ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Nọ́ńbà 2
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Nọ́ńbà

      • Wọ́n pàgọ́ bí wọ́n ṣe pín àwọn ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta (1-34)

        • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Júdà wà ní apá ìlà oòrùn (3-9)

        • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Rúbẹ́nì wà ní apá gúúsù (10-16)

        • Àgọ́ àwọn ọmọ Léfì wà ní àárín (17)

        • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Éfúrémù wà ní apá ìwọ̀ oòrùn (18-24)

        • Ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Dánì wà ní apá àríwá (25-31)

        • Iye gbogbo ọkùnrin tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ (32-34)

Nọ́ńbà 2:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àmì.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:52

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    8/1/2004, ojú ìwé 24

Nọ́ńbà 2:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 7:12; 10:14; Rut 4:20; Mt 1:4

Nọ́ńbà 2:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:27

Nọ́ńbà 2:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 7:11, 18; 10:15

Nọ́ńbà 2:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:29

Nọ́ńbà 2:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 7:11, 24; 10:16

Nọ́ńbà 2:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:31

Nọ́ńbà 2:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 10:14

Nọ́ńbà 2:10

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:20
  • +Nọ 7:11, 30; 10:18

Nọ́ńbà 2:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:21

Nọ́ńbà 2:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 7:11, 36; 10:19

Nọ́ńbà 2:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:23

Nọ́ńbà 2:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 7:11, 42; 10:20

Nọ́ńbà 2:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:25

Nọ́ńbà 2:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 10:18

Nọ́ńbà 2:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:51
  • +1Kọ 14:33, 40

Nọ́ńbà 2:18

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 7:11, 48; 10:22

Nọ́ńbà 2:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:33

Nọ́ńbà 2:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 48:20
  • +Nọ 7:11, 54; 10:23

Nọ́ńbà 2:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:35

Nọ́ńbà 2:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 7:11, 60; 10:24

Nọ́ńbà 2:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:37

Nọ́ńbà 2:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 10:22

Nọ́ńbà 2:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 7:11, 66; 10:25

Nọ́ńbà 2:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:39

Nọ́ńbà 2:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 7:11, 72; 10:26

Nọ́ńbà 2:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:41

Nọ́ńbà 2:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 7:11, 78; 10:27

Nọ́ńbà 2:30

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:43

Nọ́ńbà 2:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 10:25

Nọ́ńbà 2:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 15:5; Ẹk 38:26; Nọ 1:46; 14:29; 26:51, 64

Nọ́ńbà 2:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 1:47; 26:62, 63
  • +Nọ 3:15

Nọ́ńbà 2:34

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 2:2
  • +Nọ 10:28

Àwọn míì

Nọ́ń. 2:2Nọ 1:52
Nọ́ń. 2:3Nọ 7:12; 10:14; Rut 4:20; Mt 1:4
Nọ́ń. 2:4Nọ 1:27
Nọ́ń. 2:5Nọ 7:11, 18; 10:15
Nọ́ń. 2:6Nọ 1:29
Nọ́ń. 2:7Nọ 7:11, 24; 10:16
Nọ́ń. 2:8Nọ 1:31
Nọ́ń. 2:9Nọ 10:14
Nọ́ń. 2:10Nọ 1:20
Nọ́ń. 2:10Nọ 7:11, 30; 10:18
Nọ́ń. 2:11Nọ 1:21
Nọ́ń. 2:12Nọ 7:11, 36; 10:19
Nọ́ń. 2:13Nọ 1:23
Nọ́ń. 2:14Nọ 7:11, 42; 10:20
Nọ́ń. 2:15Nọ 1:25
Nọ́ń. 2:16Nọ 10:18
Nọ́ń. 2:17Nọ 1:51
Nọ́ń. 2:171Kọ 14:33, 40
Nọ́ń. 2:18Nọ 7:11, 48; 10:22
Nọ́ń. 2:19Nọ 1:33
Nọ́ń. 2:20Jẹ 48:20
Nọ́ń. 2:20Nọ 7:11, 54; 10:23
Nọ́ń. 2:21Nọ 1:35
Nọ́ń. 2:22Nọ 7:11, 60; 10:24
Nọ́ń. 2:23Nọ 1:37
Nọ́ń. 2:24Nọ 10:22
Nọ́ń. 2:25Nọ 7:11, 66; 10:25
Nọ́ń. 2:26Nọ 1:39
Nọ́ń. 2:27Nọ 7:11, 72; 10:26
Nọ́ń. 2:28Nọ 1:41
Nọ́ń. 2:29Nọ 7:11, 78; 10:27
Nọ́ń. 2:30Nọ 1:43
Nọ́ń. 2:31Nọ 10:25
Nọ́ń. 2:32Jẹ 15:5; Ẹk 38:26; Nọ 1:46; 14:29; 26:51, 64
Nọ́ń. 2:33Nọ 1:47; 26:62, 63
Nọ́ń. 2:33Nọ 3:15
Nọ́ń. 2:34Nọ 2:2
Nọ́ń. 2:34Nọ 10:28
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Nọ́ńbà 2:1-34

Nọ́ńbà

2 Jèhófà wá sọ fún Mósè àti Áárónì pé: 2 “Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pàgọ́ síbi tí wọ́n pín àwọn ẹ̀yà wọn sí ní mẹ́ta-mẹ́ta,+ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan pàgọ́ síbi àkọlé* agbo ilé bàbá rẹ̀. Kí àgọ́ wọn dojú kọ àgọ́ ìpàdé, kí wọ́n pàgọ́ yí i ká.

3 “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Júdà pàgọ́ sí ìlà oòrùn, lápá ibi tí oòrùn ti ń yọ, ní àwùjọ-àwùjọ;* Náṣónì+ ọmọ Ámínádábù ni ìjòyè àwọn ọmọ Júdà. 4 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (74,600).+ 5 Kí ẹ̀yà Ísákà pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Nétánélì+ ọmọ Súárì ni ìjòyè àwọn ọmọ Ísákà. 6 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (54,400).+ 7 Kí ẹ̀yà Sébúlúnì wá tẹ̀ lé wọn; Élíábù+ ọmọ Hélónì ni ìjòyè àwọn ọmọ Sébúlúnì. 8 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (57,400).+

9 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Júdà jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (186,400). Àwọn ni kó kọ́kọ́ máa tú àgọ́ wọn ká.+

10 “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Rúbẹ́nì+ wà ní apá gúúsù, ní àwùjọ-àwùjọ;* Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì ni ìjòyè àwọn ọmọ Rúbẹ́nì. 11 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (46,500).+ 12 Kí ẹ̀yà Síméónì pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì ni ìjòyè àwọn ọmọ Síméónì. 13 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (59,300).+ 14 Kí ẹ̀yà Gádì wá tẹ̀ lé wọn; Élíásáfù+ ọmọ Rúẹ́lì ni ìjòyè àwọn ọmọ Gádì. 15 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti àádọ́ta (45,650).+

16 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti àádọ́ta (151,450), àwọn ni kó sì máa tú àgọ́ wọn ká ṣìkejì.+

17 “Nígbà tí ẹ bá ń gbé àgọ́ ìpàdé kúrò,+ àgọ́ àwọn ọmọ Léfì ni kó wà láàárín àwọn àgọ́ yòókù.

“Bí wọ́n bá ṣe pàgọ́ náà ni kí wọ́n ṣe tẹ̀ léra tí wọ́n bá ń rìnrìn àjò,+ kí kálukú wà ní àyè rẹ̀, bí wọ́n ṣe pín ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta.

18 “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Éfúrémù wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, ní àwùjọ-àwùjọ;* Élíṣámà+ ọmọ Ámíhúdù ni ìjòyè àwọn ọmọ Éfúrémù. 19 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (40,500).+ 20 Kí ẹ̀yà Mánásè+ pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Gàmálíẹ́lì+ ọmọ Pédásúrì ni ìjòyè àwọn ọmọ Mánásè. 21 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gbọ̀n ó lé igba (32,200).+ 22 Kí ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì wá tẹ̀ lé wọn; Ábídánì+ ọmọ Gídéónì ni ìjòyè àwọn ọmọ Bẹ́ńjámínì. 23 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (35,400).+

24 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun ibùdó Éfúrémù jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìdínláàádọ́fà ó lé ọgọ́rùn-ún (108,100), àwọn ni kó sì máa tú àgọ́ wọn ká ṣìkẹta.+

25 “Kí ẹ̀yà mẹ́ta ti ibùdó Dánì wà ní apá àríwá, ní àwùjọ-àwùjọ;* Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì ni ìjòyè àwọn ọmọ Dánì. 26 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje (62,700).+ 27 Kí ẹ̀yà Áṣérì pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ wọn; Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì ni ìjòyè àwọn ọmọ Áṣérì. 28 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (41,500).+ 29 Kí ẹ̀yà Náfútálì wá tẹ̀ lé wọn; Áhírà+ ọmọ Énánì ni ìjòyè àwọn ọmọ Náfútálì. 30 Àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (53,400).+

31 “Gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ibùdó Dánì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́jọ ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (157,600). Àwọn ni kó máa tú àgọ́ wọn ká kẹ́yìn,+ bí wọ́n ṣe pín ẹ̀yà wọn ní mẹ́ta-mẹ́ta.”

32 Èyí ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí agbo ilé bàbá wọn; gbogbo àwọn tó wà nínú àwọn ibùdó tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ láti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550).+ 33 Àmọ́ wọn ò forúkọ àwọn ọmọ Léfì sílẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ yòókù, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè. 34 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè. Báyìí ni wọ́n ṣe ń pàgọ́, lọ́nà mẹ́ta-mẹ́ta tí wọ́n pín ẹ̀yà wọn sí,+ tí wọ́n sì máa ń tú àgọ́ wọn ká,+ ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́