Sáàmù
Orin. Orin àwọn ọmọ Kórà.+ Sí olùdarí; lọ́nà ti Máhálátì,* kí a kọ ọ́ ní àkọgbà. Másíkílì* ti Hémánì+ tó jẹ́ Ẹ́síráhì.
4 Wọ́n ti kà mí mọ́ àwọn tó ń lọ sínú kòtò;*+
Mo ti di ẹni tí kò lè ṣe nǹkan kan,*+
5 Tí wọ́n fi sílẹ̀ láàárín àwọn òkú,
Bí ẹni tí wọ́n pa, tó dùbúlẹ̀ sínú sàréè,
Ẹni tí o kò rántí mọ́,
Tí kò sì sí lábẹ́ àbójútó* rẹ mọ́.
6 O ti fi mí sínú kòtò tó jìn jù lọ,
Ní ibi tó ṣókùnkùn, nínú ọ̀gbun ńlá tí kò nísàlẹ̀.
7 Ìrunú rẹ pọ̀ lórí mi,+
O sì fi ìgbì rẹ tó ń pariwo bò mí mọ́lẹ̀. (Sélà)
8 O ti lé àwọn ojúlùmọ̀ mi jìnnà réré sí mi;+
O ti sọ mí di ohun ìríra sí wọn.
Mo ti kó sí pańpẹ́, mi ò sì lè jáde.
9 Ojú mi ti di bàìbàì nítorí ìyà tó ń jẹ mí.+
Mo ké pè ọ́, Jèhófà, láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;+
Ìwọ ni mo tẹ́wọ́ àdúrà sí.
10 Ṣé àwọn òkú lo máa ṣe iṣẹ́ àgbàyanu hàn?
Ṣé àwọn tí ikú ti pa* lè dìde wá yìn ọ́?+ (Sélà)
11 Ṣé a lè kéde ìfẹ́ rẹ tí kì í yẹ̀ nínú sàréè
Tàbí òtítọ́ rẹ ní ibi ìparun?*
12 Ṣé a lè mọ àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ nínú òkùnkùn
Tàbí òdodo rẹ ní ilẹ̀ àwọn ẹni ìgbàgbé?+
14 Jèhófà, kí ló dé tí o fi kọ̀ mí* sílẹ̀?+
Kí ló dé tí o fi gbé ojú rẹ pa mọ́ fún mi?+
15 Láti ìgbà èwe mi
Ni ìyà ti ń jẹ mí, mo sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú;+
Àwọn àjálù tí o jẹ́ kó dé bá mi ti jẹ́ kí n kú sára.
16 Ìbínú rẹ tó ń jó bí iná bò mí mọ́lẹ̀;+
Jìnnìjìnnì láti ọ̀dọ̀ rẹ ti pa mí tán.
17 Wọ́n yí mi ká bí omi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;
Wọ́n gba ibi gbogbo yọ sí mi, wọ́n sì ká mi mọ́.*
18 O ti lé àwọn ọ̀rẹ́ mi àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ mi jìnnà réré sí mi;+
Òkùnkùn ti di alábàákẹ́gbẹ́ mi.