ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 27
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Àwọn ọmọbìnrin Sélóféhádì (1-11)

      • Mósè fa iṣẹ́ lé Jóṣúà lọ́wọ́ (12-23)

Nọ́ńbà 27:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 26:33

Nọ́ńbà 27:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 18:25, 26

Nọ́ńbà 27:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:35; 16:1, 2, 19, 35

Nọ́ńbà 27:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 18:15, 16; 33:11; Le 24:11, 12

Nọ́ńbà 27:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 36:2; Joṣ 17:3, 4

Nọ́ńbà 27:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:47; Di 32:48, 49
  • +Jẹ 13:14, 15; Di 3:27; 32:52; 34:1

Nọ́ńbà 27:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 31:2; Di 34:7
  • +Nọ 20:24, 28; 33:38; Di 10:6; 32:50

Nọ́ńbà 27:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 20:10, 12; Di 1:37
  • +Sm 106:32, 33
  • +Di 1:2
  • +Joṣ 15:1

Nọ́ńbà 27:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹ̀mí gbogbo ẹran ara.”

Nọ́ńbà 27:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 34:9; Iṣe 6:5, 6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2002, ojú ìwé 12

Nọ́ńbà 27:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 31:7

Nọ́ńbà 27:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “iyì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 1:38; 31:3; 34:10
  • +Joṣ 1:17

Nọ́ńbà 27:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:30; 1Sa 23:9; 28:6; Ne 7:65

Nọ́ńbà 27:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 27:18
  • +Di 3:28; 31:14, 23

Àwọn míì

Nọ́ń. 27:1Nọ 26:33
Nọ́ń. 27:2Ẹk 18:25, 26
Nọ́ń. 27:3Nọ 14:35; 16:1, 2, 19, 35
Nọ́ń. 27:5Ẹk 18:15, 16; 33:11; Le 24:11, 12
Nọ́ń. 27:7Nọ 36:2; Joṣ 17:3, 4
Nọ́ń. 27:12Nọ 33:47; Di 32:48, 49
Nọ́ń. 27:12Jẹ 13:14, 15; Di 3:27; 32:52; 34:1
Nọ́ń. 27:13Nọ 31:2; Di 34:7
Nọ́ń. 27:13Nọ 20:24, 28; 33:38; Di 10:6; 32:50
Nọ́ń. 27:14Nọ 20:10, 12; Di 1:37
Nọ́ń. 27:14Sm 106:32, 33
Nọ́ń. 27:14Di 1:2
Nọ́ń. 27:14Joṣ 15:1
Nọ́ń. 27:18Di 34:9; Iṣe 6:5, 6
Nọ́ń. 27:19Di 31:7
Nọ́ń. 27:20Di 1:38; 31:3; 34:10
Nọ́ń. 27:20Joṣ 1:17
Nọ́ń. 27:21Ẹk 28:30; 1Sa 23:9; 28:6; Ne 7:65
Nọ́ń. 27:23Nọ 27:18
Nọ́ń. 27:23Di 3:28; 31:14, 23
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 27:1-23

Nọ́ńbà

27 Àwọn ọmọ Sélóféhádì+ wá sí tòsí, Sélóféhádì yìí ni ọmọ Héfà, ọmọ Gílíádì, ọmọ Mákírù, ọmọ Mánásè, látọ̀dọ̀ àwọn ìdílé Mánásè ọmọ Jósẹ́fù. Orúkọ àwọn ọmọ Sélóféhádì ni Málà, Nóà, Hógílà, Mílíkà àti Tírísà. 2 Wọ́n dúró síwájú Mósè, àlùfáà Élíásárì, àwọn ìjòyè+ àti gbogbo àpéjọ náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, wọ́n sì sọ pé: 3 “Bàbá wa ti kú ní aginjù, àmọ́ kò sí lára àwọn tó gbìmọ̀ pọ̀ láti ta ko Jèhófà, àwọn tó ti Kórà+ lẹ́yìn. Torí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ló ṣe kú, kò sì ní ọmọkùnrin kankan. 4 Kí ló dé tí orúkọ bàbá wa fi máa pa rẹ́ nínú ìdílé rẹ̀ torí pé kò bímọ ọkùnrin? Fún wa ní ohun ìní láàárín àwọn arákùnrin bàbá wa.” 5 Mósè wá mú ọ̀rọ̀ wọn tọ Jèhófà+ lọ.

6 Jèhófà sọ fún Mósè pé: 7 “Òótọ́ làwọn ọmọ Sélóféhádì sọ. Rí i pé o fún wọn ní ohun ìní tí wọ́n lè jogún láàárín àwọn arákùnrin bàbá wọn, kí o sì mú kí ogún bàbá wọn di tiwọn.+ 8 Kí o wá sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọkùnrin kan bá kú láì bímọ ọkùnrin, kí ẹ jẹ́ kí ogún rẹ̀ di ti ọmọbìnrin rẹ̀. 9 Tí kò bá sì bímọ obìnrin, kí ẹ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ ní ogún rẹ̀. 10 Tí kò bá sì ní arákùnrin, kí ẹ fún àwọn arákùnrin bàbá rẹ̀ ní ogún rẹ̀. 11 Tí bàbá rẹ̀ ò bá sì ní arákùnrin, kí ẹ fún mọ̀lẹ́bí rẹ̀ tó sún mọ́ ọn jù ní ogún rẹ̀, yóò sì di tirẹ̀. Èyí ni àṣẹ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì á máa tẹ̀ lé láti ṣèdájọ́, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.’”

12 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Gun orí òkè Ábárímù+ yìí, kí o sì wo ilẹ̀ tí màá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ 13 Tí o bá ti rí i, a máa kó ọ jọ pẹ̀lú àwọn èèyàn rẹ,*+ bíi ti Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ,+ 14 torí nígbà tí àpéjọ náà ń bá mi jà ní aginjù Síínì, ẹ ṣe ohun tó lòdì sí àṣẹ tí mo pa pé kí ẹ tipasẹ̀ omi+ náà fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ níṣojú wọn. Èyí ni omi Mẹ́ríbà+ tó wà ní Kádéṣì + ní aginjù Síínì.”+

15 Mósè wá sọ fún Jèhófà pé: 16 “Kí Jèhófà, Ọlọ́run tó ni ẹ̀mí gbogbo èèyàn* yan ọkùnrin kan ṣe olórí àpéjọ náà, 17 ẹni tí yóò máa jáde, tí yóò sì máa wọlé níwájú wọn, tí yóò máa darí wọn jáde, tí yóò sì máa kó wọn wọlé, kí àpéjọ àwọn èèyàn Jèhófà má bàa dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́.” 18 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Mú Jóṣúà ọmọ Núnì, ọkùnrin tí ẹ̀mí wà nínú rẹ̀, kí o sì gbé ọwọ́ rẹ lé e.+ 19 Kí o wá mú un dúró níwájú àlùfáà Élíásárì àti gbogbo àpéjọ, kí o sì fa iṣẹ́ lé e lọ́wọ́ níṣojú+ wọn. 20 Kí o sì fún un+ lára àṣẹ* tí o ní, kí gbogbo àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máa gbọ́ tirẹ̀.+ 21 Á sì máa dúró níwájú àlùfáà Élíásárì, ẹni tí yóò máa bá a ṣe ìwádìí níwájú Jèhófà nípasẹ̀ ohun tí Úrímù+ bá sọ. Àṣẹ rẹ̀ ni wọ́n á máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń jáde, àṣẹ rẹ̀ ni wọ́n á sì máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ń wọlé, òun àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pẹ̀lú gbogbo àpéjọ náà.”

22 Mósè ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́. Ó mú Jóṣúà dúró níwájú àlùfáà Élíásárì àti níwájú gbogbo àpéjọ náà, 23 ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, ó sì fa iṣẹ́ lé e+ lọ́wọ́ bí Jèhófà ṣe gbẹnu Mósè+ sọ gẹ́lẹ́.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́