ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 22
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Ìjẹ́mímọ́ àwọn àlùfáà àti jíjẹ àwọn ohun mímọ́ (1-16)

      • Ẹran tó dá ṣáṣá nìkan ló máa rí ìtẹ́wọ́gbà (17-33)

Léfítíkù 22:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò lára.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:38; Nọ 18:32
  • +Le 21:6

Léfítíkù 22:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:20

Léfítíkù 22:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 13:2
  • +Le 15:2
  • +Le 14:2; 15:13
  • +Le 21:1; Nọ 19:11, 22
  • +Le 15:16

Léfítíkù 22:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 11:24, 43
  • +Le 15:7, 19

Léfítíkù 22:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ọkàn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 19:6, 7

Léfítíkù 22:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:11

Léfítíkù 22:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:31; Le 17:15; Di 14:21

Léfítíkù 22:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Àjèjì kankan,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ara ìdílé Áárónì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:33

Léfítíkù 22:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:11

Léfítíkù 22:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fẹ́ àjèjì.”

Léfítíkù 22:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “àjèjì kankan,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ara ìdílé Áárónì.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 10:14; Nọ 18:19

Léfítíkù 22:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 5:15, 16

Léfítíkù 22:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:32

Léfítíkù 22:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 15:14, 16
  • +Le 7:16; Nọ 15:3; Di 12:5, 6

Léfítíkù 22:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 1:3; 22:22

Léfítíkù 22:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 15:19, 21; 17:1; Mal 1:8; Heb 9:14; 1Pe 1:19

Léfítíkù 22:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 3:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    2/2019, ojú ìwé 3

Léfítíkù 22:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ògòdò.”

Léfítíkù 22:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:30

Léfítíkù 22:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:19; Di 22:6

Léfítíkù 22:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:12

Léfítíkù 22:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:15

Léfítíkù 22:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:37; Nọ 15:40; Di 4:40

Léfítíkù 22:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:21; 19:12
  • +Le 10:3
  • +Ẹk 19:5; Le 20:8; 21:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Orukọ Atọrunwa, ojú ìwé 28

Léfítíkù 22:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:7; Le 11:45

Àwọn míì

Léf. 22:2Ẹk 28:38; Nọ 18:32
Léf. 22:2Le 21:6
Léf. 22:3Le 7:20
Léf. 22:4Le 13:2
Léf. 22:4Le 15:2
Léf. 22:4Le 14:2; 15:13
Léf. 22:4Le 21:1; Nọ 19:11, 22
Léf. 22:4Le 15:16
Léf. 22:5Le 11:24, 43
Léf. 22:5Le 15:7, 19
Léf. 22:6Nọ 19:6, 7
Léf. 22:7Nọ 18:11
Léf. 22:8Ẹk 22:31; Le 17:15; Di 14:21
Léf. 22:10Ẹk 29:33
Léf. 22:11Nọ 18:11
Léf. 22:13Le 10:14; Nọ 18:19
Léf. 22:14Le 5:15, 16
Léf. 22:15Nọ 18:32
Léf. 22:18Nọ 15:14, 16
Léf. 22:18Le 7:16; Nọ 15:3; Di 12:5, 6
Léf. 22:19Le 1:3; 22:22
Léf. 22:20Di 15:19, 21; 17:1; Mal 1:8; Heb 9:14; 1Pe 1:19
Léf. 22:21Le 3:1
Léf. 22:27Ẹk 22:30
Léf. 22:28Ẹk 23:19; Di 22:6
Léf. 22:29Le 7:12
Léf. 22:30Le 7:15
Léf. 22:31Le 19:37; Nọ 15:40; Di 4:40
Léf. 22:32Le 18:21; 19:12
Léf. 22:32Le 10:3
Léf. 22:32Ẹk 19:5; Le 20:8; 21:8
Léf. 22:33Ẹk 6:7; Le 11:45
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 22:1-33

Léfítíkù

22 Jèhófà tún sọ fún Mósè pé: 2 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n kíyè sára pẹ̀lú bí wọ́n á ṣe máa ṣe* ohun mímọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n má sì fi àwọn ohun tí wọ́n ń yà sí mímọ́ fún mi+ sọ orúkọ mímọ́+ mi di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà. 3 Sọ fún wọn pé, ‘Jálẹ̀ àwọn ìran yín, èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ yín tó bá ṣì jẹ́ aláìmọ́, tó wá sún mọ́ àwọn ohun mímọ́ tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yà sí mímọ́ fún Jèhófà, kí ẹ pa ẹni* náà kúrò níwájú mi.+ Èmi ni Jèhófà. 4 Ìkankan nínú àwọn ọmọ Áárónì tó bá jẹ́ adẹ́tẹ̀+ tàbí tí nǹkan ń dà lára rẹ̀+ ò gbọ́dọ̀ jẹ nínú àwọn ohun mímọ́ títí ẹni náà yóò fi di mímọ́,+ bẹ́ẹ̀ náà ni ẹnikẹ́ni tó bá fara kan ẹni tí òkú èèyàn* sọ di aláìmọ́+ tàbí ọkùnrin tó ń da àtọ̀+ 5 tàbí ẹni tó bá fara kan ẹ̀dá tó ń gbá yìn-ìn+ tó jẹ́ aláìmọ́ tàbí tó fara kan ẹnì kan tí ohunkóhun mú kó di aláìmọ́, tó sì lè sọ ọ́ di aláìmọ́.+ 6 Ẹni* tó bá fara kan ìkankan nínú ìwọ̀nyí yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di alẹ́, kó má sì jẹ ìkankan nínú àwọn ohun mímọ́, àmọ́ kó fi omi wẹ̀.+ 7 Tí oòrùn bá ti wọ̀, yóò di mímọ́, lẹ́yìn náà, ó lè jẹ nínú àwọn ohun mímọ́, torí oúnjẹ rẹ̀ ni.+ 8 Bákan náà, kò gbọ́dọ̀ jẹ òkú ẹran èyíkéyìí tàbí ohunkóhun tí ẹranko burúkú fà ya, kó sì di aláìmọ́ nípasẹ̀ rẹ̀.+ Èmi ni Jèhófà.

9 “‘Wọ́n gbọ́dọ̀ máa ṣe ojúṣe wọn sí mi, kí wọ́n má bàa tipa bẹ́ẹ̀ ṣẹ̀, kí wọ́n sì kú torí rẹ̀, torí pé wọ́n sọ ọ́ di aláìmọ́. Èmi ni Jèhófà, tó ń sọ wọ́n di mímọ́.

10 “‘Ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí* ohunkóhun tó jẹ́ mímọ́ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.+ Àlejò èyíkéyìí tó wà lọ́dọ̀ àlùfáà tàbí alágbàṣe ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tó jẹ́ mímọ́. 11 Àmọ́ tí àlùfáà bá fi owó rẹ̀ ra ẹnì kan,* ẹni náà lè jẹ nínú rẹ̀. Àwọn ẹrú tí wọ́n bí ní ilé rẹ̀ náà lè jẹ nínú oúnjẹ rẹ̀.+ 12 Tí ọmọbìnrin àlùfáà bá fẹ́ ẹni tí kì í ṣe àlùfáà,* kó má jẹ nínú àwọn ohun mímọ́ tí wọ́n fi ṣe ọrẹ. 13 Àmọ́ tí ọmọbìnrin àlùfáà bá di opó tàbí tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí kò sì ní ọmọ, tó sì pa dà sí ilé bàbá rẹ̀ bí ìgbà tó wà léwe, ó lè jẹ nínú oúnjẹ bàbá rẹ̀;+ àmọ́ ẹni tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i* kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́.

14 “‘Tí ẹnì kan bá ṣèèṣì jẹ ohun mímọ́, kó fi ìdá márùn-ún rẹ̀ kún un, kó sì fún àlùfáà ní ọrẹ mímọ́ náà.+ 15 Torí náà, kí wọ́n má sọ ohun mímọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà di aláìmọ́,+ 16 kí wọ́n sì mú wọn fa ìyà sórí ara wọn torí pé wọ́n jẹ̀bi bí wọ́n ṣe jẹ àwọn ohun mímọ́ wọn; torí èmi ni Jèhófà, ẹni tó ń sọ wọ́n di mímọ́.’”

17 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 18 “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tàbí àjèjì kan ní Ísírẹ́lì bá mú ẹran ẹbọ sísun+ wá fún Jèhófà kó lè fi san ẹ̀jẹ́ rẹ̀ tàbí kó lè fi ṣe ọrẹ àtinúwá,+ 19 akọ ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá+ ni kó mú wá látinú ọ̀wọ́ ẹran, àwọn ọmọ àgbò tàbí àwọn ewúrẹ́ kó lè rí ìtẹ́wọ́gbà. 20 Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú ohunkóhun tó ní àbùkù+ wá, torí kò ní mú kí ẹ rí ìtẹ́wọ́gbà.

21 “‘Tí ẹnì kan bá mú ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ wá fún Jèhófà kó lè fi san ẹ̀jẹ́ tàbí kó lè fi ṣe ọrẹ àtinúwá, ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ni kó mú wá látinú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, kó lè rí ìtẹ́wọ́gbà. Ẹran náà ò gbọ́dọ̀ ní àbùkù kankan. 22 Ẹran tí ẹ fẹ́ fi ṣe ọrẹ ò gbọ́dọ̀ fọ́jú, kò gbọ́dọ̀ kán léegun, kò gbọ́dọ̀ ní ọgbẹ́, èkúrú,* èépá tàbí làpálàpá; ẹ ò gbọ́dọ̀ mú ẹran tó ní èyíkéyìí nínú nǹkan wọ̀nyí wá fún Jèhófà tàbí kí ẹ fi irú rẹ̀ rúbọ lórí pẹpẹ sí Jèhófà. 23 Ẹ lè mú akọ màlúù tàbí àgùntàn tí apá tàbí ẹsẹ̀ rẹ̀ kan kéré jù tàbí tó gùn jù wá, láti fi ṣe ọrẹ àtinúwá, àmọ́ tí ẹ bá mú un wá láti fi san ẹ̀jẹ́, kò ní rí ìtẹ́wọ́gbà. 24 Ẹ má ṣe mú ẹran tí nǹkan ti ṣe kórópọ̀n rẹ̀ wá fún Jèhófà tàbí èyí tí kórópọ̀n rẹ̀ fọ́ tàbí tí wọ́n tẹ̀ lọ́dàá tàbí tí wọ́n gé kórópọ̀n rẹ̀ kúrò, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fi irú àwọn ẹran bẹ́ẹ̀ rúbọ ní ilẹ̀ yín. 25 Ẹ ò gbọ́dọ̀ mú èyíkéyìí nínú àwọn ẹran yìí wá láti ọwọ́ àjèjì láti fi ṣe oúnjẹ Ọlọ́run yín, torí pé wọ́n ní àbùkù, aláàbọ̀ ara sì ni wọ́n. Wọn ò ní rí ìtẹ́wọ́gbà tí ẹ bá mú wọn wá.’”

26 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 27 “Tí màlúù, àgbò tàbí ewúrẹ́ bá bímọ, ọjọ́ méje+ ni kí ọmọ náà fi wà pẹ̀lú ìyá rẹ̀, àmọ́ láti ọjọ́ kẹjọ sókè, tí wọ́n bá fi ṣe ọrẹ, ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, ó máa rí ìtẹ́wọ́gbà. 28 Ẹ ò gbọ́dọ̀ pa akọ màlúù tàbí àgùntàn pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà.+

29 “Tí ẹ bá rú ẹbọ ìdúpẹ́ sí Jèhófà,+ kí ẹ rú ẹbọ náà kí ẹ bàa lè rí ìtẹ́wọ́gbà. 30 Ọjọ́ yẹn ni kí ẹ jẹ ẹ́. Ẹ ò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ ìkankan lára rẹ̀ kù di àárọ̀ ọjọ́ kejì.+ Èmi ni Jèhófà.

31 “Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn.+ Èmi ni Jèhófà. 32 Ẹ ò gbọ́dọ̀ sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́,+ ṣe ni kí ẹ fi hàn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.+ Èmi ni Jèhófà, ẹni tó ń sọ yín di mímọ́,+ 33 ẹni tó mú yín kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì láti jẹ́ kí ẹ mọ̀ pé èmi ni Ọlọ́run.+ Èmi ni Jèhófà.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́