ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Oníwàásù 9
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Oníwàásù

      • Ohun kan náà ló ń gbẹ̀yìn gbogbo wọn (1-3)

      • Gbádùn ayé rẹ bí ikú tiẹ̀ máa dé (4-12)

        • Àwọn òkú ò mọ nǹkan kan (5)

        • Èèyàn ò lè ṣe nǹkan kan nínú Isà Òkú (10)

        • Ìgbà àti èèṣì (11)

      • Kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn èèyàn máa ń mọyì ọgbọ́n (13-18)

Oníwàásù 9:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 33:3; 1Sa 2:9; Sm 37:5

Oníwàásù 9:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Àtúbọ̀tán kan náà ló wà fún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 5:15
  • +Onw 8:10

Oníwàásù 9:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

  • *

    Tàbí “àtúbọ̀tán.”

  • *

    Ní Héb., “lẹ́yìn náà, ọ̀dọ̀ àwọn òkú yá!”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 3:17-19; Onw 2:15

Oníwàásù 9:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 38:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jí!,

    11/2014, ojú ìwé 6

    7/8/1998, ojú ìwé 31

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    4/1/1993, ojú ìwé 29

    5/15/1991, ojú ìwé 31

Oníwàásù 9:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mọ̀ dáadáa.”

  • *

    Tàbí “owó iṣẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 3:19; Ro 5:12
  • +Sm 88:10; 115:17; 146:4; Ais 38:18; Jo 11:11
  • +Job 7:9, 10; Onw 2:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 29

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2005, ojú ìwé 3

    2/15/1997, ojú ìwé 16

    6/1/1995, ojú ìwé 6-7

    5/15/1995, ojú ìwé 5

    Jí!,

    7/8/1998, ojú ìwé 31

Oníwàásù 9:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 9:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/1/1995, ojú ìwé 6-7

Oníwàásù 9:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:7; Sm 104:15; Onw 2:24
  • +Di 16:15; Iṣe 14:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/1997, ojú ìwé 17

Oníwàásù 9:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, aṣọ tí àwọ̀ rẹ̀ ń tàn tó fi hàn pé inú èèyàn ń dùn, kì í ṣe aṣọ ọ̀fọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 10:2, 3

Oníwàásù 9:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 5:18
  • +Onw 5:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/15/2006, ojú ìwé 27-28

Oníwàásù 9:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 115:17; 146:3, 4; Ais 38:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 29

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2006, ojú ìwé 5

Oníwàásù 9:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

  • *

    Tàbí “ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 17:50; Sm 33:16
  • +Onw 2:15
  • +2Sa 17:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2021 ojú ìwé 8

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    2/2017, ojú ìwé 29

    Jí!,

    No. 3 2017 ojú ìwé 6

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/2009, ojú ìwé 4-5

    9/15/2007, ojú ìwé 5

    9/1/2003, ojú ìwé 9-10

    10/15/2001, ojú ìwé 13-14

    8/15/1998, ojú ìwé 15-16

    9/15/1992, ojú ìwé 5

    10/15/1991, ojú ìwé 5

Oníwàásù 9:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 8:8; Jem 4:13, 14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2005, ojú ìwé 3-4

Oníwàásù 9:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “lábẹ́ oòrùn.”

Oníwàásù 9:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Onw 9:11

Oníwàásù 9:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 21:22; 24:5; Onw 7:12, 19; 9:18
  • +Mk 6:3; 1Kọ 2:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2000, ojú ìwé 32

Oníwàásù 9:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 22:20; 1Kọ 5:6; Heb 12:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 3 2021 ojú ìwé 11

Àwọn míì

Oníw. 9:1Di 33:3; 1Sa 2:9; Sm 37:5
Oníw. 9:2Onw 5:15
Oníw. 9:2Onw 8:10
Oníw. 9:3Job 3:17-19; Onw 2:15
Oníw. 9:4Ais 38:19
Oníw. 9:5Jẹ 3:19; Ro 5:12
Oníw. 9:5Sm 88:10; 115:17; 146:4; Ais 38:18; Jo 11:11
Oníw. 9:5Job 7:9, 10; Onw 2:16
Oníw. 9:6Onw 9:10
Oníw. 9:7Di 12:7; Sm 104:15; Onw 2:24
Oníw. 9:7Di 16:15; Iṣe 14:17
Oníw. 9:8Da 10:2, 3
Oníw. 9:9Owe 5:18
Oníw. 9:9Onw 5:18
Oníw. 9:10Sm 115:17; 146:3, 4; Ais 38:18
Oníw. 9:111Sa 17:50; Sm 33:16
Oníw. 9:11Onw 2:15
Oníw. 9:112Sa 17:23
Oníw. 9:12Onw 8:8; Jem 4:13, 14
Oníw. 9:15Onw 9:11
Oníw. 9:16Owe 21:22; 24:5; Onw 7:12, 19; 9:18
Oníw. 9:16Mk 6:3; 1Kọ 2:8
Oníw. 9:18Joṣ 22:20; 1Kọ 5:6; Heb 12:15
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Oníwàásù 9:1-18

Oníwàásù

9 Nítorí náà, mo fọkàn sí gbogbo èyí, mo sì gbà pé ọwọ́ Ọlọ́run tòótọ́ ni àwọn olódodo àti àwọn ọlọ́gbọ́n wà pẹ̀lú iṣẹ́ wọn.+ Àwọn èèyàn kò mọ ìfẹ́ àti ìkórìíra tó ti wà ṣáájú wọn. 2 Ohun kan náà ló ń gbẹ̀yìn* gbogbo wọn,+ àti olódodo àti ẹni burúkú,+ ẹni rere pẹ̀lú ẹni tó mọ́ àti ẹni tí ò mọ́, àwọn tó ń rúbọ àti àwọn tí kì í rúbọ. Ìkan náà ni ẹni rere àti ẹlẹ́ṣẹ̀; bákan náà ni ẹni tó búra rí pẹ̀lú ẹni tó ń bẹ̀rù láti búra. 3 Ohun kan ń ṣẹlẹ̀ lábẹ́ ọ̀run* tó ń kó ìdààmú báni: Nítorí ohun* kan náà ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn,+ aburú ló kún ọkàn àwọn ọmọ èèyàn; ìwà wèrè wà lọ́kàn wọn ní ọjọ́ ayé wọn, lẹ́yìn náà wọ́n á kú!*

4 Ìrètí wà fún ẹni tó bá ṣì wà láàyè, nítorí ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ.+ 5 Nítorí àwọn alààyè mọ̀* pé àwọn máa kú,+ àmọ́ àwọn òkú kò mọ nǹkan kan rárá,+ wọn kò sì ní èrè* kankan mọ́, nítorí pé wọ́n ti di ẹni ìgbàgbé.+ 6 Bákan náà, ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn pẹ̀lú owú wọn ti ṣègbé, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ nínú ohun tí à ń ṣe lábẹ́ ọ̀run.*+

7 Máa lọ, máa fi ayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, kí o sì máa fi ìdùnnú mu wáìnì rẹ,+ nítorí inú Ọlọ́run tòótọ́ ti dùn sí àwọn iṣẹ́ rẹ.+ 8 Kí aṣọ rẹ máa funfun* ní gbogbo ìgbà, kí o sì máa fi òróró pa orí rẹ.+ 9 Máa gbádùn ayé rẹ pẹ̀lú aya rẹ ọ̀wọ́n+ ní gbogbo ọjọ́ ayé asán rẹ, tí Ó fún ọ lábẹ́ ọ̀run,* ní gbogbo ọjọ́ ayé asán rẹ, torí ìyẹn ni ìpín rẹ nígbèésí ayé àti nínú iṣẹ́ àṣekára rẹ, èyí tí ò ń fi gbogbo agbára rẹ ṣe lábẹ́ ọ̀run.+ 10 Ohunkóhun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí èrò tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n nínú Isà Òkú,*+ ibi tí ìwọ ń lọ.

11 Mo tún ti rí nǹkan míì lábẹ́ ọ̀run,* pé ìgbà gbogbo kọ́ ni ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ yá máa ń mókè nínú eré ìje, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe gbogbo ìgbà ni àwọn alágbára máa ń borí lójú ogun,+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọlọ́gbọ́n kì í fìgbà gbogbo rí oúnjẹ jẹ, ìgbà gbogbo kọ́ sì ni àwọn olórí pípé máa ń ní ọrọ̀,+ bákan náà àwọn tó ní ìmọ̀ kì í fìgbà gbogbo ṣe àṣeyọrí,+ nítorí ìgbà àti èèṣì* ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn. 12 Èèyàn kò mọ ìgbà tirẹ̀.+ Bí ẹja ṣe ń kó sínú àwọ̀n ikú, tí àwọn ẹyẹ sì ń kó sínú pańpẹ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ èèyàn ṣe ń kó sínú ìdẹkùn ní àkókò àjálù, nígbà tó bá dé bá wọn lójijì.

13 Mo tún kíyè sí nǹkan kan nípa ọgbọ́n lábẹ́ ọ̀run,* ó sì wú mi lórí: 14 Ìlú kékeré kan wà tí èèyàn ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ sí; ọba alágbára kan wá gbéjà kò ó, ó yí i ká, ó sì ṣe àwọn nǹkan ńlá tí á fi gbógun ti ìlú náà. 15 Ọkùnrin kan wà níbẹ̀ tó jẹ́ aláìní àmọ́ tó ní ọgbọ́n, ó sì fi ọgbọ́n rẹ̀ gba ìlú náà sílẹ̀. Àmọ́ kò sẹ́ni tó rántí ọkùnrin aláìní náà.+ 16 Mo wá sọ fún ara mi pé: ‘Ọgbọ́n sàn ju agbára lọ;+ síbẹ̀ àwọn èèyàn kì í ka ọgbọ́n aláìní sí, wọn kì í sì í ṣe ohun tó bá sọ.’+

17 Ó sàn kéèyàn tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ tí ọlọ́gbọ́n sọ ju kéèyàn máa fetí sí ariwo ẹni tó ń ṣàkóso láàárín àwọn òmùgọ̀.

18 Ọgbọ́n sàn ju àwọn ohun ìjà ogun lọ, àmọ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ṣoṣo lè ba ọ̀pọ̀ ohun rere jẹ́.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́