ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 43
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ògo Jèhófà kún inú tẹ́ńpìlì náà (1-12)

      • Pẹpẹ (13-27)

Ìsíkíẹ́lì 43:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 40:6; 42:15; 44:1

Ìsíkíẹ́lì 43:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 9:3; 11:23
  • +Isk 1:24; Jo 12:28, 29
  • +Ais 6:3; Isk 10:4

Ìsíkíẹ́lì 43:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “ó.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 1:3, 4; 3:23

Ìsíkíẹ́lì 43:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ilé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 10:19; 44:1, 2

Ìsíkíẹ́lì 43:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 40:34; 1Ọb 8:10; Isk 44:4

Ìsíkíẹ́lì 43:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 40:3

Ìsíkíẹ́lì 43:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:1; Jer 3:17; Isk 1:26
  • +1Kr 28:2
  • +Ẹk 29:45; Sm 68:16; 132:14; Joẹ 3:17
  • +Isk 39:7; Sek 13:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2007, ojú ìwé 10

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 397

Ìsíkíẹ́lì 43:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 8:3
  • +Da 9:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 150

Ìsíkíẹ́lì 43:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 37:23, 26; 2Kọ 6:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 150

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2007, ojú ìwé 10

    3/1/1999, ojú ìwé 9, 12-13

    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà, Apá Kejì, ojú ìwé 397

Ìsíkíẹ́lì 43:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “mọ ìwọ̀n rẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 40:4
  • +Isk 16:63

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 147

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    9/2017, ojú ìwé 2

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 162

Ìsíkíẹ́lì 43:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 44:5
  • +Isk 11:19, 20; 36:27

Ìsíkíẹ́lì 43:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 93:5; Isk 40:2; 42:20

Ìsíkíẹ́lì 43:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ń tọ́ka sí ìgbọ̀nwọ́ tó gùn. Wo Àfikún B14.

  • *

    Ìyẹn, nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà 22.2 (ínǹṣì 8.75). Wo Àfikún B14.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 27:1; 2Kr 4:1

Ìsíkíẹ́lì 43:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 27:2; Ifi 9:13

Ìsíkíẹ́lì 43:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 38:1; 2Kr 4:1

Ìsíkíẹ́lì 43:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 40:29; Le 1:5; 8:18-21; Isk 45:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1999, ojú ìwé 19-20

Ìsíkíẹ́lì 43:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 40:46; 44:15; 48:11
  • +Ẹk 29:10; Le 8:14

Ìsíkíẹ́lì 43:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:36, 37; Le 8:15; Heb 9:23

Ìsíkíẹ́lì 43:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:14; Le 8:17; Heb 13:11

Ìsíkíẹ́lì 43:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 2:13

Ìsíkíẹ́lì 43:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ẹran tí ara wọn pé.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:35

Ìsíkíẹ́lì 43:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ìyẹn, ti àwọn èèyàn náà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 9:1
  • +Isk 20:40

Àwọn míì

Ìsík. 43:1Isk 40:6; 42:15; 44:1
Ìsík. 43:2Isk 9:3; 11:23
Ìsík. 43:2Isk 1:24; Jo 12:28, 29
Ìsík. 43:2Ais 6:3; Isk 10:4
Ìsík. 43:3Isk 1:3, 4; 3:23
Ìsík. 43:4Isk 10:19; 44:1, 2
Ìsík. 43:5Ẹk 40:34; 1Ọb 8:10; Isk 44:4
Ìsík. 43:6Isk 40:3
Ìsík. 43:7Ais 6:1; Jer 3:17; Isk 1:26
Ìsík. 43:71Kr 28:2
Ìsík. 43:7Ẹk 29:45; Sm 68:16; 132:14; Joẹ 3:17
Ìsík. 43:7Isk 39:7; Sek 13:2
Ìsík. 43:8Isk 8:3
Ìsík. 43:8Da 9:12
Ìsík. 43:9Isk 37:23, 26; 2Kọ 6:16
Ìsík. 43:10Isk 40:4
Ìsík. 43:10Isk 16:63
Ìsík. 43:11Isk 44:5
Ìsík. 43:11Isk 11:19, 20; 36:27
Ìsík. 43:12Sm 93:5; Isk 40:2; 42:20
Ìsík. 43:13Ẹk 27:1; 2Kr 4:1
Ìsík. 43:15Ẹk 27:2; Ifi 9:13
Ìsík. 43:16Ẹk 38:1; 2Kr 4:1
Ìsík. 43:18Ẹk 40:29; Le 1:5; 8:18-21; Isk 45:19
Ìsík. 43:19Isk 40:46; 44:15; 48:11
Ìsík. 43:19Ẹk 29:10; Le 8:14
Ìsík. 43:20Ẹk 29:36, 37; Le 8:15; Heb 9:23
Ìsík. 43:21Ẹk 29:14; Le 8:17; Heb 13:11
Ìsík. 43:24Le 2:13
Ìsík. 43:25Ẹk 29:35
Ìsík. 43:27Le 9:1
Ìsík. 43:27Isk 20:40
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 43:1-27

Ìsíkíẹ́lì

43 Lẹ́yìn náà, ó mú mi lọ sí ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn.+ 2 Mo rí ògo Ọlọ́run Ísírẹ́lì níbẹ̀ tó ń bọ̀ láti ìlà oòrùn,+ ohùn rẹ̀ sì dà bí ìró omi tó ń rọ́ jáde;+ ògo rẹ̀ sì tan ìmọ́lẹ̀ sí ayé.+ 3 Ohun tí mo rí dà bí ìran tí mo rí nígbà tí mo* wá pa ìlú náà run, ó sì dà bí ohun tí mo rí lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Kébárì;+ mo sì dojú bolẹ̀.

4 Ògo Jèhófà wá gba ẹnubodè tó dojú kọ ìlà oòrùn wọnú tẹ́ńpìlì* náà.+ 5 Ẹ̀mí kan gbé mi sókè, ó mú mi wá sí àgbàlá inú, mo sì rí i pé ògo Jèhófà kún inú tẹ́ńpìlì náà.+ 6 Mo wá gbọ́ tí ẹnì kan ń bá mi sọ̀rọ̀ láti inú tẹ́ńpìlì náà, ọkùnrin náà sì wá dúró sí ẹ̀gbẹ́ mi.+ 7 Ó sọ fún mi pé:

“Ọmọ èèyàn, ibi ìtẹ́ mi+ àti ibi tí màá gbé ẹsẹ̀ mi sí nìyí,+ ibẹ̀ ni èmi yóò máa gbé títí láé láàárín àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.+ Ilé Ísírẹ́lì àti àwọn ọba wọn kò ní fi àgbèrè ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe àti òkú àwọn ọba wọn nígbà tí wọ́n bá kú sọ orúkọ mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin mọ́.+ 8 Wọ́n fi ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe sọ orúkọ mímọ́ mi di ẹlẹ́gbin bí wọ́n ṣe gbé ibi àbáwọlé wọn sí ẹ̀gbẹ́ ibi àbáwọlé mi, tí wọ́n sì gbé férémù ẹnu ọ̀nà wọn sí ẹ̀gbẹ́ férémù ẹnu ọ̀nà mi, ògiri nìkan ló sì wà láàárín èmi àti àwọn.+ Torí náà, inú bí mi, mo sì pa wọ́n run.+ 9 Kí wọ́n gbé àgbèrè ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe àti òkú àwọn ọba wọn jìnnà sí mi, èmi yóò sì máa gbé láàárín wọn títí láé.+

10 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, ṣàlàyé bí tẹ́ńpìlì náà ṣe rí fún ilé Ísírẹ́lì,+ kí ojú lè tì wọ́n torí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,+ kí wọ́n sì ṣàyẹ̀wò àwòrán ìkọ́lé rẹ̀.* 11 Tí ojú bá tì wọ́n torí gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe, jẹ́ kí wọ́n mọ àwòrán ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì náà, fi bí wọ́n ṣe tò ó hàn wọ́n, kí o sì fi àwọn ẹnu ọ̀nà àbájáde àti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé rẹ̀ hàn wọ́n.+ Fi gbogbo àwòrán ìpìlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn ìlànà rẹ̀ hàn wọ́n, fi àwòrán ìpìlẹ̀ rẹ̀ àti àwọn òfin rẹ̀ hàn wọ́n, kí o sì kọ wọ́n sílẹ̀ níṣojú wọn, kí wọ́n lè máa fiyè sí gbogbo àwòrán ìpìlẹ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì máa pa àwọn ìlànà rẹ̀ mọ́.+ 12 Òfin tẹ́ńpìlì náà nìyí. Gbogbo agbègbè tó yí orí òkè náà ká jẹ́ mímọ́ jù lọ.+ Wò ó! Òfin tẹ́ńpìlì náà nìyí.

13 “Ìwọ̀n pẹpẹ náà ní ìgbọ̀nwọ́ nìyí + (wọ́n fi ìbú ọwọ́ kan kún ìgbọ̀nwọ́ kan).* Ìgbọ̀nwọ́ kan ni ìsàlẹ̀ rẹ̀, ó sì fẹ̀ tó ìgbọ̀nwọ́ kan. Igun rẹ̀ ní etí yí ká, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan.* Ìsàlẹ̀ pẹpẹ náà nìyí. 14 Láti ilẹ̀ dé etí ìgbásẹ̀ ìsàlẹ̀ tó yí i ká jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. Láti ìgbásẹ̀ kékeré dé etí ìgbásẹ̀ ńlá jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan. 15 Ibi tí wọ́n ti ń dáná lórí pẹpẹ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin ní gíga, ìwo mẹ́rin sì wà níbi ìdáná náà.+ 16 Ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ibi ìdáná pẹpẹ náà dọ́gba, gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá (12), fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjìlá (12).+ 17 Ìgbásẹ̀ tó yí ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ká jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá (14) ní gígùn, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rìnlá (14); etí rẹ̀ yí ká jẹ́ ààbọ̀ ìgbọ̀nwọ́, ìsàlẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan yí ká.

“Àtẹ̀gùn rẹ̀ dojú kọ ìlà oòrùn.”

18 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Àwọn ìtọ́ni tí wọ́n á máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá ti ṣe pẹpẹ nìyí, kí wọ́n lè máa fi odindi ẹbọ sísun rúbọ lórí rẹ̀, kí wọ́n sì lè máa wọ́n ẹ̀jẹ̀ sórí rẹ̀.’+

19 “‘Kí o fún àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, tí wọ́n jẹ́ ọmọ Sádókù+ ní akọ ọmọ màlúù kan látinú agbo ẹran láti fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀,+ àwọn ló ń wá síwájú mi láti ṣiṣẹ́ fún mi,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 20 ‘Kí o mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, kí o sì fi í sára ìwo pẹpẹ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sára igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìgbásẹ̀ tó yí i ká àti sí etí rẹ̀ yí ká, láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti láti ṣe ètùtù fún un.+ 21 Kí o wá mú akọ ọmọ màlúù náà tó jẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o lè lọ sun ún níbi tí wọ́n ti ṣètò sílẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì náà, ní ìta ibi mímọ́.+ 22 Ní ọjọ́ kejì, wàá fi òbúkọ kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀; wọ́n á sì wẹ pẹpẹ náà mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ bí wọ́n ṣe fi akọ ọmọ màlúù náà wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.’

23 “‘Tí o bá ti wẹ̀ ẹ́ mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ tán, kí o mú akọ ọmọ màlúù kan látinú agbo ẹran, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá àti àgbò kan látinú ọ̀wọ́ ẹran, èyí tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá, kí o sì fi wọ́n rúbọ. 24 Kí o gbé wọn wá síwájú Jèhófà, kí àwọn àlùfáà da iyọ̀ sí wọn lára,+ kí wọ́n sì fi wọ́n rú odindi ẹbọ sísun sí Jèhófà. 25 Ojoojúmọ́ ni wàá máa fi òbúkọ kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ọjọ́ méje,+ bẹ́ẹ̀ náà ni akọ ọmọ màlúù kan látinú agbo ẹran àti àgbò kan látinú ọ̀wọ́ ẹran; àwọn ẹran tí kò ní àbààwọ́n* ni kí o fi rúbọ. 26 Ọjọ́ méje ni kí wọ́n fi ṣe ètùtù pẹpẹ náà, kí wọ́n wẹ̀ ẹ́ mọ́, kí wọ́n sì ṣètò rẹ̀ sílẹ̀. 27 Tí àwọn ọjọ́ náà bá pé, bẹ̀rẹ̀ láti ọjọ́ kẹjọ+ síwájú, àwọn àlùfáà yóò rú àwọn odindi ẹbọ sísun yín* àti àwọn ẹbọ ìrẹ́pọ̀ yín lórí pẹpẹ; inú mi yóò sì dùn sí yín,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́