ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 1 Tẹsalóníkà 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 1 Tẹsalóníkà

      • Ọjọ́ Jèhófà ń bọ̀ (1-5)

        • “Àlàáfíà àti ààbò!” (3)

      • Ẹ wà lójúfò, ẹ máa ronú bó ṣe tọ́ (6-11)

      • Ọ̀rọ̀ ìyànjú (12-24)

      • Ìkíni tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ (25-28)

1 Tẹsalóníkà 5:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àfikún A5.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 1:14
  • +Mt 24:36; 2Pe 3:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2019, ojú ìwé 8-9

    9/2019, ojú ìwé 9

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 222

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2012, ojú ìwé 3-4

    7/15/2010, ojú ìwé 5

    5/1/2009, ojú ìwé 13-14

    5/15/2008, ojú ìwé 15-16

1 Tẹsalóníkà 5:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 37:10; Jer 8:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2019, ojú ìwé 8-9

    9/2019, ojú ìwé 9-10

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 222-223

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2013, ojú ìwé 12-13

    1/1/2013, ojú ìwé 7

    9/15/2012, ojú ìwé 3-4

    7/15/2010, ojú ìwé 5

    5/15/2008, ojú ìwé 15-16

    2/1/2004, ojú ìwé 20-21

    6/1/1997, ojú ìwé 9-10

    4/15/1995, ojú ìwé 25

    8/1/1994, ojú ìwé 6

    9/15/1991, ojú ìwé 16

    9/1/1991, ojú ìwé 5-6, 7-8

    4/15/1991, ojú ìwé 7

    Jí!,

    4/2008, ojú ìwé 7

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 251

    Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 182

    Ọlọrun Bikita, ojú ìwé 21

    Ète Igbesi-Aye, ojú ìwé 28

1 Tẹsalóníkà 5:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 12:36; Ro 13:12; Ef 5:8
  • +Jo 8:12; Kol 1:13; 1Pe 2:9

1 Tẹsalóníkà 5:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 13:11
  • +Mt 24:42
  • +1Pe 5:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2019, ojú ìwé 9

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2012, ojú ìwé 10

    1/1/2003, ojú ìwé 11

1 Tẹsalóníkà 5:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 13:13

1 Tẹsalóníkà 5:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Irú èyí tí àwọn ọmọ ogun máa ń dé.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 6:14-17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    ‘Ìfẹ́ Ọlọ́run’, ojú ìwé 203

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2013, ojú ìwé 11

    12/15/2008, ojú ìwé 7

    10/1/2006, ojú ìwé 29

    1/1/2003, ojú ìwé 20-22

    6/1/2000, ojú ìwé 9-10

    4/15/1993, ojú ìwé 11-13

    1/15/1991, ojú ìwé 22

    Jí!,

    5/8/2004, ojú ìwé 22

1 Tẹsalóníkà 5:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Tẹ 2:13

1 Tẹsalóníkà 5:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sùn nínú ikú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 5:8
  • +1Tẹ 4:16, 17

1 Tẹsalóníkà 5:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tu ara yín nínú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 1:11, 12; 15:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 48

    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba,

    9/2005, ojú ìwé 7

1 Tẹsalóníkà 5:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2011, ojú ìwé 24-28

    6/1/1999, ojú ìwé 18

    8/15/1991, ojú ìwé 19

1 Tẹsalóníkà 5:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Flp 2:29, 30; 1Ti 5:17; Heb 13:7
  • +Mk 9:50; 2Kọ 13:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/1999, ojú ìwé 18-19

    8/15/1991, ojú ìwé 19

1 Tẹsalóníkà 5:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gba àwọn tó ń ṣe ségesège níyànjú.”

  • *

    Tàbí “àwọn tó rẹ̀wẹ̀sì.” Ní Grk., “àwọn tó ní ọkàn kékeré.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:17; 2Ti 4:2
  • +1Kọ 13:4; Ga 5:22; Ef 4:1, 2; Kol 3:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    10/2017, ojú ìwé 10

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2015, ojú ìwé 9

    8/15/2013, ojú ìwé 22

    6/15/2010, ojú ìwé 12-13

    5/1/2004, ojú ìwé 21

    11/1/2001, ojú ìwé 17-18

    10/1/1995, ojú ìwé 15-16

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 102-103, 166-167

    Jí!,

    11/2013, ojú ìwé 10

    Ayọ̀ Ìdílé, ojú ìwé 36-37

1 Tẹsalóníkà 5:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 5:39
  • +Ro 12:17, 19

1 Tẹsalóníkà 5:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 6:4, 10; Flp 4:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    12/15/1991, ojú ìwé 8-9

1 Tẹsalóníkà 5:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 18:1; Ro 12:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2010, ojú ìwé 9

    9/15/2003, ojú ìwé 15-20

1 Tẹsalóníkà 5:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 5:20; Kol 3:17

1 Tẹsalóníkà 5:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ef 4:30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2000, ojú ìwé 10

1 Tẹsalóníkà 5:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 14:1

1 Tẹsalóníkà 5:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Jo 4:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/15/1996, ojú ìwé 17

    Jí!,

    2/8/1996, ojú ìwé 6

1 Tẹsalóníkà 5:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 2:3

1 Tẹsalóníkà 5:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹ̀mí.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 1:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2008, ojú ìwé 29

    5/1/1993, ojú ìwé 11

1 Tẹsalóníkà 5:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ro 15:30

1 Tẹsalóníkà 5:26

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2019, ojú ìwé 4-5

1 Tẹsalóníkà 5:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Kol 4:16

Àwọn míì

1 Tẹs. 5:2Sef 1:14
1 Tẹs. 5:2Mt 24:36; 2Pe 3:10
1 Tẹs. 5:3Sm 37:10; Jer 8:11
1 Tẹs. 5:5Jo 12:36; Ro 13:12; Ef 5:8
1 Tẹs. 5:5Jo 8:12; Kol 1:13; 1Pe 2:9
1 Tẹs. 5:6Ro 13:11
1 Tẹs. 5:6Mt 24:42
1 Tẹs. 5:61Pe 5:8
1 Tẹs. 5:7Ro 13:13
1 Tẹs. 5:8Ef 6:14-17
1 Tẹs. 5:92Tẹ 2:13
1 Tẹs. 5:10Ro 5:8
1 Tẹs. 5:101Tẹ 4:16, 17
1 Tẹs. 5:11Ro 1:11, 12; 15:2
1 Tẹs. 5:13Flp 2:29, 30; 1Ti 5:17; Heb 13:7
1 Tẹs. 5:13Mk 9:50; 2Kọ 13:11
1 Tẹs. 5:14Le 19:17; 2Ti 4:2
1 Tẹs. 5:141Kọ 13:4; Ga 5:22; Ef 4:1, 2; Kol 3:13
1 Tẹs. 5:15Mt 5:39
1 Tẹs. 5:15Ro 12:17, 19
1 Tẹs. 5:162Kọ 6:4, 10; Flp 4:4
1 Tẹs. 5:17Lk 18:1; Ro 12:12
1 Tẹs. 5:18Ef 5:20; Kol 3:17
1 Tẹs. 5:19Ef 4:30
1 Tẹs. 5:201Kọ 14:1
1 Tẹs. 5:211Jo 4:1
1 Tẹs. 5:22Job 2:3
1 Tẹs. 5:231Kọ 1:8
1 Tẹs. 5:25Ro 15:30
1 Tẹs. 5:27Kol 4:16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
1 Tẹsalóníkà 5:1-28

Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Tẹsalóníkà

5 Ẹ̀yin ará, ní ti àwọn ìgbà àti àwọn àsìkò, ẹ ò nílò kí a kọ nǹkan kan ránṣẹ́ sí yín. 2 Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ dáadáa pé ọjọ́ Jèhófà*+ ń bọ̀ bí olè ní òru.+ 3 Nígbàkigbà tí wọ́n bá ń sọ pé, “Àlàáfíà àti ààbò!” ìgbà náà ni ìparun òjijì yóò dé lọ́gán sórí wọn,+ bí ìgbà tí obìnrin tó lóyún bá bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, wọn ò sì ní yè bọ́ lọ́nàkọnà. 4 Àmọ́, ẹ̀yin ará, ẹ ò sí nínú òkùnkùn, tí ọjọ́ yẹn á fi dé bá yín lójijì bí ìgbà tí ilẹ̀ mọ́ bá olè, 5 nítorí gbogbo yín jẹ́ ọmọ ìmọ́lẹ̀ àti ọmọ ọ̀sán.+ Àwa kì í ṣe ti òru tàbí ti òkùnkùn.+

6 Torí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a máa sùn bí àwọn yòókù ti ń ṣe,+ àmọ́ ẹ jẹ́ kí a wà lójúfò,+ kí a sì máa ronú bó ṣe tọ́.+ 7 Nítorí àwọn tó ń sùn máa ń sùn ní òru, àwọn tó sì ń mutí yó máa ń mutí yó ní òru.+ 8 Àmọ́ ní ti àwa tí a jẹ́ ti ọ̀sán, ẹ jẹ́ kí a máa ronú bó ṣe tọ́, kí a gbé àwo ìgbàyà ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ wọ̀, kí a sì dé ìrètí ìgbàlà bí akoto*+ 9 nítorí Ọlọ́run kò yàn wá fún ìrunú, bí kò ṣe láti rí ìgbàlà+ nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa. 10 Ó kú fún wa,+ kó lè jẹ́ pé, bóyá a sùn* tàbí a ò sùn, a máa lè wà láàyè pẹ̀lú rẹ̀.+ 11 Nítorí náà, ẹ máa fún ara yín níṣìírí,* kí ẹ sì máa gbé ara yín ró,+ bí ẹ ti ń ṣe ní tòótọ́.

12 Ní báyìí, ẹ̀yin ará, a fẹ́ kí ẹ máa bọ̀wọ̀ fún àwọn tó ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, tí wọ́n ń ṣe àbójútó yín nínú Olúwa, tí wọ́n sì ń gbà yín níyànjú; 13 ẹ máa kà wọ́n sí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nínú ìfẹ́ nítorí iṣẹ́ wọn.+ Ẹ wà ní àlàáfíà pẹ̀lú ara yín.+ 14 Lẹ́sẹ̀ kan náà, ẹ̀yin ará, à ń rọ̀ yín pé kí ẹ máa kìlọ̀ fún àwọn tó ń ṣe ségesège,*+ ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn tó sorí kọ́,* ẹ máa ran àwọn aláìlera lọ́wọ́, ẹ máa mú sùúrù fún gbogbo èèyàn.+ 15 Ẹ rí i pé ẹnikẹ́ni ò fi búburú san búburú fún ẹnì kankan,+ kí ẹ sì máa fìgbà gbogbo wá ohun rere fún ara yín àti fún gbogbo àwọn míì.+

16 Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo.+ 17 Ẹ máa gbàdúrà nígbà gbogbo.+ 18 Ẹ máa dúpẹ́ ohun gbogbo.+ Ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún yín nìyí nínú Kristi Jésù. 19 Ẹ má ṣe pa iná ẹ̀mí.+ 20 Ẹ má ṣe kó àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ dà nù.+ 21 Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú;+ ẹ di èyí tó dára mú ṣinṣin. 22 Ẹ yẹra fún gbogbo ìwà burúkú.+

23 Kí Ọlọ́run àlàáfíà fúnra rẹ̀ sọ yín di mímọ́ pátápátá. Kí ẹ̀mí àti ọkàn* àti ara ẹ̀yin ará, tó dára ní gbogbo ọ̀nà, jẹ́ aláìlẹ́bi nígbà tí Olúwa wa Jésù Kristi bá wà níhìn-ín.+ 24 Ẹni tó ń pè yín jẹ́ olóòótọ́, ó sì dájú pé ó máa ṣe bẹ́ẹ̀.

25 Ẹ̀yin ará, ẹ máa gbàdúrà fún wa.+

26 Ẹ fi ìfẹnukonu mímọ́ kí gbogbo àwọn ará.

27 Mò ń fi dandan lé e fún yín ní orúkọ Olúwa pé kí ẹ ka lẹ́tà yìí fún gbogbo àwọn ará.+

28 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Olúwa wa Jésù Kristi wà pẹ̀lú yín.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́