ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Wọ́n ṣẹ́gun ọba Árádì (1-3)

      • Ejò tí wọ́n fi bàbà ṣe (4-9)

      • Ísírẹ́lì lọ yí ká Móábù (10-20)

      • Wọ́n ṣẹ́gun Síhónì ọba àwọn Ámórì (21-30)

      • Wọ́n ṣẹ́gun Ógù ọba àwọn Ámórì (31-35)

Nọ́ńbà 21:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:40; Joṣ 12:7, 14

Nọ́ńbà 21:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó túmọ̀ sí “Ìparun Pátápátá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 14:45

Nọ́ńbà 21:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn àwọn èèyàn náà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:41
  • +Nọ 20:21; Di 2:8; Ond 11:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1995, ojú ìwé 17

Nọ́ńbà 21:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn wa.”

  • *

    Tàbí “kórìíra oúnjẹ játijàti yìí tẹ̀gbintẹ̀gbin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 14:11; 15:24; Nọ 16:13
  • +Nọ 20:5
  • +Ẹk 16:15; Nọ 11:6; Sm 78:24, 25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/1999, ojú ìwé 26-27

Nọ́ńbà 21:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ejò oníná.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 10:6, 9

Nọ́ńbà 21:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 78:34
  • +Ẹk 32:11

Nọ́ńbà 21:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ejò oníná.”

Nọ́ńbà 21:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 18:1, 4
  • +Jo 3:14, 15
  • +Jo 6:40

Nọ́ńbà 21:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:43

Nọ́ńbà 21:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:44

Nọ́ńbà 21:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 2:13

Nọ́ńbà 21:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 22:36; Ond 11:18

Nọ́ńbà 21:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 64

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2009, ojú ìwé 32

    8/1/2004, ojú ìwé 26

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 152, 159-160

Nọ́ńbà 21:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹnu.”

Nọ́ńbà 21:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ẹ dá a lóhùn.”

Nọ́ńbà 21:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 13:15, 17

Nọ́ńbà 21:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “pápá.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “aṣálẹ̀, aginjù ”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 33:49
  • +Di 3:27; 34:1
  • +Nọ 23:28

Nọ́ńbà 21:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 2:26-28

Nọ́ńbà 21:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 20:14, 17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ilẹ̀ Dáradára,” ojú ìwé 8-9

Nọ́ńbà 21:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 2:30-35; 29:7; Ond 11:19, 20

Nọ́ńbà 21:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 135:10, 11
  • +Nọ 32:33; Ne 9:22
  • +Nọ 21:13; Di 3:16
  • +Ond 11:21, 22
  • +Joṣ 12:1, 2
  • +Nọ 32:1; 1Kr 6:77, 81

Nọ́ńbà 21:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 10:15, 16; 15:16; Ẹk 3:8; Di 7:1

Nọ́ńbà 21:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ond 11:23, 24; 1Ọb 11:7; 2Ọb 23:13

Nọ́ńbà 21:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 13:15, 17
  • +Joṣ 13:8, 9

Nọ́ńbà 21:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìlú tó yí i ká.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 32:1

Nọ́ńbà 21:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 3:11; 4:47; Joṣ 13:8, 12
  • +Di 3:1, 8, 10

Nọ́ńbà 21:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 20:3
  • +Ẹk 23:27; Di 7:24
  • +Di 3:2; Sm 135:10, 11

Nọ́ńbà 21:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 3:3
  • +Joṣ 12:4-6

Àwọn míì

Nọ́ń. 21:1Nọ 33:40; Joṣ 12:7, 14
Nọ́ń. 21:3Nọ 14:45
Nọ́ń. 21:4Nọ 33:41
Nọ́ń. 21:4Nọ 20:21; Di 2:8; Ond 11:18
Nọ́ń. 21:5Ẹk 14:11; 15:24; Nọ 16:13
Nọ́ń. 21:5Nọ 20:5
Nọ́ń. 21:5Ẹk 16:15; Nọ 11:6; Sm 78:24, 25
Nọ́ń. 21:61Kọ 10:6, 9
Nọ́ń. 21:7Sm 78:34
Nọ́ń. 21:7Ẹk 32:11
Nọ́ń. 21:92Ọb 18:1, 4
Nọ́ń. 21:9Jo 3:14, 15
Nọ́ń. 21:9Jo 6:40
Nọ́ń. 21:10Nọ 33:43
Nọ́ń. 21:11Nọ 33:44
Nọ́ń. 21:12Di 2:13
Nọ́ń. 21:13Nọ 22:36; Ond 11:18
Nọ́ń. 21:19Joṣ 13:15, 17
Nọ́ń. 21:20Nọ 33:49
Nọ́ń. 21:20Di 3:27; 34:1
Nọ́ń. 21:20Nọ 23:28
Nọ́ń. 21:21Di 2:26-28
Nọ́ń. 21:22Nọ 20:14, 17
Nọ́ń. 21:23Di 2:30-35; 29:7; Ond 11:19, 20
Nọ́ń. 21:24Sm 135:10, 11
Nọ́ń. 21:24Nọ 32:33; Ne 9:22
Nọ́ń. 21:24Nọ 21:13; Di 3:16
Nọ́ń. 21:24Ond 11:21, 22
Nọ́ń. 21:24Joṣ 12:1, 2
Nọ́ń. 21:24Nọ 32:1; 1Kr 6:77, 81
Nọ́ń. 21:25Jẹ 10:15, 16; 15:16; Ẹk 3:8; Di 7:1
Nọ́ń. 21:29Ond 11:23, 24; 1Ọb 11:7; 2Ọb 23:13
Nọ́ń. 21:30Joṣ 13:15, 17
Nọ́ń. 21:30Joṣ 13:8, 9
Nọ́ń. 21:32Nọ 32:1
Nọ́ń. 21:33Di 3:11; 4:47; Joṣ 13:8, 12
Nọ́ń. 21:33Di 3:1, 8, 10
Nọ́ń. 21:34Di 20:3
Nọ́ń. 21:34Ẹk 23:27; Di 7:24
Nọ́ń. 21:34Di 3:2; Sm 135:10, 11
Nọ́ń. 21:35Di 3:3
Nọ́ń. 21:35Joṣ 12:4-6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 21:1-35

Nọ́ńbà

21 Nígbà tí ọba ìlú Árádì+ ti ilẹ̀ Kénáánì, tó ń gbé Négébù gbọ́ pé Ísírẹ́lì ti ń gba ọ̀nà Átárímù bọ̀, ó gbéjà ko Ísírẹ́lì, ó sì kó lára wọn lọ. 2 Ísírẹ́lì wá jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Jèhófà pé: “Tí o bá fi àwọn èèyàn yìí lé mi lọ́wọ́, ó dájú pé màá run àwọn ìlú wọn pátápátá.” 3 Jèhófà fetí sí ohùn Ísírẹ́lì, ó sì fi àwọn ọmọ Kénáánì lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì pa àwọn àti àwọn ìlú wọn run pátápátá. Wọ́n wá pe orúkọ ibẹ̀ ní Hóómà.*+

4 Bí wọ́n ṣe ń bá ìrìn àjò wọn lọ láti Òkè Hóórì,+ wọ́n gba ọ̀nà Òkun Pupa kọjá, kí wọ́n lè lọ gba ẹ̀yìn ilẹ̀ Édómù,+ ìrìn àjò náà sì tán àwọn èèyàn náà* lókun. 5 Àwọn èèyàn náà wá ń sọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run àti Mósè+ pé: “Kí ló dé tí ẹ kó wa kúrò ní Íjíbítì ká lè wá kú sínú aginjù? Kò sí oúnjẹ, kò sí omi,+ a* sì ti kórìíra oúnjẹ játijàti+ yìí.”* 6 Ni Jèhófà bá rán àwọn ejò olóró* sí àwọn èèyàn náà, wọ́n sì ń ṣán àwọn èèyàn náà débi pé ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló kú.+

7 Àwọn èèyàn náà wá bá Mósè, wọ́n sì sọ pé: “A ti ṣẹ̀, torí a ti sọ̀rọ̀ sí Jèhófà àti ìwọ.+ Bá wa bẹ Jèhófà pé kó mú àwọn ejò náà kúrò lọ́dọ̀ wa.” Mósè sì bá àwọn èèyàn+ náà bẹ̀bẹ̀. 8 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: “Ṣe ejò kan tó dà bí ejò olóró,* kí o sì gbé e kọ́ sára òpó. Tí ejò bá ṣán ẹnikẹ́ni, onítọ̀hún máa ní láti wò ó kó má bàa kú.” 9 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Mósè fi bàbà ṣe ejò+ kan, ó sì gbé e kọ́ sára òpó+ náà. Nígbàkigbà tí ejò bá ṣán ẹnì kan, tó sì wo ejò bàbà náà, ẹni náà ò ní kú.+

10 Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò níbẹ̀, wọ́n sì pàgọ́ sí Óbótì.+ 11 Wọ́n kúrò ní Óbótì, wọ́n sì pàgọ́ sí Iye-ábárímù,+ ní aginjù tó dojú kọ Móábù, lápá ìlà oòrùn. 12 Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sì pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ Àfonífojì Séréédì.+ 13 Wọ́n kúrò níbẹ̀, wọ́n sì pàgọ́ sí agbègbè Áánónì,+ tó wà ní aginjù tó bẹ̀rẹ̀ láti ààlà àwọn Ámórì, torí Áánónì ni ààlà Móábù, láàárín Móábù àti àwọn Ámórì. 14 Ìdí nìyẹn tí ìwé Àwọn Ogun Jèhófà fi sọ̀rọ̀ nípa “Fáhébù tó wà ní Súfà àtàwọn àfonífojì Áánónì 15 àti gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́* àwọn àfonífojì, èyí tó dé ibi tí ìlú Árì wà, títí lọ dé ààlà Móábù.”

16 Lẹ́yìn náà, wọ́n lọ sí Bíà. Èyí ni kànga tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ fún Mósè pé: “Kó àwọn èèyàn náà jọ, kí n sì fún wọn ní omi.”

17 Ìgbà yẹn ni Ísírẹ́lì kọ orin yìí pé:

“Sun jáde, ìwọ kànga! Ẹ kọrin sí i!*

18 Kànga tí àwọn olórí gbẹ́, tí àwọn ìjòyè láàárín àwọn èèyàn wà,

Pẹ̀lú ọ̀pá àṣẹ àtàwọn ọ̀pá tiwọn.”

Wọ́n wá gbéra láti aginjù lọ sí Mátánà, 19 láti Mátánà, wọ́n lọ sí Náhálíélì, láti Náhálíélì, wọ́n lọ sí Bámótì.+ 20 Láti Bámótì, wọ́n lọ sí àfonífojì tó wà ní agbègbè* Móábù,+ ní òkè Písígà,+ tó kọjú sí Jéṣímónì.*+

21 Ísírẹ́lì wá ní kí àwọn ìránṣẹ́ lọ bá Síhónì ọba àwọn Ámórì pé:+ 22 “Jẹ́ ká gba ilẹ̀ rẹ kọjá. A ò ní yà sínú oko tàbí sínú ọgbà àjàrà. A ò ní mu omi inú kànga kankan. Ojú Ọ̀nà Ọba la máa gbà títí a fi máa kọjá ní ilẹ̀+ rẹ.” 23 Àmọ́ Síhónì ò jẹ́ kí Ísírẹ́lì gba ilẹ̀ rẹ̀ kọjá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Síhónì kó gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ jọ, wọ́n sì lọ gbéjà ko Ísírẹ́lì ní aginjù, nígbà tí wọ́n dé Jáhásì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá Ísírẹ́lì+ jà. 24 Àmọ́ Ísírẹ́lì fi idà+ ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì gba ilẹ̀+ rẹ̀ láti Áánónì+ lọ dé Jábókù,+ nítòsí àwọn ọmọ Ámónì, torí pé ààlà àwọn ọmọ Ámónì+ ni Jásérì+ wà.

25 Bí Ísírẹ́lì ṣe gba gbogbo àwọn ìlú yìí nìyẹn, wọ́n wá ń gbé ní gbogbo ìlú àwọn Ámórì,+ ní Hẹ́ṣíbónì àti gbogbo àrọko rẹ̀.* 26 Torí Hẹ́ṣíbónì ni ìlú Síhónì ọba àwọn Ámórì, ẹni tó bá ọba Móábù jà, tó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ títí lọ dé Áánónì. 27 Ìdí nìyẹn tí àwọn kan fi máa ń sọ̀rọ̀ àbùkù yìí lówelówe pé:

“Wá sí Hẹ́ṣíbónì.

Jẹ́ ká kọ́ ìlú Síhónì, ká sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in.

28 Torí iná jáde wá láti Hẹ́ṣíbónì, ọwọ́ iná láti ìlú Síhónì.

Ó ti jó Árì ti Móábù run, àwọn olúwa àwọn ibi gíga Áánónì.

29 O gbé, ìwọ Móábù! Ẹ máa pa run, ẹ̀yin ará Kémóṣì!+

Ó sọ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ di ìsáǹsá, ó sì sọ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ di ẹrú Síhónì, ọba àwọn Ámórì.

30 Ẹ jẹ́ ká ta wọ́n lọ́fà;

Hẹ́ṣíbónì máa pa run títí lọ dé Díbónì;+

Ẹ jẹ́ ká sọ ọ́ di ahoro títí dé Nófà;

Iná máa ràn dé Médébà.”+

31 Ísírẹ́lì wá ń gbé ní ilẹ̀ àwọn Ámórì. 32 Mósè rán àwọn ọkùnrin kan lọ ṣe amí Jásérì.+ Wọ́n gba àwọn àrọko rẹ̀,* wọ́n sì lé àwọn Ámórì tí wọ́n wà níbẹ̀ kúrò. 33 Lẹ́yìn náà, wọ́n pa dà, wọ́n sì lọ gba Ọ̀nà Báṣánì. Ógù+ ọba Báṣánì àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ sì jáde wá gbéjà kò wọ́n ní Édíréì.+ 34 Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Má bẹ̀rù rẹ̀,+ torí màá fi òun àti gbogbo àwọn èèyàn rẹ̀ àti ilẹ̀ rẹ̀ lé ọ lọ́wọ́,+ ohun tí o ṣe sí Síhónì, ọba àwọn Ámórì tó gbé ní Hẹ́ṣíbónì+ gẹ́lẹ́ ni wàá ṣe sí i.” 35 Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo èèyàn rẹ̀ jà, títí ìkankan nínú àwọn èèyàn rẹ̀ ò fi ṣẹ́ kù,+ wọ́n sì gba ilẹ̀+ rẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́