ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Fífa iṣẹ́ àlùfáà lé Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ (1-36)

Léfítíkù 8:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:1
  • +Ẹk 28:4; 39:33, 41
  • +Ẹk 30:23-25; 40:15
  • +Ẹk 29:1, 2

Léfítíkù 8:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:4; 40:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2014, ojú ìwé 8-9

Léfítíkù 8:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀já ìgbànú.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:39
  • +Ẹk 39:27, 29
  • +Ẹk 39:22
  • +Ẹk 28:6; 39:2
  • +Ẹk 28:8; 29:5; 39:20

Léfítíkù 8:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:15; 39:9
  • +Ẹk 28:30

Léfítíkù 8:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “adé mímọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:6; 39:27, 28
  • +Ẹk 28:36; 39:30

Léfítíkù 8:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 30:26-28

Léfítíkù 8:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:4, 7; 30:30; 40:13; Le 21:10; Sm 133:2

Léfítíkù 8:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fi.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 28:40; 29:8, 9

Léfítíkù 8:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:10-14; Le 4:3, 4; 16:6

Léfítíkù 8:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Heb 9:21, 22

Léfítíkù 8:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 4:8, 9

Léfítíkù 8:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 4:11, 12; 16:27

Léfítíkù 8:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:15-18; Le 1:4

Léfítíkù 8:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọ̀rá tó yí kíndìnrín ká.”

Léfítíkù 8:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Léfítíkù 8:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 8:33
  • +Ẹk 29:19, 20

Léfítíkù 8:23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2014, ojú ìwé 9-10

Léfítíkù 8:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 24:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    11/15/2014, ojú ìwé 9-10

Léfítíkù 8:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:22-25

Léfítíkù 8:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 2:4
  • +Ẹk 29:1, 2

Léfítíkù 8:28

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”

Léfítíkù 8:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 7:29, 30
  • +Ẹk 29:26, 27; Le 7:34, 35

Léfítíkù 8:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 30:30
  • +Nọ 3:2, 3
  • +Ẹk 29:21

Léfítíkù 8:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 6:28
  • +Ẹk 29:31, 32; 1Kọ 9:13

Léfítíkù 8:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:34

Léfítíkù 8:33

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “fi kún ọwọ́ yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:30, 35; Nọ 3:2, 3

Léfítíkù 8:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:36; Le 17:11

Léfítíkù 8:35

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 29:37
  • +Nọ 1:53

Àwọn míì

Léf. 8:2Ẹk 28:1
Léf. 8:2Ẹk 28:4; 39:33, 41
Léf. 8:2Ẹk 30:23-25; 40:15
Léf. 8:2Ẹk 29:1, 2
Léf. 8:6Ẹk 29:4; 40:12
Léf. 8:7Ẹk 28:39
Léf. 8:7Ẹk 39:27, 29
Léf. 8:7Ẹk 39:22
Léf. 8:7Ẹk 28:6; 39:2
Léf. 8:7Ẹk 28:8; 29:5; 39:20
Léf. 8:8Ẹk 28:15; 39:9
Léf. 8:8Ẹk 28:30
Léf. 8:9Ẹk 29:6; 39:27, 28
Léf. 8:9Ẹk 28:36; 39:30
Léf. 8:10Ẹk 30:26-28
Léf. 8:12Ẹk 29:4, 7; 30:30; 40:13; Le 21:10; Sm 133:2
Léf. 8:13Ẹk 28:40; 29:8, 9
Léf. 8:14Ẹk 29:10-14; Le 4:3, 4; 16:6
Léf. 8:15Heb 9:21, 22
Léf. 8:16Le 4:8, 9
Léf. 8:17Le 4:11, 12; 16:27
Léf. 8:18Ẹk 29:15-18; Le 1:4
Léf. 8:22Le 8:33
Léf. 8:22Ẹk 29:19, 20
Léf. 8:24Ẹk 24:6
Léf. 8:25Ẹk 29:22-25
Léf. 8:26Le 2:4
Léf. 8:26Ẹk 29:1, 2
Léf. 8:29Le 7:29, 30
Léf. 8:29Ẹk 29:26, 27; Le 7:34, 35
Léf. 8:30Ẹk 30:30
Léf. 8:30Nọ 3:2, 3
Léf. 8:30Ẹk 29:21
Léf. 8:31Le 6:28
Léf. 8:31Ẹk 29:31, 32; 1Kọ 9:13
Léf. 8:32Ẹk 29:34
Léf. 8:33Ẹk 29:30, 35; Nọ 3:2, 3
Léf. 8:34Ẹk 29:36; Le 17:11
Léf. 8:35Ẹk 29:37
Léf. 8:35Nọ 1:53
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 8:1-36

Léfítíkù

8 Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 2 “Mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀+ pẹ̀lú àwọn aṣọ,+ òróró àfiyanni,+ akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú,+ 3 kí o sì mú kí gbogbo àpéjọ náà kóra jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.”

4 Mósè ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún un gẹ́lẹ́, àpéjọ náà sì kóra jọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 5 Mósè sọ fún àpéjọ àwọn èèyàn náà pé: “Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ pé ká ṣe nìyí.” 6 Mósè wá mú Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sún mọ́ tòsí, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n.+ 7 Lẹ́yìn náà, ó wọ aṣọ+ fún un, ó de ọ̀já+ mọ́ ọn, ó wọ aṣọ àwọ̀lékè tí kò lápá+ fún un, ó wọ éfódì+ fún un, ó sì fi àmùrè éfódì tí wọ́n hun pọ̀*+ dè é mọ́ ọn pinpin. 8 Ó wá wọ aṣọ ìgbàyà+ fún un, ó sì fi Úrímù àti Túmímù+ sí aṣọ ìgbàyà náà. 9 Lẹ́yìn náà, ó wé láwàní+ sí i lórí, ó sì fi irin wúrà pẹlẹbẹ tó ń dán tó jẹ́ àmì mímọ́ ti ìyàsímímọ́*+ sí iwájú láwàní náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.

10 Mósè bá mú òróró àfiyanni, ó sì fòróró yan àgọ́ ìjọsìn àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀,+ ó sì yà wọ́n sí mímọ́. 11 Lẹ́yìn náà, ó wọ́n lára rẹ̀ sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀méje, ó sì fòróró yan pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti bàsíà àti ẹsẹ̀ rẹ̀ láti yà wọ́n sí mímọ́. 12 Níkẹyìn, ó dà lára òróró àfiyanni sórí Áárónì, ó sì fòróró yàn án láti sọ ọ́ di mímọ́.+

13 Mósè mú àwọn ọmọ Áárónì sún mọ́ tòsí, ó wọ aṣọ fún wọn, ó so ọ̀já mọ́ wọn lára, ó sì wé* aṣọ sí wọn lórí,+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún un.

14 Lẹ́yìn náà, ó mú akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá, Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ lé orí akọ màlúù ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀+ náà. 15 Mósè pa á, ó fi ìka rẹ̀ mú ẹ̀jẹ̀ ẹran náà,+ ó fi sára àwọn ìwo tó wà ní gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, ó sì wẹ ẹ̀ṣẹ̀ kúrò lára pẹpẹ náà, àmọ́ ó da ẹ̀jẹ̀ tó kù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ, kó lè yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù lórí rẹ̀. 16 Lẹ́yìn náà, ó mú gbogbo ọ̀rá tó wà lára ìfun, àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, Mósè sì mú kí wọ́n rú èéfín lórí pẹpẹ.+ 17 Ó wá fi iná sun ohun tó ṣẹ́ kù lára akọ màlúù náà, awọ rẹ̀, ẹran rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ẹ̀yìn ibùdó+ bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún un.

18 Ó mú àgbò tó fẹ́ fi rú ẹbọ sísun náà wá sí tòsí, Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ lé orí àgbò náà.+ 19 Lẹ́yìn náà, Mósè pa á, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 20 Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, Mósè sì mú kí orí àgbò náà, àwọn ègé rẹ̀ àti ọ̀rá rẹ̀ líle* rú èéfín. 21 Ó fi omi fọ ìfun àti ẹsẹ̀ rẹ̀, Mósè sì mú kí odindi àgbò náà rú èéfín lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun tó ní òórùn dídùn* ni. Ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ló jẹ́, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè.

22 Lẹ́yìn náà, ó mú àgbò kejì wá, àgbò àfiyanni,+ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbé ọwọ́ lé orí àgbò náà.+ 23 Mósè pa á, ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ó fi sí ìsàlẹ̀ etí ọ̀tún Áárónì àti àtàǹpàkò ọwọ́ rẹ̀ ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ rẹ̀ ọ̀tún. 24 Lẹ́yìn náà, Mósè mú àwọn ọmọ Áárónì wá síwájú, ó sì fi lára ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ etí wọn ọ̀tún àti àtàǹpàkò ọwọ́ wọn ọ̀tún àti àtàǹpàkò ẹsẹ̀ wọn ọ̀tún; àmọ́ Mósè wọ́n ẹ̀jẹ̀ tó kù sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà.+

25 Ó wá mú ọ̀rá rẹ̀, ìrù ọlọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára ìfun, àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, pẹ̀lú ẹsẹ̀ ọ̀tún.+ 26 Ó mú búrẹ́dì aláìwú kan tó rí bí òrùka,+ búrẹ́dì kan tí wọ́n fi òróró sí tó rí bí òrùka+ àti búrẹ́dì pẹlẹbẹ kan látinú apẹ̀rẹ̀ búrẹ́dì aláìwú tó wà níwájú Jèhófà. Ó sì kó wọn sórí àwọn ọ̀rá náà àti ẹsẹ̀ ọ̀tún. 27 Lẹ́yìn náà, ó kó gbogbo rẹ̀ sórí àtẹ́lẹwọ́ Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fì ọrẹ náà síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà. 28 Lẹ́yìn náà, Mósè gbà á lọ́wọ́ wọn, ó sì mú kí wọ́n rú èéfín lórí pẹpẹ lórí ẹbọ sísun. Wọ́n jẹ́ ẹbọ ìyannisípò tó ní òórùn dídùn.* Ọrẹ àfinásun sí Jèhófà ni.

29 Mósè tún mú igẹ̀, ó sì fì í síwá-sẹ́yìn bí ọrẹ fífì níwájú Jèhófà.+ Ó di ìpín Mósè látinú àgbò àfiyanni, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún un.+

30 Mósè mú lára òróró àfiyanni,+ ó sì mú lára ẹ̀jẹ̀ tó wà lórí pẹpẹ, ó wọ́n ọn sára Áárónì àti aṣọ rẹ̀ àti sára àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà pẹ̀lú rẹ̀. Bó ṣe sọ Áárónì àti aṣọ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀+ àti aṣọ wọn+ di mímọ́ nìyẹn.

31 Lẹ́yìn náà, Mósè sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ se+ ẹran náà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, ibẹ̀ sì ni kí ẹ ti jẹ ẹ́ pẹ̀lú búrẹ́dì tó wà nínú apẹ̀rẹ̀ àfiyanni, bí àṣẹ tí mo gbà tó sọ pé, ‘Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ ẹ́.’+ 32 Kí ẹ fi iná sun ẹran àti búrẹ́dì tó bá ṣẹ́ kù.+ 33 Ẹ ò gbọ́dọ̀ jáde ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje, títí ọjọ́ tí wọ́n á fa iṣẹ́ lé yín lọ́wọ́ yóò fi pé, torí ọjọ́ méje ló máa gbà láti sọ yín di àlùfáà.*+ 34 Jèhófà pàṣẹ pé ká ṣe ohun tí a ṣe lónìí láti ṣe ètùtù fún yín.+ 35 Kí ẹ wà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé tọ̀sántòru fún ọjọ́ méje,+ kí ẹ sì ṣe ohun tí Jèhófà ní kí ẹ ṣe,+ kí ẹ má bàa kú; torí àṣẹ tí mo gbà ni.”

36 Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́