Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí
April-June 2007
Kí Ni Ìwàkiwà Tó Gbayé Kan Yìí Túmọ̀ Sí?
Ìwà rere ti ń jó rẹ̀yìn kárí ayé báyìí o. Ìgbà wo gan-an ni ìjórẹ̀yìn náà bẹ̀rẹ̀ sí i peléke, kí ló sì fà á tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ibo gan-an lọ̀rọ̀ ilé ayé wa yìí ń lọ?
4 Bí Ìwà Rere Ṣe Ṣàdédé Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Jó Rẹ̀yìn
21 Mi Ò Ṣi Iṣẹ́ Tí Màá Ṣe Láyé Mi Yàn
30 Kí Ló Fà Á Tí Mo FI Máa Ń Dákú?
31 Wíwo Ayé
32 “Ohun Èlò Àtàtà Tó Ṣeé Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́!”
Kí Ló Dé Tí Wọ́n Ń Fi Mí Wé Àwọn Ẹlòmíì? 11
Kí ló fà á tó fi máa ń dun èèyàn wọra bí wọ́n bá ń fi í wé ẹlòmíì? Ṣó lóore tírú àfiwé bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe fúnni?
Bí Ọkùnrin Tàbí Obìnrin Kan Bá Ní Kí N Jẹ́ Ká Jọ Gbéra Wa Sùn Ńkọ́? 14
Bí ìgbà téèyàn ń jẹun tó sì ń mumi làwọn ọ̀dọ́ kan ń bára wọn lò pọ̀ báyìí o. O ò kúkú ṣe kọ́ bó o ṣe lè sá fún àṣà tó ń pani lára yìí, kó o sì gbara ẹ lọ́wọ́ ìbànújẹ́ tó pọ̀.