Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ September 1
“Ǹjẹ́ o mọ ibi tí orúkọ náà Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti wá? [Jẹ́ kó fèsì.] Inú Bíbélì la ti lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí torí pé Ọlọ́run sọ orúkọ tó ń jẹ́ fún wa nínú rẹ̀. [Ka Sáàmù 83:18.] Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń sọ ìhìn rere nípa Jèhófà àti ohun tó máa ṣe fún aráyé. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí dáhùn ọ̀pọ̀ ìbéèrè táwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa wa.”
Ji! September–October
“Bí nǹkan ṣe rí láyé yìí ti tojú sú àwọn kan, ṣé ìwọ náà gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ ohun tí kò yẹ ká ṣe tá a bá ní ìṣòro. [Ka Òwe 24:10.] Ìwé ìròyìn yìí dábàá àwọn ohun tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòrò tó le koko, ó sì sọ àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tó ti tẹ̀ lé àwọn àbá náà.”