Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Ilé Ìṣọ́ October 1
“À ń fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tó gbádùn mọ́ni yìí han àwọn èèyàn ládùúgbò yín. [Fi iwájú ìwé ìròyìn náà hàn án.] Àwọn kan rò pé ṣe lèèyàn kàn ń fi àkókò ṣòfò tó bá ń gbàdúrà, pé kò sí ẹni tó ń gbọ́ àdúrà. Àwọn míì sì gbà pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà àwọn. Kí lèrò yín? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹ gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa àdúrà. [Ka Aísáyà 30:19.] Ìwé ìròyìn yìí fi ẹ̀rí hàn pé Ọlọrun máa ń gbọ́ àdúrà tá a bá gbà lọ́nà tó yẹ àti lórí ohun tó tọ́.”
Ji! September—October
“A wá fi àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa bí a ṣe lè túbọ̀ ní àmúmọ́ra han àwọn aládùúgbò wa. [Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 14 àti 15 hàn án.] Báwo ni ìfẹ́ ṣe ń jẹ́ ká lè rí ara gba nǹkan sí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹ gbọ́ ìmọ̀ràn tó wúlò yìí tí Bíbélì gbà wá. [Ka 1 Pétérù 4:8.] Tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó ṣe kedere yìí, a ó máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú láìka àwọn ìkùdíẹ̀-káàtó wọn sí.”