ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w07 12/15 ojú ìwé 11-15
  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ọjọ́ Jèhófà?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ọjọ́ Jèhófà?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Múra Sílẹ̀
  • Àwọn Ìyípadà Wo Ló Yẹ Kó O Ṣe?
  • Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíì
  • Má Ṣe Jẹ́ Apá Kan Ayé
  • Ronú Nípa Ohun Tó Máa Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ọjọ́ Jèhófà
  • Ọjọ́ Jèhófà—Ẹṣin Ọ̀rọ̀ Pàtàkì
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Ìwọ Ha Wà ní Sẹpẹ́ De Ọjọ́ Jèhófà Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Dúró Sọ́dọ̀ Jèhófà
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ẹ Wà Ní Ìmúratán De Ọjọ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
w07 12/15 ojú ìwé 11-15

Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Ọjọ́ Jèhófà?

“Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé. Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” —SEFANÁYÀ 1:14.

1-3. (a) Kí ni Bíbélì sọ nípa ọjọ́ Jèhófà? (b) “Ọjọ́ Jèhófà” wo ló ń bọ̀ lọ́nà?

ỌJỌ́ ńlá Jèhófà kì í ṣe ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún. Ó jẹ́ àkókò gígùn kan tí Ọlọ́run máa fi ṣèdájọ́ àwọn ẹni ibi. Àwọn tí kò sin Ọlọ́run ní láti máa bẹ̀rù ọjọ́ yẹn nítorí ó jẹ́ ọjọ́ òkùnkùn àti ìbínú kíkan, ọjọ́ ìbínú jíjófòfò, ọjọ́ wàhálà àti ìsọdahoro. (Aísáyà 13:9; Ámósì 5:18-20; Sefanáyà 1:15) Wòlíì Jóẹ́lì sàsọtẹ́lẹ̀ pé: “Págà fún ọjọ́ náà; nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé, yóò sì dé gẹ́gẹ́ bí ìfiṣèjẹ láti ọ̀dọ̀ Ẹni tí í ṣe Olódùmarè!” (Jóẹ́lì 1:15) Bó ti wù kó rí, Ọlọ́run máa jẹ́ Olùgbàlà fáwọn “adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà” ní ọjọ́ ńlá yẹn.—Sáàmù 7:10.

2 Gbólóhùn náà “ọjọ́ Jèhófà” túmọ̀ sí àwọn ìdájọ́ Ọlọ́run lórí àwọn ẹni ibi láwọn ìgbà tó yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, “ọjọ́ Jèhófà” dé sórí àwọn ará Jerúsálẹ́mù nígbà tó lo àwọn ará Bábílónì láti ṣèdájọ́ wọn lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. (Sefanáyà 1: 4-7) Irú ìdájọ́ yìí tún wáyé lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni nígbà tí Ọlọ́run lo àwọn ará Róòmù láti ṣèdájọ́ orílẹ̀-èdè Júù tó kọ Ọmọ rẹ̀ sílẹ̀. (Dáníẹ́lì 9:24-27; Jòhánù 19:15) Bíbélì tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa “ọjọ́ Jèhófà” tó ń bọ̀ nígbà tí Jèhófà yóò ‘bá gbogbo orílẹ̀-èdè jagun.’ (Sekaráyà 14:1-3) Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti sọ pé ọjọ́ Jèhófà so pọ̀ mọ́ wíwàníhìn-ín Kristi, èyí tó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Jésù jọba lọ́run lọ́dún 1914. (2 Tẹsalóníkà 2:1, 2) Bí gbogbo ẹ̀rí ti fi hàn pé ọjọ́ Jèhófà ń yára sún mọ́lé, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2007 fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bọ́ sákòókò gan-an ni. Ó wà nínú ìwé Sefanáyà 1:14, ó kà pé: “Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé.”

3 Níwọ̀n bí ọjọ́ ńlá Ọlọ́run ti sún mọ́lé, ìsinsìnyí gan-an ló yẹ ká múra sílẹ̀. Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ náà? Àwọn nǹkan míì wo ló yẹ kó o ṣe láti múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà?

Múra Sílẹ̀

4. Àdánwò ńlá wo ni Jésù múra sílẹ̀ fún?

4 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tí Jésù Kristi sọ nípa ìparí ètò àwọn nǹkan, ó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ wà ní ìmúratán.” (Mátíù 24:44) Nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ yìí, òun pàápàá ti múra sílẹ̀ fún àdánwò ńlá kan, ìyẹn ikú rẹ̀ tí yóò fi ṣe ẹbọ ìràpadà. (Mátíù 20:28) Kí la lè rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jésù gbà múra sílẹ̀?

5, 6. (a) Báwo ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà ní ìmúrasílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà? (b) Àpẹẹrẹ wo ni Jésù fi lélẹ̀ fún wa nípa bá a ṣe lè nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn?

5 Jésù nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn ìlànà òdodo Rẹ̀ tọkàntọkàn. Hébérù 1:9 sọ nípa Jésù pé: “Ìwọ nífẹ̀ẹ́ òdodo, o sì kórìíra ìwà àìlófin. Ìdí nìyẹn tí Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ, fi fòróró ayọ̀ ńláǹlà yàn ọ́ ju àwọn alájọṣe rẹ.” Jésù jẹ́ olóòótọ́ sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Táwa náà bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bíi ti Jésù tá a sì ń ṣe àwọn ohun tó ní ká ṣe, yóò dáàbò bò wá. (Sáàmù 31:23) Irú ìfẹ́ àti ìgbọ́ràn yìí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ de ọjọ́ ńlá Jèhófà.

6 Ànímọ́ tó tayọ jù lọ lára àwọn ànímọ́ tí Jésù ní ni ìfẹ́ tó ní sáwọn èèyàn. Kódà, “àánú wọn ṣe é, nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:36) Ìyẹn ló mú kí Jésù wàású ìhìn rere fáwọn èèyàn, bí ìfẹ́ ṣe ń mú káwa náà máa kéde Ìjọba Ọlọ́run fáwọn aládùúgbò wa. Torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn èèyàn la ṣe ń ṣiṣẹ́ òjíṣẹ wa tọkàntọkàn, ìyẹn sì ń jẹ́ ká wà ní ìmúrasílẹ̀ de ọjọ́ ńlá Jèhófà.—Mátíù 22:37-39.

7. Bá a ti ń dúró de ọjọ́ Jèhófà, kí ló lè máa múnú wa dùn?

7 Inú Jésù dùn láti ṣe ìfẹ́ Jèhófà. (Sáàmù 40:8) Táwa pẹ̀lú bá ní irú èrò tí Jésù ní, inú wa yóò máa dùn láti ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run. Bá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ bí Jésù ti ṣe, ìyẹn á jẹ́ ká máa ní ojúlówó ayọ̀. (Ìṣe 20:35) Bẹ́ẹ̀ ni, “ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára [wa].” Ìdùnnú yìí ló máa jẹ́ ká túbọ̀ lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ ńlá Ọlọ́run.—Nehemáyà 8:10.

8. Kí nìdí tó fi yẹ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà?

8 Àdúrà tí Jésù gbà sí Ọlọ́run tọkàntọkàn ràn án lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún àwọn ohun tó máa dán ìgbàgbọ́ rẹ̀ wò. Ó gbàdúrà nígbà tí Jòhánù ṣèrìbọmi fún un. Ó tún fi gbogbo òru gbàdúrà kó tó yan àwọn àpọ́sítélì rẹ̀. (Lúùkù 6:12-16) Ta ló máa ka àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa àdúrà tí Jésù gbà tọkàntọkàn lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ ikú rẹ̀ tórí rẹ̀ ò ní wú? (Máàkù 14:32-42; Jòhánù 17:1-26) Ṣé ìwọ náà máa ń gbàdúrà dáadáa bíi ti Jésù? Máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo, máa fara balẹ̀ gba àwọn àdúrà rẹ, bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí rẹ, tí ẹ̀mí mímọ́ bá sì ti tọ́ ẹ sọ́nà tètè tẹ̀ lé e. Ó ṣe pàtàkì pé ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Bàbá wa ọ̀run lákòókò tó le koko tí ọjọ́ Ọlọ́run ń yára sún mọ́lé yìí. Nítorí náà, rí i dájú pé o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà.—Jákọ́bù 4:8.

9. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fẹ́ kí orúkọ Jèhófà di mímọ́?

9 Ìfẹ́ tí Jésù ní láti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ wà lára ohun tó ràn án lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fáwọn àdánwò tó dojú kọ. Kódà, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa fi kún àdúrà wọn sí Ọlọ́run pé: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la fẹ́ kí orúkọ Jèhófà di mímọ́ tàbí la fẹ́ kó wà ní mímọ́, ńṣe la óò máa sapá láti yẹra fún ṣíṣe ohunkóhun tó lè kó ẹ̀gàn bá orúkọ rẹ̀. Ìyẹn á jẹ́ ká lè múra sílẹ̀ dáadáa fún ọjọ́ ńlá Jèhófà.

Àwọn Ìyípadà Wo Ló Yẹ Kó O Ṣe?

10. Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣàyẹ̀wò ìgbésí ayé wa?

10 Bọ́jọ́ Jèhófà bá dé lọ́la, ṣé lóòótọ́ lo ti múra sílẹ̀ dè é? Ó yẹ kí gbogbo wa ṣàyẹ̀wò ìgbésí ayé wa lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ká lè mọ̀ bóyá a ní àwọn ìwà tàbí ìṣe tó yẹ ká yí pádà. Nítorí pé ìgbésí ayé àwa ẹ̀dá kúrú gan-an àti pé èèyàn lè kú nígbàkugbà, ńṣe ló yẹ ká jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà máa dára sí i lójoojúmọ́. (Oníwàásù 9:11, 12; Jákọ́bù 4:13-15) Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ohun kan yẹ̀ wò tó yẹ ká fiyè sí nígbèésí ayé wa.

11. Ètò wo lo ṣe nípa Bíbélì kíkà?

11 Ìmọ̀ràn pàtàkì kan tí “ẹrú olóòótọ́” fún wa ni pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́. (Mátíù 24:45) O ò ṣe máa lépa láti ka odindi Ìwé Mímọ́ lọ́dọọdún, kó o sì máa ṣàṣàrò lórí ohun tó o bá kà? Bó o bá ń ka orí mẹ́rin péré lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan, wàá ka gbogbo ẹgbẹ̀fà ó dín mọ́kànlá [1,189] orí Bíbélì tán láàárín ọdún kan. Gbogbo ọba tó bá jẹ ní Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ máa ka Òfin Jèhófà “ní gbogbo ọjọ́ ìgbésí ayé rẹ̀.” Ẹ̀rí fi hàn pé Jóṣúà ṣe ohun tó jọ ọ́. (Diutarónómì 17:14-20; Jóṣúà 1:7, 8) Ẹ ò ri bó ti ṣe pàtàkì tó pé káwọn alàgbà nínú ìjọ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, nítorí èyí á ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kọ́ni láwọn “ẹ̀kọ́ afúnni-nílera”!—Títù 2:1.

12. Kí ló yẹ kí ọjọ́ Jèhófà tó sún mọ́lé gan-an yìí mú kó o máa ṣe?

12 Bí ọjọ́ Jèhófà ṣe sún mọ́lé gan-an yìí yẹ kó sún ọ láti máa lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé kó o sì máa kópa nínú wọn bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Hébérù 10:24, 25) Èyí á jẹ́ kó o lè dẹni tó já fáfá nínú kíkéde Ìjọba Ọlọ́run, kó o máa sapá láti wá àwọn tó fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun, kó o sì máa ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ìṣe 13:48) O sì tún lè ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ láwọn ọ̀nà mìí, irú bíi ríran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́ àti fífún àwọn ọ̀dọ́ níṣìírí. Wàá rí i pé àwọn ìsapá wọ̀nyí á fún ọ láyọ̀ gan-an ni!

Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Àwọn Ẹlòmíì

13. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa tó máa fi hàn bóyá à ń gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀?

13 Níwọ̀n bí ọjọ́ Jèhófà ti sún mọ́lé gan-an, ṣé kò yẹ kó o túbọ̀ sapá láti “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run nínú òdodo tòótọ́ àti ìdúróṣinṣin”? (Éfésù 4:20-24) Bó o ti ń fi ànímọ́ Ọlọ́run hàn, àwọn ẹlòmíì yóò rí i pé ò ń ‘rìn nípa ẹ̀mí Ọlọ́run’ o sì ń fi èso rẹ̀ hàn. (Gálátíà 5:16, 22-25) Ǹjẹ́ o lè tọ́ka sí ohun kan pàtó tí ìwọ àti ìdílé rẹ ti ṣe tó fi hàn pé ẹ ti gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀? (Kólósè 3:9, 10) Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ àwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí ẹni tó má a ń ṣoore fáwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ àtàwọn ẹlòmíì? (Gálátíà 6:10) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ déédéé yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tó máa jẹ́ kó o lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jèhófà.

14. Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn gbàdúrà láti béèré fún ẹ̀mí mímọ́ bó ti ń sapá láti ní ìkóra-ẹni-níjàánu?

14 Tó bá jẹ́ pé o máa ń tètè bínú ńkọ́, tó o sì wá rí i pé ó yẹ kó o túbọ̀ máa kó ara rẹ níjàánu? Ìkóra-ẹni-níjàánu wà lára ànímọ́ tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ní. Nítorí náà, gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ọ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín; ẹ máa bá a nìṣó ní wíwá kiri, ẹ ó sì rí; ẹ máa bá a nìṣó ní kíkànkùn, a ó sì ṣí i fún yín. . . . Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—Lúùkù 11:9-13.

15. Bí ìwọ àti ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ bá ní aáwọ̀, kí ló yẹ kó o ṣe?

15 Ká ní aáwọ̀ wà láàárín ìwọ àti ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́, rí i dájú pé o ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti yanjú ìṣòro náà kí àlàáfíà àti ìṣọ̀kan lè wà nínú ìjọ. (Sáàmù 133:1-3) Fi ìmọ̀ràn Jésù tó wà nínú ìwé Mátíù 5:23, 24 tàbí Mátíù 18:15-17 sílò. Bó o bá ń jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ọ nínú ipò ìbínú tẹ́lẹ̀, tètè ṣàtúnṣe báyìí o! Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó yẹ kó o ṣe ni pé kó o múra tán láti dárí jini. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí ẹ di onínúrere sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ máa dárí ji ara yín fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì yín fàlàlà.”—Éfésù 4:25, 26, 32.

16. Àwọn ọ̀nà wo ló yẹ kí tọkọtaya máa gbà fi àánú hàn sí ara wọn?

16 Ó yẹ kí tọkọtaya máa fi àánú hàn sí ara wọn kí wọ́n sì máa dáríji ara wọn. Nítorí náà, bó o bá fẹ́ túbọ̀ jẹ́ aláàánú sí ọkọ tàbí aya rẹ kó o sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, sa gbogbo ipá rẹ láti jẹ́ kí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ràn ọ́ lọ́wọ́. Ǹjẹ́ ohun kan wà tó yẹ kó o ṣe láti lè fi ìmọ̀ràn 1 Kọ́ríńtì 7:1-5 sílò kó o lè jẹ́ olóòótọ́ sí ẹnì kejì rẹ kí ọkàn rẹ̀ sì balẹ̀? Ó dájú pé apá ibí yìí gan-an ló ti yẹ kí tọkọtaya ní ‘ìyọ́nú,’ ìyẹn ni pé kí wọ́n ní àánú sí ara wọn.

17. Kí ló yẹ kó o ṣe tó o bá dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá?

17 Bó bá jẹ́ pé o ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ńkọ́? Ṣàtúnṣe tó yẹ ní kíá! Rí i dájú pé o wá ìrànwọ́ àwọn alàgbà nínú ìjọ. Ìmọ̀ràn àti àdúrà wọn yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti padà ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. (Jákọ́bù 5:13-16) Ronú pìwàdà kó o sì gbàdúrà sí Jèhófà. Bó o bá kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí ọkàn rẹ á máa dà ọ́ láàmú, wàá sì tún máa dá ara rẹ lẹ́bi. Irú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì nìyẹn, àmọ́ ẹ wo bí ara ti tù ú tó lẹ́yìn tó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún Jèhófà! Dáfídì kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí ìdìtẹ̀ rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀. Aláyọ̀ ni ènìyàn tí Jèhófà kò ka ìṣìnà sí lọ́rùn, ẹni tí ẹ̀tàn kò sì sí nínú ẹ̀mí rẹ̀.” (Sáàmù 32:1-5) Jèhófà máa ń dárí ji àwọn tó dẹ́ṣẹ̀ tí wọ́n sì ronú pìwàdà tọkàntọkàn.—Sáàmù 103:8-14; Òwe 28:13.

Má Ṣe Jẹ́ Apá Kan Ayé

18. Kí ló yẹ kó jẹ́ èrò rẹ nípa ayé yìí?

18 Láìsí àní-àní, ò ń retí ayé tuntun àgbàyanu tí Bàbá wa ọ̀run ṣèlérí. Nígbà náà, kí ni èrò rẹ nípa ayé táwọn èèyàn aláìṣòótọ́ tó ti kẹ̀yìn sí Ọlọ́run kúnnú rẹ̀ yìí? Sátánì tó jẹ́ “olùṣàkóso ayé” kò nípa kankan lórí Jésù Kristi. (Jòhánù 12:31; 14:30) Ó dájú pé ìwọ pẹ̀lù ò ní fẹ́ kí Èṣù àti ayé rẹ̀ nípa lórí rẹ. Nítorí náà fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù sọ́kàn, ó ní: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé.” Ohun tó bọ́gbọ́n mu tó yẹ kéèyàn ṣe nìyẹn, torí pé “ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:15-17.

19. Àwọn ohun wo ni a gba àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni níyànjú láti máa lé?

19 Ṣé ò ń ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ‘pa ara wọn mọ́ láìní èérí kúrò nínú ayé’? (Jákọ́bù 1:27) Sátánì fẹ́ fi ìwọ̀ mú àwọn ọmọ rẹ bí ìgbà téèyan bá fi ìwọ̀ mú ẹja lódò. Oríṣiríṣi ẹgbẹ́ àti ètò làwọn èèyàn dá sílẹ̀ láti mú káwọn ọ̀dọ́ di apá kan ayé Sátánì. Ṣùgbọ́n àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti wà nínú ètò kan ṣoṣo tó máa rẹ́yìn ètò àwọn nǹkan búburú yìí. Nítorí náà, ó yẹ ká gba àwọn ọ̀dọ́ Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n “ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe . . . nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) Àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run ní láti ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti máa lé àwọn ohun táá jẹ́ kí ìgbésí ayé wọn dùn, kó lérè, kó fògo fún Ọlọ́run, èyí yóò sì wá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti múra de ọjọ́ Jèhófà.

Ronú Nípa Ohun Tó Máa Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ọjọ́ Jèhófà

20. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa retí ìyè àìnípẹ̀kun?

20 Tó o bá ń ronú pé ìyè àìnípẹ̀kun ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú, wàá lè màa retí ọjọ́ Jèhófà pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀. (Júúdà 20, 21) Wàá máa retí ìyè ayérayé nínú Párádísè níbi tí wàá ti padà ní irú okun tó o ní nígbà èwe, tí wàá tún ní àkókò tó pọ̀ láti máa fi lé àwọn ohun tó lérè, wàá sì tún mọ ọ̀pọ̀ nǹkan sí i nípa Jèhófà. Nígbà náà, á ṣeé ṣe fún ẹ láti kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run nítorí pé ‘díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà rẹ̀’ la ṣì mọ̀ nísinsìnyí. (Jóòbù 26:14) Ohun tá à ń retí yìí mà múnú ẹni dùn o!

21, 22. Kí làwọn ohun tó o máa gbọ́ látẹnu àwọn tó bá jíǹde, kí nìwọ náà sì máa ṣe fún wọn?

21 Nínú Párádísè, àwọn tó jíǹde yóò ṣàlàyé ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá fún wa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Énọ́kù yóò ṣàlàyé bóun ṣe nígboyà láti polongo iṣẹ́ Jèhófà fún àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run. (Júúdà 14, 15) Ó dájú pé Nóà yóò sọ bí nǹkan ṣe rí nígbà tó ń kan ọkọ̀ áàkì. Ábúráhámù àti Sárà yóò sọ bó ṣe rí lára wọn láti fi ìgbé ayé gbẹdẹmukẹ nílùú Úrì sílẹ̀ tí wọ́n wá ń gbé inú àgọ́. Ronú nípa bí Ẹ́sítérì á ṣe ṣàlàyé kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bó ṣe dúró ti àwọn èèyan rẹ̀ láti mú kí ọ̀tẹ̀ Hámánì já sásán. (Ẹ́sítérì 7:1-6) Fojú inú wo bí Jónà yóò ṣe máa ròyìn nípa ọjọ́ mẹ́ta tó lò níkùn ẹja ńlá àti bí Jòhánù Olùbatisí á ṣe máa sọ ohun tó ń rò nígbà tó ń batisí Jésù. (Lúùkù 3:21, 22; 7:28) Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan alárinrin la máa kọ́!

22 Nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi, o lè láǹfààní láti ran àwọn tó bá jíǹde lọ́wọ́ láti ní “ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.” (Òwe 2:1-6) Ẹ wo bí inú wa ti máa ń dùn tó lónìí láti rí àwọn èèyàn tó gba ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tí wọ́n sì ń fi sílò! Tún wo bí ayọ̀ rẹ á ti pọ̀ tó lọ́jọ́ iwájú nígbà tí Jèhófà bá bù kún ìsapá rẹ láti kọ́ àwọn èèyàn ìgbà láéláé wọ̀nyẹn lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n sì mọyì àwọn ẹ̀kọ́ náà!

23. Kí ló yẹ ká pinnu láti ṣe?

23 Àwọn ìbùkún táwa èèyàn Jèhófà ń gbádùn báyìí kọjá ohun tẹ́dàá aláìpé lè fẹnu sọ. (Sáàmù 40:5) A mọrírì rẹ̀ gan-an bí Ọlọ́run ṣe ń pèsè àwọn ohun tó ń ràn wá lọ́wọ́ nínú ìjọ́sìn rẹ̀. (Aísáyà 48:17, 18) Ipò yóówù ká wà, ẹ jẹ́ ká máa ṣiṣẹ́ ìsìn mímọ́ tọkàntọkàn bá a ti ń dúró de ọjọ́ ńlá Jèhófà.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni “ọjọ́ Jèhófà”?

• Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ de ọjọ́ Jehofa?

• Bí ọjọ́ ńlá Ọlọ́run ti ń sún mọ́lé gan-an, àwọn ìyípadà wo ló yẹ ká ṣe?

• Kí lò ń fojú sọ́nà láti rí lẹ́yìn tí ọjọ́ Jèhófà bá ti kọjá?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Jésù múra sílẹ̀ de àdánwò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àǹfààní ńláǹlà ni yóò jẹ́ láti ran àwọn tó jíǹde lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní ìmọ̀ Jèhófà!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́