Fún Wọn Ní Ìwé Ìròyìn Méjèèjì, àmọ́ Àkòrí Kan Ni Kó O Sọ̀rọ̀ Lé Lórí
Oríṣiríṣi àkòrí tó fani mọ́ra ló máa ń wà nínú àwọn ìwé ìròyìn wa. Tá a bá fẹ́ fún àwọn èèyàn, kókó ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo ló máa dáa pé ká sọ̀rọ̀ lé lórí, dípò ká sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣì àkòrí tó wà nínú àwọn ìwé náà. Tá a bá ti ka àwọn ìwé náà dáadáa, tá a sì kíyè sí irú ẹni tá a fẹ́ bá sọ̀rọ̀, a lè yan àkòrí kan tá a mọ̀ pé onílé máa nífẹ̀ẹ́ sí látinú Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! Bí àpẹẹrẹ, nílé tá a bá ti rí ohun ìṣeré àwọn ọmọdé, a lè sọ̀rọ̀ nípa àpilẹ̀kọ tó dá lórí ìdílé. Tó bá jẹ́ baálé ilé la bá pàdé, a lè sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ń jẹ ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin lọ́kàn, irú bí ọ̀rọ̀ nípa ìjọba rere. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kókó ọ̀rọ̀ kan ṣoṣo la ó máa sọ̀rọ̀ lé lórí, ìwé ìròyìn méjèèjì ló dáa ká máa fún àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ wa.