Ka Jeremáyà 18:7-10.
5 Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ò gbà kí Jèhófà mọ òun ńkọ́? Báwo ni Jèhófà ṣe máa lo àṣẹ lórí onítọ̀hún? Ẹ jẹ́ ká wò ó báyìí ná: Ká sọ pé amọ̀kòkò kan rí i pé kò ṣeé ṣe láti fi amọ̀ mọ ohun kan tí òun ní lọ́kàn, ó lè fi amọ̀ náà mọ nǹkan mí ì tàbí kó dà á nù. Tírú nǹkan bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀, ó ní láti jẹ́ pé ọwọ́ amọ̀kòkò ni àṣìṣe yẹn ti wá. Àmọ́ Jèhófà kì í ṣàṣìṣe ní tiẹ̀. (Diu. 32:4) Tó bá ṣẹlẹ̀ pé Jèhófà pa ẹnì kan tì, onítọ̀hún ló fà á. Ohun tí ẹnì kan bá ṣe nígbà tí Jèhófà bá ń tọ́ ọ sọ́nà ló máa pinnu ohun tó máa fi irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ. Tó bá ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ó máa wúlò fún un. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jẹ́ “ohun èlò àánú,” tí Ọlọ́run sọ di ohun èlò fún “ìlò ọlọ́lá.” Àmọ́, àwọn tí kò gbà kí Jèhófà tọ́ wọn sọ́nà di “àwọn ohun èlò ìrunú tí a mú yẹ fún ìparun.”—Róòmù 9:19-23.