ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 37
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Àwọn ará Kálídíà ṣígun lọ fúngbà díẹ̀ (1-10)

      • Wọ́n fi Jeremáyà sẹ́wọ̀n (11-16)

      • Sedekáyà pàdé Jeremáyà (17-21)

        • Wọ́n ń fún Jeremáyà ní búrẹ́dì (21)

Jeremáyà 37:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wọ́n tún ń pè é ní Jèhóákínì àti Jekonáyà.

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:17-19; 1Kr 3:15
  • +2Ọb 24:12; Jer 22:24
  • +2Kr 36:10-12

Jeremáyà 37:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 38:1, 4
  • +2Ọb 25:18, 21; Jer 21:1, 2; 29:25

Jeremáyà 37:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 37:15

Jeremáyà 37:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 17:15
  • +Jer 34:21

Jeremáyà 37:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 17:5; Ida 4:17; Isk 17:17

Jeremáyà 37:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 32:29; 34:22; 39:8

Jeremáyà 37:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Jeremáyà 37:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:4

Jeremáyà 37:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 34:21

Jeremáyà 37:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:1

Jeremáyà 37:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb, “wọ́n fi í sínú ilé ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 26:11; 38:4
  • +Jer 20:2; Heb 11:32, 36

Jeremáyà 37:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ilé kòtò omi.”

Jeremáyà 37:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 38:14
  • +Jer 21:7; 24:8; 34:21; Isk 12:12, 13

Jeremáyà 37:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 14:13; 23:16, 17; 27:14; 28:1, 2; Ida 2:14

Jeremáyà 37:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 37:15
  • +Jer 26:15; 38:8, 9

Jeremáyà 37:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 3:25; Jer 32:2; 33:1; 38:13, 28
  • +1Ọb 17:6
  • +2Ọb 25:3; Jer 38:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/1997, ojú ìwé 3-4

Àwọn míì

Jer. 37:12Ọb 24:17-19; 1Kr 3:15
Jer. 37:12Ọb 24:12; Jer 22:24
Jer. 37:12Kr 36:10-12
Jer. 37:3Jer 38:1, 4
Jer. 37:32Ọb 25:18, 21; Jer 21:1, 2; 29:25
Jer. 37:4Jer 37:15
Jer. 37:5Isk 17:15
Jer. 37:5Jer 34:21
Jer. 37:7Jer 17:5; Ida 4:17; Isk 17:17
Jer. 37:8Jer 32:29; 34:22; 39:8
Jer. 37:10Jer 21:4
Jer. 37:11Jer 34:21
Jer. 37:12Jer 1:1
Jer. 37:15Jer 26:11; 38:4
Jer. 37:15Jer 20:2; Heb 11:32, 36
Jer. 37:17Jer 38:14
Jer. 37:17Jer 21:7; 24:8; 34:21; Isk 12:12, 13
Jer. 37:19Jer 14:13; 23:16, 17; 27:14; 28:1, 2; Ida 2:14
Jer. 37:20Jer 37:15
Jer. 37:20Jer 26:15; 38:8, 9
Jer. 37:21Ne 3:25; Jer 32:2; 33:1; 38:13, 28
Jer. 37:211Ọb 17:6
Jer. 37:212Ọb 25:3; Jer 38:9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 37:1-21

Jeremáyà

37 Ọba Sedekáyà+ ọmọ Jòsáyà bẹ̀rẹ̀ sí í jọba ní ipò Konáyà*+ ọmọ Jèhóákímù, nítorí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì fi jẹ ọba ní ilẹ̀ Júdà.+ 2 Àmọ́ òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà kò fetí sí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí wòlíì Jeremáyà sọ.

3 Ọba Sedekáyà rán Jéhúkálì  + ọmọ Ṣelemáyà àti Sefanáyà+ ọmọ àlùfáà Maaseáyà sí wòlíì Jeremáyà pé: “Jọ̀wọ́, bá wa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run wa.” 4 Jeremáyà ń rìn fàlàlà láàárín àwọn èèyàn náà, torí wọn kò tíì fi í sẹ́wọ̀n.+ 5 Nígbà náà, àwọn ọmọ ogun Fáráò jáde kúrò ní Íjíbítì,+ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó ti Jerúsálẹ́mù sì gbọ́ ìròyìn nípa wọn. Torí náà, wọ́n ṣígun kúrò ní Jerúsálẹ́mù.+ 6 Ìgbà náà ni Jèhófà bá wòlíì Jeremáyà sọ̀rọ̀, ó ní: 7 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ohun tí ẹ máa sọ fún ọba Júdà, tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi láti wádìí nìyí: “Wò ó! Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó ń bọ̀ wá ràn yín lọ́wọ́ yóò ní láti pa dà sí Íjíbítì, ilẹ̀ wọn.+ 8 Àwọn ará Kálídíà á sì pa dà wá, wọ́n á bá ìlú yìí jà, wọ́n á gbà á, wọ́n á sì dáná sun ún.”+ 9 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, “Ẹ má tan ara* yín jẹ pé, ‘Àwọn ará Kálídíà kò ní pa dà wá,’ torí ó dájú pé wọ́n á pa dà wá. 10 Kódà bí ẹ bá pa gbogbo ọmọ ogun Kálídíà tó ń bá yín jà, tó sì jẹ́ pé àwọn tó fara pa nìkan ló ṣẹ́ kù, wọ́n ṣì máa wá látinú àgọ́ wọn, wọ́n á sì dáná sun ìlú yìí.”’”+

11 Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Kálídíà ti ṣígun kúrò ní Jerúsálẹ́mù nítorí àwọn ọmọ ogun Fáráò,+ 12 Jeremáyà jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì+ láti lọ gba ìpín rẹ̀ tó wà láàárín àwọn èèyàn rẹ̀ níbẹ̀. 13 Àmọ́ nígbà tó dé Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì, ọ̀gá tó ń bójú tó àwọn ẹ̀ṣọ́, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Íríjà ọmọ Ṣelemáyà ọmọ Hananáyà mú wòlíì Jeremáyà, ó sì sọ pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn ará Kálídíà lò ń sá lọ!” 14 Ṣùgbọ́n Jeremáyà sọ pé: “Rárá o! Mi ò sá lọ sọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà.” Àmọ́ kò gbọ́ tirẹ̀. Torí náà Íríjà mú Jeremáyà, ó sì mú un wá sọ́dọ̀ àwọn ìjòyè. 15 Inú bí àwọn ìjòyè gan-an sí Jeremáyà,+ wọ́n lù ú, wọ́n sì fi í sẹ́wọ̀n*+ ní ilé Jèhónátánì akọ̀wé, tí wọ́n ti sọ di ọgbà ẹ̀wọ̀n. 16 Wọ́n fi Jeremáyà sínú ẹ̀wọ̀n abẹ́ ilẹ̀,* nínú àwọn yàrá tó láàbò, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ló sì fi wà níbẹ̀.

17 Lẹ́yìn náà, Ọba Sedekáyà ránṣẹ́ pè é, ọba sì bi í ní ìbéèrè ní bòókẹ́lẹ́ nínú ilé* rẹ̀.+ Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ kankan wà látọ̀dọ̀ Jèhófà?” Jeremáyà fèsì pé, “Ó wà!” ó sì fi kún un pé, “A ó fi ọ́ lé ọwọ́ ọba Bábílónì!”+

18 Jeremáyà tún sọ fún Ọba Sedekáyà pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ ìwọ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ pẹ̀lú àwọn èèyàn yìí, tí ẹ fi fi mí sẹ́wọ̀n? 19 Ibo wá ni àwọn wòlíì yín wà, àwọn tó sọ tẹ́lẹ̀ fún yín pé, ‘Ọba Bábílónì kò ní wá gbéjà ko ẹ̀yin àti ilẹ̀ yìí’?+ 20 Jọ̀wọ́, ní báyìí, fetí sílẹ̀, olúwa mi ọba. Jọ̀wọ́, gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, kí o sì ṣojú rere sí mi. Má ṣe dá mi pa dà sí ilé Jèhónátánì+ akọ̀wé, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ibẹ̀ ni màá kú sí.”+ 21 Nítorí náà, Ọba Sedekáyà ní kí wọ́n fi Jeremáyà sínú àhámọ́ ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́,+ wọ́n sì ń fún un ní ìṣù búrẹ́dì ribiti kan lójúmọ́ láti òpópónà àwọn tó ń ṣe búrẹ́dì,+ títí gbogbo búrẹ́dì ìlú náà fi tán.+ Jeremáyà kò sì kúrò ní Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́