Kíróníkà Kìíní
11 Nígbà tó yá, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ sọ́dọ̀ Dáfídì ní Hébúrónì,+ wọ́n sì sọ pé: “Wò ó! Ẹ̀jẹ̀* kan náà ni wá.+ 2 Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí Sọ́ọ̀lù jẹ́ ọba, ìwọ lò ń kó Ísírẹ́lì jáde ogun.*+ Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì sọ fún ọ pé: ‘Ìwọ́ ni wàá máa bójú tó àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì bí àgùntàn, wàá sì di aṣáájú àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’”+ 3 Nítorí náà, gbogbo àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì wá sọ́dọ̀ ọba ní Hébúrónì, Dáfídì sì bá wọn dá májẹ̀mú ní Hébúrónì níwájú Jèhófà. Lẹ́yìn náà, wọ́n fòróró yan Dáfídì ṣe ọba lórí Ísírẹ́lì,+ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà gbẹnu Sámúẹ́lì sọ.+
4 Lẹ́yìn náà, Dáfídì àti gbogbo Ísírẹ́lì jáde lọ sí Jerúsálẹ́mù, ìyẹn ní Jébúsì,+ ilẹ̀ tí àwọn ará Jébúsì+ ń gbé. 5 Àwọn tó ń gbé ní Jébúsì pẹ̀gàn Dáfídì pé: “O ò ní wọ ibí yìí!”+ Síbẹ̀, Dáfídì gba ibi ààbò Síónì,+ èyí tó wá di Ìlú Dáfídì.+ 6 Torí náà, Dáfídì sọ pé: “Ẹni tó bá kọ́kọ́ gbéjà ko àwọn ará Jébúsì ló máa di balógun* àti ìjòyè.” Jóábù+ ọmọ Seruáyà ló kọ́kọ́ lọ, ó sì di balógun. 7 Nígbà náà, Dáfídì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ibi ààbò, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń pe ibẹ̀ ní Ìlú Dáfídì. 8 Ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ìlú náà yí ká láti Òkìtì* títí dé àyíká rẹ̀, Jóábù sì tún apá tó kù lára ìlú náà kọ́. 9 Bí agbára Dáfídì ṣe ń pọ̀ sí i+ nìyẹn, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sì wà pẹ̀lú rẹ̀.
10 Àwọn tó jẹ́ olórí àwọn jagunjagun Dáfídì tó lákíkanjú nìyí, àwọn àti gbogbo Ísírẹ́lì ló tì í lẹ́yìn nínú ìjọba rẹ̀, kí wọ́n lè fi í jọba gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Ísírẹ́lì.+ 11 Orúkọ àwọn jagunjagun Dáfídì tó lákíkanjú nìyí: Jáṣóbéámù+ ọmọ ará Hákímónì, olórí àwọn mẹ́ta náà.+ Ìgbà kan wà tó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin.+ 12 Ẹni tí ó tẹ̀ lé e ni Élíásárì+ ọmọ Dódò ọmọ Áhóhì.+ Ó wà lára àwọn jagunjagun mẹ́ta tó lákíkanjú. 13 Ó wà pẹ̀lú Dáfídì ní Pasi-dámímù,+ níbi tí àwọn Filísínì kóra jọ sí láti jagun. Lákòókò náà, ilẹ̀ kan wà tí ọkà bálì pọ̀ sí, àwọn èèyàn sì ti sá lọ nítorí àwọn Filísínì. 14 Àmọ́ ó dúró ní àárín ilẹ̀ náà, kò jẹ́ kí wọ́n gbà á, ó sì ń pa àwọn Filísínì náà, tó fi jẹ́ pé Jèhófà mú kí ìṣẹ́gun*+ ńlá wáyé.
15 Mẹ́ta lára ọgbọ̀n (30) ọkùnrin tó jẹ́ olórí lọ sí ibi àpáta lọ́dọ̀ Dáfídì ní ihò àpáta Ádúlámù,+ lákòókò yìí, àwùjọ àwọn ọmọ ogun Filísínì kan pàgọ́ sí Àfonífojì* Réfáímù.+ 16 Nígbà yẹn, Dáfídì wà ní ibi ààbò, àwùjọ ọmọ ogun Filísínì tó wà ní àdádó sì wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. 17 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sọ ohun tó ń wù ú, ó ní: “Ì bá dára ká ní mo lè rí omi mu láti inú kòtò omi tó wà ní ẹnubodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù!”+ 18 Ni àwọn mẹ́ta náà bá fipá wọnú ibùdó àwọn Filísínì, wọ́n fa omi láti inú kòtò omi tó wà ní ẹnubodè Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, wọ́n sì gbé e wá fún Dáfídì; àmọ́ Dáfídì kọ̀, kò mu ún, ńṣe ló dà á jáde fún Jèhófà. 19 Ó sọ pé: “Ọlọ́run ò gbọ́dọ̀ gbọ́ pé mo ṣe nǹkan yìí! Ṣé ó yẹ kí n mu ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkùnrin tó fẹ̀mí*+ ara wọn wewu yìí? Nítorí ẹ̀mí* wọn ni wọ́n fi wewu kí wọ́n lè gbé e wá.” Torí náà, ó kọ̀, kò mu ún. Àwọn ohun tí àwọn jagunjagun rẹ̀ mẹ́ta tó lákíkanjú ṣe nìyẹn.
20 Ábíṣáì+ ẹ̀gbọ́n Jóábù+ di olórí àwọn mẹ́ta míì; ó fi ọ̀kọ̀ rẹ̀ pa ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọkùnrin, òun náà sì lórúkọ bí àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.+ 21 Láàárín àwọn mẹ́ta kejì, òun ló ta yọ jù, òun sì ni olórí wọn; síbẹ̀ kò wọ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.
22 Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà jẹ́ akíkanjú ọkùnrin* tó gbé ọ̀pọ̀ nǹkan ṣe ní Kábúséélì.+ Ó pa àwọn ọmọkùnrin méjèèjì tí Áríélì ará Móábù bí, ó wọ inú kòtò omi lọ́jọ́ kan tí yìnyín bolẹ̀, ó sì pa kìnnìún.+ 23 Ó tún mú ọkùnrin ará Íjíbítì kan tó tóbi fàkìàfakia balẹ̀ tó ga ní ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún.*+ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀kọ̀ tó wà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà dà bí ọ̀pá àwọn ahunṣọ,*+ ó fi ọ̀pá bá a jà, ó já ọ̀kọ̀ náà gbà ní ọwọ́ ará Íjíbítì náà, ó sì fi ọ̀kọ̀ òun fúnra rẹ̀ pa á.+ 24 Àwọn ohun tí Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà ṣe nìyẹn, ó lórúkọ bí àwọn akíkanjú jagunjagun mẹ́ta náà. 25 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ta yọ ju àwọn ọgbọ̀n (30) náà, kò wọ ẹgbẹ́ àwọn mẹ́ta àkọ́kọ́.+ Àmọ́ Dáfídì yàn án ṣe olórí àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀.
26 Àwọn jagunjagun tó lákíkanjú nínú ẹgbẹ́ ológun ni Ásáhélì+ arákùnrin Jóábù, Élíhánánì ọmọ Dódò ará Bẹ́tílẹ́hẹ́mù,+ 27 Ṣámótì ará Hárórù, Hélésì tó jẹ́ Pélónì, 28 Írà+ ọmọ Íkéṣì ará Tékóà, Abi-ésérì+ ọmọ Ánátótì, 29 Síbékáì+ ọmọ Húṣà, Íláì ọmọ Áhóhì, 30 Máháráì+ ará Nétófà, Hélédì+ ọmọ Báánà ará Nétófà, 31 Ítááì ọmọ Ríbáì ará Gíbíà ti àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì,+ Bẹnáyà ará Pírátónì, 32 Húráì tó wá láti àwọn àfonífojì Gááṣì,+ Ábíélì tó jẹ́ Ábátì, 33 Ásímáfẹ́tì ará Báhúrímù, Élíábà tó jẹ́ Ṣáálíbónì, 34 àwọn ọmọ Háṣémù tó jẹ́ Gísónì, Jónátánì ọmọ Ṣágéè tó jẹ́ Hárárì, 35 Áhíámù ọmọ Sákárì tó jẹ́ Hárárì, Élífálì ọmọ Úrì, 36 Héfà ọmọ Mékérà, Áhíjà tó jẹ́ Pélónì, 37 Hésírò ará Kámẹ́lì, Nááráì ọmọ Ésíbáì, 38 Jóẹ́lì arákùnrin Nátánì, Míbúhárì ọmọ Hágírì, 39 Sélékì ọmọ Ámónì, Náháráì ará Bérótì, tó ń bá Jóábù ọmọ Seruáyà gbé ìhámọ́ra; 40 Írà tó jẹ́ Ítírì, Gárébù tó jẹ́ Ítírì, 41 Ùráyà+ ọmọ Hétì, Sábádì ọmọ Áláì, 42 Ádínà ọmọ Ṣísà ọmọ Rúbẹ́nì, ọ̀kan lára olórí àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àti ọgbọ̀n (30) èèyàn tó wà pẹ̀lú rẹ̀; 43 Hánánì ọmọ Máákà, Jóṣáfátì tó jẹ́ Mítínì, 44 Úsíà ará Áṣítárótì, Ṣémà àti Jéélì, àwọn ọmọ Hótámù ará Áróérì; 45 Jédáélì ọmọ Ṣímúrì, Jóhà arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ Tísì; 46 Élíélì tó jẹ́ Máháfì, Jéríbáì àti Joṣafáyà àwọn ọmọ Élínáámù, Ítímà ọmọ Móábù; 47 Élíélì, Óbédì àti Jáásíélì ará Sóbà.