-
Léfítíkù 21:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Kí wọ́n jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run wọn,+ kí wọ́n má sì sọ orúkọ Ọlọ́run wọn di aláìmọ́,+ torí àwọn ló ń mú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà wá, oúnjẹ* Ọlọ́run wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́.+ 7 Wọn ò gbọ́dọ̀ fẹ́ aṣẹ́wó,+ obìnrin tí wọ́n ti bá sùn tàbí obìnrin tí ọkọ rẹ̀ kọ̀ sílẹ̀,+ torí àlùfáà jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run rẹ̀. 8 Kí o sọ ọ́ di mímọ́,+ torí òun ló ń gbé oúnjẹ Ọlọ́run rẹ wá. Kó jẹ́ mímọ́ sí ọ, torí èmi Jèhófà, tó ń sọ yín di mímọ́, jẹ́ mímọ́.+
-