ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Oníwàásù 5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

      • Wá síwájú Ọlọ́run pẹ̀lú ìbẹ̀rù tó yẹ (1-7)

      • Àwọn tó ga ju àwọn tó wà nípò gíga ń ṣọ́ wọn (8, 9)

      • Asán tó wà nínú ọrọ̀ (10-20)

        • Owó kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ owó (10)

        • Oorun òṣìṣẹ́ máa ń dùn (12)

Oníwàásù 5:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 15:1, 2
  • +Di 31:12; Iṣe 17:11
  • +1Sa 13:12, 13; 15:22; Owe 21:27; Ais 1:13; Ho 6:6

Oníwàásù 5:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 30:2; 1Sa 14:24
  • +Owe 10:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 14

Oníwàásù 5:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àníyàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 6:25, 34; Lk 12:18-20
  • +Owe 10:19; 15:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 14-15

Oníwàásù 5:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 23:21; Sm 76:11; Mt 5:33
  • +Onw 10:12
  • +Nọ 30:2; Sm 66:13

Oníwàásù 5:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 23:22; Owe 20:25

Oníwàásù 5:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ara rẹ.”

  • *

    Tàbí “òjíṣẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 11:35
  • +Le 5:4
  • +Sm 127:1; Hag 1:11

Oníwàásù 5:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 5:3
  • +Onw 12:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 14-15

Oníwàásù 5:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 3:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    9/2020, ojú ìwé 31

Oníwàásù 5:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 8:11, 12; 1Ọb 4:7; 2Kr 26:9, 10; Sol 8:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2006, ojú ìwé 14

Oníwàásù 5:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 4:8
  • +Mt 6:24; Lk 12:15; 1Ti 6:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    11/2014, ojú ìwé 4

    1/2012, ojú ìwé 8

    4/2006, ojú ìwé 5

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/1998, ojú ìwé 4-5

Oníwàásù 5:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 4:22, 23
  • +Owe 23:4, 5; 1Jo 2:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/1998, ojú ìwé 4-5

Oníwàásù 5:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2021 ojú ìwé 8

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/1998, ojú ìwé 23

Oníwàásù 5:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Àjálù.”

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Oníwàásù 5:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “iṣẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 23:4, 5; Mt 6:19

Oníwàásù 5:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 1:21
  • +Sm 49:17; Lk 12:20; 1Ti 6:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/1998, ojú ìwé 6

Oníwàásù 5:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àjálù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 16:26; Jo 6:27

Oníwàásù 5:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ti 6:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/1998, ojú ìwé 5

Oníwàásù 5:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

  • *

    Tàbí “ìpín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 4:20
  • +Onw 2:24; 3:22; Ais 65:21, 22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/1998, ojú ìwé 6

Oníwàásù 5:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìpín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 3:12, 13; Job 42:12
  • +Di 8:10; Onw 3:12, 13; 1Ti 6:17; Jem 1:17

Oníwàásù 5:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “rántí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:8; Sm 4:7

Àwọn míì

Oníw. 5:1Sm 15:1, 2
Oníw. 5:1Di 31:12; Iṣe 17:11
Oníw. 5:11Sa 13:12, 13; 15:22; Owe 21:27; Ais 1:13; Ho 6:6
Oníw. 5:2Nọ 30:2; 1Sa 14:24
Oníw. 5:2Owe 10:19
Oníw. 5:3Mt 6:25, 34; Lk 12:18-20
Oníw. 5:3Owe 10:19; 15:2
Oníw. 5:4Nọ 30:2; Sm 66:13
Oníw. 5:4Di 23:21; Sm 76:11; Mt 5:33
Oníw. 5:4Onw 10:12
Oníw. 5:5Di 23:22; Owe 20:25
Oníw. 5:6Ond 11:35
Oníw. 5:6Le 5:4
Oníw. 5:6Sm 127:1; Hag 1:11
Oníw. 5:7Onw 5:3
Oníw. 5:7Onw 12:13
Oníw. 5:8Onw 3:16
Oníw. 5:91Sa 8:11, 12; 1Ọb 4:7; 2Kr 26:9, 10; Sol 8:11
Oníw. 5:10Onw 4:8
Oníw. 5:10Mt 6:24; Lk 12:15; 1Ti 6:10
Oníw. 5:111Ọb 4:22, 23
Oníw. 5:11Owe 23:4, 5; 1Jo 2:16
Oníw. 5:14Owe 23:4, 5; Mt 6:19
Oníw. 5:15Job 1:21
Oníw. 5:15Sm 49:17; Lk 12:20; 1Ti 6:7
Oníw. 5:16Mt 16:26; Jo 6:27
Oníw. 5:171Ti 6:10
Oníw. 5:181Ọb 4:20
Oníw. 5:18Onw 2:24; 3:22; Ais 65:21, 22
Oníw. 5:191Ọb 3:12, 13; Job 42:12
Oníw. 5:19Di 8:10; Onw 3:12, 13; 1Ti 6:17; Jem 1:17
Oníw. 5:20Di 28:8; Sm 4:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Oníwàásù 5:1-20

Oníwàásù

5 Ṣọ́ ẹsẹ̀ rẹ nígbàkigbà tí o bá lọ sí ilé Ọlọ́run tòótọ́;+ ó sàn kéèyàn wá fetí sílẹ̀+ ju kó mú ẹbọ wá bí àwọn òmùgọ̀ ti ń ṣe,+ nítorí wọn ò mọ̀ pé ohun tí wọ́n ń ṣe kò dáa.

2 Má ṣe yánu sọ̀rọ̀ tàbí kí ọkàn rẹ sọ̀rọ̀ láìronú níwájú Ọlọ́run tòótọ́,+ nítorí Ọlọ́run tòótọ́ wà ní ọ̀run àmọ́ ìwọ wà ní ayé. Ìdí nìyẹn tó fi yẹ kí ọ̀rọ̀ rẹ mọ níwọ̀n.+ 3 Nítorí ọ̀pọ̀ iṣẹ́* máa ń mú kí èèyàn lá àlá,+ àpọ̀jù ọ̀rọ̀+ sì máa ń mú kí àwọn òmùgọ̀ máa wí ìrégbè. 4 Nígbàkigbà tí o bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Ọlọ́run, má fi falẹ̀, san án,+ nítorí inú rẹ̀ kì í dùn sí àwọn òmùgọ̀.+ Ohun tí o jẹ́jẹ̀ẹ́, san án.+ 5 Ó sàn kí o má ṣe jẹ́jẹ̀ẹ́ ju pé kí o jẹ́jẹ̀ẹ́, kí o má sì san án.+ 6 Má ṣe jẹ́ kí ẹnu rẹ mú ọ* dẹ́ṣẹ̀,+ má sì sọ níwájú áńgẹ́lì* pé àṣìṣe ni.+ Kí nìdí tí wàá fi mú Ọlọ́run tòótọ́ bínú nítorí ohun tí o sọ, tí á sì pa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ run?+ 7 Nítorí bí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ṣe ń mú kí èèyàn lá àlá,+ bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ púpọ̀ ṣe ń já sí asán. Àmọ́, Ọlọ́run tòótọ́ ni kí o bẹ̀rù.+

8 Tí o bá rí i tí wọ́n ń ni àwọn aláìní lára tàbí tí wọ́n ń tẹ ìdájọ́ òdodo àti òtítọ́ lójú ní agbègbè rẹ, má ṣe jẹ́ kó yà ọ́ lẹ́nu.+ Torí ẹnì kan wà tó ń ṣọ́ ẹni tó wà nípò gíga, ẹni yẹn sì ga jù ú lọ, síbẹ̀ àwọn míì tún wà tó ga jù wọ́n lọ.

9 Bákan náà, wọ́n pín èrè ilẹ̀ náà láàárín ara wọn; kódà inú oko ni oúnjẹ ọba ti ń wá.+

10 Fàdákà kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ fàdákà, bẹ́ẹ̀ ni owó kì í tó ẹni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọrọ̀.+ Asán ni èyí pẹ̀lú.+

11 Nígbà tí ohun rere bá pọ̀ sí i, àwọn tó ń jẹ ẹ́ á pọ̀ sí i.+ Àǹfààní wo ló sì jẹ́ fún ẹni tó ní in ju pé kó máa fi ojú rẹ̀ wò ó?+

12 Oorun ẹni tó ń sìn máa ń dùn, bóyá oúnjẹ díẹ̀ ló jẹ tàbí púpọ̀, àmọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ tí ọlọ́rọ̀ ní kì í jẹ́ kó rí oorun sùn.

13 Àdánù* ńlá kan wà tí mo ti rí lábẹ́ ọ̀run:* ọrọ̀ tí àwọn ọlọ́rọ̀ kó pa mọ́ fún ìpalára ara wọn. 14 Àwọn ọrọ̀ yẹn ṣègbé nítorí òwò* àṣedànù, nígbà tó sì bímọ, kò ní ohun ìní kankan lọ́wọ́ mọ́.+

15 Bí èèyàn ṣe jáde wá látinú ìyá rẹ̀ ní ìhòòhò, bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe lọ.+ Kò lè mú ohunkóhun lọ nínú gbogbo iṣẹ́ àṣekára tó ti ṣe.+

16 Èyí pẹ̀lú jẹ́ àdánù* ńlá: Bí ẹni náà ṣe wá gẹ́lẹ́, bẹ́ẹ̀ ló ṣe máa lọ; èrè wo ló sì wà fún ẹni tó ń ṣiṣẹ́ kára lórí asán?+ 17 Yàtọ̀ síyẹn, ojoojúmọ́ ló ń jẹun nínú òkùnkùn pẹ̀lú ìbànújẹ́ ńlá àti àìsàn àti ìbínú.+

18 Ohun tí mo rí pé ó dára tí ó sì tọ́ ni pé: kéèyàn máa jẹ, kó máa mu, kó sì jẹ ìgbádùn gbogbo iṣẹ́ àṣekára+ tó fi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe lábẹ́ ọ̀run* láàárín ọjọ́ díẹ̀ tí Ọlọ́run tòótọ́ fún un, nítorí èrè* rẹ̀ nìyẹn.+ 19 Bákan náà, nígbà tí Ọlọ́run tòótọ́ bá fún ẹnì kan ní ọrọ̀ àti ohun ìní,+ tó sì jẹ́ kó lè gbádùn wọn, kí ẹni náà gba èrè* rẹ̀ kó sì máa yọ̀ nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ̀. Ẹ̀bùn Ọlọ́run ni èyí.+ 20 Torí bóyá ló fi máa mọ̀* pé ọjọ́ ayé òun ń lọ, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ ti mú kí ayọ̀ gbà á lọ́kàn.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́