ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ẹ́kísódù

      • Wọ́n bí Mósè (1-4)

      • Ọmọbìnrin Fáráò fi Mósè ṣe ọmọ rẹ̀ (5-10)

      • Mósè sá lọ sí Mídíánì, ó sì fẹ́ Sípórà (11-22)

      • Ọlọ́run gbọ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń kérora (23-25)

Ẹ́kísódù 2:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:20; Nọ 26:59

Ẹ́kísódù 2:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:20; Heb 11:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1997, ojú ìwé 30

Ẹ́kísódù 2:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “áàkì; àpótí.”

  • *

    Ìyẹn, koríko etí omi.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:18, 19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2002, ojú ìwé 9-10

    5/1/1997, ojú ìwé 30

Ẹ́kísódù 2:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:20; 1Kr 6:3; Mik 6:4

Ẹ́kísódù 2:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/1/1997, ojú ìwé 30

Ẹ́kísódù 2:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2002, ojú ìwé 9-10

    5/1/1997, ojú ìwé 30

Ẹ́kísódù 2:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2002, ojú ìwé 10-11

Ẹ́kísódù 2:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2002, ojú ìwé 10

Ẹ́kísódù 2:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2002, ojú ìwé 10-11

    5/1/1997, ojú ìwé 30-31

Ẹ́kísódù 2:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ẹni Tí Wọ́n Gbé Jáde,” ìyẹn, ẹní tí wọ́n gba ẹ̀mí rẹ̀ là látinú omi.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 11:24, 25
  • +Iṣe 7:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 19-20

    6/15/2002, ojú ìwé 10

    5/1/1997, ojú ìwé 31

    Jí!,

    4/8/2004, ojú ìwé 6-7

Ẹ́kísódù 2:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “bí Mósè ṣe ń lágbára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 1:11; 3:7; Iṣe 7:23

Ẹ́kísódù 2:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:24

Ẹ́kísódù 2:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:26

Ẹ́kísódù 2:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:27, 28

Ẹ́kísódù 2:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 25:1, 2; Ẹk 3:1; 4:19

Ẹ́kísódù 2:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 18:12

Ẹ́kísódù 2:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ó gbèjà àwọn obìnrin náà.”

Ẹ́kísódù 2:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, Jẹ́tírò.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 4:18; 18:1; Nọ 10:29

Ẹ́kísódù 2:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:22

Ẹ́kísódù 2:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 18:2-4; Nọ 12:1

Ẹ́kísódù 2:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ó Di Àjèjì Níbẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 23:15
  • +Iṣe 7:29

Ẹ́kísódù 2:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọjọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:7; Iṣe 7:30
  • +Ẹk 3:7; 1Ọb 8:51

Ẹ́kísódù 2:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 7:34
  • +Jẹ 15:13, 14; Ẹk 6:5; Nọ 20:15, 16

Àwọn míì

Ẹ́kís. 2:1Ẹk 6:20; Nọ 26:59
Ẹ́kís. 2:2Iṣe 7:20; Heb 11:23
Ẹ́kís. 2:3Iṣe 7:18, 19
Ẹ́kís. 2:4Ẹk 15:20; 1Kr 6:3; Mik 6:4
Ẹ́kís. 2:5Iṣe 7:21
Ẹ́kís. 2:8Ẹk 6:20
Ẹ́kís. 2:10Heb 11:24, 25
Ẹ́kís. 2:10Iṣe 7:21
Ẹ́kís. 2:11Ẹk 1:11; 3:7; Iṣe 7:23
Ẹ́kís. 2:12Iṣe 7:24
Ẹ́kís. 2:13Iṣe 7:26
Ẹ́kís. 2:14Iṣe 7:27, 28
Ẹ́kís. 2:15Jẹ 25:1, 2; Ẹk 3:1; 4:19
Ẹ́kís. 2:16Ẹk 18:12
Ẹ́kís. 2:18Ẹk 4:18; 18:1; Nọ 10:29
Ẹ́kís. 2:19Iṣe 7:22
Ẹ́kís. 2:21Ẹk 18:2-4; Nọ 12:1
Ẹ́kís. 2:221Kr 23:15
Ẹ́kís. 2:22Iṣe 7:29
Ẹ́kís. 2:23Ẹk 7:7; Iṣe 7:30
Ẹ́kís. 2:23Ẹk 3:7; 1Ọb 8:51
Ẹ́kís. 2:24Iṣe 7:34
Ẹ́kís. 2:24Jẹ 15:13, 14; Ẹk 6:5; Nọ 20:15, 16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ẹ́kísódù 2:1-25

Ẹ́kísódù

2 Ní àkókò yẹn, ọkùnrin kan láti ìdílé Léfì fẹ́ ọmọbìnrin Léfì kan.+ 2 Obìnrin náà lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan. Nígbà tó rí bí ọmọ náà ṣe rẹwà tó, ó gbé e pa mọ́ fún oṣù mẹ́ta.+ 3 Nígbà tí kò lè gbé e pa mọ́ mọ́,+ ó mú apẹ̀rẹ̀* kan tí wọ́n fi òrépèté ṣe, ó fi ọ̀dà bítúmẹ́nì dídì àti ọ̀dà bítúmẹ́nì rírọ̀ kùn ún, ó sì gbé ọmọ náà sínú rẹ̀. Ó wá gbé e sáàárín àwọn esùsú* etí odò Náílì. 4 Àmọ́ ẹ̀gbọ́n ọmọ náà obìnrin+ dúró ní ọ̀ọ́kán kó lè rí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí i.

5 Nígbà tí ọmọbìnrin Fáráò wá wẹ̀ ní odò Náílì, àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ń rìn létí odò Náílì. Obìnrin náà tajú kán rí apẹ̀rẹ̀ náà láàárín àwọn esùsú. Ló bá rán ẹrúbìnrin rẹ̀ kó lọ gbé e wá lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+ 6 Nígbà tó ṣí apẹ̀rẹ̀ náà, ó rí ọmọ náà, ọmọ náà sì ń sunkún. Àánú rẹ̀ ṣe é, àmọ́ ó sọ pé: “Ọ̀kan lára ọmọ àwọn Hébérù ni.” 7 Ẹ̀gbọ́n ọmọ náà wá sọ fún ọmọbìnrin Fáráò pé: “Ṣé kí n lọ bá ọ pe obìnrin Hébérù kan tó jẹ́ olùtọ́jú wá kó lè máa bá ọ tọ́jú rẹ̀?” 8 Ọmọbìnrin Fáráò fèsì pé: “Lọ pè é wá!” Ni ọmọbìnrin náà bá lọ pe ìyá ọmọ náà wá.+ 9 Ọmọbìnrin Fáráò wá sọ fún obìnrin náà pé: “Gbé ọmọ yìí lọ kí o máa bá mi tọ́jú rẹ̀, màá sì sanwó fún ọ.” Obìnrin náà wá gbé ọmọ náà, ó sì ń tọ́jú rẹ̀. 10 Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, obìnrin náà mú un wá fún ọmọbìnrin Fáráò, ó sì fi ṣe ọmọ rẹ̀.+ Ó sọ ọ́ ní Mósè,* ó sì sọ pé: “Ìdí ni pé inú omi ni mo ti gbé e jáde.”+

11 Nígbà yẹn, lẹ́yìn tí Mósè dàgbà,* ó jáde lọ sọ́dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, kó lè lọ wo ìnira tí wọ́n ń fara dà,+ ó sì tajú kán rí ọmọ Íjíbítì kan tó ń lu Hébérù kan tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èèyàn rẹ̀. 12 Ó wọ̀tún wòsì, nígbà tí kò sì rí ẹnì kankan, ó pa ọmọ Íjíbítì náà, ó sì fi iyẹ̀pẹ̀ bo òkú rẹ̀.+

13 Àmọ́ lọ́jọ́ kejì, ó jáde, ó sì rí àwọn ọkùnrin Hébérù méjì tó ń bára wọn jà. Ó wá sọ fún ẹni tó jẹ̀bi pé: “Kí ló dé tí o lu ọ̀rẹ́ rẹ?”+ 14 Nìyẹn bá fèsì pé: “Ta ló fi ọ́ ṣe olórí àti onídàájọ́ wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ọmọ Íjíbítì yẹn ni?”+ Ẹ̀rù wá ba Mósè, ó sì sọ pé: “Ó dájú pé àwọn èèyàn ti mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí!”

15 Lẹ́yìn náà, Fáráò gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sì fẹ́ pa Mósè; àmọ́ Mósè sá lọ torí Fáráò, ó sì lọ ń gbé ní ilẹ̀ Mídíánì.+ Nígbà tó dé ibẹ̀, ó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ kànga kan. 16 Àlùfáà Mídíánì+ ní ọmọbìnrin méje, àwọn ọmọ yìí wá fa omi, wọ́n sì pọnmi kún àwọn ọpọ́n ìmumi kí wọ́n lè fún agbo ẹran bàbá wọn lómi. 17 Àmọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn wá lé wọn kúrò, bí wọ́n ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ni Mósè bá dìde, ó ran àwọn obìnrin náà lọ́wọ́,* ó sì fún agbo ẹran wọn lómi. 18 Nígbà tí wọ́n dé ilé lọ́dọ̀ Réúẹ́lì*+ bàbá wọn, ó yà á lẹ́nu, ó sì bi wọ́n pé: “Kí ló mú kí ẹ tètè pa dà sílé lónìí?” 19 Wọ́n fèsì pé: “Ará Íjíbítì+ kan ló gbà wá lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn, ó tún bá wa fa omi, ó sì fún agbo ẹran lómi.” 20 Ó bi àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ pé: “Ẹni náà wá dà? Kí ló dé tí ẹ fi ọkùnrin ọ̀hún sílẹ̀? Ẹ lọ pè é wá, kó lè bá wa jẹun.” 21 Lẹ́yìn náà, Mósè gbà láti dúró lọ́dọ̀ ọkùnrin náà, ó sì fún Mósè ní Sípórà+ ọmọ rẹ̀ kó fi ṣe aya. 22 Nígbà tó yá, obìnrin náà bí ọmọkùnrin kan, Mósè sì sọ ọ́ ní Gẹ́ṣómù,*+ torí ó sọ pé, “Mo ti di àjèjì nílẹ̀ àjèjì.”+

23 Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún,* ọba Íjíbítì kú,+ àmọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń kérora torí wọ́n wà lóko ẹrú, wọ́n sì ń ráhùn, igbe tí wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ torí pé wọ́n ń fi wọ́n ṣe ẹrú sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́.+ 24 Nígbà tó yá, Ọlọ́run gbọ́ bí wọ́n ṣe ń kérora,+ Ọlọ́run sì rántí májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù dá.+ 25 Torí náà, Ọlọ́run yíjú sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì; Ọlọ́run sì kíyè sí wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́