ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 135
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sáàmù

      • Ẹ yin Jáà nítorí ó tóbi

        • Iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu lórí Íjíbítì (8, 9)

        • “Orúkọ rẹ wà títí láé” (13)

        • Òrìṣà aláìlẹ́mìí (15-18)

Sáàmù 135:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Halelúyà!” “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 113:1; Ifi 19:5

Sáàmù 135:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 96:8; 116:19

Sáàmù 135:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kọrin.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 119:68; Mt 19:17

Sáàmù 135:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ohun ìní rẹ̀ tó ṣeyebíye.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5; Di 7:6

Sáàmù 135:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:17; Sm 97:9

Sáàmù 135:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 115:3; Ais 46:10

Sáàmù 135:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “oruku.”

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ọ̀ṣọ̀ọ̀rọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 14:21; Nọ 11:31; Jer 10:13; 51:16; Jon 1:4

Sáàmù 135:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 12:12, 29

Sáàmù 135:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 7:20; 8:6, 17; 9:6, 10, 23; 10:12, 21
  • +Sm 136:15

Sáàmù 135:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 44:2
  • +Joṣ 12:7, 8

Sáàmù 135:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 21:23, 24
  • +Nọ 21:33-35

Sáàmù 135:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 11:23

Sáàmù 135:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “orúkọ rẹ yóò wà.” Ní Héb., “ìrántí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:15; Sm 102:12

Sáàmù 135:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gba ẹjọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ rò.”

  • *

    Tàbí “kẹ́dùn nítorí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 14:31
  • +Di 32:36

Sáàmù 135:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 115:4-8; Ais 46:6; Iṣe 17:29; 1Kọ 10:19

Sáàmù 135:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Hab 2:19

Sáàmù 135:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 10:14

Sáàmù 135:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 44:9
  • +Sm 97:7

Sáàmù 135:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 10:8

Sáàmù 135:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 48:1; 132:13
  • +Jer 3:17
  • +Ifi 19:6

Àwọn míì

Sm 135:1Sm 113:1; Ifi 19:5
Sm 135:2Sm 96:8; 116:19
Sm 135:3Sm 119:68; Mt 19:17
Sm 135:4Ẹk 19:5; Di 7:6
Sm 135:5Di 10:17; Sm 97:9
Sm 135:6Sm 115:3; Ais 46:10
Sm 135:7Ẹk 14:21; Nọ 11:31; Jer 10:13; 51:16; Jon 1:4
Sm 135:8Ẹk 12:12, 29
Sm 135:9Ẹk 7:20; 8:6, 17; 9:6, 10, 23; 10:12, 21
Sm 135:9Sm 136:15
Sm 135:10Sm 44:2
Sm 135:10Joṣ 12:7, 8
Sm 135:11Nọ 21:23, 24
Sm 135:11Nọ 21:33-35
Sm 135:12Joṣ 11:23
Sm 135:13Ẹk 3:15; Sm 102:12
Sm 135:14Ẹk 14:31
Sm 135:14Di 32:36
Sm 135:15Sm 115:4-8; Ais 46:6; Iṣe 17:29; 1Kọ 10:19
Sm 135:16Hab 2:19
Sm 135:17Jer 10:14
Sm 135:18Ais 44:9
Sm 135:18Sm 97:7
Sm 135:20Di 10:8
Sm 135:21Sm 48:1; 132:13
Sm 135:21Jer 3:17
Sm 135:21Ifi 19:6
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sáàmù 135:1-21

Sáàmù

135 Ẹ yin Jáà!*

Ẹ yin orúkọ Jèhófà;

Ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà,+

2 Ẹ̀yin tó ń ṣiṣẹ́ nínú ilé Jèhófà,

Nínú àwọn àgbàlá ilé Ọlọ́run wa.+

3 Ẹ yin Jáà, nítorí Jèhófà jẹ́ ẹni rere.+

Ẹ kọ orin ìyìn* sí orúkọ rẹ̀, nítorí ó dára.

4 Jáà ti yan Jékọ́bù fún ara rẹ̀,

Ó ti yan Ísírẹ́lì ṣe ohun ìní rẹ̀ pàtàkì.*+

5 Mo mọ̀ dáadáa pé Jèhófà tóbi;

Olúwa wa ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ.+

6 Jèhófà ń ṣe gbogbo ohun tó bá fẹ́+

Ní ọ̀run àti ní ayé, nínú òkun àti nínú gbogbo ibú omi.

7 Ó ń mú kí ìkùukùu* ròkè láti ìkángun ayé;

Ó ń ṣe mànàmáná* fún òjò;

Ó ń mú ẹ̀fúùfù jáde látinú àwọn ilé ìṣúra rẹ̀.+

8 Ó pa àwọn àkọ́bí Íjíbítì,

Àti èèyàn àti ẹranko.+

9 Ó rán àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu sáàárín rẹ, ìwọ Íjíbítì,+

Sí Fáráò àti sí gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀.+

10 Ó pa ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè+ run,

Ó sì pa àwọn ọba alágbára+

11 —Síhónì ọba àwọn Ámórì,+

Ógù ọba Báṣánì+

Àti gbogbo àwọn ìjọba Kénáánì.

12 Ó fi ilẹ̀ wọn ṣe ogún,

Ó fi ṣe ogún fún Ísírẹ́lì, àwọn èèyàn rẹ̀.+

13 Jèhófà, orúkọ rẹ wà títí láé.

Jèhófà, òkìkí rẹ yóò máa kàn* láti ìran dé ìran.+

14 Nítorí Jèhófà yóò gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀,*+

Yóò sì ṣàánú* àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀.+

15 Àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè jẹ́ fàdákà àti wúrà,

Iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn.+

16 Wọ́n ní ẹnu, àmọ́ wọn ò lè sọ̀rọ̀;+

Wọ́n ní ojú, àmọ́ wọn ò lè ríran;

17 Wọ́n ní etí, àmọ́ wọn ò lè gbọ́ràn.

Kò sí èémí kankan ní ẹnu wọn.+

18 Àwọn tó ń ṣe wọ́n yóò dà bíi wọn gẹ́lẹ́,+

Bẹ́ẹ̀ ló sì ṣe máa rí fún gbogbo àwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé wọn.+

19 Ilé Ísírẹ́lì, ẹ yin Jèhófà.

Ilé Áárónì, ẹ yin Jèhófà.

20 Ilé Léfì, ẹ yin Jèhófà.+

Ẹ̀yin tí ẹ bẹ̀rù Jèhófà, ẹ yin Jèhófà.

21 Ìyìn ni fún Jèhófà láti Síónì,+

Ẹni tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù.+

Ẹ yin Jáà!+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́