ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 25
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jeremáyà

      • Ìdájọ́ Jèhófà lórí àwọn orílẹ̀-èdè (1-38)

        • Àwọn orílẹ̀-èdè máa fi 70 ọdún sin Bábílónì (11)

        • Ife wáìnì ìbínú Ọlọ́run (15)

        • Àjálù láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè (32)

        • Àwọn tí Jèhófà pa (33)

Jeremáyà 25:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 24:1; Jer 36:1; 46:2; Da 1:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ojú ìwé 18-19

Jeremáyà 25:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “sí.”

Jeremáyà 25:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “mò ń dìde ní kùtùkùtù, mo sì ń sọ̀rọ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:2
  • +Jer 7:13; 13:10

Jeremáyà 25:4

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ó ń dìde ní kùtùkùtù, ó sì ń rán wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 29:19

Jeremáyà 25:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 17:13; Ais 55:7; Jer 18:11; 35:15; Isk 18:30; 33:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 19

Jeremáyà 25:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 19

Jeremáyà 25:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 32:21; Ne 9:26

Jeremáyà 25:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 19

Jeremáyà 25:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “Nebukadirésárì,” ọ̀nà míì tí wọ́n ń gbà kọ orúkọ yìí.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 26:25; Ais 5:26; Jer 1:15
  • +Jer 27:6; 43:10
  • +Di 28:49, 50; Jer 5:15; Isk 7:24
  • +Isk 26:7; 29:19; Hab 1:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 19

Jeremáyà 25:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 24:7; Isk 26:13
  • +Jer 7:34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    7/1/2015, ojú ìwé 15

    6/1/2014, ojú ìwé 9

    3/1/1994, ojú ìwé 19-20

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 270

Jeremáyà 25:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Kr 36:20, 21; Da 9:2; Sek 1:12; 7:5

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    10/1/2011, ojú ìwé 26-28

    3/1/1994, ojú ìwé 19-20

    Jeremáyà, ojú ìwé 162

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 270

    “Kí Ijọba Rẹ Dé,” ojú ìwé 138, 188

    “Ete aiyeraiye,” ojú ìwé 128-130

Jeremáyà 25:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fìyà jẹ ọba Bábílónì àti orílẹ̀-èdè yẹn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 30:3; Ẹsr 1:1, 2; Jer 29:10
  • +Ais 47:1; Jer 51:1; Da 5:26, 30
  • +Ais 13:1, 19; 14:4, 23

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 20

Jeremáyà 25:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 20

Jeremáyà 25:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 50:9; 51:27
  • +Ais 14:2; Hab 2:8
  • +Sm 137:8; Jer 50:29; 51:6, 24; Ifi 18:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 20

Jeremáyà 25:15

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 206-207

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 20

Jeremáyà 25:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 51:7; Ida 4:21; Isk 23:32-34; Na 3:7, 11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 206-207

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 20

Jeremáyà 25:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 1:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 20-21

Jeremáyà 25:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 51:17
  • +Jer 24:9

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 20-21

Jeremáyà 25:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 46:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 20-21

Jeremáyà 25:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 47:1
  • +Jer 47:5

Jeremáyà 25:21

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 49:17; Ida 4:21
  • +Jer 48:1
  • +Jer 49:1

Jeremáyà 25:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 27:2, 3; 47:4

Jeremáyà 25:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 49:8
  • +Jer 9:25, 26; 49:32

Jeremáyà 25:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 49:31, 32

Jeremáyà 25:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 49:34
  • +Jer 51:11

Jeremáyà 25:26

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ orúkọ àṣírí tí wọ́n fi ń pe Bábélì (Bábílónì).

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 51:41

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 20-21

Jeremáyà 25:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 63:6; Hab 2:16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 21

Jeremáyà 25:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 21

Jeremáyà 25:29

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ọb 9:7; Jer 7:12, 14; Da 9:18; Ho 12:2; Mik 6:2
  • +Jer 49:12; Ọbd 16

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 21

Jeremáyà 25:30

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 22

Jeremáyà 25:31

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “gbogbo ẹlẹ́ran ara.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Joẹ 3:2

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 22

Jeremáyà 25:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 34:2, 3; Jer 25:17
  • +Sef 3:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 22

Jeremáyà 25:33

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 22

Jeremáyà 25:34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 282-283

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 22-23

Jeremáyà 25:35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 22-23

Jeremáyà 25:36

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 22-23

Jeremáyà 25:37

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 23

Jeremáyà 25:38

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọmọ kìnnìún tó tó ọdẹ ṣe (onígọ̀gọ̀).”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ho 5:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    3/1/1994, ojú ìwé 23

Àwọn míì

Jer. 25:12Ọb 24:1; Jer 36:1; 46:2; Da 1:1
Jer. 25:3Jer 1:2
Jer. 25:3Jer 7:13; 13:10
Jer. 25:4Jer 29:19
Jer. 25:52Ọb 17:13; Ais 55:7; Jer 18:11; 35:15; Isk 18:30; 33:11
Jer. 25:7Di 32:21; Ne 9:26
Jer. 25:9Le 26:25; Ais 5:26; Jer 1:15
Jer. 25:9Jer 27:6; 43:10
Jer. 25:9Di 28:49, 50; Jer 5:15; Isk 7:24
Jer. 25:9Isk 26:7; 29:19; Hab 1:6
Jer. 25:10Ais 24:7; Isk 26:13
Jer. 25:10Jer 7:34
Jer. 25:112Kr 36:20, 21; Da 9:2; Sek 1:12; 7:5
Jer. 25:12Di 30:3; Ẹsr 1:1, 2; Jer 29:10
Jer. 25:12Ais 47:1; Jer 51:1; Da 5:26, 30
Jer. 25:12Ais 13:1, 19; 14:4, 23
Jer. 25:14Jer 50:9; 51:27
Jer. 25:14Ais 14:2; Hab 2:8
Jer. 25:14Sm 137:8; Jer 50:29; 51:6, 24; Ifi 18:6
Jer. 25:16Jer 51:7; Ida 4:21; Isk 23:32-34; Na 3:7, 11
Jer. 25:17Jer 1:10
Jer. 25:18Ais 51:17
Jer. 25:18Jer 24:9
Jer. 25:19Jer 46:2
Jer. 25:20Jer 47:1
Jer. 25:20Jer 47:5
Jer. 25:21Jer 49:17; Ida 4:21
Jer. 25:21Jer 48:1
Jer. 25:21Jer 49:1
Jer. 25:22Jer 27:2, 3; 47:4
Jer. 25:23Jer 49:8
Jer. 25:23Jer 9:25, 26; 49:32
Jer. 25:24Jer 49:31, 32
Jer. 25:25Jer 49:34
Jer. 25:25Jer 51:11
Jer. 25:26Jer 51:41
Jer. 25:27Ais 63:6; Hab 2:16
Jer. 25:291Ọb 9:7; Jer 7:12, 14; Da 9:18; Ho 12:2; Mik 6:2
Jer. 25:29Jer 49:12; Ọbd 16
Jer. 25:31Joẹ 3:2
Jer. 25:32Ais 34:2, 3; Jer 25:17
Jer. 25:32Sef 3:8
Jer. 25:38Ho 5:14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jeremáyà 25:1-38

Jeremáyà

25 Ọ̀rọ̀ tí Jeremáyà gbọ́ nípa gbogbo àwọn èèyàn Júdà ní ọdún kẹrin Jèhóákímù+ ọmọ Jòsáyà, ọba Júdà, ìyẹn ní ọdún kìíní Nebukadinésárì* ọba Bábílónì. 2 Ohun tí wòlíì Jeremáyà sọ nípa* gbogbo àwọn èèyàn Júdà àti gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù nìyí:

3 “Láti ọdún kẹtàlá ìjọba Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì, ọba Júdà, títí di òní yìí, ọdún kẹtàlélógún rèé tí Jèhófà ti ń bá mi sọ̀rọ̀, léraléra ni mo sì ń bá yín sọ̀rọ̀,* ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀.+ 4 Jèhófà sì rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì sí yín, léraléra ló ń rán wọn,* ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dẹ etí yín sílẹ̀ láti gbọ́.+ 5 Wọ́n ń sọ pé, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yí pa dà, kí kálukú yín kúrò nínú ọ̀nà búburú rẹ̀ àti kúrò nínú ìwà ibi rẹ̀,+ kí ẹ lè máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ tí Jèhófà ti fún ẹ̀yin àti àwọn baba ńlá yín tipẹ́tipẹ́. 6 Ẹ má ṣe tẹ̀ lé àwọn ọlọ́run míì, ẹ má sìn wọ́n, ẹ má forí balẹ̀ fún wọn, kí ẹ má sì fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣe ni màá mú àjálù bá yín.’

7 “‘Ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sí mi,’ ni Jèhófà wí. ‘Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe lẹ̀ ń fi iṣẹ́ ọwọ́ yín mú mi bínú, tí èyí sì ń fa àjálù bá yín.’+

8 “Nítorí náà, ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘“Nítorí pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu, 9 Màá ránṣẹ́ pe gbogbo ìdílé tó wà ní àríwá,”+ ni Jèhófà wí, “màá ránṣẹ́ sí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi,+ màá mú wọn wá láti gbéjà ko ilẹ̀ yìí+ àti àwọn tó ń gbé lórí rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí i ká.+ Màá pa wọ́n run pátápátá, màá sì sọ wọ́n di ohun àríbẹ̀rù àti ohun àrísúfèé àti ibi àwókù títí láé. 10 Màá fòpin sí ìró ayọ̀ àti ìró ìdùnnú láàárín wọn,+ màá sì tún fòpin sí ohùn ọkọ ìyàwó àti ohùn ìyàwó,+ ìró ọlọ àti ìmọ́lẹ̀ fìtílà. 11 Gbogbo ilẹ̀ yìí á di àwókù àti ohun àríbẹ̀rù, àwọn orílẹ̀-èdè yìí á sì ní láti fi àádọ́rin (70) ọdún sin ọba Bábílónì.”’+

12 “‘Ṣùgbọ́n tí àádọ́rin (70) ọdún bá pé,+ màá pe ọba Bábílónì àti orílẹ̀-èdè yẹn wá jíhìn* nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,’+ ni Jèhófà wí, ‘màá sì sọ ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà di ahoro títí láé.+ 13 Màá mú gbogbo ọ̀rọ̀ mi ṣẹ sórí ilẹ̀ náà, èyí tí mo ti sọ sí i, ìyẹn gbogbo ohun tó wà nínú ìwé yìí tí Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè. 14 Nítorí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè àti àwọn ọba ńlá+ á sọ wọ́n di ẹrú,+ màá sì san èrè wọn pa dà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti iṣẹ́ ọwọ́ wọn.’”+

15 Nítorí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ fún mi nìyí: “Gba ife wáìnì ìbínú yìí ní ọwọ́ mi, kí o sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí mo bá rán ọ sí mu ún. 16 Wọ́n á mu, wọ́n á ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n, wọ́n á sì máa ṣe bíi wèrè nítorí idà tí màá rán sí àárín wọn.”+

17 Torí náà, mo gba ife náà lọ́wọ́ Jèhófà, mo sì mú kí gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà rán mi sí mu ún:+ 18 bẹ̀rẹ̀ láti Jerúsálẹ́mù àti àwọn ìlú Júdà,+ àwọn ọba rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, láti sọ wọ́n di ahoro, ohun àríbẹ̀rù, ohun àrísúfèé àti ẹni ègún,+ bó ṣe rí lónìí, 19 lẹ́yìn náà, Fáráò ọba Íjíbítì àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ìjòyè rẹ̀ àti gbogbo èèyàn rẹ̀+ 20 àti onírúurú àjèjì tó wà láàárín wọn, gbogbo ọba ilẹ̀ Úsì, gbogbo ọba ilẹ̀ Filísínì+ àti Áṣíkẹ́lónì+ àti Gásà àti Ẹ́kírónì àti àwọn tó ṣẹ́ kù ní Áṣídódì, 21 Édómù,+ Móábù+ àti àwọn ọmọ Ámónì,+ 22 gbogbo ọba Tírè, gbogbo ọba Sídónì+ àti àwọn ọba erékùṣù tó wà ní ẹ̀gbẹ́ òkun, 23 Dédánì,+ Témà, Búsì àti gbogbo àwọn tí wọ́n gé irun wọn mọ́lẹ̀ ní ẹ̀bátí,+ 24 gbogbo ọba àwọn ará Arébíà+ àti gbogbo ọba onírúurú àjèjì tó ń gbé ní aginjù, 25 gbogbo ọba Símírì, gbogbo ọba Élámù+ àti gbogbo ọba àwọn ará Mídíà,+ 26 àti gbogbo ọba àríwá, ti tòsí àti ti ọ̀nà jíjìn, ọ̀kan tẹ̀ lé èkejì àti gbogbo ìjọba yòókù tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ọba Ṣéṣákì*+ pẹ̀lú á mu wáìnì náà lẹ́yìn wọn.

27 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, sọ nìyí: “Ẹ mu, kí ẹ sì yó, ẹ bì, kí ẹ sì ṣubú, tí ẹ kò fi ní lè dìde+ nítorí idà tí màá rán sáàárín yín.”’ 28 Bí wọn ò bá sì gba ife náà lọ́wọ́ rẹ láti mu ún, kí o sọ fún wọn pé, ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Ẹ gbọ́dọ̀ mu ún! 29 Nítorí tó bá jẹ́ pé ìlú tí à ń fi orúkọ mi+ pè ni màá kọ́kọ́ mú àjálù bá, ṣé ẹ̀yin á wá lọ láìjìyà ni?”’+

“‘Ẹ ò ní lọ láìjìyà, nítorí màá pe idà wá bá gbogbo àwọn tó ń gbé láyé,’ ni Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun wí.

30 “Sọ àsọtẹ́lẹ̀ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí fún wọn, kí o sì sọ fún wọn pé,

‘Láti ibi gíga ni Jèhófà á ti bú ramúramù

Àti láti ibùgbé rẹ̀ mímọ́ ni á ti mú kí a gbọ́ ohùn rẹ̀.

Á bú ramúramù mọ́ ibi gbígbé rẹ̀.

Á hó yèè bíi ti àwọn tó ń tẹ àjàrà níbi tí wọ́n ti ń fún wáìnì,

Á sì máa kọrin ìṣẹ́gun lórí gbogbo àwọn tó ń gbé láyé.’

31 ‘Ariwo kan á dún títí dé ìkángun ayé,

Nítorí Jèhófà ní ẹjọ́ kan pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè.

Òun fúnra rẹ̀ á ṣe ìdájọ́ gbogbo àwọn èèyàn.*+

Á sì fi idà pa àwọn ẹni burúkú,’ ni Jèhófà wí.

32 Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí:

‘Wò ó! Àjálù kan ń ṣẹlẹ̀ kiri láti orílẹ̀-èdè dé orílẹ̀-èdè,+

A ó sì tú ìjì líle jáde láti ibi tó jìnnà jù lọ láyé.+

33 “‘Àwọn tí Jèhófà máa pa ní ọjọ́ yẹn máa pọ̀ láti ìkángun kan ayé títí dé ìkángun kejì. A ò ní ṣọ̀fọ̀ wọn, a ò ní kó wọn jọ, bẹ́ẹ̀ ni a ò ní sin wọ́n. Wọ́n á dà bí ajílẹ̀ lórí ilẹ̀.’

34 Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin olùṣọ́ àgùntàn, kí ẹ sì ké!

Ẹ yíràá, ẹ̀yin ọlọ́lá inú agbo ẹran,

Nítorí ọjọ́ tí wọ́n á pa yín, tí wọ́n á sì tú yín ká ti pé,

Ẹ ó sì bọ́ lulẹ̀ bí ìgbà tí ohun èlò tó ṣeyebíye bá bọ́ lulẹ̀!

35 Àwọn olùṣọ́ àgùntàn kò rí ibì kankan sá sí,

Kò sì sí ọ̀nà láti sá àsálà fún àwọn ọlọ́lá inú agbo ẹran.

36 Ẹ fetí sílẹ̀! Ẹ gbọ́ igbe àwọn olùṣọ́ àgùntàn

Àti ìpohùnréré ẹkún àwọn ọlọ́lá inú agbo ẹran,

Nítorí Jèhófà ń ba ibi ìjẹko wọn jẹ́.

37 Ibi gbígbé tó ní àlàáfíà sì ti di aláìlẹ́mìí

Nítorí ìbínú Jèhófà tó ń jó fòfò.

38 Ó ti fi ibùgbé rẹ̀ sílẹ̀ bí ọmọ kìnnìún,*+

Torí ilẹ̀ wọn ti di ohun àríbẹ̀rù

Nítorí idà tó ń hanni léèmọ̀

Àti nítorí ìbínú rẹ̀ tó ń jó fòfò.”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́