ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sáàmù 118
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sáàmù

      • Ó dúpẹ́ nítorí ìṣẹ́gun Jèhófà

        • ‘Mo ké pe Jáà, ó sì dá mi lóhùn’ (5)

        • “Jèhófà wà lẹ́yìn mi” (6, 7)

        • Òkúta tí wọ́n kọ̀ sílẹ̀ yóò di olórí òkúta igun ilé (22)

        • “Ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà” (26)

Sáàmù 118:1

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 19:17

Sáàmù 118:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    “Jáà” ni ìkékúrú Jèhófà.

  • *

    Tàbí “ibi tó láyè fífẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 18:19

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    6/1/1993, ojú ìwé 23-24

Sáàmù 118:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 27:1
  • +Ais 51:12; Ro 8:31; Heb 13:6

Sáàmù 118:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “pẹ̀lú àwọn tó ń ràn mí lọ́wọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:52, 53
  • +Sm 54:7

Sáàmù 118:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 40:4; 146:3, 4; Jer 17:5

Sáàmù 118:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 29:6, 7

Sáàmù 118:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 20:15, 17

Sáàmù 118:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 14:11

Sáàmù 118:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí kó jẹ́, “O.”

Sáàmù 118:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:2; Sm 18:2; Ais 12:2

Sáàmù 118:15

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìṣẹ́gun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 89:13; Ais 63:12

Sáàmù 118:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:6; Ais 40:26

Sáàmù 118:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 6:5; 71:17

Sáàmù 118:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 66:10; 94:12
  • +Sm 16:10

Sáàmù 118:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 26:2; Ifi 22:14

Sáàmù 118:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 24:3, 4

Sáàmù 118:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 116:1

Sáàmù 118:22

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “olórí igun.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 28:16; Lk 20:17; Iṣe 4:11; 1Kọ 3:11; Ef 2:19, 20; 1Pe 2:4-7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    6/2018, ojú ìwé 32

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2017, ojú ìwé 9-10

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 246-247

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2011, ojú ìwé 12-13

    7/15/2000, ojú ìwé 14

    Yiyan, ojú ìwé 55

Sáàmù 118:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Iṣe 5:31
  • +Mk 12:10, 11

Sáàmù 118:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/1/1991, ojú ìwé 17

Sáàmù 118:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2017, ojú ìwé 9

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    1/1/1991, ojú ìwé 17

Sáàmù 118:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 21:7-9; 23:39; Mk 11:7-10; Lk 19:37, 38

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    12/2017, ojú ìwé 9

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 254

Sáàmù 118:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 18:28; 1Pe 2:9
  • +Le 23:34; Sm 42:4
  • +Ẹk 27:2

Sáàmù 118:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 15:2; Ais 25:1

Sáàmù 118:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sm 50:23
  • +Ẹsr 3:11; Sm 118:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    1/15/2002, ojú ìwé 13

Àwọn míì

Sm 118:1Mt 19:17
Sm 118:5Sm 18:19
Sm 118:6Sm 27:1
Sm 118:6Ais 51:12; Ro 8:31; Heb 13:6
Sm 118:7Mt 26:52, 53
Sm 118:7Sm 54:7
Sm 118:8Sm 40:4; 146:3, 4; Jer 17:5
Sm 118:9Isk 29:6, 7
Sm 118:102Kr 20:15, 17
Sm 118:122Kr 14:11
Sm 118:14Ẹk 15:2; Sm 18:2; Ais 12:2
Sm 118:15Sm 89:13; Ais 63:12
Sm 118:16Ẹk 15:6; Ais 40:26
Sm 118:17Sm 6:5; 71:17
Sm 118:18Sm 66:10; 94:12
Sm 118:18Sm 16:10
Sm 118:19Ais 26:2; Ifi 22:14
Sm 118:20Sm 24:3, 4
Sm 118:21Sm 116:1
Sm 118:22Ais 28:16; Lk 20:17; Iṣe 4:11; 1Kọ 3:11; Ef 2:19, 20; 1Pe 2:4-7
Sm 118:23Iṣe 5:31
Sm 118:23Mk 12:10, 11
Sm 118:26Mt 21:7-9; 23:39; Mk 11:7-10; Lk 19:37, 38
Sm 118:27Sm 18:28; 1Pe 2:9
Sm 118:27Le 23:34; Sm 42:4
Sm 118:27Ẹk 27:2
Sm 118:28Ẹk 15:2; Ais 25:1
Sm 118:29Sm 50:23
Sm 118:29Ẹsr 3:11; Sm 118:1
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sáàmù 118:1-29

Sáàmù

118 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà, nítorí ó jẹ́ ẹni rere;+

Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.

 2 Kí Ísírẹ́lì sọ pé:

“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”

 3 Kí àwọn ará ilé Áárónì sọ pé:

“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”

 4 Kí àwọn tó ń bẹ̀rù Jèhófà sọ pé:

“Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.”

 5 Mo ké pe Jáà* nínú wàhálà mi;

Jáà dá mi lóhùn, ó sì mú mi wá síbi ààbò.*+

 6 Jèhófà wà lẹ́yìn mi; mi ò ní bẹ̀rù.+

Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?+

 7 Jèhófà wà lẹ́yìn mi láti ràn mí lọ́wọ́;*+

Màá rí ìṣubú àwọn tó kórìíra mi.+

 8 Ó sàn láti fi Jèhófà ṣe ibi ààbò

Ju láti gbẹ́kẹ̀ lé èèyàn.+

 9 Ó sàn láti fi Jèhófà ṣe ibi ààbò

Ju láti gbẹ́kẹ̀ lé àwọn olórí.+

10 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yí mi ká,

Àmọ́ ní orúkọ Jèhófà,

Mo lé wọn sẹ́yìn.+

11 Wọ́n yí mi ká, bẹ́ẹ̀ ni, wọ́n yí mi ká pátápátá,

Àmọ́ ní orúkọ Jèhófà,

Mo lé wọn sẹ́yìn.

12 Wọ́n yí mi ká bí oyin,

Àmọ́ wọ́n kú kíákíá bí iná ẹ̀gún.

Ní orúkọ Jèhófà,

Mo lé wọn sẹ́yìn.+

13 Wọ́n* fi agbára tì mí kí n lè ṣubú,

Àmọ́ Jèhófà ràn mí lọ́wọ́.

14 Jáà ni ibi ààbò mi àti agbára mi,

Ó sì ti di ìgbàlà mi.+

15 Ìró ayọ̀ àti ti ìgbàlà*

Wà ní àgọ́ àwọn olódodo.

Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń fi agbára rẹ̀ hàn.+

16 Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń ṣẹ́gun;

Ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà ń fi agbára rẹ̀ hàn.+

17 Mi ò ní kú, ṣe ni màá wà láàyè,

Kí n lè máa kéde àwọn iṣẹ́ Jáà.+

18 Jáà bá mi wí gan-an,+

Àmọ́ kò fi mí lé ikú lọ́wọ́.+

19 Ẹ ṣí àwọn ẹnubodè òdodo fún mi;+

Màá wọ inú wọn, màá sì yin Jáà.

20 Ẹnubodè Jèhófà nìyí.

Olódodo yóò gba ibẹ̀ wọlé.+

21 Màá yìn ọ́, nítorí o dá mi lóhùn,+

O sì di ìgbàlà mi.

22 Òkúta tí àwọn kọ́lékọ́lé kọ̀ sílẹ̀

Ti di olórí òkúta igun ilé.*+

23 Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni èyí ti wá;+

Ó jẹ́ ohun ìyanu lójú wa.+

24 Ọjọ́ tí Jèhófà dá nìyí;

Inú wa yóò máa dùn, a ó sì máa yọ̀ nínú rẹ̀.

25 Jèhófà, a bẹ̀ ọ́, jọ̀wọ́ gbà wá!

Jèhófà, jọ̀wọ́ fún wa ní ìṣẹ́gun!

26 Ìbùkún ni fún ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Jèhófà;+

À ń bù kún yín látinú ilé Jèhófà.

27 Jèhófà ni Ọlọ́run;

Ó ń fún wa ní ìmọ́lẹ̀.+

Ẹ já ewé dání, kí ẹ sì dara pọ̀ mọ́ àwọn tó ń kọ́wọ̀ọ́ rìn lọ síbi àjọyọ̀,+

Títí dé ibi àwọn ìwo pẹpẹ.+

28 Ìwọ ni Ọlọ́run mi, màá yìn ọ́;

Ìwọ Ọlọ́run mi, màá gbé ọ ga.+

29 Ẹ fi ọpẹ́ fún Jèhófà,+ nítorí ó jẹ́ ẹni rere;

Ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí láé.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́