ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Émọ́sì 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Émọ́sì

      • Ísírẹ́lì dà bíi wúńdíá tó ṣubú (1-3)

      • Wá Ọlọ́run, kí o lè máa wà láàyè (4-17)

        • Kórìíra ohun búburú, nífẹ̀ẹ́ ohun rere (15)

      • Ọjọ́ Jèhófà máa jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn (18-27)

        • Ọlọ́run kọ ẹbọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì (22)

Émọ́sì 5:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”

Émọ́sì 5:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:27; 28:62

Émọ́sì 5:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 15:2; Ais 55:3, 6

Émọ́sì 5:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ohun abàmì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 12:28, 29; Emọ 3:14
  • +Ho 4:15; Emọ 4:4
  • +Emọ 8:14
  • +2Ọb 17:6; Ho 9:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 14

Émọ́sì 5:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 33:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    11/2017, ojú ìwé 2

Émọ́sì 5:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìkorò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 6:12

Émọ́sì 5:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àwọn ìràwọ̀ Píláédì tó wà nínú àgbájọ ìràwọ̀ Tọ́rọ́sì.

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àgbájọ ìràwọ̀ Óríónì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 9:9; 38:31-33
  • +Ẹk 10:21, 22
  • +Job 36:27, 28; Onw 1:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2009, ojú ìwé 16-17

Émọ́sì 5:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 18:17; 22:8

Émọ́sì 5:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “owó ilẹ̀.”

  • *

    Tàbí “owó òde.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 2:2
  • +Ais 9:9, 10
  • +Di 28:30

Émọ́sì 5:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìwà ọ̀daràn.”

  • *

    Tàbí “owó mẹ́numọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 10:1, 2; Emọ 2:6, 7

Émọ́sì 5:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 2:3

Émọ́sì 5:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:16, 17; Mik 6:8
  • +Le 18:5; Di 30:19, 20
  • +2Kr 15:2; Mik 3:11

Émọ́sì 5:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 34:14; 97:10; Ro 12:9
  • +2Kr 19:6; Emọ 5:24
  • +Jer 31:7; Sek 10:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 90-91

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2004, ojú ìwé 22-24

Émọ́sì 5:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 9:2

Émọ́sì 5:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 5:18, 19
  • +Emọ 4:12
  • +Sef 1:14, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 15

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 38-40

Émọ́sì 5:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 38

Émọ́sì 5:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 15:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2004, ojú ìwé 22

Émọ́sì 5:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 50:8; Ais 66:3; Ho 6:6
  • +Ais 1:11

Émọ́sì 5:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Emọ 6:5; 8:10

Émọ́sì 5:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 6:8

Émọ́sì 5:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:42, 43

Émọ́sì 5:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí àwọn òrìṣà méjèèjì yìí máa tọ́ka sí pílánẹ́ẹ̀tì Sátọ̀n tí wọ́n ń sìn bí ọlọ́run.

Émọ́sì 5:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 15:29; 17:6
  • +Emọ 4:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2007, ojú ìwé 14

Àwọn míì

Émọ́sì 5:3Di 4:27; 28:62
Émọ́sì 5:42Kr 15:2; Ais 55:3, 6
Émọ́sì 5:51Ọb 12:28, 29; Emọ 3:14
Émọ́sì 5:5Ho 4:15; Emọ 4:4
Émọ́sì 5:5Emọ 8:14
Émọ́sì 5:52Ọb 17:6; Ho 9:15
Émọ́sì 5:6Isk 33:11
Émọ́sì 5:7Emọ 6:12
Émọ́sì 5:8Job 9:9; 38:31-33
Émọ́sì 5:8Ẹk 10:21, 22
Émọ́sì 5:8Job 36:27, 28; Onw 1:7
Émọ́sì 5:101Ọb 18:17; 22:8
Émọ́sì 5:11Mik 2:2
Émọ́sì 5:11Ais 9:9, 10
Émọ́sì 5:11Di 28:30
Émọ́sì 5:12Ais 10:1, 2; Emọ 2:6, 7
Émọ́sì 5:13Mik 2:3
Émọ́sì 5:14Ais 1:16, 17; Mik 6:8
Émọ́sì 5:14Le 18:5; Di 30:19, 20
Émọ́sì 5:142Kr 15:2; Mik 3:11
Émọ́sì 5:15Sm 34:14; 97:10; Ro 12:9
Émọ́sì 5:152Kr 19:6; Emọ 5:24
Émọ́sì 5:15Jer 31:7; Sek 10:6
Émọ́sì 5:17Ho 9:2
Émọ́sì 5:18Ais 5:18, 19
Émọ́sì 5:18Emọ 4:12
Émọ́sì 5:18Sef 1:14, 15
Émọ́sì 5:21Owe 15:8
Émọ́sì 5:22Sm 50:8; Ais 66:3; Ho 6:6
Émọ́sì 5:22Ais 1:11
Émọ́sì 5:23Emọ 6:5; 8:10
Émọ́sì 5:24Mik 6:8
Émọ́sì 5:25Iṣe 7:42, 43
Émọ́sì 5:272Ọb 15:29; 17:6
Émọ́sì 5:27Emọ 4:13
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Émọ́sì 5:1-27

Émọ́sì

5 “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí tí màá fi orin arò* sọ fún yín, ilé Ísírẹ́lì:

 2 ‘Wúńdíá náà, Ísírẹ́lì, ti ṣubú;

Kò lè dìde mọ́.

Wọ́n ti pa á tì sórí ilẹ̀ rẹ̀;

Kò sí ẹnì kankan tó máa gbé e dìde.’

3 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:

‘Ìlú tó ń jáde lọ sí ogun pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún (1,000) máa ṣẹ́ ku ọgọ́rùn-ún (100);

Èyí tó sì ń jáde lọ pẹ̀lú ọgọ́rùn-ún (100) máa ṣẹ́ ku mẹ́wàá fún ilé Ísírẹ́lì.’+

4 “Ohun tí Jèhófà sọ fún ilé Ísírẹ́lì nìyí:

‘Wá mi, kí o lè máa wà láàyè.+

 5 Ẹ má ṣe wá Bẹ́tẹ́lì kiri,+

Ẹ má lọ sí Gílígálì,+ ẹ má sì kọjá sí Bíá-ṣébà,+

Torí ó dájú pé Gílígálì máa lọ sí ìgbèkùn,+

Bẹ́tẹ́lì á sì di asán.*

 6 Wá Jèhófà, kí o lè máa wà láàyè,+

Kó má bàa bú jáde bí iná sórí ilé Jósẹ́fù,

Kó má bàa jó Bẹ́tẹ́lì run láìsí ẹni tó máa pa iná náà.

 7 Ẹ sọ ìdájọ́ òdodo di iwọ,*

Ẹ sì tẹ òdodo mọ́lẹ̀.+

 8 Ẹni tó dá àgbájọ ìràwọ̀ Kímà* àti àgbájọ ìràwọ̀ Késílì,*+

Ẹni tó ń sọ òkùnkùn biribiri di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,

Ẹni tó ń mú kí ọ̀sán ṣókùnkùn bí òru,+

Ẹni tó ń wọ́ omi jọ látinú òkun

Kí ó lè dà á sórí ilẹ̀,+

Jèhófà ni orúkọ rẹ̀.

 9 Á mú kí ìparun dé bá alágbára lójijì,

Á sì mú kí àwọn ibi olódi pa run.

10 Wọ́n kórìíra àwọn tó ń báni wí ní ẹnubodè ìlú,

Wọ́n sì kórìíra àwọn tó ń sọ òtítọ́.+

11 Nítorí pé ẹ̀ ń gba owó oko* lọ́wọ́ àwọn aláìní tí ẹ gbé oko fún

Ẹ sì ń gba ọkà lọ́wọ́ wọn bí ìṣákọ́lẹ̀,*+

Ẹ kò ní máa gbé inú àwọn ilé tí ẹ fi òkúta gbígbẹ́ kọ́+

Bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní máa mu wáìnì àwọn ọgbà àjàrà dáradára tí ẹ gbìn.+

12 Nítorí mo mọ bí ìdìtẹ̀* yín ṣe pọ̀ tó

Àti bí ẹ̀ṣẹ̀ yín ṣe pọ̀ tó

Ẹ̀ ń dààmú àwọn olódodo,

Ẹ̀ ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,*

Ẹ sì ń fi ẹ̀tọ́ àwọn aláìní dù wọ́n ní ẹnubodè.+

13 Torí náà, àwọn tó ní ìjìnlẹ̀ òye máa dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò yẹn,

Nítorí ó máa jẹ́ àkókò àjálù.+

14 Ẹ máa wá ohun rere, ẹ má ṣe wá ohun búburú,+

Kí ẹ lè máa wà láàyè.+

Nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun á lè wà pẹ̀lú yín,

Bí ẹ ti sọ pé ó wà pẹ̀lú yín.+

15 Ẹ kórìíra ohun búburú, kí ẹ sì nífẹ̀ẹ́ ohun rere,+

Ẹ jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ ní ẹnubodè ìlú.+

Bóyá Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun

Máa fi ojúure hàn sí àwọn tó ṣẹ́ kù lára Jósẹ́fù.’+

16 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, àní Jèhófà sọ nìyí:

‘Ìpohùnréré ẹkún máa wà ní gbogbo ojúde ìlú,

Àti ní gbogbo ojú ọ̀nà, àwọn èèyàn á máa sọ pé, “Áà, ó mà ṣe o!”

Wọ́n á pe àwọn àgbẹ̀ pé kí wọ́n wá ṣọ̀fọ̀

Àti àwọn tó ń fi ẹkún sísun ṣiṣẹ́ ṣe láti pohùn réré ẹkún.’

17 ‘Ìpohùnréré ẹkún máa wà ní gbogbo ọgbà àjàrà;+

Nítorí màá la àárín rẹ kọjá,’ ni Jèhófà wí.

18 ‘Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fẹ́ kí ọjọ́ Jèhófà dé, ẹ gbé!+

Àǹfààní wo wá ni ọjọ́ Jèhófà máa ṣe yín?+

Òkùnkùn ló máa jẹ́, kì í ṣe ìmọ́lẹ̀.+

19 Ńṣe ló máa dà bí ọkùnrin kan tó ń sá fún kìnnìún, tó wá pàdé bíárì,

Nígbà tó wọ ilé rẹ̀, tó fi ọwọ́ ti ògiri, ejò bù ú ṣán.

20 Ọjọ́ Jèhófà máa jẹ́ òkùnkùn, kì í ṣe ìmọ́lẹ̀;

Ó máa jẹ́ ìṣúdùdù, kì í ṣe ìtànyòò.

21 Mo kórìíra àwọn àjọyọ̀ yín, mo sì kọ̀ wọ́n,+

Inú mi ò dùn sí òórùn àwọn àpéjọ ọlọ́wọ̀ yín.

22 Kódà bí ẹ tiẹ̀ rú odindi ẹbọ sísun, tí ẹ sì fún mi ní ẹ̀bùn,

Inú mi ò ní dùn sí ọrẹ wọ̀nyẹn;+

Mi ò sì ní fi ojúure wo àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ tí ẹ fi ẹran àbọ́sanra rú.+

23 Gbé ariwo orin rẹ kúrò lọ́dọ̀ mi;

Má sì jẹ́ kí n gbọ́ ìró ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín rẹ.+

24 Jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo ṣàn wálẹ̀ bí omi,+

Àti òdodo bí odò tó ń ṣàn nígbà gbogbo.

25 Ǹjẹ́ ẹ mú ẹbọ àti ọrẹ wá fún mi

Ní gbogbo ogójì (40) ọdún tí ẹ fi wà ní aginjù, ilé Ísírẹ́lì?+

26 Ní báyìí, ẹ ó gbé Sákútì ọba yín àti Káíwánì kúrò,*

Àwọn ère yín, ìràwọ̀ ọlọ́run yín, tí ẹ ṣe fún ara yín,

27 Màá sì rán yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damásíkù,’+ ni ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́