ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Àwọn Ọba 25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Àwọn Ọba

      • Nebukadinésárì dó ti Jerúsálẹ́mù (1-7)

      • Ìparun Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì rẹ̀; wọ́n kó wọn lọ nígbà kejì (8-21)

      • Wọ́n fi Gẹdaláyà ṣe gómìnà (22-24)

      • Wọ́n pa Gẹdaláyà; àwọn èèyàn sá lọ sí Íjíbítì (25, 26)

      • Wọ́n tú Jèhóákínì sílẹ̀ ní Bábílónì (27-30)

2 Àwọn Ọba 25:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 27:8; 43:10; Da 4:1
  • +2Kr 36:17; Jer 34:2; Isk 24:1, 2
  • +Ais 29:3; Jer 32:2, 28; 39:1; 52:4, 5; Isk 4:1, 2; 21:21, 22

2 Àwọn Ọba 25:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:26; Di 28:53; Jer 37:21; 38:2; Ida 4:4; Isk 4:16; 5:10, 12
  • +Jer 52:6-11

2 Àwọn Ọba 25:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:4; 39:2, 4-7; Isk 33:21
  • +Isk 12:12

2 Àwọn Ọba 25:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:7

2 Àwọn Ọba 25:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 32:4, 5; Isk 12:12, 13; 17:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2017,

2 Àwọn Ọba 25:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 40:1
  • +Jer 52:12-14; Ida 4:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 11

2 Àwọn Ọba 25:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ààfin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 9:8; Sm 74:3; 79:1; Ais 64:11; Jer 7:14; Ida 1:10; 2:7; Mik 3:12
  • +1Ọb 7:1
  • +Jer 34:22
  • +2Kr 36:19

2 Àwọn Ọba 25:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 1:3; Jer 39:8

2 Àwọn Ọba 25:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 15:2; 39:9; 52:15, 30; Isk 5:2

2 Àwọn Ọba 25:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:10; 52:16

2 Àwọn Ọba 25:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:15
  • +1Ọb 7:27
  • +1Ọb 7:23
  • +2Ọb 20:17; Jer 52:17-20

2 Àwọn Ọba 25:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ojú ìwé 1709

2 Àwọn Ọba 25:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:48, 50
  • +2Kr 24:14; 36:18; Ẹsr 1:7, 10, 11; Da 5:2

2 Àwọn Ọba 25:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:47

2 Àwọn Ọba 25:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìgbọ̀nwọ́ kan jẹ́ sẹ̀ǹtímítà 44.5 (ínǹṣì 17.5). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 7:15
  • +1Ọb 7:16, 20; Jer 52:21-23

2 Àwọn Ọba 25:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 7:1
  • +Jer 21:1, 2; 29:25, 29
  • +Jer 52:24-27

2 Àwọn Ọba 25:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:8; Jer 39:9; 40:1
  • +Jer 39:5

2 Àwọn Ọba 25:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 34:2, 8; 1Ọb 8:65
  • +Di 28:36, 64; 2Ọb 23:27; Jer 25:11

2 Àwọn Ọba 25:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 39:13, 14
  • +Jer 26:24
  • +2Ọb 22:8
  • +Jer 40:5, 6

2 Àwọn Ọba 25:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 40:7-9

2 Àwọn Ọba 25:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 27:12

2 Àwọn Ọba 25:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “látinú èso ìjọba náà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 40:15
  • +Jer 41:1, 2

2 Àwọn Ọba 25:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 42:14; 43:4, 7
  • +Jer 41:17, 18

2 Àwọn Ọba 25:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbé orí Jèhóákínì ọba Júdà sókè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:8, 12; Jer 24:1; Mt 1:11
  • +Jer 52:31-34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2012, ojú ìwé 5

Àwọn míì

2 Ọba 25:1Jer 27:8; 43:10; Da 4:1
2 Ọba 25:12Kr 36:17; Jer 34:2; Isk 24:1, 2
2 Ọba 25:1Ais 29:3; Jer 32:2, 28; 39:1; 52:4, 5; Isk 4:1, 2; 21:21, 22
2 Ọba 25:3Le 26:26; Di 28:53; Jer 37:21; 38:2; Ida 4:4; Isk 4:16; 5:10, 12
2 Ọba 25:3Jer 52:6-11
2 Ọba 25:4Jer 21:4; 39:2, 4-7; Isk 33:21
2 Ọba 25:4Isk 12:12
2 Ọba 25:6Jer 21:7
2 Ọba 25:7Jer 32:4, 5; Isk 12:12, 13; 17:16
2 Ọba 25:8Jer 40:1
2 Ọba 25:8Jer 52:12-14; Ida 4:12
2 Ọba 25:91Ọb 9:8; Sm 74:3; 79:1; Ais 64:11; Jer 7:14; Ida 1:10; 2:7; Mik 3:12
2 Ọba 25:91Ọb 7:1
2 Ọba 25:9Jer 34:22
2 Ọba 25:92Kr 36:19
2 Ọba 25:10Ne 1:3; Jer 39:8
2 Ọba 25:11Jer 15:2; 39:9; 52:15, 30; Isk 5:2
2 Ọba 25:12Jer 39:10; 52:16
2 Ọba 25:131Ọb 7:15
2 Ọba 25:131Ọb 7:27
2 Ọba 25:131Ọb 7:23
2 Ọba 25:132Ọb 20:17; Jer 52:17-20
2 Ọba 25:151Ọb 7:48, 50
2 Ọba 25:152Kr 24:14; 36:18; Ẹsr 1:7, 10, 11; Da 5:2
2 Ọba 25:161Ọb 7:47
2 Ọba 25:171Ọb 7:15
2 Ọba 25:171Ọb 7:16, 20; Jer 52:21-23
2 Ọba 25:18Ẹsr 7:1
2 Ọba 25:18Jer 21:1, 2; 29:25, 29
2 Ọba 25:18Jer 52:24-27
2 Ọba 25:202Ọb 25:8; Jer 39:9; 40:1
2 Ọba 25:20Jer 39:5
2 Ọba 25:21Nọ 34:2, 8; 1Ọb 8:65
2 Ọba 25:21Di 28:36, 64; 2Ọb 23:27; Jer 25:11
2 Ọba 25:22Jer 39:13, 14
2 Ọba 25:22Jer 26:24
2 Ọba 25:222Ọb 22:8
2 Ọba 25:22Jer 40:5, 6
2 Ọba 25:23Jer 40:7-9
2 Ọba 25:24Jer 27:12
2 Ọba 25:25Jer 40:15
2 Ọba 25:25Jer 41:1, 2
2 Ọba 25:26Jer 42:14; 43:4, 7
2 Ọba 25:26Jer 41:17, 18
2 Ọba 25:272Ọb 24:8, 12; Jer 24:1; Mt 1:11
2 Ọba 25:27Jer 52:31-34
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Àwọn Ọba 25:1-30

Àwọn Ọba Kejì

25 Ní ọdún kẹsàn-án ìjọba Sedekáyà, ní oṣù kẹwàá, ní ọjọ́ kẹwàá oṣù náà, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì dé pẹ̀lú gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù.+ Ó dó tì í, ó mọ òkìtì yí i ká,+ 2 wọ́n sì dó ti ìlú náà títí di ọdún kọkànlá ìṣàkóso Ọba Sedekáyà. 3 Ní ọjọ́ kẹsàn-án oṣù kẹrin, ìyàn mú gan-an+ ní ìlú náà, kò sì sí oúnjẹ kankan tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà máa jẹ.+ 4 Wọ́n fọ́ ògiri ìlú náà wọlé,+ gbogbo ọmọ ogun sì sá gba ẹnubodè tó wà láàárín ògiri oníbejì nítòsí ọgbà ọba lóru, lákòókò yìí, àwọn ará Kálídíà yí ìlú náà ká; ọba sì sá gba ọ̀nà Árábà.+ 5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé ọba, wọ́n sì bá a ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 6 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú,+ wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́. 7 Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀; Nebukadinésárì wá fọ́ ojú Sedekáyà, ó fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó sì mú un wá sí Bábílónì.+

8 Ní oṣù karùn-ún, ní ọjọ́ keje oṣù náà, ìyẹn ní ọdún kọkàndínlógún Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́, ìránṣẹ́ ọba Bábílónì, wá sí Jerúsálẹ́mù.+ 9 Ó dáná sun ilé Jèhófà+ àti ilé* ọba+ pẹ̀lú gbogbo ilé tó wà ní Jerúsálẹ́mù;+ ó tún sun ilé gbogbo àwọn ẹni ńlá.+ 10 Gbogbo ògiri tó yí Jerúsálẹ́mù ká ni gbogbo àwọn ọmọ ogun Kálídíà tó wà pẹ̀lú olórí ẹ̀ṣọ́ wó lulẹ̀.+ 11 Nebusarádánì olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn èèyàn tó wà ní ìlú náà lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì àti àwọn tó sá wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó kù.+ 12 Àmọ́ olórí ẹ̀ṣọ́ fi lára àwọn aláìní sílẹ̀ ní ilẹ̀ náà kí wọ́n lè máa rẹ́ ọwọ́ àjàrà, kí wọ́n sì máa ṣe lébìrà àpàpàǹdodo.+ 13 Àwọn ará Kálídíà fọ́ àwọn òpó bàbà+ ilé Jèhófà àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù+ àti Òkun bàbà+ tó wà ní ilé Jèhófà sí wẹ́wẹ́, wọ́n sì kó àwọn bàbà náà lọ sí Bábílónì.+ 14 Wọ́n tún kó àwọn garawa, àwọn ṣọ́bìrì, àwọn ohun tí wọ́n fi ń pa fìtílà, àwọn ife àti gbogbo nǹkan èlò bàbà tí wọ́n ń lò nínú tẹ́ńpìlì. 15 Olórí ẹ̀ṣọ́ kó àwọn ìkóná àti àwọn abọ́ tí wọ́n fi ojúlówó wúrà+ ṣe àti àwọn tí wọ́n fi ojúlówó fàdákà+ ṣe. 16 Ní ti àwọn òpó méjèèjì àti Òkun pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Sólómọ́nì ṣe fún ilé Jèhófà, bàbà tó wà lára gbogbo àwọn nǹkan èlò yìí kọjá wíwọ̀n.+ 17 Gíga ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn òpó náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́* méjìdínlógún (18),+ bàbà ni wọ́n fi ṣe ọpọ́n tó wà lórí rẹ̀; gíga ọpọ́n náà sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta, bàbà ni wọ́n fi ṣe àwọ̀n àti àwọn pómégíránétì tó yí ọpọ́n náà ká.+ Òpó kejì àti àwọ̀n rẹ̀ sì dà bíi ti àkọ́kọ́.

18 Olórí ẹ̀ṣọ́ tún mú Seráyà+ olórí àlùfáà àti Sefanáyà+ àlùfáà kejì pẹ̀lú àwọn aṣọ́nà mẹ́ta.+ 19 Ó mú òṣìṣẹ́ ààfin kan tó jẹ́ kọmíṣọ́nnà lórí àwọn ọmọ ogun láti inú ìlú náà àti ọkùnrin márùn-ún tó rí nínú ìlú náà tí wọ́n sún mọ́ ọba àti akọ̀wé olórí àwọn ọmọ ogun, tó máa ń pe àwọn èèyàn ilẹ̀ náà jọ àti ọgọ́ta (60) ọkùnrin lára àwọn èèyàn ilẹ̀ náà, tó tún rí nínú ìlú náà. 20 Nebusarádánì+ olórí ẹ̀ṣọ́ mú wọn, ó sì kó wọn wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà.+ 21 Ọba Bábílónì ṣá wọn balẹ̀, ó sì pa wọ́n ní Ríbúlà ní ilẹ̀ Hámátì.+ Bí Júdà ṣe lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀ nìyẹn.+

22 Nebukadinésárì ọba Bábílónì yan Gẹdaláyà+ ọmọ Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì+ ṣe olórí àwọn èèyàn tí ó fi sílẹ̀ ní ilẹ̀ Júdà.+ 23 Nígbà tí gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Bábílónì ti yan Gẹdaláyà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà. Àwọn ni Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà, Jóhánánì ọmọ Káréà, Seráyà ọmọ Táńhúmétì ará Nétófà àti Jaasanáyà ọmọ ará Máákátì pẹ̀lú àwọn ọkùnrin wọn.+ 24 Gẹdaláyà búra fún wọn àti fún àwọn ọkùnrin wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ má bẹ̀rù láti sin àwọn ará Kálídíà. Ẹ máa gbé ilẹ̀ yìí, kí ẹ máa sin ọba Bábílónì, nǹkan á sì máa lọ dáadáa fún yín.”+

25 Ní oṣù keje, Íṣímáẹ́lì+ ọmọ Netanáyà ọmọ Élíṣámà, tó wá láti ìdílé ọba,* wá pẹ̀lú àwọn ọkùnrin mẹ́wàá míì, wọ́n ṣá Gẹdaláyà balẹ̀, ó sì kú, òun àti àwọn Júù àti àwọn ará Kálídíà tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Mísípà.+ 26 Lẹ́yìn ìyẹn, gbogbo àwọn èèyàn náà dìde, látorí ẹni kékeré dórí ẹni ńlá, títí kan àwọn olórí ọmọ ogun, wọ́n sì lọ sí Íjíbítì,+ nítorí ẹ̀rù àwọn ará Kálídíà ń bà wọ́n.+

27 Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Jèhóákínì+ ọba Júdà ti wà ní ìgbèkùn, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù náà, Efili-méródákì ọba Bábílónì, ní ọdún tó jọba, dá Jèhóákínì ọba Júdà sílẹ̀* lẹ́wọ̀n.+ 28 Ó bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba yòókù tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì. 29 Torí náà, Jèhóákínì bọ́ ẹ̀wù ẹ̀wọ̀n rẹ̀, iwájú ọba ló sì ti ń jẹun déédéé ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 30 Ó ń rí oúnjẹ gbà déédéé látọ̀dọ̀ ọba, lójoojúmọ́ ayé rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́