ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • bt orí 7 ojú ìwé 52-59
  • Fílípì Kéde “Ìhìn Rere Nípa Jésù”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Fílípì Kéde “Ìhìn Rere Nípa Jésù”
  • “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Àwọn Tó Ti Tú Ká” (Ìṣe 8:4-8)
  • “Ẹ Fún Èmi Náà ní Àṣẹ Yìí” (Ìṣe 8:9-25)
  • “Ǹjẹ́ O Tiẹ̀ Lóye Ohun Tí Ò Ń Kà?” (Ìṣe 8:26-40)
  • Fílípì—Ajíhìnrere Tó Nítara
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Fílípì Batisí Ìjòyè Òṣìṣẹ́ Ará Etiópíà kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Ẹ Ní Ẹ̀mí Aṣáájú Ọ̀nà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
Àwọn Míì
“Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
bt orí 7 ojú ìwé 52-59

ORÍ 7

Fílípì Kéde “Ìhìn Rere Nípa Jésù”

Fílípì fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa lẹ́nu iṣẹ́ ajíhìnrere

Ó dá lórí Ìṣe 8:4-40

1, 2. Báwo ni ìsapá àwọn èèyàn láti mú kí ìwàásù ìhìn rere dáwọ́ dúró ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe já sí asán?

ÀWỌN alátakò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni, Sọ́ọ̀lù sì ń “hùwà ìkà sí ìjọ.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé inúnibíni náà le gan-an. (Ìṣe 8:3) Torí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í sá kúrò ní Jerúsálẹ́mù. Lójú àwọn kan, ó lè jọ pé Sọ́ọ̀lù máa pa ẹ̀sìn Kristẹni run bó ṣe sọ. Àmọ́ o, ohun téèyàn ò retí ló ṣẹlẹ̀ látinú báwọn Kristẹni ṣe tú ká káàkiri. Kí lohun náà?

2 Àwọn tó tú ká bẹ̀rẹ̀ sí í “kéde ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà” láwọn ilẹ̀ tí wọ́n sá lọ. (Ìṣe 8:4) Àbí ẹ ò rí nǹkan! Kàkà kí inúnibíni náà dá ìhìn rere dúró, ńṣe ló jẹ́ kó túbọ̀ tàn kálẹ̀! Àwọn tó ń ṣe inúnibíni sáwọn ọmọ ẹ̀yìn ò mọ̀ pé báwọn ṣe ń mú kí wọ́n fi ibi tí wọ́n wà sílẹ̀ lọ sáwọn ibòmíì ń mú kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà túbọ̀ gbòòrò dé apá ibi tó jìnnà jù lọ lórí ilẹ̀ ayé. Bá a ṣe máa rí i, irú ohun kan náà ti ṣẹlẹ̀ lóde òní.

“Àwọn Tó Ti Tú Ká” (Ìṣe 8:4-8)

3. (a) Ta ni Fílípì? (b) Kí nìdí tí wọn ò fi tíì wàásù ní Samáríà, àmọ́ kí ni Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ó ṣì máa ṣẹlẹ̀ níbẹ̀?

3 Fílípì wà lára “àwọn tó ti tú ká.”a (Ìṣe 8:4; wo àpótí náà, “Fílípì ‘Ajíhìnrere.’”) Ó lọ sí Samáríà, ìlú tí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere ò tíì dé, torí pé nígbà kan Jésù ti sọ fáwọn àpọ́sítélì pé: ‘Ẹ má wọ ìlú Samáríà kankan; kàkà bẹ́ẹ̀, léraléra ni kí ẹ máa lọ sọ́dọ̀ àwọn àgùntàn ilé Ísírẹ́lì tó sọ nù.’ (Mát. 10:5, 6) Àmọ́, Jésù mọ̀ pé tó bá tákòókò wọ́n máa jẹ́rìí kúnnákúnná fáwọn ará Samáríà, torí ṣáájú kó tó lọ sọ́run ó sọ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù, ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé.”​—Ìṣe 1:8.

4. Kí làwọn ará Samáríà ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ ìwàásù Fílípì, kí ló sì mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?

4 Fílípì rí i pé Samáríà ti ‘funfun, ó sì ti tó kórè.’ (Jòh. 4:35) Ìhìn rere rẹ̀ tu àwọn tó ń gbébẹ̀ lára, ó sì rọrùn láti mọ ohun tó mú kó rí bẹ́ẹ̀. Kò sí àjọṣe kankan láàárín àwọn Júù àtàwọn ará Samáríà, ọ̀pọ̀ àwọn Júù sì ń fi hàn pé àwọn kórìíra wọn. Ní ìyàtọ̀ sí èyí, àwọn ará Samáríà rí i pé ìhìn rere náà mú kí gbogbo èèyàn ní ìrètí láìsí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà níbẹ̀, èyí sì mú kó yàtọ̀ sí èrò àwọn Farisí tí kì í gba tàwọn ẹlòmíì rò. Bí Fílípì tún ṣe ń fìtara wàásù láìṣojúsàájú fáwọn ará Samáríà fi hàn pé, ìwà ẹ̀tanú àwọn tó ń fojú tẹ́ńbẹ́lú wọn kò kó èèràn ran òun. Torí náà, kò yani lẹ́nu pé, ogunlọ́gọ̀ àwọn ará Samáríà “pọkàn pọ̀,” wọ́n sì fetí sílẹ̀ sí Fílípì.​—Ìṣe 8:6.

5-7. Sọ àpẹẹrẹ tó fi hàn pé báwọn Kristẹni ṣe ń sá lọ sápá ibòmíì ni ìhìn rere náà ń tàn kálẹ̀.

5 Lóde òní, bíi ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn èèyàn Ọlọ́run kò tíì dá iṣẹ́ ìwàásù náà dúró. Lọ́pọ̀ ìgbà, bí wọ́n ṣe ń fipá máwọn Kristẹni láti ibì kan lọ sí ibòmíì, bóyá látinú ẹ̀wọ̀n kan lọ sí òmíràn tàbí láti ìlú kan lọ sí òmíràn, ti mú kí ìhìn rere Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn lápá ibòmíì. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti wàásù lọ́nà títayọ kódà nígbà tí wọ́n wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Júù kan tó pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí ní àgọ́ náà sọ pé: “Báwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ní okun láti fàyà rán nǹkan ti mú kí n gbà gbọ́ dájú pé orí Ìwé Mímọ́ ni wọ́n gbé ìgbàgbọ́ kà, èmi fúnra mi sì di Ẹlẹ́rìí.”

6 Kódà nígbà míì, àwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa náà máa ń gbọ́ ìhìn rere tí wọ́n á sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí wọ́n gbé Arákùnrin Franz Desch lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Gusen ní orílẹ̀-èdè Austria, ó ṣeé ṣe fún un láti kọ́ ẹ̀ṣọ́ SS kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ wo bí inú àwọn méjèèjì ṣe máa dùn tó nígbà tí wọ́n pàdé ní àpéjọ àgbègbè kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, tí wọ́n sì jọ ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run!

7 Irú ohun kan náà ṣẹlẹ̀ nígbà tí inúnibíni mú káwọn Kristẹni sá láti orílẹ̀-èdè kan lọ sí òmíràn. Àpẹẹrẹ kan ni ti ìjẹ́rìí àrà ọ̀tọ̀ tó wáyé lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì láàárín ọdún 1970 sí ọdún 1979, nígbà tí wọ́n fipá mú káwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè Màláwì sá lọ síbẹ̀. Kódà, nígbà tí inúnibíni bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Mòsáńbíìkì lẹ́yìn náà, iṣẹ́ ìwàásù ò dáwọ́ dúró. Arákùnrin Francisco Coana sọ pé: “Òótọ́ ni pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n mú àwọn kan lára wa, tí wọ́n sì tì wá mọ́lé nítorí iṣẹ́ ìwàásù. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà, èyí sì mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ń tì wá lẹ́yìn, bó ṣe ti àwọn Kristẹni ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lẹ́yìn.”

8. Báwo ni ìṣòro ètò òṣèlú àti àyípadà ètò ọrọ̀ ajé ṣe ń jẹ́ kí ìhìn rere tàn kálẹ̀?

8 Àmọ́ o, inúnibíni nìkan kọ́ ló ń jẹ́ kí ẹ̀sìn Kristẹni tàn kálẹ̀ lọ́pọ̀ ilẹ̀ kárí ayé. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ìṣòro ètò òṣèlú àti àyípadà ètò ọrọ̀ ajé ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn èèyàn tó ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àtàwọn tó wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà. Ogun àti ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀ ti mú káwọn kan ṣí lọ síbi tí nǹkan ti fara rọ, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀. Báwọn tó ń ṣí lọ láti ibì kan síbòmíì ṣe ń pọ̀ sí i, ìyẹn ti jẹ́ ká túbọ̀ máa dá àwọn àwùjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ òkèèrè sílẹ̀. Ṣéwọ náà ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kó o lè máa wàásù fáwọn tó wá “látinú gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti èèyàn àti ahọ́n”?​—Ìfi. 7:9.

“Ẹ Fún Èmi Náà ní Àṣẹ Yìí” (Ìṣe 8:9-25)

Símónì tó ń ṣe iṣẹ́ idán pípa tẹ́lẹ̀ gbé àpò owó dání, ó wá dúró sẹ́yìn àpọ́sítélì kan. Àpọ́sítélì náà ń gbé ọwọ́ lé èjìká Kristẹni kan. Kristẹni míì wà lẹ́yìn tó ń mú ọmọbìnrin kan tó jẹ́ arọ lára dá, inú àwọn tó wà níbẹ̀ sí ń dùn.

“Nígbà tí Símónì rí i pé àwọn èèyàn ń rí ẹ̀mí gbà tí àwọn àpọ́sítélì bá ti gbọ́wọ́ lé wọn, ó fi owó lọ̀ wọ́n.”​—Ìṣe 8:18

9. Ta ni Símónì, kí ló sì mú kó di Kristẹni?

9 Fílípì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àmì ní Samáríà. Bí àpẹẹrẹ, ó wo àwọn aláàbọ̀ ara sàn, ó sì lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde. (Ìṣe 8:6-8) Ọkùnrin kan wà táwọn iṣẹ́ ìyanu tí Fílípì ṣe jọ lójú. Símónì lorúkọ rẹ̀, iṣẹ́ idán pípa ló ń ṣe, àwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún un gan-an débi tí wọ́n fi ń sọ pé: “Ọkùnrin yìí ni Agbára Ọlọ́run.” Àmọ́ nígbà tí Símónì rí àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Fílípì ṣe, ó gbà pé òun ti rí agbára Ọlọ́run gangan, ó sì di Kristẹni. (Ìṣe 8:9-13) Ṣùgbọ́n, ohun kan ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn tó jẹ́ ká mọ ohun tó wà lọ́kàn Símónì. Kí ló ṣẹlẹ̀?

10. (a) Kí ni Pétérù àti Jòhánù ṣe nígbà tí wọ́n dé Samáríà? (b) Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun gba ẹ̀mí mímọ́ lẹ́yìn tí Pétérù àti Jòhánù gbé ọwọ́ lé wọn, kí ni Símónì ṣe?

10 Nígbà táwọn àpọ́sítélì gbọ́ bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe ń tẹ̀ síwájú ní Samáríà, wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù lọ síbẹ̀. (Wo àpótí náà, “Pétérù Lo ‘Àwọn Kọ́kọ́rọ́ Ìjọba Ọ̀run.’ ”) Lẹ́yìn tí wọ́n débẹ̀, àwọn àpọ́sítélì méjèèjì gbé ọwọ́ lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn sì rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.b Nígbà tí Símónì rí ohun táwọn àpọ́sítélì náà ṣe, ó yà á lẹ́nu gan-an. Ló bá sọ fún wọn pé: “Ẹ fún èmi náà ní àṣẹ yìí, kí ẹnikẹ́ni tí mo bá gbé ọwọ́ mi lé lè rí ẹ̀mí mímọ́ gbà.” Kódà, ó fowó lọ̀ wọ́n, torí ó rò pé òun lè ra àǹfààní iyebíye yìí!​—Ìṣe 8:14-19.

11. Kí ni Pétérù sọ fún Símónì pé kó ṣe, kí ni Símónì sì ṣe?

11 Pétérù ò fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fún Símónì. Pétérù sọ fún un pé: “Kí fàdákà rẹ ṣègbé pẹ̀lú rẹ, torí o rò pé o lè fi owó ra ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ Ọlọ́run. O kò ní ipa tàbí ìpín kankan nínú ọ̀rọ̀ yìí, nítorí pé ọkàn rẹ kò tọ́ lójú Ọlọ́run.” Lẹ́yìn náà, Pétérù sọ fún Símónì pé kó ronú pìwà dà, kó sì bẹ Ọlọ́run pé kó dárí ji òun. Pétérù sọ fún un pé: “Rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé, tó bá ṣeé ṣe, kí ó dárí èrò ibi tó wà lọ́kàn rẹ jì ọ́.” Ó dájú pé Símónì kì í ṣe èèyàn burúkú; ohun tó tọ́ ló fẹ́ ṣe, ò kàn jẹ́ kí èrò tí kò tọ́ darí òun ni. Torí náà, ó bẹ àwọn àpọ́sítélì pé: “Ẹ bá mi rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà kí ìkankan nínú ohun tí ẹ sọ má bàa ṣẹlẹ̀ sí mi.”​—Ìṣe 8:20-24.

12. Báwo ni àṣà ká máa ra ipò tàbí ta ipò ṣe rí nínú ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì?

12 Ìkìlọ̀ ni ìbáwí tí Pétérù fún Símónì jẹ́ fáwa Kristẹni lóde òní. Ó jẹ́ ká rí i pé kò yẹ ká máa ra ipò tàbí ta ipò nínú ìjọ Kristẹni. Irú àṣà yìí sì wọ́pọ̀ gan-an nínú ìtàn ìsìn àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Bí àpẹẹrẹ, ìwé kan tí wọ́n kọ lọ́dún 1878 sọ pé kò sígbà tí wọ́n ń yan Póòpù sípò tí kì í ṣe pé ńṣe ni wọ́n ń fi owó ra ipò náà. Kódà, àwọn èèyàn ò kà á sí ohun ìtìjú, wọn ò sì fi pa mọ́.

13. Báwo làwa Kristẹni ṣe lè ṣọ́ra fún àṣà ríra ipò tàbí títa ipò nínú ìjọ?

13 Àwa Kristẹni ò gbọ́dọ̀ fàyè gba àṣà ríra ipò tàbí títa ipò, torí pé ẹ̀ṣẹ̀ ni. Bí àpẹẹrẹ, kò yẹ ká máa fún àwọn èèyàn lẹ́bùn tàbí ká máa yìn wọ́n jù torí kí wọ́n lè fún wa láǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ. Bákan náà, ó yẹ káwọn alábòójútó máa kíyè sára kí wọ́n má bàa máa ṣe ojúsàájú láàárín àwọn tó lówó àtàwọn tí ò ní, tó bá kan ọ̀rọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Ó yẹ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa hùwà bí “ẹni tó kéré,” kí wọ́n jẹ́ kí ẹ̀mí Jèhófà máa yan àwọn tó máa ní àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. (Lúùkù 9:48) Kò yẹ káwa èèyàn Jèhófà máa “wá ògo ara” wa.​—Òwe 25:27.

PÉTÉRÙ LO “ÀWỌN KỌ́KỌ́RỌ́ ÌJỌBA Ọ̀RUN”

Jésù sọ fún Pétérù pé: “Màá fún ọ ní àwọn kọ́kọ́rọ́ Ìjọba ọ̀run.” (Mát. 16:19) Kí ni Jésù ní lọ́kàn? Ọ̀rọ̀ náà, “àwọn kọ́kọ́rọ́” fi hàn pé Pétérù máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwùjọ méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti gbọ́ ìhìn rere, kí wọ́n sì láǹfààní láti jọba pẹ̀lú Jésù lọ́run. Ìgbà wo ni Pétérù lo àwọn kọ́kọ́rọ́ yìí?

  • Pétérù lo kọ́kọ́rọ́ àkọ́kọ́ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, nígbà tó rọ àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe Júù pé kí wọ́n ronú pìwà dà kí á sì batisí wọn. Lọ́jọ́ yẹn, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) èèyàn ló ṣèrìbọmi, tí wọ́n sì nírètí láti jọba pẹ̀lú Kristi.​—Ìṣe 2:1-41.

  • Kò pẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n pa Sítéfánù ni Pétérù lo kọ́kọ́rọ́ kejì. Nígbà yẹn, Pétérù àti Jòhánù gbọ́wọ́ lé àwọn ará Samáríà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ batisí, àwọn èèyàn náà sì gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́.​—Ìṣe 8:14-17.

  • Ọdún 36 Sànmánì Kristẹni ni Pétérù lo kọ́kọ́rọ́ kẹta. Ìgbà yẹn ni àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ ní ìrètí láti lọ sọ́run. Ìyẹn sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pétérù wàásù fún Kọ̀nílíù tó jẹ́ Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ àkọ́kọ́ tó di Kristẹni.​—Ìṣe 10:1-48.

“Ǹjẹ́ O Tiẹ̀ Lóye Ohun Tí Ò Ń Kà?” (Ìṣe 8:26-40)

14, 15. (a) Ta ni “ìwẹ̀fà ará Etiópíà,” báwo ni Fílípì sì ṣe rí i? (b) Kí ni ará Etiópíà náà ṣe nígbà tí Fílípì ṣàlàyé Ìwé Mímọ́ fún un, kí sì nìdí tá ò fi lè sọ pé ìrìbọmi yẹn ti yá jù? (Wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

14 Áńgẹ́lì Jèhófà darí Fílípì gba ọ̀nà tó lọ láti Jerúsálẹ́mù sí Gásà. Ó ṣeé ṣe kí Fílípì máa ronú nípa ohun tóun fẹ́ lọ ṣe lójú ọ̀nà yẹn. Ọ̀rọ̀ náà wá yé e nígbà tó pàdé ìwẹ̀fà ará Etiópíà kan tó ń “ka ìwé wòlíì Àìsáyà sókè.” (Wo àpótí náà, “Ọ̀nà Wo Ló Gbà Jẹ́ ‘Ìwẹ̀fà’?”) Ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà mú kí Fílípì sún mọ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọkùnrin ará Etiópíà náà. Bí Fílípì ṣe ń rìn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọkùnrin náà, ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ǹjẹ́ o tiẹ̀ lóye ohun tí ò ń kà?” Ọkùnrin náà dáhùn pé: “Báwo ni mo ṣe lè lóye, láìjẹ́ pé ẹnì kan tọ́ mi sọ́nà?”​—Ìṣe 8:26-31.

15 Ọkùnrin ará Etiópíà náà sọ fún Fílípì pé kó wọ inú kẹ̀kẹ́ ẹṣin òun. Fojú inú wo bí ìjíròrò wọn ṣe máa rí lọ́jọ́ yẹn! Ṣáájú àsìkò náà, ọ̀pọ̀ èèyàn ò mọ ìtumọ̀ “àgùntàn” tàbí “ìránṣẹ́” tí wòlíì Àìsáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀. (Àìsá. 53:1-12) Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń lọ, Fílípì ṣàlàyé fún ìwẹ̀fà ará Etiópíà náà pé Jésù Kristi ni àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ sí lára. Aláwọ̀ṣe Júù ni ọkùnrin ará Etiópíà yìí, torí náà bíi tàwọn tí wọ́n batisí ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ojú ẹsẹ̀ ni ọkùnrin náà mọ ohun tó yẹ kóun ṣe. Ó sọ fún Fílípì pé: “Wò ó! Omi rèé; kí ló ń dá mi dúró láti ṣèrìbọmi?” Láìjáfara, Fílípì ṣèrìbọmi fún ọkùnrin ará Etiópíà náà!c (Wo àpótí náà, “Ìrìbọmi ní ‘Ibi Tí Omi Wà’ ”) Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí tún darí Fílípì lọ sí Áṣídódù, ó sì ń bá a lọ láti máa kéde ìhìn rere níbẹ̀.​—Ìṣe 8:32-40.

Ọ̀NÀ WO LÓ GBÀ JẸ́ “ÌWẸ̀FÀ”?

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà eu·nouʹkhos, tá a tú sí “ìwẹ̀fà” lè túmọ̀ sí ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá, ìyẹn ni pé irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ò ní lè bímọ. Ọ̀rọ̀ náà tún lè túmọ̀ sí òṣìṣẹ́ ààfin kan tó wà nípò gíga. Wọ́n sábà máa ń tẹ àwọn òṣìṣẹ́ ààfin tó ń bójú tó àwọn ìyàwó ọba lọ́dàá, àmọ́ wọn kì í ṣe bẹ́ẹ̀ fáwọn òṣìṣẹ́ míì láàfin, irú bí agbọ́tí tàbí ẹni tó ń bó jú tó ètò ìnáwó. Òṣìṣẹ́ ààfin tí wọn ò tẹ̀ lọ́dàá ni ìwẹ̀fà ará Etiópíà tí Fílípì wàásù fún, torí pé ìṣúra ọba ló ń bójú tó. Torí náà, a lè pè é ní mínísítà ètò ìnáwó.

Ìwẹ̀fà yìí tún jẹ́ aláwọ̀ṣe Júù, ìyẹn ẹnì kan tí kì í ṣe Júù àmọ́ tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. Kódà, Jerúsálẹ́mù ló ti ń bọ̀ lẹ́yìn tó lọ jọ́sìn níbẹ̀. (Ìṣe 8:27) Torí náà, a lè gbà pé ará Etiópíà yìí kì í ṣe ìwẹ̀fà tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá, torí Òfin Mósè ò gba àwọn ọkùnrin tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá láyè láti wá sínú ìjọ Ísírẹ́lì.​—Diu. 23:1.

ÌRÌBỌMI NÍ “IBI TÍ OMI WÀ”

Báwo ló ṣe yẹ káwọn Kristẹni máa ṣe batisí tàbí ìrìbọmi? Àwọn kan gbà pé ohun tó túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n da omi sí ẹnì kan lórí tàbí kí wọ́n fi omi wọ́n ọn lórí. Àmọ́, nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa ìwẹ̀fà ará Etiópíà, ó sọ pé ìwẹ̀fà náà dá kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ dúró ní “ibi tí omi wà.” Lẹ́yìn ìyẹn, “Fílípì àti ìwẹ̀fà náà wá wọ inú omi, Fílípì sì ṣèrìbọmi fún un.” (Ìṣe 8:36, 38) Tó bá jẹ́ pé ohun tí ìrìbọmi túmọ̀ sí ni pé kí wọ́n da omi síni lórí tàbí wọ́n omi léni lórí, ìwẹ̀fà yẹn ò ní dá kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà dúró níbi tí omi wà. Kódà, omi kékeré tó wà nínú ìgò awọ ì bá tó láti fi ṣèrìbọmi fún un. Ó sì dájú pé ìwẹ̀fà náà máa ní irú ìgò awọ bẹ́ẹ̀, torí pé “ọ̀nà aṣálẹ̀” ló ti ń rìnrìn àjò.​—Ìṣe 8:26.

Ìwé atúmọ̀ èdè náà, A Greek-English Lexicon látọwọ́ Liddell àti Scott sọ pé ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà ba·ptiʹzo, tá a tú sí “batisí” tàbí “ìrìbọmi” túmọ̀ sí ni “láti rì bọ̀” tàbí “láti tẹ̀ bọ̀.” Ohun tí Bíbélì sọ nípa batisí tàbí ìrìbọmi sì bá ọ̀rọ̀ yẹn mu. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Jòhánù 3:23 sọ pé, Jòhánù “ń ṣèrìbọmi ní Áínónì nítòsí Sálímù, torí pé omi púpọ̀ wà níbẹ̀.” Bákan náà, nínú àkọsílẹ̀ nípa ìrìbọmi Jésù, Bíbélì sọ pé: “Bó ṣe ń jáde látinú omi, ó rí i tí ọ̀run ń pínyà.” (Máàkù 1:9, 10) Torí náà, táwọn Kristẹni tòótọ́ bá fẹ́ ṣe batisí tàbí ìrìbọmi, ńṣe ló yẹ kí wọ́n ri ẹni náà bọ inú omi pátápátá.

16, 17. Báwo làwọn áńgẹ́lì ṣe ń lọ́wọ́ sí iṣẹ́ ìwàásù lóde òní?

16 Lónìí, àwa Kristẹni láǹfààní láti ṣe irú iṣẹ́ tí Fílípì ṣe yìí. Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn tá a bá rí lójú ọ̀nà, irú bíi nígbà tá a bá ń rìnrìn àjò. Ó dájú pé kì í ṣe pé a kàn ṣàdédé ń pàdé àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Èyí sì bá ohun tí Bíbélì sọ mu pé àwọn áńgẹ́lì ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà, kó lè dé ọ̀dọ̀ “gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti èèyàn.” (Ìfi. 14:6) Bákan náà, Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn áńgẹ́lì á máa darí iṣẹ́ ìwàásù. Nínú àkàwé tí Jésù ṣe nípa àlìkámà àti èpò, ó sọ pé ‘àwọn áńgẹ́lì ló máa jẹ́ olùkórè’ nígbà ìkórè, ìyẹn ní ìparí ètò àwọn nǹkan. Ó wá fi kún un pé àwọn áńgẹ́lì náà máa “kó gbogbo ohun tó ń fa ìkọ̀sẹ̀ àti àwọn arúfin jáde kúrò nínú Ìjọba rẹ̀.” (Mát. 13:37-41) Bákan náà, àwọn áńgẹ́lì yẹn máa kó àwọn ajogún Ìjọba náà jọ, lẹ́yìn náà “ogunlọ́gọ̀ èèyàn” ti àwọn “àgùntàn mìíràn,” láti wá sínú ètò rẹ̀.​—Ìfi. 7:9; Jòh. 6:44, 65; 10:16.

17 Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló fi hàn pé àwọn áńgẹ́lì ń darí iṣẹ́ ìwàásù lóòótọ́, torí pé àwọn kan lára àwọn tá à ń bá pàdé lóde ẹ̀rí ló máa ń sọ pé àwọn ti ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́. Àpẹẹrẹ kan rèé; àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì mú ọmọdé kan dání lọ sóde ìwàásù. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà fẹ́ ṣíwọ́ iṣẹ́ ìwàásù láàárọ̀ ọjọ́ yẹn, ńṣe ni ọmọ tí wọ́n mú dání ń hára gàgà láti lọ sí ilé tó kàn. Ó sá lọ sí ẹnu ọ̀nà ilé náà, ó sì kan ilẹ̀kùn. Ni ọ̀dọ́bìnrin kan bá ṣílẹ̀kùn. Bàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì náà ṣe sún mọ́ ọn nìyẹn kí wọ́n lè bá a sọ̀rọ̀. Ó yà wọ́n lẹ́nu nígbà tí obìnrin náà ṣàlàyé fún wọn pé òun ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà tán ni pé kí Ọlọ́run rán ẹnì kan sóun láti wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n ṣètò bí wọ́n á ṣe máa kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Tọkọtaya kan wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n ń tẹ aago ẹnu ọ̀nà obìnrin kan, obìnrin náà sì ń gbàdúrà nínú ilé.

“Ọlọ́run, irú ẹni yòówù kó o jẹ́, jọ̀wọ́ ràn mí lọ́wọ́”

18. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú iṣẹ́ ìwàásù?

18 Torí pé o wà nínú ìjọ Kristẹni, ìwọ náà láǹfààní láti máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn áńgẹ́lì bá a ṣe túbọ̀ ń wàásù ìhìn rere náà fún ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní. Má ṣe fọwọ́ yẹpẹrẹ mú àǹfààní tó o ní yìí o! Túbọ̀ máa fìtara wàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá máa láyọ̀ bó o ṣe ń kéde “ìhìn rere nípa Jésù.”​—Ìṣe 8:35.

FÍLÍPÌ “AJÍHÌNRERE”

Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi tú ká nítorí inúnibíni, Fílípì lọ sí Samáríà. Ó dájú pé, ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, torí pé “nígbà tí àwọn àpọ́sítélì tó wà ní Jerúsálẹ́mù gbọ́ pé Samáríà ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n rán Pétérù àti Jòhánù sí wọn.” Ìyẹn sì mú kó ṣeé ṣe fáwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Kristẹni níbẹ̀ láti gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́.​—Ìṣe 8:14-17.

Fílípì jókòó sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin pẹ̀lú ìwẹ̀fà ará Etiópíà.

Ẹ̀ẹ̀kan péré ni wọ́n tún dárúkọ Fílípì nínú ìwé Ìṣe lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Ìṣe orí 8 sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Èyí sì jẹ́ ní nǹkan bí ogún ọdún lẹ́yìn tí Fílípì kọ́kọ́ wàásù ní Samáríà. Ìgbà yẹn ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tó bá a rìnrìn àjò ń pa dà lọ sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta. Wọ́n yà ní Tólémáísì. Lúùkù sọ pé: “Lọ́jọ́ kejì, a gbéra, a sì dé Kesaríà, a wọ ilé Fílípì ajíhìnrere, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin méje náà, a sì dúró lọ́dọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin yìí ní àwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tí kò tíì lọ́kọ, tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀.”​—Ìṣe 21:8, 9.

Ó jọ́ pé ńṣe ni Fílípì lọ wàásù ìhìn rere ní Kesaríà, tó sì ń gbébẹ̀ pẹ̀lú ìdílé rẹ̀. Àmọ́, ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa ẹ̀ ni bí Lúùkù ṣe pè é ní “ajíhìnrere,” torí àwọn tó fi ilé wọn sílẹ̀ láti lọ wàásù ní agbègbè tí iṣẹ́ ìwàásù ò tíì dé ni Ìwé Mímọ́ máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí fún. Ó ní láti jẹ́ pé ìdí tí Lúùkù fi pe Fílípì bẹ́ẹ̀ ni pé ìtara tó ní fún iṣẹ́ ìwàásù ò dín kù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó pẹ́ tó ti dé agbègbè náà. Yàtọ̀ síyẹn, bó ṣe láwọn ọmọbìnrin mẹ́rin tó ń sọ tẹ́lẹ̀ fi hàn pé ó kọ́ ìdílé rẹ̀ láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kí wọ́n sì máa sìn ín.

a Ẹni yìí kì í ṣe àpọ́sítélì Fílípì o. Àmọ́ bá a ṣe sọ ní Orí 5, òun ni Fílípì tó wà lára àwọn ‘ọkùnrin méje tí wọ́n lórúkọ rere’ tí wọ́n yàn láti máa bójú tó pípín oúnjẹ láàárín àwọn Kristẹni opó tó ń sọ èdè Gíríìkì àtàwọn tó ń sọ èdè Hébérù ní Jerúsálẹ́mù.​—Ìṣe 6:1-6.

b Ṣáájú àsìkò yẹn, ó dájú pé ìgbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun bá ṣèrìbọmi ni Ọlọ́run máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n. Èyí ló mú kí wọ́n nírètí láti jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. (2 Kọ́r. 1:21, 22; Ìfi. 5:9, 10; 20:6) Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, Ọlọ́run ò fẹ̀mí mímọ́ yan àwọn ọmọ ẹ̀yìn tuntun náà nígbà tí wọ́n ṣèrìbọmi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìgbà tí Pétérù àti Jòhánù gbọ́wọ́ lé wọn ni wọ́n tó gba ẹ̀bùn ẹ̀mí mímọ́, tí wọ́n sì láǹfààní láti máa ṣe iṣẹ́ ìyanu.

c Ìrìbọmi yẹn ò yá jù. Ó ṣe tán, aláwọ̀ṣe Júù ni ará Etiópíà yìí, ó sì ti ní ìmọ̀ Ìwé Mímọ́, títí kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà. Ní báyìí tó ti wá mọ ipa tí Jésù kó láti mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ, ó lè ṣèrìbọmi lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́