ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Ẹbọ sísun (1-17)

Léfítíkù 1:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 40:34

Léfítíkù 1:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:18-20

Léfítíkù 1:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 15:19, 21; Mal 1:14
  • +2Kọ 9:7

Léfítíkù 1:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 10:11
  • +Heb 9:13, 14

Léfítíkù 1:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:8

Léfítíkù 1:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 6:12

Léfítíkù 1:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀rá tó yí kíndìnrín ká.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 18:23

Léfítíkù 1:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 8:20, 21; Nọ 15:2, 3

Léfítíkù 1:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 4:4
  • +Le 12:6; 22:18-20

Léfítíkù 1:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:16-18; Le 8:18-21; 9:12-14

Léfítíkù 1:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀rá tó yí kíndìnrín ká.”

Léfítíkù 1:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Léfítíkù 1:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 5:7; 12:8; Lk 2:24

Léfítíkù 1:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “eérú ọlọ́ràá,” ìyẹn, eérú tí ọ̀rá tí wọ́n fi rúbọ ti rin.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 27:3; Le 4:11, 12; 6:10

Léfítíkù 1:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Àwọn míì

Léf. 1:1Ẹk 40:34
Léf. 1:2Le 22:18-20
Léf. 1:3Di 15:19, 21; Mal 1:14
Léf. 1:32Kọ 9:7
Léf. 1:5Heb 10:11
Léf. 1:5Heb 9:13, 14
Léf. 1:6Le 7:8
Léf. 1:7Le 6:12
Léf. 1:81Ọb 18:23
Léf. 1:9Jẹ 8:20, 21; Nọ 15:2, 3
Léf. 1:10Jẹ 4:4
Léf. 1:10Le 12:6; 22:18-20
Léf. 1:11Ẹk 29:16-18; Le 8:18-21; 9:12-14
Léf. 1:14Le 5:7; 12:8; Lk 2:24
Léf. 1:16Ẹk 27:3; Le 4:11, 12; 6:10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 1:1-17

Léfítíkù

1 Jèhófà pe Mósè, ó sì bá a sọ̀rọ̀ látinú àgọ́ ìpàdé,+ pé: 2 “Bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* sọ̀rọ̀, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Tí ẹnikẹ́ni nínú yín bá fẹ́ fi ẹran ọ̀sìn ṣe ọrẹ fún Jèhófà, kó mú ọrẹ rẹ̀ wá látinú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran.+

3 “‘Tó bá fẹ́ mú ẹran wá láti fi rú ẹbọ sísun látinú ọ̀wọ́ ẹran, kó jẹ́ akọ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá.+ Tinútinú+ ni kó mú un wá síwájú Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 4 Kó gbé ọwọ́ rẹ̀ lé orí ẹran náà, ọrẹ rẹ̀ yóò sì ní ìtẹ́wọ́gbà, á sì jẹ́ ètùtù fún un.

5 “‘Lẹ́yìn náà, kí wọ́n pa akọ màlúù náà níwájú Jèhófà, àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà,+ yóò sì gbé ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá, wọ́n á wọ́n ọn sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà,+ èyí tó wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 6 Kí wọ́n bó awọ ẹran náà, kí wọ́n sì gé e sí wẹ́wẹ́.+ 7 Kí àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, dá iná sórí pẹpẹ,+ kí wọ́n sì to igi sí iná náà. 8 Kí àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, to àwọn ègé ẹran náà+ sórí igi tó wà lórí iná lórí pẹpẹ, pẹ̀lú orí rẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ líle.* 9 Kí wọ́n fi omi fọ ìfun rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì mú kí gbogbo rẹ̀ rú èéfín lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó ní òórùn dídùn.*+

10 “‘Tó bá fẹ́ mú ẹran wá láti fi rú ẹbọ sísun látinú agbo ẹran,+ lára àwọn ọmọ àgbò tàbí àwọn ewúrẹ́, kó jẹ́ akọ tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá.+ 11 Kí wọ́n pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Jèhófà, kí àwọn ọmọ Áárónì, tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.+ 12 Kó gé e sí wẹ́wẹ́, kó gé orí rẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ líle,* kí àlùfáà sì tò ó sórí igi tó wà lórí iná lórí pẹpẹ. 13 Kó fi omi fọ ìfun àti ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì mú gbogbo rẹ̀ wá, kó sun ún lórí pẹpẹ kó lè rú èéfín. Ẹbọ sísun ni, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó ní òórùn dídùn.*

14 “‘Àmọ́ tó bá jẹ́ pé ẹyẹ ló fẹ́ mú wá láti fi rú ẹbọ sísun sí Jèhófà, kó mú ọrẹ rẹ̀ wá látinú àwọn ẹyẹ oriri tàbí ọmọ ẹyẹlé.+ 15 Kí àlùfáà sì mú un wá síbi pẹpẹ, kó já ọrùn rẹ̀ láìjá a tán, kó sì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, àmọ́ kó ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 16 Kó yọ àpò oúnjẹ ẹyẹ náà, kó tu àwọn ìyẹ́ rẹ̀, kó sì jù wọ́n sẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ lápá ìlà oòrùn, níbi tí eérú*+ wà. 17 Kó là á níbi àwọn ìyẹ́ rẹ̀ láìgé e sí méjì. Lẹ́yìn náà, kí àlùfáà mú kó rú èéfín lórí igi tó wà lórí iná lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, tó ní òórùn dídùn.*

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́