ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 47
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Ìṣubú Bábílónì (1-15)

        • Àṣírí àwọn awòràwọ̀ tú (13-15)

Àìsáyà 47:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 137:8; Jer 50:41, 42
  • +Da 5:30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 106-107

Àìsáyà 47:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 106-107

Àìsáyà 47:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “mi ò sì ní ṣàánú ẹnikẹ́ni.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:35, 41; Sm 94:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 107

Àìsáyà 47:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:14; 43:3; 44:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 107-108

Àìsáyà 47:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọbabìnrin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 47:1
  • +Ais 13:19; 14:4; Ifi 17:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 108

Àìsáyà 47:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:15, 16; Ais 42:24, 25; Sek 1:15
  • +Di 28:63; Isk 24:21
  • +Jer 52:14
  • +2Ọb 25:18-21; Sm 137:8
  • +Di 28:49, 50

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 108-109

Àìsáyà 47:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọbabìnrin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 4:30; Ifi 18:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 109

Àìsáyà 47:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 18:3
  • +Da 5:22, 23
  • +Ifi 18:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 110-111, 119

Àìsáyà 47:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Láìka.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 18:10
  • +Jer 51:29
  • +Isk 21:21; Da 5:7; Ifi 18:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 112, 119

Àìsáyà 47:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 112-113

Àìsáyà 47:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “O ò sì ní lè sa oògùn sí i.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ifi 18:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 113

Àìsáyà 47:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 2:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 113

Àìsáyà 47:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “Àwọn tó ń pín ọ̀run; Àwọn awòràwọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 5:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 113-114

Àìsáyà 47:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 114-115

Àìsáyà 47:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “kálukú lọ sí agbègbè rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 51:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 114-115

Àwọn míì

Àìsá. 47:1Sm 137:8; Jer 50:41, 42
Àìsá. 47:1Da 5:30
Àìsá. 47:3Di 32:35, 41; Sm 94:1
Àìsá. 47:4Ais 41:14; 43:3; 44:6
Àìsá. 47:5Ais 47:1
Àìsá. 47:5Ais 13:19; 14:4; Ifi 17:5
Àìsá. 47:62Kr 36:15, 16; Ais 42:24, 25; Sek 1:15
Àìsá. 47:6Di 28:63; Isk 24:21
Àìsá. 47:6Jer 52:14
Àìsá. 47:62Ọb 25:18-21; Sm 137:8
Àìsá. 47:6Di 28:49, 50
Àìsá. 47:7Da 4:30; Ifi 18:7
Àìsá. 47:8Ifi 18:3
Àìsá. 47:8Da 5:22, 23
Àìsá. 47:8Ifi 18:7
Àìsá. 47:9Ifi 18:10
Àìsá. 47:9Jer 51:29
Àìsá. 47:9Isk 21:21; Da 5:7; Ifi 18:23
Àìsá. 47:11Ifi 18:10
Àìsá. 47:12Da 2:2
Àìsá. 47:13Da 5:7
Àìsá. 47:15Jer 51:6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 47:1-15

Àìsáyà

47 Sọ̀ kalẹ̀ wá jókòó sínú iyẹ̀pẹ̀,

Ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Bábílónì.+

Jókòó sílẹ̀ níbi tí kò sí ìtẹ́,+

Ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà,

Torí àwọn èèyàn ò tún ní pè ọ́ ní ẹlẹgẹ́ àti àkẹ́jù mọ́.

 2 Mú ọlọ, kí o sì lọ ìyẹ̀fun.

Yọ ìbòjú rẹ.

Bọ́ aṣọ rẹ, ká aṣọ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.

Sọdá àwọn odò.

 3 A máa tú ọ sí ìhòòhò.

Ìtìjú rẹ máa hàn síta.

Màá gbẹ̀san, + èèyàn kankan ò sì ní dá mi dúró.*

 4 “Ẹni tó ń tún wa rà,

Ni Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì,+

Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.”

 5 Jókòó síbẹ̀, dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí o sì lọ sínú òkùnkùn,

Ìwọ ọmọbìnrin àwọn ará Kálídíà;+

Wọn ò ní pè ọ́ ní Ìyálóde* Àwọn Ìjọba mọ́.+

 6 Inú bí mi sí àwọn èèyàn mi.+

Mo sọ ogún mi di aláìmọ́,+

Mo sì fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́.+

Àmọ́ o ò ṣàánú wọn rárá.+

Kódà, o gbé àjàgà tó wúwo lé àgbàlagbà.+

 7 O sọ pé: “Títí láé ni màá jẹ́ Ìyálóde.”*+

O ò fi àwọn nǹkan yìí sọ́kàn;

O ò ro ibi tí ọ̀rọ̀ náà máa já sí.

 8 Wá gbọ́ èyí, ìwọ ẹni tó fẹ́ràn fàájì,+

Tó jókòó láìséwu, tó ń sọ lọ́kàn rẹ̀ pé:

“Èmi ni ẹni náà, kò sí ẹlòmíì.+

Mi ò ní di opó.

Mi ò ní ṣòfò ọmọ láé.”+

 9 Àmọ́ nǹkan méjèèjì yìí máa dé bá ọ lójijì, lọ́jọ́ kan ṣoṣo:+

Wàá ṣòfò ọmọ, wàá sì di opó.

Wọ́n máa dé bá ọ ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́,+

Torí* ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ àti gbogbo èèdì rẹ tó lágbára.+

10 O gbẹ́kẹ̀ lé ìwà burúkú rẹ.

O sọ pé: “Kò sẹ́ni tó ń rí mi.”

Ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ ló kó ọ ṣìnà,

O sì ń sọ lọ́kàn rẹ pé: “Èmi ni ẹni náà, kò sí ẹlòmíì.”

11 Àmọ́ àjálù máa dé bá ọ,

Ìkankan nínú àwọn oògùn rẹ ò sì ní dá a dúró.*

O máa ko àgbákò; o ò ní lè yẹ̀ ẹ́.

Ìparun òjijì máa dé bá ọ, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ sí ọ rí.+

12 Máa fi èèdì di àwọn èèyàn lọ, kí o sì máa ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àjẹ́ rẹ,+

Èyí tí o ti ń ṣe kára látìgbà ọ̀dọ́ rẹ.

Bóyá wàá lè jàǹfààní;

Bóyá wàá lè mú kí ẹ̀rù ba àwọn èèyàn.

13 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn agbani-nímọ̀ràn rẹ ti tán ọ lókun.

Kí wọ́n dìde báyìí, kí wọ́n sì gbà ọ́ là,

Àwọn tó ń jọ́sìn ọ̀run,* tí wọ́n ń wo ìràwọ̀,+

Àwọn tó ń fúnni ní ìmọ̀ nígbà òṣùpá tuntun,

Nípa àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí ọ.

14 Wò ó! Wọ́n dà bí àgékù pòròpórò.

Iná máa jó wọn run.

Wọn ò lè gba ara* wọn lọ́wọ́ agbára ọwọ́ iná.

Àwọn èédú yìí kì í ṣe èyí tí a lè fi yáná,

Iná yìí kì í sì í ṣe èyí tí a lè jókòó síwájú rẹ̀.

15 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn atujú rẹ máa rí sí ọ,

Àwọn tí ẹ jọ ṣiṣẹ́ kára látìgbà ọ̀dọ́ rẹ.

Wọ́n máa rìn gbéregbère, kálukú ní ọ̀nà tirẹ̀.*

Kò ní sí ẹni tó máa gbà ọ́ là.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́