Máa Lo Àwọn Ìtẹ̀jáde Wa Lọ́nà Tó Dáa
1. How may we imitate Jesus’ example of appreciation for Jehovah’s provisions?
1 Lẹ́yìn tí Jésù bọ́ ogunlọ́gọ̀ èèyàn lọ́nà ìyanu, ó ní kí wọ́n tọ́jú àwọn oúnjẹ tó ṣẹ́ kù. (Mát. 14:19-21) Ohun tí Jésù ṣe yìí fi hàn pé ó mọrírì ohun tí Jèhófà pèsè, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wa láti máa ‘fi ara wa hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́,’ nípa lílo gbogbo nǹkan tí Jèhófà ń tipasẹ̀ “olóòótọ́ ìríjú náà” pèsè fún wa lọ́nà tó dáa.—Kól. 3:15; Lúùkù 12:42; Mát. 24:45-47.
2. How may we prevent the accumulation of magazines?
2 Ìwé Ìròyìn: Àwọn ìwé ìròyìn kì í pẹ́ pọ̀ lọ́wọ́ wa. Tá a bá rí i pé ìwé ìròyìn máa ń ṣẹ́ jọ sí wa lọ́wọ́, ó yẹ ká lọ dín iye tá à ń gbà kù. Àwọn ìwé ìròyìn tó ti pẹ́ lọ́wọ́ ńkọ́? Àwọn ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ṣì wúlò ní gbogbo ìgbà téèyàn bá kà á. Torí náà, táwọn ìwé ìròyìn tó ti pẹ́ bá pọ̀ lọ́wọ́ wa, alábòójútó iṣẹ́ ìsìn tàbí alàgbà míì lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ bá a ṣe máa pín wọn.
3, 4. What points should we keep in mind when we obtain literature at the Kingdom Hall?
3 Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Míì: Kó o tó gba ìwé tá a fẹ́ fi ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí lóṣù kan, kọ́kọ́ wo ilé ná bóyá o ní ẹ̀dà ìwé náà tó o lè lò lóde ẹ̀rí kó o tó lọ gba ẹ̀dà míì ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Rí i pé èyí tó o máa lò lọ́sẹ̀ kan lo gbà, kó o sì pa dà lọ gba òmíràn tí èyí tó o gbà bá ti tán.
4 Tó bá jẹ́ èyí tó o máa lo fúnra ẹ̀, èyí tó o nílò nìkan ni kó o gbà. Kó o sì kọ orúkọ rẹ sí àyè tá a pèsè fún un. Ìyẹn á jẹ́ kó o lè rí i tó bá sọ nù. Tó o bá ń lo àkójọ ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a ṣe sórí àwo CD-ROM, tó o sì ń tọ́jú ẹ̀dà ìwé ìròyìn tó o ń gbà, kò pọn dandan kó o tún béèrè fún àdìpọ̀ ìwé ìròyìn ilé ìṣọ́ àti Jí! mọ́.
5. What should we keep in mind when placing our publications?
5 Fífi Ìwé Sóde: Kìkì àwọn tó bá fìfẹ́ hàn nìkan la máa ń fún ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ wa. Kó o sì máa fi sọ́kàn pé ojúṣe tiwa fúnra wa ni láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìwé tá à ń lò lóde ẹ̀rí. Tó o bá ń fìwé sílẹ̀ fún ẹni tó fìfẹ́ hàn, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn náà làǹfààní láti fowó ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé.
6 Jésù pèsè oúnjẹ tara fáwọn èèyàn lọ́nà ìyanu, àmọ́ ìgbà tó bọ́ wọn nípa tẹ̀mí ló pọ̀ jù. Jésù sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mát. 4:4) Àwọn ìwé wa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó máa jẹ́ kéèyàn ní ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòh. 17:3) Wọ́n ṣeyebíye ju ohun tá a kàn lè máa fi ṣòfò!
6. Why do we value our publications so much, and what will this move us to do with them?