Sáàmù
Sí olùdarí; lórí Gítítì.* Ti Ásáfù.+
81 Ẹ kígbe ayọ̀ sí Ọlọ́run tó jẹ́ agbára wa.+
Ẹ kígbe ìṣẹ́gun sí Ọlọ́run Jékọ́bù.
2 Ẹ bẹ̀rẹ̀ orin, ẹ gbé ìlù tanboríìnì,
Háàpù tó ń dún dáadáa àti ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín.
4 Nítorí pé òfin ló jẹ́ fún Ísírẹ́lì,
Àṣẹ Ọlọ́run Jékọ́bù.+
Mo gbọ́ ohùn* kan tí mi ò mọ̀, tó sọ pé:
6 “Mo gbé ẹrù kúrò ní èjìká rẹ̀;+
Mo gba apẹ̀rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.
Mo dán ọ wò níbi omi Mẹ́ríbà.*+ (Sélà)
8 Ẹ gbọ́, ẹ̀yin èèyàn mi, màá ta kò yín.
Ìwọ Ísírẹ́lì, ká ní o lè fetí sí mi.+
9 Kò ní sí ọlọ́run àjèjì láàárín rẹ,
O kò sì ní forí balẹ̀ fún ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè.+
10 Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ,
Ẹni tó mú ọ jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+
La gbogbo ẹnu rẹ, màá sì fi oúnjẹ kún un.+
11 Àmọ́ àwọn èèyàn mi ò fetí sí ohùn mi;
Ísírẹ́lì kò ṣègbọràn sí mi.+
14 Kíákíá ni mi ò bá ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn;
Mi ò bá yí ọwọ́ mi pa dà sí àwọn elénìní wọn.+
15 Àwọn tó kórìíra Jèhófà yóò ba búrúbúrú níwájú rẹ̀,
Ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí wọn* yóò sì wà títí láé.