ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Gálátíà 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Gálátíà

      • Ìkíni (1-5)

      • Kò sí ìhìn rere míì (6-9)

      • Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìhìn rere tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù ti wá (10-12)

      • Bí Pọ́ọ̀lù ṣe yí pa dà àti àwọn ohun tó kọ́kọ́ ṣe (13-24)

Gálátíà 1:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 9:15; 26:15, 16
  • +Iṣe 22:14, 15

Gálátíà 1:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àsìkò.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Jo 2:1, 2
  • +Jo 15:19
  • +1Ti 2:3, 4

Gálátíà 1:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “a ti sáré mú yín kúrò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kọ 11:3, 4; Ga 5:7

Gálátíà 1:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ga 5:10

Gálátíà 1:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Tẹ 2:13

Gálátíà 1:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “tó dé ìwọ̀n tó pọ̀ lápọ̀jù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 23:6
  • +Iṣe 8:3; 9:1, 2; 22:4; 26:9-11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/1999, ojú ìwé 29-31

Gálátíà 1:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 22:3; Flp 3:4-6

Gálátíà 1:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kọ 15:10

Gálátíà 1:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 9:15; Ro 11:13

Gálátíà 1:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 9:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2008, ojú ìwé 22

    1/15/2005, ojú ìwé 28-29

Gálátíà 1:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wọ́n tún ń pè é ní Pétérù.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 9:26
  • +Jo 1:42; 1Kọ 15:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 12

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2007, ojú ìwé 15-17

Gálátíà 1:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 13:55; Iṣe 12:17

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jíjẹ́rìí Kúnnákúnná, ojú ìwé 112

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2007, ojú ìwé 16-17

Gálátíà 1:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 9:29, 30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/15/2000, ojú ìwé 26

Gálátíà 1:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Grk., “ìgbàgbọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ga 1:13
  • +Iṣe 8:3

Àwọn míì

Gál. 1:1Iṣe 9:15; 26:15, 16
Gál. 1:1Iṣe 22:14, 15
Gál. 1:41Jo 2:1, 2
Gál. 1:4Jo 15:19
Gál. 1:41Ti 2:3, 4
Gál. 1:62Kọ 11:3, 4; Ga 5:7
Gál. 1:7Ga 5:10
Gál. 1:111Tẹ 2:13
Gál. 1:13Iṣe 23:6
Gál. 1:13Iṣe 8:3; 9:1, 2; 22:4; 26:9-11
Gál. 1:14Iṣe 22:3; Flp 3:4-6
Gál. 1:151Kọ 15:10
Gál. 1:16Iṣe 9:15; Ro 11:13
Gál. 1:17Iṣe 9:19
Gál. 1:18Iṣe 9:26
Gál. 1:18Jo 1:42; 1Kọ 15:5
Gál. 1:19Mt 13:55; Iṣe 12:17
Gál. 1:21Iṣe 9:29, 30
Gál. 1:23Ga 1:13
Gál. 1:23Iṣe 8:3
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Gálátíà 1:1-24

Sí Àwọn Ará Gálátíà

1 Pọ́ọ̀lù, àpọ́sítélì, tí kì í ṣe látọwọ́ àwọn èèyàn tàbí nípasẹ̀ èèyàn kan, bí kò ṣe nípasẹ̀ Jésù Kristi+ àti Ọlọ́run tó jẹ́ Baba,+ ẹni tó gbé e dìde kúrò nínú ikú 2 àti gbogbo àwọn ará tó wà pẹ̀lú mi, sí àwọn ìjọ tó wà ní Gálátíà:

3 Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Baba wa àti Jésù Kristi Olúwa wà pẹ̀lú yín. 4 Ó fi ara rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa,+ kó lè gbà wá sílẹ̀ nínú ètò àwọn nǹkan* búburú ìsinsìnyí,+ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa,+ 5 ẹni tí ògo jẹ́ tirẹ̀ títí láé àti láéláé. Àmín.

6 Ó yà mí lẹ́nu pé ẹ ti sáré yà kúrò* lọ́dọ̀ Ẹni tó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Kristi pè yín, ẹ sì ń lọ sínú oríṣi ìhìn rere míì.+ 7 Kì í kúkú ṣe pé ìhìn rere míì wà; àmọ́ àwọn kan wà tó ń dá wàhálà sílẹ̀ fún yín,+ tí wọ́n sì fẹ́ yí ìhìn rere nípa Kristi po. 8 Àmọ́ ṣá o, bí àwa tàbí áńgẹ́lì kan láti ọ̀run bá kéde ohun kan fún yín pé ó jẹ́ ìhìn rere, àmọ́ tó yàtọ̀ sí ìhìn rere tí a ti kéde fún yín, kí ó di ẹni ègún. 9 Bí a ṣe sọ ṣáájú, mo tún ń sọ ọ́ báyìí pé, Ẹnikẹ́ni tí ì báà jẹ́ tó bá ń kéde ohun kan fún yín pé ó jẹ́ ìhìn rere, àmọ́ tó yàtọ̀ sí ìhìn rere tí ẹ ti gbà, kí ó di ẹni ègún.

10 Ṣé ojú rere èèyàn ni mò ń wá báyìí ni àbí ti Ọlọ́run? Àbí ìfẹ́ èèyàn ni mo fẹ́ ṣe? Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ èèyàn ni mo ṣì ń ṣe, á jẹ́ pé èmi kì í ṣe ẹrú Kristi. 11 Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ìhìn rere tí mo kéde fún yín kì í ṣe látọ̀dọ̀ èèyàn;+ 12 nítorí mi ò gbà á lọ́wọ́ èèyàn, bẹ́ẹ̀ ni a ò fi kọ́ mi, àmọ́ ó jẹ́ nípasẹ̀ ìfihàn látọwọ́ Jésù Kristi.

13 Ẹ ti gbọ́ nípa ìwà mi tẹ́lẹ̀ nínú Ìsìn Àwọn Júù,+ pé mò ń ṣe inúnibíni tó gbóná* sí ìjọ Ọlọ́run, mo sì ń dà á rú;+ 14 mò ń tẹ̀ síwájú nínú Ìsìn Àwọn Júù ju ọ̀pọ̀ nínú àwọn tí a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ lórílẹ̀-èdè mi, torí mo ní ìtara púpọ̀ fún àṣà àwọn baba mi.+ 15 Àmọ́ nígbà tí Ọlọ́run, ẹni tó yọ mí nínú ikùn ìyá mi, tó sì pè mí nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀,+ rí i pé ó dára 16 láti ṣí Ọmọ rẹ̀ payá nípasẹ̀ mi, kí n lè kéde ìhìn rere nípa rẹ̀ fún àwọn orílẹ̀-èdè,+ mi ò lọ fọ̀rọ̀ lọ ẹnikẹ́ni* lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀; 17 bẹ́ẹ̀ ni mi ò lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọ̀ àwọn tó jẹ́ àpọ́sítélì ṣáájú mi, àmọ́ mo lọ sí Arébíà, lẹ́yìn náà, mo pa dà sí Damásíkù.+

18 Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, mo lọ sí Jerúsálẹ́mù+ lọ́dọ̀ Kéfà,*+ mo sì lo ọjọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) lọ́dọ̀ rẹ̀. 19 Àmọ́ mi ò rí ìkankan nínú àwọn àpọ́sítélì yòókù, àfi Jémíìsì+ àbúrò Olúwa. 20 Ní ti àwọn ohun tí mò ń kọ sí yín, mo fi dá yín lójú níwájú Ọlọ́run pé mi ò parọ́.

21 Lẹ́yìn ìyẹn, mo lọ sí agbègbè Síríà àti ti Sìlíṣíà.+ 22 Àmọ́ àwọn ìjọ Jùdíà tó wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú Kristi kò dá mi mọ̀. 23 Wọ́n kàn máa ń gbọ́ pé: “Ọkùnrin tó ń ṣe inúnibíni sí wa tẹ́lẹ̀+ ti ń kéde ìhìn rere nípa ẹ̀sìn* tí òun fúnra rẹ̀ ń gbógun tì tẹ́lẹ̀.”+ 24 Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í yin Ọlọ́run lógo nítorí mi.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́