ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 38
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà

      • Hẹsikáyà ṣàìsàn, ara rẹ̀ sì yá (1-22)

        • Orin ìdúpẹ́ (10-20)

Àìsáyà 38:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:24
  • +2Ọb 19:20; Ais 1:1
  • +2Ọb 20:1-3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 394

Àìsáyà 38:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 394

Àìsáyà 38:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 13:22; Sm 20:1-3; Heb 6:10
  • +2Kr 31:20, 21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 394

Àìsáyà 38:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọjọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 20:4-6
  • +Owe 15:29; 1Jo 5:14
  • +Sm 39:12; 56:8
  • +Di 32:39; 1Sa 2:6

Àìsáyà 38:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 32:22

Àìsáyà 38:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 20:8-11

Àìsáyà 38:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn àtẹ̀gùn yìí ni wọ́n fi ń ka àkókò bíi ti aago òjìji oòrùn.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 10:12, 13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2007, ojú ìwé 8

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 394-395

Àìsáyà 38:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ewì.”

Àìsáyà 38:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Àìsáyà 38:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 6:5; Onw 9:5

Àìsáyà 38:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 146:4; Onw 8:8
  • +Job 17:1

Àìsáyà 38:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 39:10

Àìsáyà 38:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ẹyẹ òfú.”

  • *

    Ní Héb., “Ṣe onídùúró mi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 102:7
  • +Ais 59:11
  • +Sm 39:7
  • +Sm 39:12; 119:82, 123

Àìsáyà 38:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tìrònútìrònú.”

  • *

    Tàbí “ọkàn mi tó gbọgbẹ́.”

Àìsáyà 38:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ohun tí Ọlọ́run ń ṣe.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 2:6; Job 33:28; Sm 71:20

Àìsáyà 38:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn mi.”

  • *

    Tàbí “mú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi kúrò níwájú rẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 30:3; 86:13; Jon 2:6
  • +Ais 43:25; Mik 7:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Sún Mọ́ Jèhófà, ojú ìwé 264

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2003, ojú ìwé 18

Àìsáyà 38:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ṣìọ́ọ̀lù,” ìyẹn ibojì aráyé. Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 30:9
  • +Sm 6:5; 115:17
  • +Onw 9:5, 10

Àìsáyà 38:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 18:19; Di 4:9; Joṣ 4:21-24

Àìsáyà 38:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 30:11, 12
  • +2Ọb 20:5; Sm 84:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kìíní, ojú ìwé 395-396

Àìsáyà 38:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 20:7

Àìsáyà 38:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 20:8

Àwọn míì

Àìsá. 38:12Kr 32:24
Àìsá. 38:12Ọb 19:20; Ais 1:1
Àìsá. 38:12Ọb 20:1-3
Àìsá. 38:3Ne 13:22; Sm 20:1-3; Heb 6:10
Àìsá. 38:32Kr 31:20, 21
Àìsá. 38:52Ọb 20:4-6
Àìsá. 38:5Owe 15:29; 1Jo 5:14
Àìsá. 38:5Sm 39:12; 56:8
Àìsá. 38:5Di 32:39; 1Sa 2:6
Àìsá. 38:62Kr 32:22
Àìsá. 38:72Ọb 20:8-11
Àìsá. 38:8Joṣ 10:12, 13
Àìsá. 38:11Sm 6:5; Onw 9:5
Àìsá. 38:12Sm 146:4; Onw 8:8
Àìsá. 38:12Job 17:1
Àìsá. 38:13Sm 39:10
Àìsá. 38:14Sm 102:7
Àìsá. 38:14Ais 59:11
Àìsá. 38:14Sm 39:7
Àìsá. 38:14Sm 39:12; 119:82, 123
Àìsá. 38:161Sa 2:6; Job 33:28; Sm 71:20
Àìsá. 38:17Sm 30:3; 86:13; Jon 2:6
Àìsá. 38:17Ais 43:25; Mik 7:18
Àìsá. 38:18Sm 30:9
Àìsá. 38:18Sm 6:5; 115:17
Àìsá. 38:18Onw 9:5, 10
Àìsá. 38:19Jẹ 18:19; Di 4:9; Joṣ 4:21-24
Àìsá. 38:20Sm 30:11, 12
Àìsá. 38:202Ọb 20:5; Sm 84:2
Àìsá. 38:212Ọb 20:7
Àìsá. 38:222Ọb 20:8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Àìsáyà 38:1-22

Àìsáyà

38 Ní àkókò náà, Hẹsikáyà ṣàìsàn dé ojú ikú.+ Wòlíì Àìsáyà+ ọmọ Émọ́ọ̀sì wá bá a, ó sì sọ fún un pé, “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: ‘Sọ ohun tí agbo ilé rẹ máa ṣe fún wọn, torí pé o máa kú; o ò ní yè é.’”+ 2 Ni Hẹsikáyà bá yíjú sí ògiri, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà sí Jèhófà, ó ní: 3 “Mo bẹ̀ ọ́, Jèhófà, jọ̀ọ́ rántí+ bí mo ṣe fi òtítọ́ àti gbogbo ọkàn mi rìn níwájú rẹ,+ ohun tó dáa ní ojú rẹ sì ni mo ṣe.” Hẹsikáyà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀.

4 Jèhófà wá sọ fún Àìsáyà pé: 5 “Pa dà lọ sọ fún Hẹsikáyà pé,+ ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Dáfídì baba ńlá rẹ sọ nìyí: “Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ.+ Mo ti rí omijé rẹ.+ Wò ó, màá fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) kún ọjọ́ ayé* rẹ,+ 6 màá gba ìwọ àti ìlú yìí lọ́wọ́ ọba Ásíríà, màá sì gbèjà ìlú yìí.+ 7 Àmì tí Jèhófà fún ọ nìyí láti mú un dá ọ lójú pé Jèhófà máa mú ọ̀rọ̀ tó sọ ṣẹ:+ 8 Màá mú kí òjìji oòrùn tó ń sọ̀ kalẹ̀ lórí àtẹ̀gùn* Áhásì pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.”’”+ Oòrùn wá pa dà sẹ́yìn ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá lẹ́yìn tó ti kọ́kọ́ lọ síwájú lórí àtẹ̀gùn náà.

9 Ìwé* tí Hẹsikáyà ọba Júdà kọ nígbà tó ń ṣàìsàn, tí ara rẹ̀ sì yá.

10 Mo sọ pé: “Ní àárín ọjọ́ ayé mi,

Mo gbọ́dọ̀ wọnú àwọn ẹnubodè Isà Òkú.*

A máa fi àwọn ọdún mi tó kù dù mí.”

11 Mo sọ pé: “Mi ò ní rí Jáà,* àní Jáà ní ilẹ̀ alààyè.+

Mi ò ní wo aráyé mọ́,

Tí mo bá wà lọ́dọ̀ àwọn tó ń gbé ibi tí gbogbo nǹkan ti dáwọ́ dúró.

12 A ti fa ibùgbé mi tu, a sì ti mú un kúrò lọ́dọ̀ mi+

Bí àgọ́ olùṣọ́ àgùntàn.

Mo ti ká ẹ̀mí mi bíi ti ẹni tó ń hun aṣọ;

Ó gé mi kúrò bí àwọn òwú tó wà lóròó.

Ò ń mú mi wá sí òpin+ láti ojúmọmọ títí di òru.

13 Mo fira mi lọ́kàn balẹ̀ títí di àárọ̀.

Ó ń fọ́ gbogbo egungun mi bíi kìnnìún;

Ò ń mú mi wá sí òpin+ láti ojúmọmọ títí di òru.

14 Mò ń ké ṣíoṣío bí ẹyẹ olófèéèré àti ẹ̀gà;*+

Mò ń ké kúùkúù bí àdàbà.+

Ojú mi ń wo ibi gíga títí ó fi rẹ̀ mí:+

‘Jèhófà, ìdààmú ti bò mí mọ́lẹ̀;

Ràn mí lọ́wọ́!’*+

15 Kí ni kí n sọ?

Ó ti bá mi sọ̀rọ̀, ó sì ti ṣe nǹkan kan.

Màá máa rìn tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀* ní gbogbo ọdún mi

Torí ẹ̀dùn ọkàn tó bá mi.*

16 ‘Jèhófà, àwọn nǹkan yìí* ló ń mú gbogbo èèyàn wà láàyè,

Ìwàláàyè ẹ̀mí mi sì wà nínú wọn.

O máa mú kí n pa dà ní ìlera tó dáa, o sì máa dá ẹ̀mí mi sí.+

17 Wò ó! Dípò àlàáfíà, ìbànújẹ́ ńlá ló bá mi;

Àmọ́ torí ìfẹ́ tí o ní sí mi,*

O pa mí mọ́ kúrò nínú kòtò ìparun.+

O ti ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi sí ẹ̀yìn rẹ.*+

18 Torí pé Isà Òkú* ò lè yìn ọ́ lógo,+

Ikú ò lè yìn ọ́.+

Àwọn tó lọ sínú kòtò kò lè retí ìṣòtítọ́ rẹ.+

19 Alààyè, àní alààyè lè yìn ọ́,

Bí mo ṣe lè yìn ọ́ lónìí.

Bàbá lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ nípa ìṣòtítọ́ rẹ.+

20 Jèhófà, gbà mí,

A sì máa fi àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín kọ àwọn orin mi+

Ní gbogbo ọjọ́ ayé wa ní ilé Jèhófà.’”+

21 Àìsáyà wá sọ pé: “Ẹ mú ìṣù ọ̀pọ̀tọ́ gbígbẹ wá, kí ẹ sì fi sí eéwo náà, kí ara rẹ̀ lè yá.”+ 22 Hẹsikáyà ti béèrè pé: “Àmì wo ni màá fi mọ̀ pé màá lọ sí ilé Jèhófà?”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́