ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 7
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Ìgbẹ́kẹ̀lé asán nípa tẹ́ńpìlì Jèhófà (1-11)

      • Tẹ́ńpìlì náà yóò dà bíi Ṣílò (12-15)

      • Ọlọ́run kọ ìjọsìn wọn (16-34)

        • Wọ́n jọ́sìn “Ọbabìnrin Ọ̀run” (18)

        • Wọ́n ń fi ọmọ rúbọ ní Hínómù (31)

Jeremáyà 7:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 26:13

Jeremáyà 7:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Wọ́n jẹ́,” ìyẹn gbogbo àwọn ilé tó wà ní tẹ́ńpìlì náà.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mik 3:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2007, ojú ìwé 10

Jeremáyà 7:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 21:12; 22:3

Jeremáyà 7:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn ọmọ aláìníbaba.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 24:17; Sm 82:3; Sek 7:9, 10; Jem 1:27
  • +Di 8:19

Jeremáyà 7:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “láti ayérayé dé ayérayé.”

Jeremáyà 7:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 30:10; Jer 5:31; 14:14

Jeremáyà 7:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “mú ẹbọ rú èéfín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 3:14; Mik 2:2
  • +Jer 5:2
  • +Jer 11:13

Jeremáyà 7:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    3/2017, ojú ìwé 3

Jeremáyà 7:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 21:13; Mk 11:17; Lk 19:45, 46

Jeremáyà 7:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 18:1
  • +Di 12:5, 11
  • +1Sa 4:11; Sm 78:60; Jer 26:6, 9

Jeremáyà 7:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “dìde ní kùtùkùtù láti bá yín sọ̀rọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:15, 16; Jer 25:3, 4
  • +Ais 65:12

Jeremáyà 7:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 25:8, 9
  • +Jer 7:4
  • +1Sa 4:10, 11; Sm 78:60; Jer 26:4, 6; Ida 2:7

Jeremáyà 7:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:22, 23

Jeremáyà 7:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:9, 10; Jer 11:14
  • +Jer 15:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jeremáyà, ojú ìwé 139

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2001, ojú ìwé 30-31

Jeremáyà 7:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Orúkọ oyè abo ọlọ́run tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì apẹ̀yìndà ń jọ́sìn; ó ṣeé ṣe kó jẹ́ abo ọlọ́run ìbímọlémọ.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 44:17
  • +Ais 57:6; Jer 19:13; Isk 20:28

Jeremáyà 7:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ṣẹ̀ sí?”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Da 9:7

Jeremáyà 7:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ida 2:3
  • +2Ọb 22:17; Jer 17:27

Jeremáyà 7:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 1:11; Jer 6:20; Ho 8:13; Emọ 5:21

Jeremáyà 7:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Sa 15:22; Ho 6:6

Jeremáyà 7:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 19:5; Le 26:3, 12
  • +Di 5:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/1999, ojú ìwé 29

Jeremáyà 7:24

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìmọ̀ràn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 32:8
  • +Ho 4:16; Sek 7:12

Jeremáyà 7:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “mò ń jí ní kùtùkùtù lójoojúmọ́, mo sì ń rán wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 9:7; 1Sa 8:8
  • +2Ọb 17:13; 2Kr 36:15; Ne 9:17, 30; Jer 25:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    2/15/1993, ojú ìwé 32

Jeremáyà 7:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “wọ́n mú ọrùn wọn le.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 33:10; Jer 25:3

Jeremáyà 7:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 26:2; Isk 2:7

Jeremáyà 7:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “a ti gé e kúrò ní ẹnu wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 5:1; Mik 7:2

Jeremáyà 7:29

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “irun ìyàsọ́tọ̀.”

  • *

    Tàbí “orin ọ̀fọ̀.”

Jeremáyà 7:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 21:1, 4; 2Kr 33:1, 4; Jer 23:11; 32:34

Jeremáyà 7:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Gẹ̀hẹ́nà.”

  • *

    Tàbí “ohun tí èmi kò ronú rẹ̀ rí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joṣ 15:8, 12
  • +Di 12:29-31; 2Ọb 17:17; 2Kr 28:1, 3; 33:1, 6; Isk 20:31
  • +Le 18:21; 20:3; Jer 19:5, 6; 32:35

Jeremáyà 7:32

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀, “Gẹ̀hẹ́nà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 19:11; Isk 6:4, 5

Jeremáyà 7:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 28:26; Sm 79:2; Jer 16:4

Jeremáyà 7:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 24:8; Jer 25:10
  • +Le 26:33; Ais 1:7; 6:11

Àwọn míì

Jer. 7:3Jer 26:13
Jer. 7:4Mik 3:11
Jer. 7:5Jer 21:12; 22:3
Jer. 7:6Di 24:17; Sm 82:3; Sek 7:9, 10; Jem 1:27
Jer. 7:6Di 8:19
Jer. 7:8Ais 30:10; Jer 5:31; 14:14
Jer. 7:9Ais 3:14; Mik 2:2
Jer. 7:9Jer 5:2
Jer. 7:9Jer 11:13
Jer. 7:11Mt 21:13; Mk 11:17; Lk 19:45, 46
Jer. 7:12Joṣ 18:1
Jer. 7:12Di 12:5, 11
Jer. 7:121Sa 4:11; Sm 78:60; Jer 26:6, 9
Jer. 7:132Kr 36:15, 16; Jer 25:3, 4
Jer. 7:13Ais 65:12
Jer. 7:142Ọb 25:8, 9
Jer. 7:14Jer 7:4
Jer. 7:141Sa 4:10, 11; Sm 78:60; Jer 26:4, 6; Ida 2:7
Jer. 7:152Ọb 17:22, 23
Jer. 7:16Ẹk 32:9, 10; Jer 11:14
Jer. 7:16Jer 15:1
Jer. 7:18Jer 44:17
Jer. 7:18Ais 57:6; Jer 19:13; Isk 20:28
Jer. 7:19Da 9:7
Jer. 7:20Ida 2:3
Jer. 7:202Ọb 22:17; Jer 17:27
Jer. 7:21Ais 1:11; Jer 6:20; Ho 8:13; Emọ 5:21
Jer. 7:221Sa 15:22; Ho 6:6
Jer. 7:23Ẹk 19:5; Le 26:3, 12
Jer. 7:23Di 5:29
Jer. 7:24Ẹk 32:8
Jer. 7:24Ho 4:16; Sek 7:12
Jer. 7:25Di 9:7; 1Sa 8:8
Jer. 7:252Ọb 17:13; 2Kr 36:15; Ne 9:17, 30; Jer 25:4
Jer. 7:262Kr 33:10; Jer 25:3
Jer. 7:27Jer 26:2; Isk 2:7
Jer. 7:28Jer 5:1; Mik 7:2
Jer. 7:302Ọb 21:1, 4; 2Kr 33:1, 4; Jer 23:11; 32:34
Jer. 7:31Joṣ 15:8, 12
Jer. 7:31Di 12:29-31; 2Ọb 17:17; 2Kr 28:1, 3; 33:1, 6; Isk 20:31
Jer. 7:31Le 18:21; 20:3; Jer 19:5, 6; 32:35
Jer. 7:32Jer 19:11; Isk 6:4, 5
Jer. 7:33Di 28:26; Sm 79:2; Jer 16:4
Jer. 7:34Ais 24:8; Jer 25:10
Jer. 7:34Le 26:33; Ais 1:7; 6:11
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 7:1-34

Jeremáyà

7 Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà bá Jeremáyà sọ nìyí, ó ní: 2 “Dúró sí ẹnubodè ilé Jèhófà, kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yìí níbẹ̀ pé, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin èèyàn Júdà tó ń gba àwọn ẹnubodè yìí wọlé láti wá forí balẹ̀ fún Jèhófà. 3 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí: “Ẹ tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe, màá sì jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí.+ 4 Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn tí wọ́n ń sọ pé, ‘Èyí ni* tẹ́ńpìlì Jèhófà, tẹ́ńpìlì Jèhófà, tẹ́ńpìlì Jèhófà!’+ 5 Tí ẹ bá tún ọ̀nà yín àti ìwà yín ṣe lóòótọ́, tó bá sì jẹ́ pé òótọ́ lẹ ṣe ìdájọ́ òdodo láàárín èèyàn kan àti ọmọnìkejì rẹ̀,+ 6 bí ẹ kò bá ni àjèjì lára àti ọmọ aláìlóbìí,* pẹ̀lú àwọn opó,+ tí ẹ kò ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ní ibí yìí, tí ẹ kò sì tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì tó máa yọrí sí ìṣeléṣe yín; + 7 nígbà náà, màá jẹ́ kí ẹ máa gbé ibí yìí, ní ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín títí láé.”’”*

8 “Àmọ́, ẹ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn,+ kò ní ṣe yín láǹfààní kankan. 9 Ṣé ẹ lè máa jalè+ tàbí kí ẹ máa pa èèyàn, kí ẹ máa ṣe àgbèrè tàbí kí ẹ máa búra èké,+ kí ẹ máa rú ẹbọ* sí Báálì,+ kí ẹ sì máa tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì tí ẹ kò mọ̀, 10 kí ẹ wá dúró níwájú mi nínú ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè, kí ẹ sì sọ pé, ‘A ó rí ìgbàlà,’ pẹ̀lú gbogbo ohun ìríra tí ẹ ti ṣe yìí? 11 Ṣé ilé yìí tí a fi orúkọ mi pè ti wá di ihò tí àwọn olè ń fara pa mọ́ sí lójú yín ni?+ Èmi fúnra mi ti rí ohun tí ẹ̀ ń ṣe,” ni Jèhófà wí.

12 “‘Àmọ́, ní báyìí ẹ lọ sí àyè mi ní Ṣílò,+ níbi tí mo mú kí orúkọ mi wà ní ìbẹ̀rẹ̀,+ kí ẹ sì wo ohun tí mo ṣe sí i nítorí ìwà búburú àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì.+ 13 Ṣùgbọ́n ẹ̀ ń ṣe gbogbo nǹkan yìí,’ ni Jèhófà wí, ‘àní bí mo tiẹ̀ bá yín sọ̀rọ̀ léraléra,* ẹ kò fetí sílẹ̀.+ Mo sì ń pè yín ṣáá, ṣùgbọ́n ẹ kò dá mi lóhùn.+ 14 Bí mo ti ṣe sí Ṣílò, bẹ́ẹ̀ ni màá ṣe sí ilé tí a fi orúkọ mi pè,+ èyí tí ẹ gbẹ́kẹ̀ lé+ àti sí ibi tí mo fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín.+ 15 Màá lé yín síta kúrò níwájú mi, bí mo ṣe lé gbogbo àwọn arákùnrin yín síta, gbogbo àwọn ọmọ Éfúrémù.’+

16 “Ní tìrẹ, má ṣe gbàdúrà nítorí àwọn èèyàn yìí. Má ṣe sunkún tàbí kí o gbàdúrà tàbí kí o bẹ̀ mí nítorí wọn,+ torí mi ò ní fetí sí ọ.+ 17 Ṣé o ò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù ni? 18 Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn bàbá ń dá iná, àwọn ìyàwó sì ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà ìrúbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run,*+ wọ́n sì ń da ọrẹ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run míì láti mú mi bínú.+ 19 ‘Àmọ́ ṣé èmi ni wọ́n ń mú bínú?’* ni Jèhófà wí. ‘Ǹjẹ́ kì í ṣe ara wọn ni wọn ń ṣe, tí wọ́n ń dójú ti ara wọn?’+ 20 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí, ‘Wò ó! Ìbínú mi àti ìrunú mi yóò dà sórí ibí yìí,+ sórí èèyàn àti ẹranko, sórí igi oko àti èso ilẹ̀. Ìbínú mi yóò máa jó bí iná tí kò ṣeé pa.’+

21 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Ẹ lọ, kí ẹ fi odindi ẹbọ sísun yín kún àwọn ẹbọ yín yòókù, kí ẹ sì jẹ ẹran rẹ̀.+ 22 Torí láti ọjọ́ tí mo ti mú àwọn baba ńlá yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì, mi ò bá wọn sọ̀rọ̀ tàbí kí n pàṣẹ fún wọn lórí àwọn odindi ẹbọ sísun àti àwọn ẹbọ.+ 23 Ṣùgbọ́n, mo pàṣẹ fún wọn pé: “Ẹ gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, màá sì di Ọlọ́run yín, ẹ ó sì di èèyàn mi.+ Kí ẹ máa rìn ní ọ̀nà tí mo pa láṣẹ fún yín, kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún yín.”’+ 24 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sílẹ̀,+ kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń rìn nínú ètekéte* wọn, wọ́n ya alágídí, wọ́n sì ń ṣe ohun tí ọkàn búburú wọn sọ,+ ńṣe ni wọ́n ń pa dà sẹ́yìn, wọn ò lọ síwájú, 25 láti ọjọ́ tí àwọn baba ńlá yín ti jáde kúrò nílẹ̀ Íjíbítì títí di òní.+ Torí náà, mò ń rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ mi wòlíì sí yín, mò ń rán wọn lójoojúmọ́, mo sì ń rán wọn léraléra.*+ 26 Ṣùgbọ́n wọn kò tẹ́tí sí mi, wọn kò sì fetí sílẹ̀.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ya alágídí,* wọ́n sì ṣe ohun tó burú ju ti àwọn baba ńlá wọn lọ!

27 “Wàá sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún wọn,+ ṣùgbọ́n wọn ò ní fetí sí ọ. Wàá pè wọ́n, ṣùgbọ́n wọn ò ní dá ọ lóhùn. 28 Wàá sì sọ fún wọn pé, ‘Orílẹ̀-èdè tí kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ nìyí, kò sì gba ìbáwí. Kò sí òtítọ́ mọ́, a ò tiẹ̀ gbúròó rẹ̀ láàárín wọn mọ́.’*+

29 “Fá irun gígùn* rẹ, kí o dà á nù, kí o sì kọ orin arò* lórí àwọn òkè, nítorí pé Jèhófà ti kọ ìran àwọn èèyàn tó mú un bínú yìí, yóò sì pa á tì. 30 ‘Nítorí àwọn èèyàn Júdà ti ṣe ohun tó burú ní ojú mi,’ ni Jèhófà wí. ‘Wọ́n ti gbé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn kalẹ̀ sínú ilé tí a fi orúkọ mi pè, láti sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin.+ 31 Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga Tófétì, èyí tó wà ní Àfonífojì Ọmọ Hínómù,*+ láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná,+ ohun tí mi ò pa láṣẹ, tí kò sì wá sí mi lọ́kàn rí.’*+

32 “‘Nítorí náà, wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘tí a kò ní pè é ní Tófétì tàbí Àfonífojì Ọmọ Hínómù mọ́,* àmọ́ Àfonífojì Ìpànìyàn la ó máa pè é. Wọ́n á sin òkú ní Tófétì títí kò fi ní sí àyè mọ́.+ 33 Òkú àwọn èèyàn yìí á di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹranko orí ilẹ̀, láìsí ẹnikẹ́ni tó máa lé wọn dà nù.+ 34 Màá fòpin sí ìró ayọ̀ àti ìró ìdùnnú, ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó+ ní àwọn ìlú Júdà àti ní àwọn ojú ọ̀nà Jerúsálẹ́mù, nítorí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.’”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́