ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb20 December ojú ìwé 8
  • Máa Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Máa Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Tó O Bá Ń Wàásù
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2005
  • Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa Lọ́nà Tí Ó Dára Jù Lọ
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Àwọn Ìwé Ìròyìn Ń Kéde Ìjọba Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ṣàṣàyàn Àwọn Àpilẹ̀kọ Láti Fi Fa Àwọn Ènìyàn Mọ́ra Lórí Ohun Tí Wọ́n Ní Ọkàn-Ìfẹ́ sí Ní Pàtó
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
Àwọn Míì
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2020
mwb20 December ojú ìwé 8
Arábìnrin kan ń fi kókó kan látinú ìwé ìròyìn ‘Jí!’ wàásù fún obìnrin kan.

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Máa Lo Àwọn Ìwé Ìròyìn Wa

Látọdún 2018, àwọn ìwé ìròyìn tá à ń fi síta máa ń sọ̀rọ̀ nípa àkòrí kan ní pàtó. Àwọn ìwé ìròyìn yìí wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Torí náà, a lè lò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A tún lè mú díẹ̀ dání tá a bá ń rìnrìn-àjò tàbí lọ sọ́jà. A kì í fàwọn ìwé ìròyìn yìí darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ ohun tó wà níbẹ̀ lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti nífẹ̀ẹ́ sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Lẹ́yìn tó o bá bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò, ka ẹsẹ Bíbélì kan, kó o sì sọ kókó kan nínú ìwé ìròyìn wa tó máa wọ ẹni náà lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ ẹni tó ní ìdílé tàbí ẹni tó ní ẹ̀dùn ọkàn lò ń bá sọ̀rọ̀, o lè sọ pé: “Mo ti ka ìwé ìròyìn kan tó sọ̀rọ̀ lórí kókó yẹn. Ṣé kí n fi hàn yín?” Tó o bá rí i pé ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí i, o lè fún un ní ìwé ìròyìn náà tàbí kó o fi ìlujá ẹ̀ ránṣẹ́ sí i, kódà kó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ máa ríra nìyẹn. Lóòótọ́, kì í ṣe bá a ṣe máa fún àwọn èèyàn níwèé ló jẹ wá lógún, síbẹ̀ tá a bá lo àwọn ìwé ìròyìn wa, a máa rí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.​—Iṣe 13:48.

2018

Àwòrán: Àwọn àkòrí iwájú ìwé ìròyìn ‘Ilé Ìṣọ́’ àti ‘Jí!’ ti ọdún 2018. 1. ‘Ṣé Bíbélì Ṣì Wúlò Lóde Òní?’ 2. ‘Kí Ló Máa Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú?’ 3. ‘Ṣé Ọlọ́run Bìkítà Nípa Rẹ?’ 4. ‘Ohun Tó Ń Fúnni Láyọ̀.’ 5. ‘Ohun Méjìlá Tó Ń Mú Kí Ìdílé Láyọ̀.’ 6. ‘Ìrànlọ́wọ́ Fún Àwọn Tó Ń Ṣọ̀fọ̀.’

2019

Àwòrán: Àwọn àkòrí iwájú ìwé ìròyìn ‘Ilé Ìṣọ́’ àti ‘Jí!’ ti ọdún 2019. 1. ‘Ta Ni Ọlọ́run?’ 2. ‘Ayé Rẹ Ṣì Máa Dùn?’ 3. ‘Ṣé Ìgbésí Ayé Ẹ̀dá Kò Jù Báyìí Náà Lọ?’ 4. ‘Ǹjẹ́ Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ọkàn Wa Máa Balẹ̀?’ 5. ‘Ohun Mẹ́fà Tó Yẹ Ká Kọ́ Àwọn Ọmọ.’ 6. ‘Ṣé Bíbélì Lè Mú Káyé Ẹ Dáa Sí I?’

2020

Àwòrán: Àwọn àkòrí iwájú ìwé ìròyìn ‘Ilé Ìṣọ́’ àti ‘Jí!’ ti ọdún 2020. 1. ‘Ibo La Ti Lè Rí Òtítọ́.’ 2. ‘Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?’ 3. ‘Ọlọ́run Ìfẹ́ Máa Bù Kún Ẹ Títí Láé.’ 4. ‘Bó O Ṣe Lè Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn.’ 5. ‘Kí Nìdí Tí Ìyà Fi Ń Jẹ Aráyé.’ 6. ‘Ṣé Ìkórìíra Lè Dópin?’

Kí ló máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn jù ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́