ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jòhánù 10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù

      • Olùṣọ́ àgùntàn àti ọgbà àgùntàn (1-21)

        • Jésù ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà (11-15)

        • “Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn” (16)

      • Àwọn Júù ta ko Jésù níbi Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́ (22-39)

        • Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ò gbà gbọ́ (24-26)

        • “Àwọn àgùntàn mi máa ń fetí sí ohùn mi” (27)

        • Ọmọ wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba (30, 38)

      • Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà ní òdìkejì Jọ́dánì gbà gbọ́ (40-42)

Jòhánù 10:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 7:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 186

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2004, ojú ìwé 14

Jòhánù 10:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:31; Mk 14:27; Jo 10:11

Jòhánù 10:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 1:17; Jo 3:28
  • +Jo 10:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 186

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    2/1/1995, ojú ìwé 9-10

    7/15/1994, ojú ìwé 31

Jòhánù 10:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 124-125

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2004, ojú ìwé 13-14, 17

    9/1/2002, ojú ìwé 17-18

    7/15/1994, ojú ìwé 31

Jòhánù 10:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2004, ojú ìwé 13-18

    7/15/1994, ojú ìwé 31

Jòhánù 10:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 80-81

Jòhánù 10:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 21:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 186

Jòhánù 10:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 7:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 186

Jòhánù 10:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 34:23; Mt 9:36
  • +1Sa 17:34, 35; Mt 20:28; Heb 13:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    2/1/1995, ojú ìwé 9

Jòhánù 10:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2012, ojú ìwé 27

Jòhánù 10:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 10:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2011, ojú ìwé 7-8

    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 9-10

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 152-153

Jòhánù 10:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 11:27
  • +Mt 20:28; Jo 15:13; 1Jo 3:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 152-153

Jòhánù 10:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 12:32
  • +Isk 34:23; 37:24; 1Pe 5:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2021, ojú ìwé 16

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 134

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2016, ojú ìwé 18

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 187

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2010, ojú ìwé 26

    4/15/1995, ojú ìwé 31

    2/1/1995, ojú ìwé 10-12

    Àìléwu Kárí-Ayé, ojú ìwé 69-72

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 152-153

Jòhánù 10:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 17:23
  • +Ais 53:12; Flp 2:8; Heb 2:9; 12:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ojú ìwé 21

Jòhánù 10:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 2:23, 24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run, ojú ìwé 21

Jòhánù 10:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 12:51; Jo 7:12; 9:16

Jòhánù 10:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 187

Jòhánù 10:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2011, ojú ìwé 14

Jòhánù 10:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìloro.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 3:11

Jòhánù 10:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn wa.”

Jòhánù 10:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 3:2; 5:36; 10:38; 14:10; Iṣe 2:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 188

Jòhánù 10:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 8:47

Jòhánù 10:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 10:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2013, ojú ìwé 22

    7/15/1996, ojú ìwé 21-22

Jòhánù 10:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 5:24; 17:1, 2
  • +Jo 6:37; 18:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2009, ojú ìwé 10

Jòhánù 10:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Pe 1:4, 5

Jòhánù 10:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “wà ní ìṣọ̀kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 10:38; 17:11, 21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 188

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2009, ojú ìwé 28

    10/15/1993, ojú ìwé 28-29

    Mẹtalọkan, ojú ìwé 24

Jòhánù 10:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 24:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 188

Jòhánù 10:34

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹni bí Ọlọ́run.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 82:6; 1Kọ 8:5

Jòhánù 10:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 82:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 188-189

Jòhánù 10:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 1:35; Jo 5:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 188-189

Jòhánù 10:38

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 5:36
  • +Jo 14:10; 17:21

Jòhánù 10:40

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 1:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 189

Jòhánù 10:41

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 1:29

Àwọn míì

Jòh. 10:1Mt 7:15
Jòh. 10:2Mt 26:31; Mk 14:27; Jo 10:11
Jòh. 10:3Lk 1:17; Jo 3:28
Jòh. 10:3Jo 10:27
Jòh. 10:7Jo 14:6
Jòh. 10:9Jo 21:17
Jòh. 10:10Mt 7:15
Jòh. 10:11Isk 34:23; Mt 9:36
Jòh. 10:111Sa 17:34, 35; Mt 20:28; Heb 13:20
Jòh. 10:14Jo 10:27
Jòh. 10:15Mt 11:27
Jòh. 10:15Mt 20:28; Jo 15:13; 1Jo 3:16
Jòh. 10:16Lk 12:32
Jòh. 10:16Isk 34:23; 37:24; 1Pe 5:4
Jòh. 10:17Jo 17:23
Jòh. 10:17Ais 53:12; Flp 2:8; Heb 2:9; 12:2
Jòh. 10:18Iṣe 2:23, 24
Jòh. 10:19Lk 12:51; Jo 7:12; 9:16
Jòh. 10:23Iṣe 3:11
Jòh. 10:25Jo 3:2; 5:36; 10:38; 14:10; Iṣe 2:22
Jòh. 10:26Jo 8:47
Jòh. 10:27Jo 10:3
Jòh. 10:28Jo 5:24; 17:1, 2
Jòh. 10:28Jo 6:37; 18:9
Jòh. 10:291Pe 1:4, 5
Jòh. 10:30Jo 10:38; 17:11, 21
Jòh. 10:33Le 24:16
Jòh. 10:34Sm 82:6; 1Kọ 8:5
Jòh. 10:35Sm 82:1
Jòh. 10:36Lk 1:35; Jo 5:18
Jòh. 10:38Jo 5:36
Jòh. 10:38Jo 14:10; 17:21
Jòh. 10:40Jo 1:28
Jòh. 10:41Jo 1:29
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
  • 41
  • 42
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jòhánù 10:1-42

Àkọsílẹ̀ Jòhánù

10 “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹni tí kò bá gba ẹnu ọ̀nà wọ ọgbà àgùntàn, àmọ́ tó gba ibòmíì gòkè wọlé, olè àti akónilẹ́rù ni ẹni yẹn.+ 2 Àmọ́ ẹni tó bá gba ẹnu ọ̀nà wọlé ni olùṣọ́ àgùntàn.+ 3 Aṣọ́nà ṣílẹ̀kùn fún ẹni yìí,+ àwọn àgùntàn sì fetí sí ohùn rẹ̀.+ Ó ń fi orúkọ pe àwọn àgùntàn rẹ̀, ó sì ń kó wọn jáde. 4 Tó bá ti kó gbogbo àwọn tirẹ̀ jáde, ó máa ń lọ níwájú wọn, àwọn àgùntàn á sì tẹ̀ lé e, torí wọ́n mọ ohùn rẹ̀. 5 Ó dájú pé wọn ò ní tẹ̀ lé àjèjì, ṣe ni wọ́n máa sá fún un, torí wọn ò mọ ohùn àwọn àjèjì.” 6 Jésù sọ àfiwé yìí fún wọn, àmọ́ ohun tó ń sọ fún wọn ò yé wọn.

7 Torí náà, Jésù tún sọ pé: “Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, èmi ni ẹnu ọ̀nà fún àwọn àgùntàn.+ 8 Olè àti akónilẹ́rù ni gbogbo àwọn tó wá dípò mi; àmọ́ àwọn àgùntàn ò fetí sí wọn. 9 Èmi ni ẹnu ọ̀nà; ẹnikẹ́ni tó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé máa rí ìgbàlà, ẹni yẹn máa wọlé, ó máa jáde, ó sì máa rí ibi ìjẹko.+ 10 Olè kì í wá àfi tó bá fẹ́ jalè, kó pani, kó sì ba nǹkan jẹ́.+ Èmi wá, kí wọ́n lè ní ìyè, kí wọ́n sì ní in lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. 11 Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà;+ olùṣọ́ àgùntàn àtàtà máa ń fi ẹ̀mí* rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.+ 12 Nígbà tí alágbàṣe tí kì í ṣe olùṣọ́ àgùntàn, tí kì í sì í ṣe òun ló ni àwọn àgùntàn, rí ìkookò tó ń bọ̀, ó pa àwọn àgùntàn tì, ó sì sá lọ—ìkookò gbá wọn mú, ó sì tú wọn ká— 13 torí pé alágbàṣe ni, ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn ò sì jẹ ẹ́ lógún. 14 Èmi ni olùṣọ́ àgùntàn àtàtà. Mo mọ àwọn àgùntàn mi, àwọn àgùntàn mi sì mọ̀ mí,+ 15 bí Baba ṣe mọ̀ mí, tí mo sì mọ Baba;+ mo fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀ nítorí àwọn àgùntàn.+

16 “Mo ní àwọn àgùntàn mìíràn, tí kò sí lára ọ̀wọ́ yìí;+ mo gbọ́dọ̀ mú àwọn yẹn náà wá, wọ́n á fetí sí ohùn mi, wọ́n á sì di agbo kan, olùṣọ́ àgùntàn kan.+ 17 Ìdí nìyí tí Baba fi nífẹ̀ẹ́ mi,+ torí pé mo fi ẹ̀mí* mi lélẹ̀,+ kí n lè tún rí i gbà. 18 Kò sí èèyàn kankan tó gbà á lọ́wọ́ mi, èmi ni mo yọ̀ǹda láti fi lélẹ̀. Mo ní àṣẹ láti fi lélẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti tún un gbà.+ Ọwọ́ Baba mi ni mo ti gba àṣẹ yìí.”

19 Àwọn Júù tún pínyà síra wọn+ nítorí àwọn ọ̀rọ̀ yìí. 20 Ọ̀pọ̀ nínú wọn ń sọ pé: “Ẹlẹ́mìí èṣù ni, orí rẹ̀ sì ti yí. Kí ló dé tí ẹ̀ ń fetí sí i?” 21 Àwọn míì sọ pé: “Àwọn ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe ti ẹlẹ́mìí èṣù. Ẹ̀mí èṣù ò lè la ojú afọ́jú, àbí ó lè là á?”

22 Ní àkókò yẹn, Àjọyọ̀ Ìyàsímímọ́ wáyé ní Jerúsálẹ́mù. Ìgbà òtútù ni, 23 Jésù sì ń rìn nínú tẹ́ńpìlì ní ọ̀dẹ̀dẹ̀* Sólómọ́nì.+ 24 Ni àwọn Júù bá yí i ká, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún un pé: “Títí dìgbà wo lo fẹ́ fi wá* sínú òkùnkùn? Tó bá jẹ́ ìwọ ni Kristi náà, sọ fún wa ní tààràtà.” 25 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Mo ti sọ fún yín, síbẹ̀ ẹ ò gbà gbọ́. Àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní orúkọ Baba mi ń jẹ́rìí nípa mi.+ 26 Àmọ́ ẹ ò gbà gbọ́, torí ẹ kì í ṣe àgùntàn mi.+ 27 Àwọn àgùntàn mi máa ń fetí sí ohùn mi, mo mọ̀ wọ́n, wọ́n sì ń tẹ̀ lé mi.+ 28 Mo fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun,+ ó sì dájú pé wọn ò ní pa run láé, ẹnikẹ́ni ò sì ní já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ mi.+ 29 Ohun tí Baba mi ti fún mi tóbi ju gbogbo nǹkan míì lọ, kò sì sẹ́ni tó lè já wọn gbà kúrò lọ́wọ́ Baba.+ 30 Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.”*+

31 Ni àwọn Júù bá tún mú òkúta kí wọ́n lè sọ ọ́ lù ú. 32 Jésù sọ fún wọn pé: “Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fi hàn yín látọ̀dọ̀ Baba. Torí èwo nínú àwọn iṣẹ́ yìí lẹ ṣe fẹ́ sọ mí lókùúta?” 33 Àwọn Júù dá a lóhùn pé: “Kì í ṣe torí iṣẹ́ rere la ṣe fẹ́ sọ ọ́ lókùúta, torí ọ̀rọ̀ òdì ni;+ torí pé o ti sọ ara rẹ di ọlọ́run, ìwọ tó jẹ́ pé èèyàn ni ọ́.” 34 Jésù sọ fún wọn pé: “Ṣebí a kọ ọ́ sínú Òfin yín pé, ‘Mo sọ pé: “ọlọ́run* ni yín”’?+ 35 Tó bá pe àwọn tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lòdì sí ní ‘ọlọ́run,’+ síbẹ̀ tí a kò lè wọ́gi lé ìwé mímọ́, 36 ṣé èmi tí Baba sọ di mímọ́, tó sì rán wá sí ayé lẹ wá ń sọ fún pé, ‘O sọ̀rọ̀ òdì,’ torí mo sọ pé, ‘Ọmọ Ọlọ́run ni mí’?+ 37 Tí mi ò bá ṣe àwọn iṣẹ́ Baba mi, ẹ má gbà mí gbọ́. 38 Àmọ́ tí mo bá ń ṣe é, bí ẹ ò tiẹ̀ gbà mí gbọ́, ẹ gba àwọn iṣẹ́ náà gbọ́,+ kí ẹ lè wá mọ̀, kí ẹ sì túbọ̀ máa mọ̀ pé Baba wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú mi, mo sì wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Baba.”+ 39 Ni wọ́n bá tún fẹ́ mú un, àmọ́ ó bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́.

40 Ó tún lọ sí òdìkejì Jọ́dánì, síbi tí Jòhánù ti kọ́kọ́ ń ṣèrìbọmi fún àwọn èèyàn,+ ó sì dúró síbẹ̀. 41 Ọ̀pọ̀ èèyàn wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé: “Jòhánù ò ṣe iṣẹ́ àmì kankan, àmọ́ òótọ́ ni gbogbo ohun tí Jòhánù sọ nípa ọkùnrin yìí.”+ 42 Ọ̀pọ̀ èèyàn sì gbà á gbọ́ níbẹ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́