ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Bí ìpẹ̀yìndà Ísírẹ́lì ṣe burú tó (1-5)

      • Ísírẹ́lì àti Júdà jẹ̀bi àgbèrè (6-11)

      • Ọlọ́run ní kí wọ́n ronú pìwà dà (12-25)

Jeremáyà 3:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 24:5; Jer 2:7
  • +Jer 2:20; Isk 16:28, 29

Jeremáyà 3:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ará Arébíà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 16:16; 20:28

Jeremáyà 3:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Iwájú orí rẹ rí bíi ti.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:19; Jer 14:4; Emọ 4:7
  • +Jer 6:15

Jeremáyà 3:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:2

Jeremáyà 3:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 2:1; 7:3

Jeremáyà 3:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 22:1
  • +Isk 20:28; Ho 4:13

Jeremáyà 3:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:13; 2Kr 30:6; Ho 14:1
  • +Isk 16:46; 23:2, 4

Jeremáyà 3:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 24:1
  • +Isk 23:4, 5, 9; Ho 2:2; 9:15
  • +2Ọb 17:19; Isk 23:4, 11

Jeremáyà 3:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 57:5, 6; Jer 2:27

Jeremáyà 3:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn òun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 16:51; 23:4, 11

Jeremáyà 3:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lejú mọ́ ọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:6; Jer 23:8
  • +Jer 4:1; Isk 33:11; Ho 14:1
  • +Ho 11:8, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 150-152

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 9

Jeremáyà 3:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè.”

Jeremáyà 3:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ọkọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 23:3

Jeremáyà 3:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 23:4; Isk 34:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 103-104

    Jeremáyà, ojú ìwé 129-130

Jeremáyà 3:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 1:10

Jeremáyà 3:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 87:3; Isk 43:7
  • +Ais 2:2, 3; 56:6, 7; 60:3; Mik 4:1, 2; Sek 2:11; 8:22, 23

Jeremáyà 3:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 50:4; Isk 37:19; Ho 1:11
  • +2Kr 36:23; Ẹsr 1:3; Emọ 9:15

Jeremáyà 3:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọmọ ogun àwọn orílẹ̀-èdè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 20:6

Jeremáyà 3:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “alábàákẹ́gbẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 48:8; Ho 3:1; 5:7

Jeremáyà 3:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 17:10; Ho 8:14; 13:6

Jeremáyà 3:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 14:1, 4
  • +Jer 31:18; Ho 3:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 72

Jeremáyà 3:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 65:7
  • +Ais 12:2

Jeremáyà 3:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọlọ́run ìtìjú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 9:10

Jeremáyà 3:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 2:19
  • +Ẹsr 9:7; Sm 106:7

Àwọn míì

Jer. 3:1Ais 24:5; Jer 2:7
Jer. 3:1Jer 2:20; Isk 16:28, 29
Jer. 3:2Isk 16:16; 20:28
Jer. 3:3Le 26:19; Jer 14:4; Emọ 4:7
Jer. 3:3Jer 6:15
Jer. 3:4Jer 2:2
Jer. 3:5Mik 2:1; 7:3
Jer. 3:62Ọb 22:1
Jer. 3:6Isk 20:28; Ho 4:13
Jer. 3:72Ọb 17:13; 2Kr 30:6; Ho 14:1
Jer. 3:7Isk 16:46; 23:2, 4
Jer. 3:8Di 24:1
Jer. 3:8Isk 23:4, 5, 9; Ho 2:2; 9:15
Jer. 3:82Ọb 17:19; Isk 23:4, 11
Jer. 3:9Ais 57:5, 6; Jer 2:27
Jer. 3:11Isk 16:51; 23:4, 11
Jer. 3:12Jer 4:1; Isk 33:11; Ho 14:1
Jer. 3:12Ho 11:8, 9
Jer. 3:122Ọb 17:6; Jer 23:8
Jer. 3:14Jer 23:3
Jer. 3:15Jer 23:4; Isk 34:23
Jer. 3:16Ho 1:10
Jer. 3:17Sm 87:3; Isk 43:7
Jer. 3:17Ais 2:2, 3; 56:6, 7; 60:3; Mik 4:1, 2; Sek 2:11; 8:22, 23
Jer. 3:18Jer 50:4; Isk 37:19; Ho 1:11
Jer. 3:182Kr 36:23; Ẹsr 1:3; Emọ 9:15
Jer. 3:19Isk 20:6
Jer. 3:20Ais 48:8; Ho 3:1; 5:7
Jer. 3:21Ais 17:10; Ho 8:14; 13:6
Jer. 3:22Ho 14:1, 4
Jer. 3:22Jer 31:18; Ho 3:5
Jer. 3:23Ais 65:7
Jer. 3:23Ais 12:2
Jer. 3:24Ho 9:10
Jer. 3:25Jer 2:19
Jer. 3:25Ẹsr 9:7; Sm 106:7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 3:1-25

Jeremáyà

3 Àwọn èèyàn béèrè pé: “Bí ọkùnrin kan bá lé ìyàwó rẹ̀ lọ, tí obìnrin náà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, tó sì lọ fẹ́ ọkùnrin míì, ṣé ó yẹ kí ọkùnrin náà tún lọ bá obìnrin yẹn?”

Ǹjẹ́ wọn ò ti sọ ilẹ̀ náà di ẹlẹ́gbin pátápátá?+

“O ti bá ọ̀pọ̀ àwọn tí ò ń bá kẹ́gbẹ́ ṣe ìṣekúṣe,+

Ṣé ó wá yẹ kí o pa dà sọ́dọ̀ mi?” ni Jèhófà wí.

 2 “Gbé ojú rẹ sókè kí o sì wo orí àwọn òkè.

Ibo ni wọn ò ti bá ọ lò pọ̀?

Ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà lo jókòó sí dè wọ́n,

Bí àwọn alárìnkiri* nínú aginjù.

O sì ń fi iṣẹ́ aṣẹ́wó rẹ àti ìwà búburú rẹ

Sọ ilẹ̀ náà di ẹlẹ́gbin.+

 3 Torí náà ni òjò kò fi rọ̀,+

Tí kò sì sí òjò ní ìgbà ìrúwé.

O rí bí* ọ̀dájú ìyàwó tó ń ṣe aṣẹ́wó;

O ò ní ìtìjú.+

 4 Àmọ́ ní báyìí ò ń ké pè mí, o ní,

‘Bàbá mi, ìwọ ni ọ̀rẹ́ tí mo ní láti ìgbà èwe mi!+

 5 Ṣé títí ayé ni wàá fi máa bínú ni,

Tàbí ṣé ìgbà gbogbo ni wàá fi dì mí sínú?’

Ohun tí ò ń sọ nìyí,

Àmọ́ gbogbo ìwà ibi tí o mọ̀ lò ń hù ṣáá.”+

6 Nígbà ayé Ọba Jòsáyà,+ Jèhófà sọ fún mi pé: “‘Ṣé o ti rí ohun tí Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ṣe? Ó ti lọ sórí gbogbo òkè ńlá àti sábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, kí ó lè ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ 7 Kódà lẹ́yìn tó ti ṣe gbogbo nǹkan yìí, mò ń sọ fún un pé kó pa dà sọ́dọ̀ mi,+ àmọ́ kò pa dà; Júdà sì ń wo arábìnrin rẹ̀ oníbékebèke+ níran. 8 Nígbà tí mo rí ìyẹn, mo lé Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ lọ, mo sì já ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀+ fún un nítorí àgbèrè rẹ̀.+ Síbẹ̀, ẹ̀rù kò ba Júdà arábìnrin rẹ̀ tó ń ṣe békebèke; ṣe ni òun náà tún lọ ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ 9 Kò ka iṣẹ́ aṣẹ́wó tó ń ṣe sí àìdáa, ó ń sọ ilẹ̀ náà di ẹlẹ́gbin, ó sì ń bá àwọn òkúta àti igi ṣe àgbèrè.+ 10 Láìka gbogbo èyí sí, Júdà arábìnrin rẹ̀ tó ń ṣe békebèke kò fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa dà sọ́dọ̀ mi, ṣe ló ń díbọ́n,’ ni Jèhófà wí.”

11 Lẹ́yìn náà, Jèhófà sọ fún mi pé: “Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ti fi hàn pé òun* jẹ́ olódodo ju Júdà oníbékebèke lọ.+ 12 Lọ, kí o sì kéde ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àríwá pé:+

“‘“Pa dà, ìwọ Ísírẹ́lì ọ̀dàlẹ̀,” ni Jèhófà wí.’+ ‘“Mi ò ní wò ọ́ tìbínútìbínú,*+ nítorí adúróṣinṣin ni mí,” ni Jèhófà wí.’ ‘“Mi ò sì ní máa bínú títí láé. 13 Kìkì pé kí o mọ ẹ̀bi rẹ lẹ́bi, nítorí o ti ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ. Ò ń bá àwọn àjèjì* lò pọ̀ lábẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, àmọ́ o kò fetí sí ohùn mi,” ni Jèhófà wí.’”

14 “Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọ̀dàlẹ̀ ọmọ,” ni Jèhófà wí. “Nítorí mo ti di ọ̀gá* yín; màá mú yín, ọ̀kan nínú ìlú kan àti méjì nínú ìdílé kan, màá sì mú yín wá sí Síónì.+ 15 Màá fún yín ní àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí ọkàn mi fẹ́,+ wọ́n á sì fi ìmọ̀ àti ìjìnlẹ̀ òye bọ́ yín. 16 Ẹ ó di púpọ̀, ẹ ó sì so èso ní ilẹ̀ náà ní àwọn àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí.+ “Wọn ò tún ní sọ pé, ‘Àpótí májẹ̀mú Jèhófà!’ Kò ní wá sí wọn lọ́kàn mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní rántí rẹ̀ mọ́ tàbí kí wọ́n ṣàárò rẹ̀, wọn kò sì ní ṣe òmíràn mọ́. 17 Ní àkókò yẹn, wọ́n á pe Jerúsálẹ́mù ní ìtẹ́ Jèhófà;+ gbogbo orílẹ̀-èdè á kóra jọ ní orúkọ Jèhófà sí Jerúsálẹ́mù,+ wọn kò ní ya alágídí, wọn kò sì ní ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ fún wọn mọ́.”

18 “Ní àkókò yẹn, ilé Júdà àti ilé Ísírẹ́lì yóò rìn pa pọ̀,+ wọ́n á sì jọ wá láti ilẹ̀ àríwá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín láti jogún.+ 19 Mo sọ lọ́kàn mi pé, ‘Wo bí mo ṣe fi ọ́ sáàárín àwọn ọmọ tí mo sì fún ọ ní ilẹ̀ tó dára, ogún tó rẹwà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè!’*+ Mo tún sọ lọ́kàn mi pé, ẹ ó pè mí ní, ‘Bàbá mi!’ ẹ kò sì ní pa dà lẹ́yìn mi. 20 ‘Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí aya tó hùwà àìṣòótọ́, tó sì kúrò lọ́dọ̀ ọkọ* rẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin ilé Ísírẹ́lì ṣe hùwà àìṣòótọ́ sí mi,’+ ni Jèhófà wí.”

21 A gbọ́ ìró kan lórí àwọn òkè kéékèèké,

Ẹkún àti àrọwà àwọn èèyàn Ísírẹ́lì,

Nítorí wọ́n lọ́ ọ̀nà wọn po;

Wọ́n ti gbàgbé Jèhófà Ọlọ́run wọn.+

22 “Ẹ pa dà, ẹ̀yin ọ̀dàlẹ̀ ọmọ.

Màá wo ọkàn ọ̀dàlẹ̀ yín sàn.”+

“Àwa nìyí! A ti wá sọ́dọ̀ rẹ,

Torí ìwọ, Jèhófà, ni Ọlọ́run wa.+

23 Lóòótọ́, àwọn òkè kéékèèké àti rúkèrúdò tó wà lórí àwọn òkè ńlá jẹ́ ẹ̀tàn.+

Àmọ́, ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa ni ìgbàlà Ísírẹ́lì wà.+

24 Látìgbà èwe wa ni ohun ìtìjú* ti gba gbogbo èrè iṣẹ́ àṣekára àwọn baba ńlá wa,+

Ó gba agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran wọn,

Àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn.

25 Ẹ jẹ́ ká dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa,

Kí ìtìjú wa sì bò wá mọ́lẹ̀,

Nítorí a ti dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run wa,+

Àwa àti àwọn bàbá wa látìgbà èwe wa títí di òní yìí,+

A kò sì ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run wa.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́