ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 30
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Ìlérí ìpadàbọ̀sípò àti ìmúláradá (1-24)

Jeremáyà 30:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:3; Isk 39:25
  • +Ẹsr 2:1; Jer 29:14; 32:44; Isk 20:42; Emọ 9:14

Jeremáyà 30:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “abẹ́nú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:31; Mik 4:9

Jeremáyà 30:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ńlá.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 2:11; Sef 1:14

Jeremáyà 30:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ìdè.”

  • *

    Tàbí “ọmọ ilẹ̀ òkèèrè.”

  • *

    Tàbí “fi í.”

Jeremáyà 30:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 34:23; 37:24; Ho 3:5

Jeremáyà 30:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:13
  • +Ais 49:25; Jer 3:18
  • +Jer 33:16; Isk 34:25; Ho 2:18; Mik 4:4

Jeremáyà 30:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tọ́ ọ sọ́nà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 50:29; 51:24
  • +Le 26:44; Ne 9:31; Ida 3:22; Emọ 9:8
  • +Ẹk 34:6, 7; Jer 46:27, 28

Jeremáyà 30:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:15, 16; Ais 6:10; Jer 8:21, 22

Jeremáyà 30:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ida 1:2, 19
  • +Ida 2:5
  • +Jer 5:6

Jeremáyà 30:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:14

Jeremáyà 30:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:11; Jer 25:12
  • +Jer 51:29, 56; Mik 5:9
  • +Sek 2:8, 9

Jeremáyà 30:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 102:13; Jer 33:6, 7
  • +Ida 2:15

Jeremáyà 30:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 85:1; Jer 24:6; 29:10
  • +Mik 4:8

Jeremáyà 30:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “kí wọ́n ní iyì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹsr 3:12; Ne 8:17; Ais 35:10
  • +Di 30:5; Ais 27:6; Sek 10:8
  • +Ais 60:22; Mik 4:7

Jeremáyà 30:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:26
  • +Ais 49:26; Jer 50:18

Jeremáyà 30:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ta ló lè fi ọkàn rẹ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́.”

Jeremáyà 30:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 2:23
  • +Jer 31:1; Isk 11:20; 36:28

Jeremáyà 30:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 25:32

Jeremáyà 30:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 4:28
  • +Jer 23:20

Àwọn míì

Jer. 30:3Di 30:3; Isk 39:25
Jer. 30:3Ẹsr 2:1; Jer 29:14; 32:44; Isk 20:42; Emọ 9:14
Jer. 30:6Jer 4:31; Mik 4:9
Jer. 30:7Joẹ 2:11; Sef 1:14
Jer. 30:9Isk 34:23; 37:24; Ho 3:5
Jer. 30:10Ais 41:13
Jer. 30:10Ais 49:25; Jer 3:18
Jer. 30:10Jer 33:16; Isk 34:25; Ho 2:18; Mik 4:4
Jer. 30:11Jer 50:29; 51:24
Jer. 30:11Le 26:44; Ne 9:31; Ida 3:22; Emọ 9:8
Jer. 30:11Ẹk 34:6, 7; Jer 46:27, 28
Jer. 30:122Kr 36:15, 16; Ais 6:10; Jer 8:21, 22
Jer. 30:14Ida 1:2, 19
Jer. 30:14Ida 2:5
Jer. 30:14Jer 5:6
Jer. 30:152Kr 36:14
Jer. 30:16Ais 41:11; Jer 25:12
Jer. 30:16Jer 51:29, 56; Mik 5:9
Jer. 30:16Sek 2:8, 9
Jer. 30:17Sm 102:13; Jer 33:6, 7
Jer. 30:17Ida 2:15
Jer. 30:18Sm 85:1; Jer 24:6; 29:10
Jer. 30:18Mik 4:8
Jer. 30:19Ẹsr 3:12; Ne 8:17; Ais 35:10
Jer. 30:19Di 30:5; Ais 27:6; Sek 10:8
Jer. 30:19Ais 60:22; Mik 4:7
Jer. 30:20Ais 1:26
Jer. 30:20Ais 49:26; Jer 50:18
Jer. 30:22Ho 2:23
Jer. 30:22Jer 31:1; Isk 11:20; 36:28
Jer. 30:23Jer 25:32
Jer. 30:24Jer 4:28
Jer. 30:24Jer 23:20
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 30:1-24

Jeremáyà

30 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, ó ní: 2 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Kọ gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún ọ sínú ìwé kan. 3 Nítorí, “wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá kó àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì àti Júdà, tó wà lóko ẹrú jọ,”+ ni Jèhófà wí, “màá mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóò sì pa dà jẹ́ tiwọn.”’”+

4 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Ísírẹ́lì àti Júdà nìyí.

 5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“A ti gbọ́ ìró àwọn tí jìnnìjìnnì bá;

Ẹ̀rù ló wà, kò sí àlàáfíà.

 6 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ bá mi béèrè bóyá ọkùnrin lè bímọ.

Kí wá nìdí tí gbogbo ọ̀dọ́kùnrin tí mo rí fi ń fọwọ́ ti ikùn*

Bí obìnrin tó ń rọbí?+

Kí nìdí tí gbogbo ojú sì fi funfun?

 7 Ó mà ṣe o! Nítorí ọjọ́ burúkú* ni ọjọ́ yẹn máa jẹ́.+

Kò sí irú rẹ̀,

Àkókò wàhálà ni fún Jékọ́bù.

Ṣùgbọ́n a ó gbà á là.”

8 “Ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí, “màá ṣẹ́ àjàgà kúrò ní ọrùn wọn, màá sì já ọ̀já* wọn sí méjì; àwọn àjèjì* ò sì ní fi wọ́n* ṣe ẹrú mọ́. 9 Wọ́n á máa sin Jèhófà Ọlọ́run wọn àti Dáfídì ọba wọn, ẹni tí màá gbé dìde fún wọn.”+

10 “Ní tìrẹ, ìwọ Jékọ́bù ìránṣẹ́ mi, má fòyà,” ni Jèhófà wí,

“Má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà ọ́, ìwọ Ísírẹ́lì.+

Nítorí màá gbà ọ́ láti ibi tó jìnnà réré

Àti àwọn ọmọ rẹ láti oko ẹrú tí wọ́n wà.+

Jékọ́bù á pa dà, ara rẹ̀ á balẹ̀, kò ní rí ìyọlẹ́nu,

Ẹnì kankan ò sì ní dẹ́rù bà wọ́n.”+

11 “Nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ,” ni Jèhófà wí, “láti gbà ọ́.

Ṣùgbọ́n màá pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí mo tú ọ ká sí àárín wọn run;+

Àmọ́ ní tìrẹ, mi ò ní pa ọ́ run.+

Mi ò ní bá ọ wí* kọjá ààlà,

Mi ò sì ní ṣàìfi ìyà jẹ ọ́.”+

12 Nítorí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Kò sí ìwòsàn fún àárẹ̀ tó ń ṣe ọ́.+

Ọgbẹ́ rẹ kò ṣeé wò sàn.

13 Kò sí ẹni tó máa gba ẹjọ́ rẹ rò,

Egbò rẹ kò ṣeé wò sàn.

Kò sí ìwòsàn fún ọ.

14 Gbogbo àwọn olólùfẹ́ rẹ àtàtà ti gbàgbé rẹ.+

Wọn kò wá ọ mọ́.

Nítorí mo nà ọ́ bí ìgbà tí ọ̀tá ẹni bá nani,+

Pẹ̀lú ìyà tí ìkà èèyàn fi ń jẹni,

Nítorí o ti jẹ ẹ̀bi lé ẹ̀bi, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sì ti pọ̀.+

15 Kí nìdí tí o fi ń ké nítorí àárẹ̀ tó ń ṣe ọ́?

Ìrora rẹ kò ṣeé wò sàn!

Nítorí o ti jẹ ẹ̀bi lé ẹ̀bi, ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sì ti pọ̀+

Ni mo fi ṣe èyí sí ọ.

16 Nítorí náà, gbogbo àwọn tó ń pa àwọn èèyàn rẹ run ni a ó pa run,+

Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ á sì lọ sí oko ẹrú.+

Àwọn tó ń fi ogun kó ọ ni a ó fi ogun kó,

Àwọn tó ń kó ọ lẹ́rù ni màá sì jẹ́ kí wọ́n kó lẹ́rù lọ.”+

17 “Ṣùgbọ́n màá mú ọ lára dá, màá sì wo ọgbẹ́ rẹ sàn,”+ ni Jèhófà wí,

“Bí wọ́n tiẹ̀ pè ọ́ ní ẹni ìtanù:

‘Síónì, tí ẹnikẹ́ni kò fẹ́.’”+

18 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:

“Wò ó, màá kó àwọn tó lọ sí oko ẹrú láti àgọ́ Jékọ́bù jọ,+

Máa sì ṣojú àánú sí àwọn àgọ́ ìjọsìn rẹ̀.

Wọ́n á tún ìlú náà kọ́ sórí òkìtì rẹ̀,+

Ibi tó sì yẹ ni wọ́n á kọ́ ilé gogoro rẹ̀ tó láàbò sí.

19 Ìdúpẹ́ àti ohùn ẹ̀rín á ti ọ̀dọ̀ wọn wá.+

Màá sọ wọ́n di púpọ̀, wọn ò sì ní kéré níye;+

Màá mú kí wọ́n pọ̀ níye,*

Wọn ò sì ní jẹ́ ẹni yẹpẹrẹ.+

20 Àwọn ọmọ rẹ̀ á dà bíi ti ìgbà àtijọ́,

Àpéjọ rẹ̀ á sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in níwájú mi.+

Màá sì fìyà jẹ gbogbo àwọn tó ń ni ín lára.+

21 Láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni olórí rẹ̀ ti máa wá,

Láti àárín rẹ̀ sì ni alákòóso ti máa jáde wá.

Màá mú kí ó sún mọ́ tòsí, á sì wá bá mi.”

“Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ta ló tó bẹ́ẹ̀* láti wá bá mi?” ni Jèhófà wí.

22 “Ẹ ó di èèyàn mi,+ màá sì di Ọlọ́run yín.”+

23 Wò ó! Ìjì Jèhófà máa fi ìbínú tú jáde,+

Ìjì líle tó ń gbá nǹkan lọ, tó sì ń tú jáde sórí àwọn ẹni burúkú.

24 Ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná kò ní dáwọ́ dúró

Títí á fi ṣe ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀, tí á sì mú èrò rẹ̀ ṣẹ.+

Ní àkókò òpin, ọ̀rọ̀ yìí á yé yín.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́