Máa Lo Ìkànnì jw.org Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ
Ohun èlò tó wúlò gan-an ni Ìkànnì wa, ó ń jẹ́ ká lè tan ìhìn rere “dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8) Ọ̀pọ̀ onílé ni kò mọ bí wọ́n ṣe lè lọ sórí ìkànnì jw.org fúnra wọn. Àfi tí àkéde kan bá kọ́ wọn ni wọ́n tó lè mọ̀ ọ́n.
Alábòójútó arìnrìn-àjò kan wa fídíò náà, Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? jáde lórí ìkànnì, ó gbé e sórí fóònù rẹ̀, ó sì ń fi han àwọn èèyàn ní gbogbo ìgbà tó bá ti láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó bá ń wàásù láti ilé-dé-ilé, ó máa ń sọ pé: “Mo ń lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn kí ń lè fi ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta kan hàn wọ́n, àwọn ìbéèrè náà ni: Kí nìdí tí ìṣòro fi pọ̀ gan-an láyé? Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa yanjú àwọn ìṣòro yìí? Báwo la ṣe lè máa fara dà á títí dìgbà tí Ọlọ́run á fi yanjú àwọn ìṣòro yìí? Fídíò kékeré yìí dáhùn àwọn ìbéèrè yẹn.” Alábòójútó arìnrìn-àjò yìí á wá tan fídíò náà, yóò sì máa wo onílé láti mọ̀ bóyá ó nífẹ̀ẹ́ sí i. Fídíò náà máa ń gba ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn débi pé wọn kì í fẹ́ gbójú kúrò títí tó fi máa parí. Lẹ́yìn tí fídíò yìí bá parí, alábòójútó arìnrìn-àjò náà yóò wá sọ pé: “Ẹ gbọ́ tí wọ́n sọ nínú fídíò yìí pé ẹ lè kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù tó wà fún bíbéèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lórí ìkànnì. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí, mo sì lè fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn yín nísinsìnyí.” Tí onílé bá nífẹ̀ẹ́ sí i, arákùnrin náà yóò lo ìwé Ìròyìn Ayọ̀ láti fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án. Bí onílé ò bá ráyè, yóò sọ fún un pé òun á pa dà wá fi bí a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án nígbà míì. Ohun kan náà ló máa ń sọ tó bá dúró sinmi díẹ̀ níbì kan, lẹ́yìn tó bá bá àwọn tó wà níbẹ̀ fọ̀rọ̀ wérọ̀, yóò fi fídíò náà hàn wọ́n. Ǹjẹ́ ìwọ náà máa ń lo ìkànnì jw.org lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ?