ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Dáníẹ́lì 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Dáníẹ́lì

      • Ìran àgbò àti òbúkọ (1-14)

        • Ìwo kékeré kan gbé ara rẹ̀ ga (9-12)

        • Títí di 2,300 alẹ́ àti àárọ̀ (14)

      • Gébúrẹ́lì túmọ̀ ìran náà (15-27)

        • Àlàyé nípa àgbò àti òbúkọ náà (20, 21)

        • Ọba kan tí ojú rẹ̀ le dìde (23-25)

Dáníẹ́lì 8:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 5:1, 30
  • +Da 7:1, 15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 165

Dáníẹ́lì 8:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Súsà.”

  • *

    Tàbí “ààfin; ibi ààbò.”

  • *

    Tàbí “agbègbè abẹ́ àṣẹ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ne 1:1; Ẹst 2:8
  • +Jẹ 10:22; Ais 11:11; 21:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 165-166

Dáníẹ́lì 8:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 13:17; Jer 51:11; Da 7:5; 8:20
  • +Ẹst 1:1, 3
  • +Ais 44:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 166-167

Dáníẹ́lì 8:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “lábẹ́ agbára rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 45:1; Jer 51:12; Da 5:30, 31

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 167-168

Dáníẹ́lì 8:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ibi tí oòrùn ti ń wọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 2:39; 7:6; 8:21
  • +Da 11:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 168-169

Dáníẹ́lì 8:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 168-169

Dáníẹ́lì 8:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “lábẹ́ agbára rẹ̀.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 168-169

Dáníẹ́lì 8:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 8:22; 11:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ilẹ̀ Dáradára,” ojú ìwé 26-27

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 169-170

Dáníẹ́lì 8:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ibi tí oòrùn ti ń yọ.”

  • *

    Tàbí “Ẹwà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 48:2; Da 11:16, 45

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2007, ojú ìwé 20

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 170-173

Dáníẹ́lì 8:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 170-171, 173-176

Dáníẹ́lì 8:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹbọ ìgbà gbogbo.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 11:31; 12:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 170-171, 175-178, 298

Dáníẹ́lì 8:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹbọ ìgbà gbogbo.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 170-171, 175-176

Dáníẹ́lì 8:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹbọ ìgbà gbogbo.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 12:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 175-176, 177-179

Dáníẹ́lì 8:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2001, ojú ìwé 28

    7/15/1997, ojú ìwé 25-29

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 177-179, 301

Dáníẹ́lì 8:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 8:2
  • +Lk 1:19, 26
  • +Da 9:21, 22

Dáníẹ́lì 8:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 10:14; 12:4, 9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 9/2017, ojú ìwé 2

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 165

Dáníẹ́lì 8:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 10:9, 10

Dáníẹ́lì 8:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 11:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 165

Dáníẹ́lì 8:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:5; 8:3; 11:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2012, ojú ìwé 10-11

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 166

Dáníẹ́lì 8:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:6
  • +Da 8:5; 11:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2012, ojú ìwé 10-11

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 168-169

    Ìmọ̀, ojú ìwé 18

Dáníẹ́lì 8:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 8:8; 11:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2012, ojú ìwé 10-11

    5/15/1993, ojú ìwé 6

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 169-170

    Ìmọ̀, ojú ìwé 18

Dáníẹ́lì 8:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣe dé ibi tí agbára wọn mọ.”

  • *

    Tàbí “tó já fáfá nínú ṣíṣe ohun tó ń rúni lójú.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 170-173

Dáníẹ́lì 8:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “Ó máa runlérùnnà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:25; 8:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    6/15/2012, ojú ìwé 16

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 170-171, 173-176

Dáníẹ́lì 8:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “láìkìlọ̀ fún wọn.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2007, ojú ìwé 20

    11/1/1993, ojú ìwé 21

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 170-171, 176-177, 179, 285

Dáníẹ́lì 8:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “torí ọjọ́ iwájú lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 10:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 171

Dáníẹ́lì 8:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 7:28; 10:16
  • +Da 2:48, 49
  • +Da 8:17

Àwọn míì

Dán. 8:1Da 5:1, 30
Dán. 8:1Da 7:1, 15
Dán. 8:2Ne 1:1; Ẹst 2:8
Dán. 8:2Jẹ 10:22; Ais 11:11; 21:2
Dán. 8:3Ais 13:17; Jer 51:11; Da 7:5; 8:20
Dán. 8:3Ẹst 1:1, 3
Dán. 8:3Ais 44:28
Dán. 8:4Ais 45:1; Jer 51:12; Da 5:30, 31
Dán. 8:5Da 2:39; 7:6; 8:21
Dán. 8:5Da 11:3
Dán. 8:8Da 8:22; 11:4
Dán. 8:9Sm 48:2; Da 11:16, 45
Dán. 8:11Da 11:31; 12:11
Dán. 8:13Da 12:11
Dán. 8:16Da 8:2
Dán. 8:16Lk 1:19, 26
Dán. 8:16Da 9:21, 22
Dán. 8:17Da 10:14; 12:4, 9
Dán. 8:18Da 10:9, 10
Dán. 8:19Da 11:27
Dán. 8:20Da 7:5; 8:3; 11:2
Dán. 8:21Da 7:6
Dán. 8:21Da 8:5; 11:3
Dán. 8:22Da 8:8; 11:4
Dán. 8:24Da 7:25; 8:10
Dán. 8:26Da 10:14
Dán. 8:27Da 7:28; 10:16
Dán. 8:27Da 2:48, 49
Dán. 8:27Da 8:17
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Dáníẹ́lì 8:1-27

Dáníẹ́lì

8 Ní ọdún kẹta àkóso Ọba Bẹliṣásárì,+ èmi Dáníẹ́lì rí ìran kan, lẹ́yìn èyí tí mo kọ́kọ́ rí.+ 2 Mo rí ìran náà, bí mo sì ṣe ń wò ó, mo wà ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá,* tó wà ní ìpínlẹ̀* Élámù;+ mo rí ìran náà, mo sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ipadò Úláì. 3 Nígbà tí mo gbé ojú mi sókè, wò ó! àgbò+ kan dúró níwájú ipadò náà, ó sì ní ìwo méjì.+ Ìwo méjèèjì ga, àmọ́ ọ̀kan ga ju ìkejì lọ, èyí tó ga jù sì jáde wá lẹ́yìn náà.+ 4 Mo rí i tí àgbò náà ń kàn ní ìwọ̀ oòrùn, àríwá àti gúúsù, kò sí ẹran inú igbó kankan tó lè dúró níwájú rẹ̀, kò sì sí ẹni tó lè gbani sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.*+ Ohun tó wù ú ló ń ṣe, ó sì gbé ara rẹ̀ ga.

5 Bí mo ṣe ń wò, mo rí òbúkọ+ kan tó ń bọ̀ láti ìwọ̀ oòrùn,* ó ń kọjá lọ ní gbogbo ayé láìfi ẹsẹ̀ kanlẹ̀. Òbúkọ náà sì ní ìwo kan tó hàn kedere láàárín àwọn ojú rẹ̀.+ 6 Ó ń bọ̀ lọ́dọ̀ àgbò tó ní ìwo méjì náà, tí mo rí tó dúró níwájú ipadò; ó ń sáré bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ìbínú tó le gan-an.

7 Mo rí i tó ń sún mọ́ àgbò náà, ó sì kórìíra rẹ̀ gan-an. Ó lu àgbò náà bolẹ̀, ó ṣẹ́ ìwo rẹ̀ méjèèjì, àgbò náà ò sì lágbára láti dìde sí i. Ó la àgbò náà mọ́lẹ̀, ó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀, kò sì sẹ́ni tó gba àgbò náà lọ́wọ́ rẹ̀.*

8 Òbúkọ náà wá gbé ara rẹ̀ ga kọjá ààlà, àmọ́ gbàrà tó di alágbára, ìwo ńlá náà ṣẹ́; ìwo mẹ́rin tó hàn kedere sì jáde dípò ìwo kan ṣoṣo náà, wọ́n dojú kọ atẹ́gùn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ọ̀run.+

9 Ìwo míì jáde látinú ọ̀kan lára wọn, ìwo kékeré ni, ó sì di ńlá gan-an, sí apá gúúsù, sí apá ìlà oòrùn* àti sí Ìṣelọ́ṣọ̀ọ́.*+ 10 Ó di ńlá débi pé ó dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ ogun ọ̀run lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún, ó sì mú kí àwọn ọmọ ogun kan àti àwọn ìràwọ̀ kan já bọ́ sí ayé, ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. 11 Ó gbéra ga sí Olórí àwọn ọmọ ogun pàápàá, a sì mú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo* kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, a sì wó ibi tó fìdí múlẹ̀ ní ibi mímọ́ rẹ̀ lulẹ̀.+ 12 A fi àwọn ọmọ ogun kan léni lọ́wọ́, pẹ̀lú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo,* torí ẹ̀ṣẹ̀; ó sì ń wó òtítọ́ lulẹ̀ ṣáá, ó gbé ìgbésẹ̀, ó sì ṣàṣeyọrí.

13 Mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ kan ń sọ̀rọ̀, ẹni mímọ́ míì sì sọ fún ẹni tó ń sọ̀rọ̀ pé: “Báwo ni ìran ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà gbogbo* àti ti ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa ìsọdahoro ṣe máa pẹ́ tó,+ láti sọ ibi mímọ́ náà àti àwọn ọmọ ogun náà di ohun tí wọ́n ń tẹ̀ mọ́lẹ̀?” 14 Ó wá sọ fún mi pé: “Títí di ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (2,300) alẹ́ àti àárọ̀; ó dájú pé ibi mímọ́ náà máa pa dà sí bó ṣe yẹ kó wà.”

15 Bí èmi Dáníẹ́lì ṣe ń rí ìran náà, tí mo sì ń wá bó ṣe máa yé mi, ṣàdédé ni mo rí ẹnì kan tó rí bí èèyàn, tó dúró níwájú mi. 16 Mo wá gbọ́ ohùn èèyàn kan láàárín Úláì,+ ó sì ké jáde pé: “Gébúrẹ́lì,+ jẹ́ kí ẹni yẹn lóye ohun tó rí.”+ 17 Torí náà, ó sún mọ́ ibi tí mo dúró sí, àmọ́ nígbà tó dé, ẹ̀rù bà mí débi pé mo dojú bolẹ̀. Ó sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ́ kó yé ọ pé àkókò òpin ni ìran náà wà fún.”+ 18 Àmọ́ bó ṣe ń bá mi sọ̀rọ̀, mo sùn lọ fọnfọn níbi tí mo dojú bolẹ̀ sí. Ó wá fọwọ́ kàn mí, ó sì mú kí n dìde dúró níbi tí mo dúró sí.+ 19 Ó wá sọ pé: “Mo fẹ́ kí o mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ ní apá ìparí ìdálẹ́bi náà, torí àkókò òpin tí a yàn ló wà fún.+

20 “Àgbò oníwo méjì tí o rí dúró fún àwọn ọba Mídíà àti Páṣíà.+ 21 Òbúkọ onírun náà dúró fún ọba ilẹ̀ Gíríìsì;+ ìwo ńlá tó wà láàárín àwọn ojú rẹ̀ sì dúró fún ọba àkọ́kọ́.+ 22 Ní ti ìwo tó ṣẹ́, tí mẹ́rin fi jáde dípò rẹ̀,+ ìjọba mẹ́rin máa dìde láti orílẹ̀-èdè rẹ̀, àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú agbára rẹ̀.

23 “Ní apá ìparí ìjọba wọn, bí ìṣe àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ bá ṣe ń parí,* ọba kan tí ojú rẹ̀ le, tó lóye àwọn ọ̀rọ̀ tó nítumọ̀ púpọ̀,* máa dìde. 24 Ó máa lágbára gan-an, àmọ́ kì í ṣe nípa agbára òun fúnra rẹ̀. Ó máa mú ìparun wá lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀,* ó máa ṣàṣeyọrí, ó sì máa ṣe ohun tó gbéṣẹ́. Ó máa pa àwọn alágbára run àti àwọn tó jẹ́ ẹni mímọ́.+ 25 Nípasẹ̀ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀, ó máa fi ẹ̀tàn ṣàṣeyọrí; ó máa gbéra ga nínú ọkàn rẹ̀; ó sì máa pa ọ̀pọ̀ run ní àkókò ààbò.* Ó tiẹ̀ máa dìde sí Olórí àwọn ọmọ aládé, àmọ́ a máa ṣẹ́ ẹ láìsí ọwọ́ èèyàn.

26 “Òótọ́ ni ohun tí wọ́n sọ nínú ìran náà nípa alẹ́ àti àárọ̀, àmọ́ kí o ṣe ìran náà ní àṣírí, torí ọ̀pọ̀ ọjọ́ sí àkókò yìí* ló ń tọ́ka sí.”+

27 Ní ti èmi, Dáníẹ́lì, okun tán nínú mi, ara mi ò sì yá fún ọjọ́ mélòó kan.+ Mo wá dìde, mo sì ń bá iṣẹ́ ọba lọ;+ àmọ́ ohun tí mo rí jẹ́ kí ara mi kú tipiri, kò sì sẹ́ni tó yé.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́