ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Diutarónómì 17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Diutarónómì

      • Ẹbọ wọn kò gbọ́dọ̀ ní àbùkù lára (1)

      • Ohun tí wọ́n máa ṣe fún ẹni tó bá sin ọlọ́run míì (2-7)

      • Àwọn ẹjọ́ tó bá ṣòroó dá (8-13)

      • Ìlànà fún ọba tí wọ́n bá yàn (14-20)

        • Kí ọba fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ẹ̀dà Òfin (18)

Diutarónómì 17:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:20; Di 15:21; Mal 1:8

Diutarónómì 17:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:23; 13:6-9

Diutarónómì 17:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 4:19
  • +Di 13:12-15

Diutarónómì 17:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 7:51

Diutarónómì 17:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 13:6, 10

Diutarónómì 17:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fi ẹnu sí i.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 18:16; Jo 8:17; 1Ti 5:19; Heb 10:28
  • +Nọ 35:30; Di 19:15

Diutarónómì 17:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 13:5; 1Kọ 5:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 7/2021,

Diutarónómì 17:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 35:11
  • +Di 12:5; 1Ọb 3:16, 28; Sm 122:2, 5

Diutarónómì 17:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 7:15, 16
  • +Di 19:17; 21:5

Diutarónómì 17:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mal 2:7
  • +Di 5:32; 12:32

Diutarónómì 17:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Lédè Hébérù, ó tún túmọ̀ sí “ìgbójú” tàbí “ìkọjá àyè.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Owe 11:2; Heb 10:28
  • +Di 13:5; 1Kọ 5:13

Diutarónómì 17:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 13:11; 19:20

Diutarónómì 17:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 8:5, 20; 10:19

Diutarónómì 17:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 9:17; 10:24; 16:12, 13

Diutarónómì 17:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 20:1; 2Sa 8:4; Sm 20:7; Owe 21:31
  • +Ais 31:1

Diutarónómì 17:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 11:1-3; Ne 13:26
  • +Job 31:24, 28; 1Ti 6:9

Diutarónómì 17:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àkájọ ìwé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 31:9, 26; 2Ọb 22:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 20

    5/1/1995, ojú ìwé 12-13

Diutarónómì 17:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 34:18
  • +Sm 1:2; 119:97

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2002, ojú ìwé 12-17

    10/1/2000, ojú ìwé 8-9

    5/1/1995, ojú ìwé 12-13

Diutarónómì 17:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    5/1/1995, ojú ìwé 12-13

Àwọn míì

Diu. 17:1Le 22:20; Di 15:21; Mal 1:8
Diu. 17:2Di 4:23; 13:6-9
Diu. 17:3Di 4:19
Diu. 17:3Di 13:12-15
Diu. 17:4Jo 7:51
Diu. 17:5Di 13:6, 10
Diu. 17:6Mt 18:16; Jo 8:17; 1Ti 5:19; Heb 10:28
Diu. 17:6Nọ 35:30; Di 19:15
Diu. 17:7Di 13:5; 1Kọ 5:13
Diu. 17:8Nọ 35:11
Diu. 17:8Di 12:5; 1Ọb 3:16, 28; Sm 122:2, 5
Diu. 17:91Sa 7:15, 16
Diu. 17:9Di 19:17; 21:5
Diu. 17:11Mal 2:7
Diu. 17:11Di 5:32; 12:32
Diu. 17:12Owe 11:2; Heb 10:28
Diu. 17:12Di 13:5; 1Kọ 5:13
Diu. 17:13Di 13:11; 19:20
Diu. 17:141Sa 8:5, 20; 10:19
Diu. 17:151Sa 9:17; 10:24; 16:12, 13
Diu. 17:16Di 20:1; 2Sa 8:4; Sm 20:7; Owe 21:31
Diu. 17:16Ais 31:1
Diu. 17:171Ọb 11:1-3; Ne 13:26
Diu. 17:17Job 31:24, 28; 1Ti 6:9
Diu. 17:18Di 31:9, 26; 2Ọb 22:8
Diu. 17:192Kr 34:18
Diu. 17:19Sm 1:2; 119:97
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Diutarónómì 17:1-20

Diutarónómì

17 “O ò gbọ́dọ̀ fi akọ màlúù tàbí àgùntàn tó ní àbùkù lára tàbí tí ohunkóhun ṣe, rúbọ sí Jèhófà Ọlọ́run rẹ, torí pé ohun ìríra ló máa jẹ́ lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+

2 “Ká sọ pé ọkùnrin tàbí obìnrin kan wà láàárín rẹ, nínú èyíkéyìí lára àwọn ìlú rẹ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, tó ń ṣe ohun tó burú lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ, tó sì ń tẹ májẹ̀mú rẹ̀ lójú,+ 3 tó wá yà bàrá, tó sì lọ ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì, tó ń forí balẹ̀ fún wọn tàbí tó ń forí balẹ̀ fún oòrùn tàbí òṣùpá tàbí gbogbo ọmọ ogun ọ̀run,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ.+ 4 Tí wọ́n bá sọ fún ọ tàbí tí o gbọ́ nípa rẹ̀, kí o wádìí ọ̀rọ̀ náà dáadáa. Tó bá jẹ́ òótọ́ ni+ ohun ìríra yìí ṣẹlẹ̀ ní Ísírẹ́lì, 5 kí o mú ọkùnrin tàbí obìnrin tó ṣe ohun burúkú yìí jáde wá sí ẹnubodè ìlú, kí ẹ sì sọ ọkùnrin tàbí obìnrin náà ní òkúta pa.+ 6 Ẹni méjì tàbí mẹ́ta ni kó jẹ́rìí sí i,*+ kí ẹ tó pa ẹni tí ikú tọ́ sí. Ẹ ò gbọ́dọ̀ pa á tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ló jẹ́rìí sí i.+ 7 Ọwọ́ àwọn ẹlẹ́rìí náà ni kó kọ́kọ́ bà á tí wọ́n bá fẹ́ pa á, lẹ́yìn náà kí gbogbo èèyàn dáwọ́ jọ láti pa á. Kí o mú ohun tó burú kúrò láàárín rẹ.+

8 “Tí ohun kan bá ṣẹlẹ̀ ní ọ̀kan lára àwọn ìlú rẹ, tí ẹjọ́ náà sì ṣòroó dá, bóyá ọ̀rọ̀ nípa ìtàjẹ̀sílẹ̀+ tàbí ẹnì kan fẹ́ gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ tàbí àwọn kan hùwà ipá tàbí àwọn ẹjọ́ míì tó jẹ mọ́ fífa ọ̀rọ̀, kí o gbéra, kí o sì lọ sí ibi tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ yàn.+ 9 Lọ bá àwọn àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì àti adájọ́+ tó ń gbẹ́jọ́ nígbà yẹn, kí o ro ẹjọ́ náà fún wọn, wọ́n á sì bá ọ dá a.+ 10 Ìdájọ́ tí wọ́n bá ṣe ní ibi tí Jèhófà yàn ni kí o tẹ̀ lé. Kí o rí i pé o ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá sọ fún ọ. 11 Kí o tẹ̀ lé òfin tí wọ́n bá fi hàn ọ́, kí o sì tẹ̀ lé ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fún ọ.+ O ò gbọ́dọ̀ yà kúrò lórí ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fún ọ, ì báà jẹ́ sí ọ̀tún tàbí sí òsì.+ 12 Ṣe ni kí ẹ pa ẹni tó bá ṣorí kunkun,* tó kọ̀ láti fetí sí àlùfáà tó ń bá Jèhófà Ọlọ́run rẹ ṣiṣẹ́ tàbí sí adájọ́ náà.+ Kí o mú ohun tó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.+ 13 Gbogbo èèyàn á wá gbọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n, wọn ò sì ní ṣorí kunkun mọ́.+

14 “Tí o bá dé ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ, tí o gbà á, tí o ti ń gbé ibẹ̀, tí o wá sọ pé, ‘Jẹ́ kí n yan ọba lé ara mi lórí, bíi ti àwọn orílẹ̀-èdè tó yí mi ká,’+ 15 nígbà náà, kí o rí i dájú pé ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá yàn ni kí o fi jọba.+ Àárín àwọn arákùnrin rẹ ni kí o ti yan ẹni tó máa jọba. O ò gbọ́dọ̀ yan àjèjì, ẹni tí kì í ṣe arákùnrin rẹ ṣe olórí rẹ. 16 Àmọ́, kò gbọ́dọ̀ kó ẹṣin rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ ní kí àwọn èèyàn náà pa dà lọ sí Íjíbítì láti lọ kó ẹṣin sí i wá,+ torí Jèhófà ti sọ fún yín pé, ‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ tún forí lé ọ̀nà yìí mọ́.’ 17 Kò sì gbọ́dọ̀ kó ìyàwó rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀, kí ọkàn rẹ̀ má bàa yí pa dà;+ bẹ́ẹ̀ ni kò gbọ́dọ̀ kó fàdákà àti wúrà rẹpẹtẹ jọ fún ara rẹ̀.+ 18 Tó bá ti jókòó sórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kó fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ẹ̀dà Òfin yìí sínú ìwé* kan, látinú èyí tí àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà tọ́jú.+

19 “Ọwọ́ rẹ̀ ni kó máa wà, kó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,+ kó lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kó sì máa tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ inú Òfin yìí àti àwọn ìlànà yìí, kí o máa pa wọ́n mọ́.+ 20 Èyí ò ní jẹ́ kó gbé ọkàn rẹ̀ ga lórí àwọn arákùnrin rẹ̀, kò sì ní jẹ́ kó yà kúrò nínú àṣẹ náà, ì báà jẹ́ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kó lè pẹ́ lórí oyè, òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ láàárín Ísírẹ́lì.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́