ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Gálátíà 4
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Gálátíà

      • Ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́, ọmọ ni yín (1-7)

      • Ọ̀rọ̀ àwọn ará Gálátíà jẹ Pọ́ọ̀lù lógún (8-20)

      • Hágárì àti Sérà: májẹ̀mú méjì (21-31)

        • Jerúsálẹ́mù ti òkè ní òmìnira, òun sì ni ìyá wa (26)

Gálátíà 4:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2008, ojú ìwé 21

Gálátíà 4:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2008, ojú ìwé 21

Gálátíà 4:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ ayé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Kol 2:8, 20-22

Gálátíà 4:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 1:14; Heb 2:14
  • +Mt 5:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/1998, ojú ìwé 13-14

Gálátíà 4:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 7:23; Ga 3:13
  • +Jo 1:12; Ro 8:23

Gálátíà 4:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ọ̀rọ̀ Hébérù tàbí Árámáíkì tó túmọ̀ sí “Bàbá!”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:26
  • +Ro 5:5
  • +Ro 8:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2009, ojú ìwé 13

Gálátíà 4:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 8:17; Ga 3:29; Ef 1:13, 14

Gálátíà 4:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “akúrẹtẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 8:3; Heb 7:18, 19
  • +Kol 2:20-22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    7/2018, ojú ìwé 8-9

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2013, ojú ìwé 13-14

Gálátíà 4:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Kol 2:16

Gálátíà 4:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ga 1:14

Gálátíà 4:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 89

Gálátíà 4:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tutọ́ sí mi lára.”

Gálátíà 4:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 23:5; Ga 6:11

Gálátíà 4:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2001, ojú ìwé 32

Gálátíà 4:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “títí Kristi yóò fi di odindi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 4:15; 1Tẹ 2:11; Flm 10

Gálátíà 4:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 16:15
  • +Jẹ 21:2, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1992, ojú ìwé 14

Gálátíà 4:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 16:1, 2
  • +Jẹ 17:15, 16

Gálátíà 4:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:20; 24:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/15/2014, ojú ìwé 10

    3/15/1992, ojú ìwé 14

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 75-80

Gálátíà 4:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/15/1992, ojú ìwé 14-15

Gálátíà 4:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2015, ojú ìwé 17

    3/15/1992, ojú ìwé 14-15

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 177-178

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 216

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 76-78, 90-92

Gálátíà 4:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 54:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2006, ojú ìwé 11

    8/1/1995, ojú ìwé 11

Gálátíà 4:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 9:8; Ga 3:29

Gálátíà 4:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 21:9
  • +Ga 5:11; 2Ti 3:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2006, ojú ìwé 11-12

    8/15/2001, ojú ìwé 26

Gálátíà 4:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 21:10

Gálátíà 4:31

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2015, ojú ìwé 17

Àwọn míì

Gál. 4:3Kol 2:8, 20-22
Gál. 4:4Jo 1:14; Heb 2:14
Gál. 4:4Mt 5:17
Gál. 4:51Kọ 7:23; Ga 3:13
Gál. 4:5Jo 1:12; Ro 8:23
Gál. 4:6Ro 8:15
Gál. 4:6Jo 14:26
Gál. 4:6Ro 5:5
Gál. 4:7Ro 8:17; Ga 3:29; Ef 1:13, 14
Gál. 4:9Ro 8:3; Heb 7:18, 19
Gál. 4:9Kol 2:20-22
Gál. 4:10Kol 2:16
Gál. 4:12Ga 1:14
Gál. 4:15Iṣe 23:5; Ga 6:11
Gál. 4:191Kọ 4:15; 1Tẹ 2:11; Flm 10
Gál. 4:22Jẹ 16:15
Gál. 4:22Jẹ 21:2, 3
Gál. 4:23Jẹ 16:1, 2
Gál. 4:23Jẹ 17:15, 16
Gál. 4:24Ẹk 19:20; 24:12
Gál. 4:25Ẹk 19:18
Gál. 4:27Ais 54:1
Gál. 4:28Ro 9:8; Ga 3:29
Gál. 4:29Jẹ 21:9
Gál. 4:29Ga 5:11; 2Ti 3:12
Gál. 4:30Jẹ 21:10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Gálátíà 4:1-31

Sí Àwọn Ará Gálátíà

4 Ní báyìí, mo sọ pé nígbà tí ajogún náà bá ṣì jẹ́ ọmọdé, kò yàtọ̀ sí ẹrú, bó tilẹ̀ jẹ́ olúwa ohun gbogbo, 2 àmọ́ ó wà lábẹ́ àwọn alábòójútó àti àwọn ìríjú títí di ọjọ́ tí bàbá rẹ̀ ti yàn. 3 Bákan náà, ní tiwa, nígbà tí a wà lọ́mọdé, àwọn èrò àti ìṣe ayé* ń mú wa lẹ́rú.+ 4 Àmọ́ nígbà tí àkókò tó, Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀, ẹni tí obìnrin bí,+ tí ó sì wà lábẹ́ òfin,+ 5 kí ó lè ra àwọn tó wà lábẹ́ òfin,+ kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ tú wọn sílẹ̀, kí a lè rí ìsọdọmọ gbà.+

6 Nítorí pé ẹ jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run ti rán ẹ̀mí+ Ọmọ rẹ̀ sínú ọkàn wa,+ ó sì ń ké jáde pé: “Ábà,* Bàbá!”+ 7 Torí náà, ẹ kì í ṣe ẹrú mọ́, ọmọ ni yín; tí ẹ bá sì jẹ́ ọmọ, ẹ tún jẹ́ ajogún nípasẹ̀ Ọlọ́run.+

8 Síbẹ̀, nígbà tí ẹ kò mọ Ọlọ́run, ẹ̀ ń ṣẹrú àwọn tí kì í ṣe ọlọ́run. 9 Àmọ́ ní báyìí tí ẹ ti mọ Ọlọ́run, tàbí ká kúkú sọ pé, tí Ọlọ́run ti mọ̀ yín, kí ló dé tí ẹ tún ń pa dà sí àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ tó jẹ́ aláìlera+ àti aláìníláárí,* tí ẹ sì tún fẹ́ ṣẹrú wọn?+ 10 Ẹ̀ ń pa àwọn ọjọ́ àti oṣù+ àti àsìkò àti ọdún mọ́ délẹ̀délẹ̀. 11 Ẹ̀rù ń bà mí nítorí yín, kó má lọ jẹ́ pé lásán ni gbogbo wàhálà tí mo ṣe lórí yín.

12 Ẹ̀yin ará, mo bẹ̀ yín, ẹ dà bí èmi, nítorí èmi náà ti máa ń ṣe bíi tiyín tẹ́lẹ̀.+ Ẹ ò ṣe àìtọ́ kankan sí mi. 13 Ṣùgbọ́n ẹ mọ̀ pé àìsàn tó ṣe mí ló jẹ́ kí n kọ́kọ́ láǹfààní láti kéde ìhìn rere fún yín. 14 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àdánwò ni àìlera mi jẹ́ fún yín, ẹ ò fojú pa mí rẹ́, ẹ ò sì kórìíra mi;* àmọ́ ṣe lẹ gbà mí bí áńgẹ́lì Ọlọ́run, bíi Kristi Jésù. 15 Ibo ni ayọ̀ tí ẹ ní tẹ́lẹ̀ wà? Nítorí mo jẹ́rìí yín pé, ká ló ṣeé ṣe ni, ẹ lè yọ ojú yín fún mi.+ 16 Ṣé mo ti wá di ọ̀tá yín torí pé mo sọ òótọ́ fún yín ni? 17 Àwọn kan ń wá ọ̀nà lójú méjèèjì láti fà yín sábẹ́ ara wọn, àmọ́ kì í ṣe fún ire yín; ṣe ni wọ́n fẹ́ fà yín kúrò lọ́dọ̀ mi, kó lè máa yá yín lára láti tẹ̀ lé wọn. 18 Síbẹ̀, ó dáa tí ẹnì kan bá ń wá yín lójú méjèèjì fún ire yín, tí kì í ṣe nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín nìkan, 19 ẹ̀yin ọmọ mi kéékèèké,+ tí mo tún tìtorí yín wà nínú ìrora ìbímọ títí ẹ ó fi lè gbé Kristi yọ* nínú yín. 20 Ó wù mí kí n wà lọ́dọ̀ yín ní báyìí, kí n sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó yàtọ̀, torí ọkàn mi ń dààmú nítorí yín.

21 Ẹ sọ fún mi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ wà lábẹ́ òfin, Ṣé ẹ ò gbọ́ ohun tí Òfin sọ ni? 22 Bí àpẹẹrẹ, ó wà lákọsílẹ̀ pé Ábúráhámù ní ọmọkùnrin méjì, ọ̀kan látọ̀dọ̀ ìránṣẹ́bìnrin,+ èkejì látọ̀dọ̀ obìnrin tó lómìnira;+ 23 àmọ́ èyí tí ìránṣẹ́bìnrin bí jẹ́ lọ́nà ti ẹ̀dá,*+ èyí tí obìnrin tó lómìnira sì bí jẹ́ nípasẹ̀ ìlérí.+ 24 A lè fi àwọn nǹkan yìí ṣe àkàwé; àwọn obìnrin yìí dúró fún májẹ̀mú méjì, èyí tó wá láti Òkè Sínáì,+ tó ń bí ọmọ fún ìsìnrú, ni Hágárì. 25 Hágárì dúró fún Sínáì,+ òkè kan ní Arébíà, ó sì ṣe rẹ́gí pẹ̀lú Jerúsálẹ́mù ti òní, torí ó ń ṣẹrú pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀. 26 Àmọ́ Jerúsálẹ́mù ti òkè ní òmìnira, òun sì ni ìyá wa.

27 Nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ; bú sígbe ayọ̀, ìwọ obìnrin tí kò ní ìrora ìbímọ; nítorí àwọn ọmọ obìnrin tó ti di ahoro pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”+ 28 Tóò, ẹ̀yin ará, ẹ̀yin náà jẹ́ ọmọ ìlérí bí Ísákì ṣe jẹ́.+ 29 Àmọ́ bó ṣe rí nígbà yẹn tí èyí tí a bí lọ́nà ti ẹ̀dá* bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe inúnibíni sí èyí tí a bí lọ́nà ti ẹ̀mí,+ bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí ní báyìí.+ 30 Síbẹ̀, kí ni ìwé mímọ́ sọ? “Lé ìránṣẹ́bìnrin náà àti ọmọkùnrin rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ìránṣẹ́bìnrin náà kò ní bá ọmọ obìnrin tó lómìnira pín ogún lọ́nàkọnà.”+ 31 Nítorí náà, ẹ̀yin ará, a kì í ṣe ọmọ ìránṣẹ́bìnrin, ọmọ obìnrin tó lómìnira ni wá.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́