Ohun Tó O Lè Sọ Nípa Àwọn Ìwé Ìròyìn
Ilé Ìṣọ́ October 1
“Ọ̀pọ̀ ló máa ń ronú pé bóyá ni Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn àníyàn àti ìṣòro tó ń bá àwa èèyàn fínra. Kí lèrò ẹ? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka Sáàmù 34:18.] Àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 19 nínú ìwé ìròyìn yìí sọ bí Ọlọ́run ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ ká lè borí èrò òdì irú bíi ríronú pé a kò já mọ́ nǹkan kan, ìdààmú ọkàn àti ẹ̀bi tó pàpọ̀jù.”
Ji! October–December
“Nínú ọ̀pọ̀ fíìmù lóde òní wọ́n máa ń ṣàfihàn àwọn ẹ̀mí èṣù, àwọn oṣó àtàwọn àjẹ́. Ǹjẹ́ o rò pé àwọn ẹ̀mí èṣù wà lóòótọ́? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà, ka 1 Kọ́ríńtì 10:20.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ẹ̀mí èṣù àti bá a ṣe lè dáàbò bo ara wa lọ́wọ́ wọn.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 22 hàn án.
Ilé Ìṣọ́ November 1
“Gbogbo wa la fẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀. Ṣé o rò pé ó dìgbà téèyàn bá lówó lọ́wọ́ kí ọkàn rẹ̀ tó lè balẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì kọ́ béèyàn ṣe máa ń ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ìwọ̀nba ohun téèyàn bá ní. [Ka Fílípì 4:11, 12.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ nǹkan márùn-ún tí Bíbélì sọ pé ó máa jẹ́ kí ọkàn èèyàn balẹ̀.”
Ji! October–December
Ka Mátíù 5:39. Lẹ́yìn náà, kó o sọ pé: “Ṣé o rò pé ohun tí Jésù ní lọ́kàn ni pé, ká máa gba gbogbo ìyà mọ́ra láìjanpata nígbà táwọn èèyàn bá ṣe ohun tó dùn wá? [Jẹ́ kó fèsì.] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa gbígbèjà ara ẹni àti fífi òfin dáàbò bo ara ẹni.” Fi àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ní ojú ìwé 24 hàn án.