ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • 2 Kíróníkà 34
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Kíróníkà

      • Jòsáyà di ọba Júdà (1, 2)

      • Àwọn àtúnṣe tí Jòsáyà ṣe (3-13)

      • Wọ́n rí Ìwé Òfin (14-21)

      • Àsọtẹ́lẹ̀ Húlídà nípa àjálù (22-28)

      • Jòsáyà ka ìwé náà fún àwọn èèyàn (29-33)

2 Kíróníkà 34:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 13:2; Sef 1:1; Mt 1:10
  • +2Ọb 22:1, 2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 21

2 Kíróníkà 34:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 21

2 Kíróníkà 34:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

  • *

    Tàbí “àwọn ère dídà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 15:2
  • +2Kr 33:17
  • +2Kr 33:21, 22
  • +2Ọb 23:4, 14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1996, ojú ìwé 8-9

2 Kíróníkà 34:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

  • *

    Tàbí “àwọn ère dídà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:6

2 Kíróníkà 34:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 13:2; 2Ọb 23:16

2 Kíróníkà 34:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:19; 2Kr 30:1

2 Kíróníkà 34:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:41
  • +2Kr 31:1

2 Kíróníkà 34:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ilé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:12
  • +2Ọb 22:3-6

2 Kíróníkà 34:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 30:11, 18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 55

2 Kíróníkà 34:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 55

2 Kíróníkà 34:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 12:11, 12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 55

2 Kíróníkà 34:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 12:15
  • +1Kr 23:6
  • +2Kr 20:19
  • +1Kr 25:1

2 Kíróníkà 34:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn tó ń ru ẹrù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 8:14

2 Kíróníkà 34:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “láti ọwọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:4
  • +Di 17:18; 31:24-26; Joṣ 1:8; 2Ọb 22:8
  • +Le 26:46

2 Kíróníkà 34:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:8
  • +Di 17:18, 19

2 Kíróníkà 34:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:11-13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2001, ojú ìwé 27

2 Kíróníkà 34:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:22; Jer 40:14

2 Kíróníkà 34:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:17, 18; 31:16, 24-26; Joṣ 1:8

2 Kíróníkà 34:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:20; Ond 4:4; Lk 2:36; Iṣe 21:8, 9
  • +2Ọb 22:14-20

2 Kíróníkà 34:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 35:17
  • +Le 26:16; Di 28:15; 30:17, 18; Da 9:11

2 Kíróníkà 34:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:20
  • +2Ọb 21:1, 3, 6; 2Kr 28:1, 3
  • +Di 29:22, 23; Jer 7:20

2 Kíróníkà 34:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 34:19

2 Kíróníkà 34:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ọkàn rẹ rọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:26; 33:11, 13

2 Kíróníkà 34:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Àkànlò èdè yìí ni wọ́n fi ń sọ pé èèyàn kú.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 21:29; Ais 39:8

2 Kíróníkà 34:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:1

2 Kíróníkà 34:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:2; 2Kr 17:3, 9; Ne 8:3

2 Kíróníkà 34:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tún májẹ̀mú dá.”

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 10:3
  • +Di 6:5
  • +Di 31:24-26; 2Ọb 22:8

2 Kíróníkà 34:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 30:1, 12; 33:1, 16

2 Kíróníkà 34:33

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn òrìṣà.”

  • *

    Ní Héb., “Ní gbogbo ọjọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2005, ojú ìwé 21

Àwọn míì

2 Kíró. 34:11Ọb 13:2; Sef 1:1; Mt 1:10
2 Kíró. 34:12Ọb 22:1, 2
2 Kíró. 34:32Kr 15:2
2 Kíró. 34:32Kr 33:17
2 Kíró. 34:32Kr 33:21, 22
2 Kíró. 34:32Ọb 23:4, 14
2 Kíró. 34:42Ọb 23:6
2 Kíró. 34:51Ọb 13:2; 2Ọb 23:16
2 Kíró. 34:62Ọb 23:19; 2Kr 30:1
2 Kíró. 34:72Ọb 17:41
2 Kíró. 34:72Kr 31:1
2 Kíró. 34:82Ọb 22:12
2 Kíró. 34:82Ọb 22:3-6
2 Kíró. 34:92Kr 30:11, 18
2 Kíró. 34:112Ọb 12:11, 12
2 Kíró. 34:122Ọb 12:15
2 Kíró. 34:121Kr 23:6
2 Kíró. 34:122Kr 20:19
2 Kíró. 34:121Kr 25:1
2 Kíró. 34:132Kr 8:14
2 Kíró. 34:142Ọb 22:4
2 Kíró. 34:14Di 17:18; 31:24-26; Joṣ 1:8; 2Ọb 22:8
2 Kíró. 34:14Le 26:46
2 Kíró. 34:182Ọb 22:8
2 Kíró. 34:18Di 17:18, 19
2 Kíró. 34:192Ọb 22:11-13
2 Kíró. 34:202Ọb 25:22; Jer 40:14
2 Kíró. 34:21Di 30:17, 18; 31:16, 24-26; Joṣ 1:8
2 Kíró. 34:22Ẹk 15:20; Ond 4:4; Lk 2:36; Iṣe 21:8, 9
2 Kíró. 34:222Ọb 22:14-20
2 Kíró. 34:24Jer 35:17
2 Kíró. 34:24Le 26:16; Di 28:15; 30:17, 18; Da 9:11
2 Kíró. 34:25Di 28:20
2 Kíró. 34:252Ọb 21:1, 3, 6; 2Kr 28:1, 3
2 Kíró. 34:25Di 29:22, 23; Jer 7:20
2 Kíró. 34:262Kr 34:19
2 Kíró. 34:272Kr 32:26; 33:11, 13
2 Kíró. 34:281Ọb 21:29; Ais 39:8
2 Kíró. 34:292Ọb 23:1
2 Kíró. 34:302Ọb 23:2; 2Kr 17:3, 9; Ne 8:3
2 Kíró. 34:31Ẹsr 10:3
2 Kíró. 34:31Di 6:5
2 Kíró. 34:31Di 31:24-26; 2Ọb 22:8
2 Kíró. 34:322Kr 30:1, 12; 33:1, 16
2 Kíró. 34:332Ọb 23:5
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
2 Kíróníkà 34:1-33

Kíróníkà Kejì

34 Ọmọ ọdún mẹ́jọ ni Jòsáyà+ nígbà tó jọba, ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n (31) ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ 2 Ó ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Jèhófà, ó rìn ní àwọn ọ̀nà Dáfídì baba ńlá rẹ̀, kò sì yà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.

3 Ní ọdún kẹjọ ìjọba rẹ̀, nígbà tó ṣì jẹ́ ọ̀dọ́kùnrin, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ̀;+ ní ọdún kejìlá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ibi gíga+ àti àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn ère gbígbẹ́+ pẹ̀lú àwọn ère onírin* kúrò ní Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+ 4 Láfikún sí i, wọ́n wó pẹpẹ àwọn Báálì lulẹ̀ níṣojú rẹ̀, ó sì gé àwọn pẹpẹ tùràrí tó wà lókè orí wọn lulẹ̀. Ó tún fọ́ àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn ère gbígbẹ́ pẹ̀lú àwọn ère onírin* sí wẹ́wẹ́, ó lọ̀ wọ́n lẹ́búlẹ́bú, ó sì wọ́n ekuru wọn sórí sàréè àwọn tó ń rúbọ sí wọn tẹ́lẹ̀.+ 5 Ó sun egungun àwọn àlùfáà lórí àwọn pẹpẹ wọn.+ Bí ó ṣe fọ Júdà àti Jerúsálẹ́mù mọ́ nìyẹn.

6 Ní àwọn ìlú Mánásè, Éfúrémù,+ Síméónì àti títí dé Náfútálì, ní àwọn ibi tó ti di àwókù tó yí wọn ká, 7 ó wó àwọn pẹpẹ, ó fọ́ àwọn òpó òrìṣà* àti àwọn ère gbígbẹ́ túútúú,+ ó sì lọ̀ wọ́n lẹ́búlẹ́bú; ó gé gbogbo àwọn pẹpẹ tùràrí lulẹ̀ ní gbogbo ilẹ̀ Ísírẹ́lì,+ lẹ́yìn náà, ó pa dà sí Jerúsálẹ́mù.

8 Ní ọdún kejìdínlógún ìjọba rẹ̀, nígbà tó ti fọ ilẹ̀ náà àti tẹ́ńpìlì* náà mọ́, ó rán Ṣáfánì + ọmọ Asaláyà àti Maaseáyà olórí ìlú náà àti Jóà ọmọ Jóáhásì akọ̀wé ìrántí láti lọ tún ilé Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ ṣe.+ 9 Wọ́n wá sọ́dọ̀ Hilikáyà àlùfáà àgbà, wọ́n sì fún un ní owó tí àwọn èèyàn mú wá sí ilé Ọlọ́run, èyí tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ aṣọ́nà ti gbà lọ́wọ́ Mánásè àti Éfúrémù àti lọ́wọ́ gbogbo ìyókù Ísírẹ́lì,+ títí kan Júdà, Bẹ́ńjámínì àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù. 10 Lẹ́yìn náà, wọ́n kó o fún àwọn tí wọ́n yàn láti máa bójú tó iṣẹ́ ilé Jèhófà. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà sì lò ó láti mú ilé náà bọ̀ sípò àti láti tún un ṣe. 11 Wọ́n kó o fún àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn kọ́lékọ́lé láti fi ra òkúta gbígbẹ́ àti àwọn ẹ̀là gẹdú láti fi ṣe àwọn agbóhunró àti àwọn ìtì igi tí wọ́n á fi kọ́ àwọn ilé tí àwọn ọba Júdà ti jẹ́ kó di àwókù.+

12 Àwọn ọkùnrin náà fi òótọ́ inú ṣe iṣẹ́ náà.+ Àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n yàn láti jẹ́ alábòójútó wọn ni Jáhátì àti Ọbadáyà látinú àwọn ọmọ Mérárì+ àti Sekaráyà pẹ̀lú Méṣúlámù látinú àwọn ọmọ Kóhátì.+ Àwọn ọmọ Léfì, tí gbogbo wọn jẹ́ olórin tó mọṣẹ́ orin,+ 13 ló ń mójú tó àwọn lébìrà,* àwọn sì tún ni alábòójútó gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà ní onírúurú ẹ̀ka; àwọn kan lára àwọn ọmọ Léfì sì jẹ́ akọ̀wé, aláṣẹ àti aṣọ́bodè.+

14 Nígbà tí wọ́n ń kó owó táwọn èèyàn mú wá sí ilé Jèhófà jáde,+ àlùfáà Hilikáyà rí ìwé Òfin+ tí Jèhófà fún wọn nípasẹ̀* Mósè.+ 15 Torí náà, Hilikáyà sọ fún Ṣáfánì akọ̀wé pé: “Mo ti rí ìwé Òfin ní ilé Jèhófà.” Ni Hilikáyà bá fún Ṣáfánì ní ìwé náà. 16 Ṣáfánì mú ìwé náà wá sọ́dọ̀ ọba, ó sì sọ fún un pé: “Àwọn ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe gbogbo ohun tí a yàn fún wọn. 17 Wọ́n ti kó owó tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà, wọ́n sì ti kó o fún àwọn ọkùnrin tí a yàn àti àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ náà.” 18 Ṣáfánì akọ̀wé tún sọ fún ọba pé: “Ìwé kan wà tí àlùfáà Hilikáyà fún mi.”+ Ṣáfánì sì bẹ̀rẹ̀ sí í kà á níwájú ọba.+

19 Gbàrà tí ọba gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú Òfin náà, ó fa aṣọ rẹ̀ ya.+ 20 Ọba wá pa àṣẹ yìí fún Hilikáyà, Áhíkámù+ ọmọ Ṣáfánì, Ábídónì ọmọ Míkà, Ṣáfánì akọ̀wé àti Ásáyà ìránṣẹ́ ọba pé: 21 “Ẹ lọ bá èmi àti àwọn tó ṣẹ́ kù ní Ísírẹ́lì àti ní Júdà wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a rí yìí; nítorí ìbínú Jèhófà tó máa tú jáde sórí wa pọ̀ gan-an torí àwọn baba ńlá wa kò pa ọ̀rọ̀ Jèhófà mọ́, wọn ò ṣe gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé yìí.”+

22 Torí náà, Hilikáyà àti àwọn tí ọba rán, lọ sọ́dọ̀ wòlíì obìnrin+ tó ń jẹ́ Húlídà. Òun ni ìyàwó Ṣálúmù ọmọ Tíkífà ọmọ Háhásì, ẹni tó ń bójú tó ibi tí wọ́n ń kó aṣọ sí. Ó ń gbé ní Apá Kejì Jerúsálẹ́mù; wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀.+ 23 Ó sọ fún wọn pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ sọ fún ọkùnrin tó rán yín wá sọ́dọ̀ mi pé: 24 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Màá mú àjálù bá ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀,+ ìyẹn gbogbo ègún tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé+ tí wọ́n kà níwájú ọba Júdà. 25 Nítorí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀,+ wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run míì láti fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,+ ìbínú mi máa tú jáde bí iná sórí ibí yìí, kò sì ní ṣeé pa.’”+ 26 Àmọ́, ní ti ọba Júdà tó rán yín pé kí ẹ lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: ‘Ní ti àwọn ọ̀rọ̀ tí o gbọ́,+ 27 nítorí pé ọlọ́kàn tútù ni ọ́,* tí o rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run bí o ṣe gbọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ nípa ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀, tí o sì rẹ ara rẹ sílẹ̀ níwájú mi, tí o fa aṣọ rẹ ya, tí o sì sunkún níwájú mi, èmi náà ti gbọ́ ohun tí o sọ,+ ni Jèhófà wí. 28 Ìdí nìyẹn tí màá fi kó ọ jọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ,* a ó tẹ́ ọ sínú sàréè rẹ ní àlàáfíà, ojú rẹ ò ní rí gbogbo àjálù tí màá mú bá ibí yìí àti àwọn tó ń gbé ibẹ̀.’”’”+

Lẹ́yìn náà, wọ́n mú èsì náà wá fún ọba. 29 Nígbà náà, ọba ránṣẹ́, ó sì pe gbogbo àwọn àgbààgbà Júdà àti Jerúsálẹ́mù jọ.+ 30 Lẹ́yìn náà, ọba lọ sí ilé Jèhófà pẹ̀lú gbogbo èèyàn Júdà, àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, ìyẹn gbogbo àwọn èèyàn náà, ẹni kékeré àti ẹni ńlá. Ó ka gbogbo ọ̀rọ̀ inú ìwé májẹ̀mú tí wọ́n rí ní ilé Jèhófà sí wọn létí.+ 31 Ọba dúró sí àyè rẹ̀, ó sì dá májẹ̀mú*+ níwájú Jèhófà pé gbogbo ọkàn àti gbogbo ara* ni òun á máa fi tẹ̀ lé Jèhófà,+ òun á sì máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn ìránnilétí rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìlànà rẹ̀, láti máa ṣe ohun tí májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí sọ.+ 32 Yàtọ̀ síyẹn, ó mú kí gbogbo àwọn tó wà ní Jerúsálẹ́mù àti Bẹ́ńjámínì fara mọ́ ọn. Àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù sì ṣe ohun tí májẹ̀mú Ọlọ́run sọ, ìyẹn Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.+ 33 Lẹ́yìn ìyẹn, Jòsáyà mú gbogbo àwọn ohun ìríra* kúrò ní gbogbo ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì,+ ó sì mú kí gbogbo àwọn tó wà ní Ísírẹ́lì máa sin Jèhófà Ọlọ́run wọn. Ní gbogbo ọjọ́ ayé* rẹ̀, wọn ò pa dà lẹ́yìn Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́