ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 22
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Ọ̀rọ̀ ìdájọ́ sí àwọn ọba búburú (1-30)

        • Nípa Ṣálúmù (10-12)

        • Nípa Jèhóákímù (13-23)

        • Nípa Konáyà (24-30)

Jeremáyà 22:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Jeremáyà 22:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aláìlóbìí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:15; Ais 1:17; Isk 22:7; Mik 2:2
  • +2Ọb 24:3, 4; Jer 7:6, 7

Jeremáyà 22:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 2:12
  • +Jer 17:24, 25

Jeremáyà 22:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:8; Mik 3:12

Jeremáyà 22:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:11; Jer 7:34

Jeremáyà 22:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ya àwọn apanirun sí mímọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 9:1
  • +Jer 21:14

Jeremáyà 22:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 29:24-26; 1Ọb 9:8, 9; Ida 2:15

Jeremáyà 22:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:16, 17

Jeremáyà 22:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wọ́n tún ń pè é ní Jèhóáhásì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 3:15; 2Kr 36:1
  • +2Ọb 23:29, 30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 158-159

Jeremáyà 22:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:34; 2Kr 36:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 158-159

Jeremáyà 22:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:13; Mik 3:9, 10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 140

Jeremáyà 22:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wíńdò.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 140

Jeremáyà 22:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:1, 2; 23:23, 25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 140-141

Jeremáyà 22:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 140-141

Jeremáyà 22:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:34; 2Kr 36:4

Jeremáyà 22:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 36:30
  • +2Kr 36:5, 6

Jeremáyà 22:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:49
  • +2Ọb 24:7

Jeremáyà 22:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:31; 6:16
  • +Di 9:7; Ond 2:11

Jeremáyà 22:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ṣe olùṣọ́ àgùntàn rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 23:1; Isk 34:2

Jeremáyà 22:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Ìrora ìrọbí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 22:6
  • +Ais 2:12, 13
  • +Jer 4:31; 6:24

Jeremáyà 22:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wọ́n tún ń pè é ní Jèhóákínì àti Jekonáyà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:6; Jer 22:28; 37:1; Mt 1:11
  • +2Ọb 23:34

Jeremáyà 22:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó ń lépa ọkàn rẹ.”

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:12, 15; 2Kr 36:9, 10; Jer 24:1; 29:1, 2

Jeremáyà 22:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tí ọkàn wọn fà sí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 52:31-34

Jeremáyà 22:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 3:17, 18

Jeremáyà 22:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ní ọjọ́ ayé rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:9, 10; Jer 36:30; Mt 1:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 10

Àwọn míì

Jer. 22:3Le 19:15; Ais 1:17; Isk 22:7; Mik 2:2
Jer. 22:32Ọb 24:3, 4; Jer 7:6, 7
Jer. 22:41Ọb 2:12
Jer. 22:4Jer 17:24, 25
Jer. 22:5Jer 39:8; Mik 3:12
Jer. 22:6Ais 6:11; Jer 7:34
Jer. 22:7Isk 9:1
Jer. 22:7Jer 21:14
Jer. 22:8Di 29:24-26; 1Ọb 9:8, 9; Ida 2:15
Jer. 22:92Ọb 22:16, 17
Jer. 22:111Kr 3:15; 2Kr 36:1
Jer. 22:112Ọb 23:29, 30
Jer. 22:122Ọb 23:34; 2Kr 36:4
Jer. 22:13Le 19:13; Mik 3:9, 10
Jer. 22:152Ọb 22:1, 2; 23:23, 25
Jer. 22:182Ọb 23:34; 2Kr 36:4
Jer. 22:19Jer 36:30
Jer. 22:192Kr 36:5, 6
Jer. 22:20Di 32:49
Jer. 22:202Ọb 24:7
Jer. 22:21Jer 2:31; 6:16
Jer. 22:21Di 9:7; Ond 2:11
Jer. 22:22Jer 23:1; Isk 34:2
Jer. 22:23Jer 22:6
Jer. 22:23Ais 2:12, 13
Jer. 22:23Jer 4:31; 6:24
Jer. 22:242Ọb 24:6; Jer 22:28; 37:1; Mt 1:11
Jer. 22:242Ọb 23:34
Jer. 22:252Ọb 24:12, 15; 2Kr 36:9, 10; Jer 24:1; 29:1, 2
Jer. 22:27Jer 52:31-34
Jer. 22:281Kr 3:17, 18
Jer. 22:302Kr 36:9, 10; Jer 36:30; Mt 1:12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 22:1-30

Jeremáyà

22 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Lọ sí ilé* ọba Júdà, kí o sì jẹ́ iṣẹ́ yìí. 2 Kí o sọ pé, ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ìwọ ọba Júdà tí o jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì, ìwọ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti àwọn èèyàn rẹ, àwọn tó ń gba àwọn ẹnubodè yìí wọlé. 3 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Ẹ máa dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, kí ẹ sì máa ṣe òdodo. Ẹ gba ẹni tí àwọn oníjìbìtì jà lólè sílẹ̀. Ẹ má ṣe ni àjèjì èyíkéyìí lára, ẹ má ṣèkà sí ọmọ aláìníbaba* èyíkéyìí tàbí opó.+ Ẹ má sì ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí.+ 4 Torí bí ẹ bá ṣe ohun tí mo sọ yìí tọkàntọkàn, nígbà náà àwọn ọba tó ń jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì+ máa gba àwọn ẹnubodè ilé yìí wọlé, àwọn àti àwọn ìránṣẹ́ wọn pẹ̀lú àwọn èèyàn wọn á gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn ẹṣin.”’+

5 “‘Àmọ́ bí ẹ ò bá ṣe ohun tí mo sọ yìí, mo fi ara mi búra pé, ilé yìí máa di ahoro,’+ ni Jèhófà wí.

6 “Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nípa ilé ọba Júdà nìyí,

‘Bíi Gílíádì lo rí sí mi,

Bí orí òkè Lẹ́bánónì.

Ṣùgbọ́n màá sọ ọ́ di aginjù;

Kò ní sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú rẹ tó máa ṣeé gbé.+

 7 Màá yan àwọn apanirun* láti wá bá ọ,

Ẹnì kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú àwọn ohun ìjà rẹ̀.+

Wọ́n á gé àwọn tó dára jù lọ lára igi kédárì rẹ lulẹ̀

Wọ́n á sì mú kí wọ́n ṣubú sínú iná.+

8 “‘Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè máa kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ́ ìlú yìí, wọ́n á sì bi ara wọn pé: “Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe irú èyí sí ìlú ńlá yìí?”+ 9 Wọ́n á fèsì pé: “Torí pé wọ́n fi májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run wọn sílẹ̀, wọ́n forí balẹ̀ fún àwọn ọlọ́run míì, wọ́n sì ń sìn wọ́n.”’+

10 Ẹ má sunkún nítorí ẹni tó ti kú,

Ẹ má sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀.

Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ nítorí ẹni tó ń lọ,

Torí kò ní pa dà mọ́ láti rí ilẹ̀ tí wọ́n bí i sí.

11 “Èyí ni ohun tí Jèhófà sọ nípa Ṣálúmù*+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà tó ń jọba nípò Jòsáyà bàbá rẹ̀,+ ẹni tó jáde kúrò ní ibí yìí: ‘Kò ní pa dà mọ́. 12 Nítorí ibi tí wọ́n mú un lọ ní ìgbèkùn ló máa kú sí, kò sì ní rí ilẹ̀ yìí mọ́.’+

13 Ẹni tó ń fi àìṣòdodo kọ́ ilé rẹ̀ ti gbé!

Tó ń fi àìṣẹ̀tọ́ kọ́ àwọn yàrá òkè rẹ̀,

Tó ń mú kí ọmọnìkejì rẹ̀ sìn ín láìgba nǹkan kan,

Tí kò sì fún un ní owó iṣẹ́ rẹ̀;+

14 Ẹni tó sọ pé, ‘Màá kọ́ ilé ńlá fún ara mi

Tí àwọn yàrá òkè rẹ̀ tóbi.

Màá ṣe àwọn fèrèsé* sí i

Màá fi igi kédárì bò ó, màá sì fi ọ̀dà tó pupa fòò kùn ún.’

15 Ṣé wàá máa ṣàkóso lọ torí pé àwọn igi kédárì tí ò ń lò pọ̀ ju ti àwọn míì lọ ni?

Bàbá rẹ jẹ, ó sì mu,

Àmọ́, ó dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́, ó ṣe òdodo,+

Nǹkan sì lọ dáadáa fún un.

16 Ó gbèjà ẹ̀tọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ àti àwọn aláìní,

Nǹkan sì lọ dáadáa.

‘Ǹjẹ́ kì í ṣe ohun tó fi hàn pé ẹnì kan mọ̀ mí nìyẹn?’ ni Jèhófà wí.

17 ‘Àmọ́ ojú rẹ àti ọkàn rẹ ò kúrò lórí bí o ṣe máa jẹ èrè tí kò tọ́,

Lórí bí o ṣe máa ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀

Àti lórí bí o ṣe máa lu jìbìtì àti bí o ṣe máa lọ́ni lọ́wọ́ gbà.’

18 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nípa Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà nìyí,

‘Wọn kò ní ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ pé:

“Áà, arákùnrin mi! Áà, arábìnrin mi!”

Wọn kò sì ní ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ pé:

“Áà, ọ̀gá! Áà, kábíyèsí!”

19 Bí wọ́n ṣe ń sin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni wọ́n máa sin ín,+

Wọ́n á wọ́ ọ kiri, wọ́n á sì gbé e sọ nù,

Sí ìta ẹnubodè Jerúsálẹ́mù.’+

20 Gòkè lọ sí Lẹ́bánónì kí o sì ké,

Gbé ohùn rẹ sókè ní Báṣánì,

Sì ké láti Ábárímù,+

Torí pé gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ àtàtà ni wọ́n ti pa.+

21 Mo bá ọ sọ̀rọ̀ nígbà tí o rò pé kò séwu.

Àmọ́, o sọ pé, ‘Mi ò ní ṣègbọràn.’+

Bí o ṣe máa ń ṣe nìyẹn láti ìgbà èwe rẹ,

Nítorí ìwọ kò ṣègbọràn sí ohùn mi.+

22 Ẹ̀fúùfù á gbé gbogbo olùṣọ́ àgùntàn rẹ lọ,*+

Àwọn olólùfẹ́ rẹ àtàtà á sì lọ sí oko ẹrú.

Ìgbà yẹn ni ojú máa tì ọ́, wàá sì di ẹni ẹ̀tẹ́ nítorí gbogbo àjálù rẹ.

23 Ẹ̀yin tó ń gbé ní Lẹ́bánónì,+

Tí ìtẹ́ yín wà láàárín igi kédárì,+

Ẹ wo bí ẹ ó ti kérora tó nígbà tí ìrora bá dé bá yín,

Ìdààmú* bíi ti obìnrin tó ń rọbí!”+

24 “‘Bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà wí, ‘kódà bí Konáyà*+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà, bá tiẹ̀ jẹ́ òrùka èdìdì ní ọwọ́ ọ̀tún mi, ibẹ̀ ni màá ti yọ ọ́ kúrò! 25 Màá fi ọ́ lé ọwọ́ àwọn tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ,* lé ọwọ́ àwọn tí ò ń bẹ̀rù, lé ọwọ́ Nebukadinésárì* ọba Bábílónì àti lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà.+ 26 Màá fi ẹ̀yin àti ìyá tó bí yín lọ́mọ sọ̀kò sí ilẹ̀ míì tí kì í ṣe ibi tí wọ́n bí yín sí, ibẹ̀ sì ni ẹ máa kú sí. 27 Wọn kò sì ní lè pa dà láé sí ilẹ̀ tí ọkàn wọn fẹ́.*+

28 Ṣé ọkùnrin yìí, Konáyà, jẹ́ ẹni ẹ̀sín, ìkòkò tó ti fọ́,

Ohun èlò tí ẹnikẹ́ni kò fẹ́?

Kí nìdí tí a fi wó òun pẹ̀lú àtọmọdọ́mọ rẹ̀ lulẹ̀

Tí a sì sọ wọ́n sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀?’+

29 “Ìwọ ilẹ̀, ilẹ̀, ilẹ̀, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.

30 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

‘Ẹ kọ ọ́ sílẹ̀ pé ọkùnrin yìí kò bímọ,

Pé ọkùnrin yìí kò ní ṣe àṣeyọrí kankan jálẹ̀ ayé rẹ̀,*

Nítorí kò sí ìkankan nínú àtọmọdọ́mọ rẹ̀ tó máa ṣàṣeyọrí

Láti jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì kí ó sì ṣàkóso ní Júdà lẹ́ẹ̀kan sí i.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́