ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìsíkíẹ́lì 44
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Ìsíkíẹ́lì

      • Ẹnubodè ìlà oòrùn yóò wà ní títì pa (1-3)

      • Ìlànà Ọlọ́run nípa àwọn àjèjì (4-9)

      • Ìlànà tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà (10-31)

Ìsíkíẹ́lì 44:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 43:1
  • +Isk 46:1

Ìsíkíẹ́lì 44:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 43:2

Ìsíkíẹ́lì 44:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “gọ̀bì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 12:5, 7
  • +Isk 46:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1999, ojú ìwé 16

Ìsíkíẹ́lì 44:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 6:1-3; Isk 10:4
  • +Isk 1:27, 28; 3:23

Ìsíkíẹ́lì 44:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fọkàn sí i.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 40:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 147

Ìsíkíẹ́lì 44:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dádọ̀dọ́.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 149

Ìsíkíẹ́lì 44:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 22:2; Nọ 18:2, 3

Ìsíkíẹ́lì 44:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “dádọ̀dọ́.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 114

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1999, ojú ìwé 13-14

Ìsíkíẹ́lì 44:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ Hébérù yìí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún “ìgbẹ́,” wọ́n sì máa ń lò ó fún ohun tí wọ́n bá kórìíra.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:8, 9; 2Kr 29:1, 5; Ne 9:34; Jer 23:11; Isk 8:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1999, ojú ìwé 9

Ìsíkíẹ́lì 44:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Kr 26:1

Ìsíkíẹ́lì 44:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 9:16; Mal 2:8

Ìsíkíẹ́lì 44:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:2, 4

Ìsíkíẹ́lì 44:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 2:35; Isk 40:46
  • +Isk 48:9, 11
  • +Le 3:14-16
  • +Le 17:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọsìn Mímọ́, ojú ìwé 150

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1999, ojú ìwé 9

Ìsíkíẹ́lì 44:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 41:21, 22
  • +Nọ 18:7

Ìsíkíẹ́lì 44:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “aṣọ àtàtà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:39, 42; 39:27, 28; Le 16:4

Ìsíkíẹ́lì 44:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:40, 42

Ìsíkíẹ́lì 44:19

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àwọn yàrá mímọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 6:10; Isk 42:14
  • +Isk 42:13

Ìsíkíẹ́lì 44:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 21:1, 5; Di 14:1

Ìsíkíẹ́lì 44:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 10:9

Ìsíkíẹ́lì 44:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 21:7
  • +Le 21:10, 14

Ìsíkíẹ́lì 44:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mal 2:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2007, ojú ìwé 11

    3/1/1999, ojú ìwé 14-15

Ìsíkíẹ́lì 44:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 17:9
  • +1Kr 23:3, 4; 2Kr 19:8
  • +Le 23:2

Ìsíkíẹ́lì 44:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 21:1-3

Ìsíkíẹ́lì 44:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 4:3

Ìsíkíẹ́lì 44:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 18:20; Di 18:1; Joṣ 13:14; Isk 45:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    3/1/1999, ojú ìwé 15

Ìsíkíẹ́lì 44:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 2:3
  • +Le 6:17, 18; 7:1, 6; 1Kọ 9:13
  • +Le 27:21; Nọ 18:14

Ìsíkíẹ́lì 44:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 23:19; Nọ 18:8, 12, 26, 27; Di 18:4
  • +Nọ 15:20; Ne 10:35-37
  • +Owe 3:9, 10; Mal 3:10

Ìsíkíẹ́lì 44:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:31; Le 22:3, 8

Àwọn míì

Ìsík. 44:1Isk 43:1
Ìsík. 44:1Isk 46:1
Ìsík. 44:2Isk 43:2
Ìsík. 44:3Di 12:5, 7
Ìsík. 44:3Isk 46:2
Ìsík. 44:4Ais 6:1-3; Isk 10:4
Ìsík. 44:4Isk 1:27, 28; 3:23
Ìsík. 44:5Isk 40:4
Ìsík. 44:8Le 22:2; Nọ 18:2, 3
Ìsík. 44:102Ọb 23:8, 9; 2Kr 29:1, 5; Ne 9:34; Jer 23:11; Isk 8:5
Ìsík. 44:111Kr 26:1
Ìsík. 44:12Ais 9:16; Mal 2:8
Ìsík. 44:14Nọ 18:2, 4
Ìsík. 44:151Ọb 2:35; Isk 40:46
Ìsík. 44:15Isk 48:9, 11
Ìsík. 44:15Le 3:14-16
Ìsík. 44:15Le 17:6
Ìsík. 44:16Isk 41:21, 22
Ìsík. 44:16Nọ 18:7
Ìsík. 44:17Ẹk 28:39, 42; 39:27, 28; Le 16:4
Ìsík. 44:18Ẹk 28:40, 42
Ìsík. 44:19Le 6:10; Isk 42:14
Ìsík. 44:19Isk 42:13
Ìsík. 44:20Le 21:1, 5; Di 14:1
Ìsík. 44:21Le 10:9
Ìsík. 44:22Le 21:7
Ìsík. 44:22Le 21:10, 14
Ìsík. 44:23Mal 2:7
Ìsík. 44:24Di 17:9
Ìsík. 44:241Kr 23:3, 4; 2Kr 19:8
Ìsík. 44:24Le 23:2
Ìsík. 44:25Le 21:1-3
Ìsík. 44:27Le 4:3
Ìsík. 44:28Nọ 18:20; Di 18:1; Joṣ 13:14; Isk 45:4
Ìsík. 44:29Le 2:3
Ìsík. 44:29Le 6:17, 18; 7:1, 6; 1Kọ 9:13
Ìsík. 44:29Le 27:21; Nọ 18:14
Ìsík. 44:30Ẹk 23:19; Nọ 18:8, 12, 26, 27; Di 18:4
Ìsík. 44:30Nọ 15:20; Ne 10:35-37
Ìsík. 44:30Owe 3:9, 10; Mal 3:10
Ìsík. 44:31Ẹk 22:31; Le 22:3, 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ìsíkíẹ́lì 44:1-31

Ìsíkíẹ́lì

44 Ó mú mi pa dà wá sí ẹnubodè ibi mímọ́ tó wà níta tó dojú kọ ìlà oòrùn,+ ó sì wà ní títì pa.+ 2 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Ẹnubodè yìí yóò wà ní títì pa. Wọn ò ní ṣí i, èèyàn kankan ò sì ní gba ibẹ̀ wọlé; torí Jèhófà, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti gba ibẹ̀ wọlé,+ torí náà, yóò wà ní títì pa. 3 Àmọ́, ìjòyè yóò jókòó síbẹ̀ kó lè jẹ oúnjẹ níwájú Jèhófà,+ torí ìjòyè ni. Yóò gba ibi àbáwọlé* ẹnubodè náà wọlé, ibẹ̀ sì ni yóò gbà jáde.”+

4 Lẹ́yìn náà, ó mú mi gba ẹnubodè àríwá wá sí iwájú tẹ́ńpìlì náà. Nígbà tí mo wò, mo rí i pé ògo Jèhófà kún inú tẹ́ńpìlì Jèhófà.+ Torí náà, mo dojú bolẹ̀.+ 5 Jèhófà wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, fiyè sílẹ̀,* la ojú rẹ sílẹ̀, kí o sì fetí sílẹ̀ dáadáa sí gbogbo ohun tí mo bá sọ fún ọ nípa àwọn ìlànà àti òfin tẹ́ńpìlì Jèhófà. Fiyè sí ẹnu ọ̀nà àbáwọlé tẹ́ńpìlì náà dáadáa àti gbogbo ọ̀nà àbájáde ibi mímọ́.+ 6 Kí o sọ fún ilé Ísírẹ́lì tí wọ́n ya ọlọ̀tẹ̀ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ìwà ìríra tí ẹ̀ ń hù tó gẹ́ẹ́, ilé Ísírẹ́lì. 7 Tí ẹ bá mú àwọn àjèjì tí kò kọlà* ọkàn àti ara wá sínú ibi mímọ́ mi, ṣe ni wọ́n ń sọ tẹ́ńpìlì mi di aláìmọ́. Ẹ̀ ń gbé oúnjẹ, ọ̀rá àti ẹ̀jẹ̀ wá fún mi, àmọ́ torí ìwà ìríra yín, ẹ̀ ń da májẹ̀mú mi. 8 Ẹ ò bójú tó àwọn ohun mímọ́ mi.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ ń yan àwọn ẹlòmíì pé kí wọ́n bójú tó iṣẹ́ nínú ibi mímọ́ mi.”’

9 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Àjèjì kankan tó ń gbé ní Ísírẹ́lì, tí kò kọlà* ọkàn àti ara kò gbọ́dọ̀ wọnú ibi mímọ́ mi.”’

10 “‘Àmọ́ àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n kúrò lẹ́yìn mi+ nígbà tí Ísírẹ́lì fi mí sílẹ̀ kí wọ́n lè tẹ̀ lé àwọn òrìṣà ẹ̀gbin* wọn yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 11 Wọ́n á di ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ mi kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn ẹnubodè tẹ́ńpìlì,+ kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì. Wọn yóò pa ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rú odindi ẹbọ sísun àti ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ torí àwọn èèyàn, wọn yóò sì dúró níwájú àwọn èèyàn náà kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ fún wọn. 12 Torí pé iwájú àwọn òrìṣà ẹ̀gbin wọn ni àwọn ọmọ Léfì náà ti ṣiṣẹ́ fún wọn, tí wọ́n sì di ohun ìkọ̀sẹ̀ tó mú kí ilé Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀,+ ìdí nìyẹn tí mo fi gbé ọwọ́ mi sókè sí wọn tí mo sì búra, wọ́n á sì jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 13 ‘Wọn ò ní wá sọ́dọ̀ mi láti ṣe àlùfáà mi, wọn ò ní sún mọ́ èyíkéyìí nínú àwọn ohun mímọ́ mi tàbí ohun mímọ́ jù lọ, ojú á sì tì wọ́n torí ohun ìríra tí wọ́n ṣe. 14 Àmọ́ èmi yóò mú kí wọ́n máa bójú tó àwọn iṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì, màá mú kí wọ́n máa bójú tó ohun tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ àti gbogbo nǹkan tó yẹ kí wọ́n ṣe nínú rẹ̀.’+

15 “‘Ní ti àwọn ọmọ Léfì tí wọ́n jẹ́ àlùfáà, àwọn ọmọ Sádókù,+ àwọn tó ń bójú tó iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe nínú ibi mímọ́ mi nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi mí sílẹ̀,+ wọn yóò wá sọ́dọ̀ mi kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ fún mi, wọn yóò sì dúró níwájú mi kí wọ́n lè fi ọ̀rá+ àti ẹ̀jẹ̀ rúbọ sí mi,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 16 ‘Àwọn ni yóò wọnú ibi mímọ́ mi, wọ́n á wá síbi tábìlì mi kí wọ́n lè ṣiṣẹ́ fún mi,+ wọ́n á sì bójú tó iṣẹ́ tó yẹ kí wọ́n ṣe fún mi.+

17 “‘Tí wọ́n bá wá sí àwọn ẹnubodè àgbàlá inú, kí wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀.*+ Wọn ò gbọ́dọ̀ wọ aṣọ kankan tí wọ́n fi irun àgùntàn ṣe nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ ní àwọn ẹnubodè àgbàlá inú tàbí tí wọ́n bá wọlé. 18 Kí wọ́n wé láwàní tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe sórí, kí wọ́n sì wọ ṣòkòtò péńpé tí wọ́n fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe tó máa bo ìbàdí wọn.+ Wọn kò gbọ́dọ̀ wọ ohunkóhun tó máa jẹ́ kí wọ́n làágùn. 19 Kí wọ́n tó jáde lọ sí àgbàlá ìta, ní àgbàlá ìta tí àwọn èèyàn wà, kí wọ́n bọ́ aṣọ tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́,+ kí wọ́n sì kó wọn sínú àwọn yàrá ìjẹun mímọ́.*+ Kí wọ́n wá wọ aṣọ míì, kí wọ́n má bàa fi aṣọ wọn sọ àwọn èèyàn di mímọ́. 20 Wọn ò gbọ́dọ̀ fá orí wọn,+ wọn ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí irun orí wọn gùn jù. Kí wọ́n máa gé irun orí wọn lọ sílẹ̀. 21 Àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ mu wáìnì tí wọ́n bá wá sí àgbàlá inú.+ 22 Wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ opó tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀;+ àmọ́ wọ́n lè fẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ wúńdíá tàbí ìyàwó àlùfáà tó ti di opó.’+

23 “‘Kí wọ́n fún àwọn èèyàn mi ní ìtọ́ni nípa ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tó mọ́ àti ohun yẹpẹrẹ; wọ́n á sì kọ́ wọn ní ìyàtọ̀ tó wà láàárín ohun tí kò mọ́ àti ohun tó mọ́.+ 24 Tí ẹjọ́ kan bá wáyé, àwọn ni kí wọ́n ṣe adájọ́;+ ẹjọ́ tí wọ́n bá dá gbọ́dọ̀ bá àwọn ìdájọ́ mi mu.+ Kí wọ́n máa tẹ̀ lé àwọn òfin àti ìlànà mi tó wà fún gbogbo àwọn àjọ̀dún mi,+ kí wọ́n sì máa sọ àwọn sábáàtì mi di mímọ́. 25 Wọn ò gbọ́dọ̀ sún mọ́ òkú èèyàn, torí yóò mú kí wọ́n di aláìmọ́. Àmọ́ wọ́n lè di aláìmọ́ torí bàbá wọn, ìyá wọn, ọmọ wọn ọkùnrin tàbí ọmọ wọn obìnrin, torí arákùnrin wọn tàbí arábìnrin wọn tí kò tíì ní ọkọ.+ 26 Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì ti wẹ àlùfáà kan mọ́, kí wọ́n jẹ́ kó dúró fún ọjọ́ méje. 27 Ní ọjọ́ tó bá wọnú ibi mímọ́, tó wá sí àgbàlá inú láti ṣiṣẹ́ ní ibi mímọ́, kó rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.

28 “‘Èyí ni yóò jẹ́ ogún wọn: Èmi ni ogún wọn.+ Ẹ má ṣe fún wọn ní ohun ìní kankan ní Ísírẹ́lì, torí èmi ni ohun ìní wọn. 29 Àwọn ni yóò máa jẹ ọrẹ ọkà,+ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹbọ ẹ̀bi,+ gbogbo ohun tí wọ́n bá sì yà sọ́tọ̀ ní Ísírẹ́lì yóò di tiwọn.+ 30 Èyí tó dáa jù nínú gbogbo àkọ́so èso àti onírúurú ọrẹ tí ẹ bá mú wá yóò di ti àwọn àlùfáà.+ Kí ẹ fún àlùfáà ní àkọ́so ọkà yín tí ẹ ò lọ̀ kúnná.+ Èyí máa mú kí ìbùkún wà lórí ilé yín.+ 31 Àwọn àlùfáà kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹyẹ tàbí ẹran kankan tó ti kú tàbí èyí tí ẹranko fà ya.’+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́